Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yóò Wà Títí Láé

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yóò Wà Títí Láé

“Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”​—AÍSÁ. 40:8.

ORIN: 116, 115

1, 2. (a) Báwo ni ìgbésí ayé ì bá ṣe rí ká ní kò sí Bíbélì? (b) Kí láá mú ká túbọ̀ jàǹfààní nínú Bíbélì kíkà?

BÁWO ni ìgbésí ayé rẹ ì bá ṣe rí ká ní kò sí Bíbélì? Kò ní sí ìtọ́sọ́nà kankan tí wàá máa tẹ̀ lé. O ò ní rí àlàyé èyíkéyìí nípa Ọlọ́run, nípa bó ṣe yẹ kó o máa gbé ìgbé ayé rẹ àti nípa ọjọ́ iwájú. Bákan náà, kò sí bó o ṣe máa mọ ohun tí Jèhófà ti ṣe fún aráyé nígbà àtijọ́.

2 A dúpẹ́ pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí torí pé Jèhófà fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún jẹ́ kó dá wa lójú pé títí láé ni Ọ̀rọ̀ òun máa wà. Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pétérù fa ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 40:8 yọ. Ẹsẹ yìí lè tọ́ka sí Bíbélì bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe Bíbélì lódindi ni Pétérù ní lọ́kàn. (Ka 1 Pétérù 1:24, 25.) Ó ṣe kedere nígbà náà pé àá túbọ̀ jàǹfààní tá a bá ń ka Bíbélì lédè tá a lóye dáadáa. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Abájọ tó fi jẹ́ pé láti ọ̀pọ̀ ọdún wá làwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì sáwọn èdè míì, kí wọ́n sì pín in kiri. Ohun tí wọ́n fẹ́ ni pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe, ìyẹn ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”​—1 Tím. 2:3, 4.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe la  àwọn nǹkan yìí já: (1) Èdè tó ń yí pa dà, (2) ìyípadà nínú agbo òṣèlú tó ń mú kí èdè àjùmọ̀lò yí pa dà àti (3) àwọn tó tako iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì. Àǹfààní wo la máa rí nínú ìjíròrò yìí? Á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bákan náà, á jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó fún wa ní Bíbélì ká lè jàǹfààní nínú rẹ̀.​—Míkà 4:2; Róòmù 15:4.

BÍ ÈDÈ ṢE Ń YÍ PA DÀ

4. (a) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí èdè bọ́dún ṣe ń gorí ọdún? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn dọ́gba-dọ́gba, báwo nìyẹn sì ṣe rí lára rẹ?

4 Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún ni èdè ń yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀rọ̀ kan táwọn èèyàn ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ ti nítumọ̀ míì lónìí. Ó ṣeé ṣe kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ sí èdè tìẹ náà. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí èdè Hébérù àti Gíríìkì tí wọ́n fi kọ èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìwé Bíbélì. Èdè Hébérù àti Gíríìkì táwọn èèyàn ń sọ nísinsìnyí yàtọ̀ pátápátá sí èyí tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Ó ṣe kedere nígbà náà pé ẹ̀dà tí wọ́n túmọ̀ ni gbogbo àwọn tó bá fẹ́ lóye Bíbélì máa kà, títí kan àwọn tó ń sọ èdè Hébérù àti Gíríìkì lóde òní. Àwọn kan rò pé á dáa káwọn kọ́ èdè Hébérù àti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ káwọn lè ka Bíbélì tí wọ́n fi èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ. Àmọ́ kò pọn dandan. * A dúpẹ́ pé Bíbélì ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000]. Kò sí àní-àní pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n” máa ka Bíbélì, kí wọ́n sì jàǹfààní nínú rẹ̀. (Ka Ìṣípayá 14:6.) Ǹjẹ́ kò wù ẹ́ pé kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run wa tó nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn dọ́gba-dọ́gba?​—Ìṣe 10:34.

5. Kí ló gbàfiyèsí nípa Bíbélì King James Version?

5 Bí ìyípadà ṣe ń bá àwọn èdè yòókù náà ló ń bá àwọn èdè tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí. Bíbélì táwọn èèyàn ti ń kà ní àkàgbádùn lè wá dèyí tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lóye mọ́. Àpẹẹrẹ kan ni Bíbélì King James Version tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì nígbà àkọ́kọ́ lọ́dún 1611. Ó wà lára Bíbélì Gẹ̀ẹ́sì táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, kódà díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ti di ara èdè táwọn èèyàn ń lò lójoojúmọ́. * Àmọ́, ibi mélòó kan ni Bíbélì King James Version ti lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. Ó wá lo “OLUWA” láwọn ibi yòókù tí orúkọ náà ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Nínú àwọn ẹ̀dà tí wọ́n ṣe jáde lẹ́yìn náà, wọ́n lo “OLUWA” láwọn ibi tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ó ṣe kedere pé Bíbélì King James Version gbà pé orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, táwọn èèyàn máa ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun.

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ pé a ní Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun?

6 Bó ti wù kó rí, èyí tó pọ̀ jù lára ọ̀rọ̀ tí Bíbélì King James Version lò ni kò bóde mu mọ́. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sáwọn Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè míì nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa dúpẹ́ pé a ní Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí èdè rẹ̀ bóde mu? Bíbélì yìí ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè tó ju àádọ́jọ [150] lọ, èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe  fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa ka Bíbélì náà lédè wọn. Àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn lóye tí wọ́n lò mú kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọni lọ́kàn. (Sm. 119:97) Ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí gbogbo ibi tó wà nínú Ìwé Mímọ́.

ÌYÍPADÀ LÁGBO ÒṢÈLÚ

7, 8. (a) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ Júù kò fi lóye Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta Ṣáájú Sànmánì Kristẹni? (b) Bíbélì wo ni Bíbélì Septuagint?

7 Bí nǹkan ṣe ń yí pa dà lágbo òṣèlú ń mú kí èdè àjùmọ̀lò yí pa dà. Kí ni Ọlọ́run ṣe láti mú káwọn èèyàn lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ń yí pa dà lọ́nà yẹn? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ láyé àtijọ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló kọ ìwé mọ́kàndínlógójì [39] àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì. Ìkáwọ́ wọn ni Ọlọ́run kọ́kọ́ “fi àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run sí.” (Róòmù 3:1, 2) Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni kò fi bẹ́ẹ̀ lóye èdè Hébérù mọ́. Ohun tó sì fà á ni pé bí Alẹkisáńdà Ńlá tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Gíríìsì ṣe ń ṣẹ́gun àwọn ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ ọba rẹ̀ ń gbòòrò sí i. (Dán. 8:5-7, 20, 21) Torí pé Gíríìkì ni èdè wọn, èdè yẹn lọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lábẹ́ àkóso wọn ń sọ, títí kan àwọn Júù. Bí èdè Gíríìkì ṣe túbọ̀ ń yọ̀ mọ́ àwọn Júù lẹ́nu, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń ṣòro fún wọn láti lóye Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Kí wá ni Jèhófà ṣe káwọn èèyàn lè lóye ọ̀rọ̀ rẹ̀?

8 Ní nǹkan bí ọdún 250 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n túmọ̀ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì. Nígbà tó yá, wọ́n túmọ̀ àwọn ìwé tó kù nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì. Torí náà, èdè Gíríìkì ni wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ àpapọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí. Àpapọ̀ àwọn ìwé yìí la wá mọ̀ sí Bíbélì Septuagint.

9. (a) Báwo ni Bíbélì Septuagint àtàwọn ìtumọ̀ míì ṣe ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́wọ́? (b) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo lo yàn láàyò nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù?

9 Bíbélì Septuagint mú kó rọrùn fún àwọn Júù àtàwọn míì tó ń sọ èdè Gíríìkì láti ka Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó dájú pé inú wọn á dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń kà á lédè tí wọ́n lóye. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, wọ́n túmọ̀ Ìwé Mímọ́ sáwọn èdè míì, bí èdè Syriac, Gothic àti Látìn. Báwọn èèyàn ṣe ń kà á lédè tí wọ́n lóye, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kódà àwọn kan tiẹ̀ yan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan láàyò bíi ti ọ̀pọ̀ wa lónìí. (Ka Sáàmù 119:162-165.) Ó ṣe kedere pé láìka bí nǹkan ṣe ń yí pa dà lágbo òṣèlú, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò pa run.

ÀWỌN ÈÈYÀN TAKO IṢẸ́ ÌTUMỌ̀ BÍBÉLÌ

10. Kí nìdí tí kò fi rọrùn fún àwọn èèyàn láti ka Bíbélì lásìkò John Wycliffe?

10 Àwọn ìgbà kan wà táwọn aláṣẹ kò jẹ́ káwọn aráàlú ní Bíbélì. Àmọ́, àwọn kan tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fàáké kọ́rí pé kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ti John Wycliffe tó gbé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá. Ọkùnrin yìí gbà pé gbogbo èèyàn ló yẹ kó ní Bíbélì kí wọ́n sì máa kà á. Àmọ́ lásìkò tá à ń sọ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè England ni kò ní Bíbélì. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì wọ́nwó gan-an torí pé ọwọ́ ni wọ́n fi ń dà á kọ. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn  ni kò mọ̀wé kà. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ka Bíbélì sí wọn létí tí wọ́n bá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, àmọ́ kò dájú pé wọ́n lóye ohun tí wọ́n gbọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé èdè Látìn ni wọ́n fi kọ Bíbélì Vulgate táwọn ṣọ́ọ̀ṣì ìgbà yẹn ń kà sétí àwọn ọmọ ìjọ. Nígbà tá a sì ń sọ yìí, ọ̀pọ̀ ni ò lóye èdè Látìn mọ́. Kí ni Jèhófà ṣe káwọn èèyàn lè rí Bíbélì kà lédè tí wọ́n lóye?​—Òwe 2:1-5.

John Wycliffe àtàwọn míì fẹ́ káwọn èèyàn níbi gbogbo ní Bíbélì. Ìwọ ńkọ́? (Wo ìpínrọ̀ 11)

11. Àǹfààní wo ni Bíbélì Wycliffe ṣe fún àwọn èèyàn?

11 Nígbà tó yá, John Wycliffe túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde lọ́dún 1382. Kíá làwọn Lollard, ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Wycliffe bẹ̀rẹ̀ sí í lo Bíbélì náà. Wọ́n ń fẹsẹ̀ rìn láti abúlé kan sí òmíì lórílẹ̀-èdè England kí wọ́n lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n máa ń ka Bíbélì Wycliffe fún àwọn èèyàn tí wọ́n bá pàdé, wọ́n á sì fún wọn ní apá kan ẹ̀dà rẹ̀ tí wọ́n fọwọ́ kọ. Ohun táwọn Lollard ṣe yẹn mú kí nǹkan yí pa dà gan-an, torí ó mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

12. Kí làwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ṣe sí Wycliffe àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

12 Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì? Inú bí wọn sí Wycliffe àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kódà wọ́n tún kórìíra Bíbélì rẹ̀. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Wycliffe. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n dáná sun gbogbo Bíbélì Wycliffe tọ́wọ́ wọn tẹ̀. Kódà lẹ́yìn tí Wycliffe kú, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì dá a lẹ́jọ́ pé aṣòdì sí ṣọ́ọ̀ṣì ni, torí náà wọ́n hú eegun rẹ̀ jáde, wọ́n dáná sun ún, wọ́n sì da eérú rẹ̀ sínú odò kan tí wọ́n ń pè ní Swift. Àmọ́ ẹ̀pa ò bóró mọ́, torí pé Bíbélì ti dọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ kà á tí wọ́n sì fẹ́ lóye rẹ̀, kò sì sóhun tí ṣọ́ọ̀ṣì lè ṣe nípa rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn kan nílẹ̀ Yúróòpù àti láwọn ilẹ̀ míì bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì sáwọn èdè míì, wọ́n sì ń pín in fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

“ẸNI TÍ Ń KỌ́ Ọ KÍ O LÈ ṢE ARA RẸ LÁǸFÀÀNÍ”

13. Ọ̀rọ̀ Jèhófà wo ló já sóòótọ́? Kí nìyẹn mú kó túbọ̀ dá wa lójú?

13 Àwa Kristẹni mọ̀ pé Jèhófà mí sí àwọn tó kọ Bíbélì. Àmọ́ o, kò mí  sí àwọn tó túmọ̀ Bíbélì Septuagint, Bíbélì Wycliffe, Bíbélì King James Version tàbí èyíkéyìí míì. Síbẹ̀, tá a bá wo àkọsílẹ̀ ìtàn nípa bí wọ́n ṣe túmọ̀ àwọn Bíbélì yìí àtàwọn míì, àá rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé Ọ̀rọ̀ òun kò ní pa run. Èyí mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlérí yòókù tí Jèhófà ṣe máa ṣẹ dandan, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?​—Jóṣ. 23:14.

14. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

14 Bí Bíbélì ṣe la onírúurú ìṣòro já títí di àsìkò wa yìí mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, ó sì tún mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà túbọ̀ jinlẹ̀. * Ó ṣe tán, kí nìdí tí Jèhófà fi fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀? Kí nìdí tó fi dáàbò bò ó káwọn èèyàn má bàa pa á run? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká jàǹfààní bí òun ṣe ń kọ́ wa. (Ka Aísáyà 48:17, 18.) Kí wá ló yẹ ká ṣe? Kò sóhun míì ju pé káwa náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn, ká sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.​—1 Jòh. 4:19; 5:3.

15. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

15 Torí pé a mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó dájú pé a máa kà á lọ́nà táá ṣe wá láǹfààní. Ìbéèrè náà ni pé, ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Báwo la ṣe lè mú káwọn tá à ń wàásù fún mọyì Bíbélì? Báwo làwọn tó ń kọ́ni látorí pèpéle ṣe lè rí i dájú pé Ìwé Mímọ́ làwọn ń gbé ẹ̀kọ́ wọn kà? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 4 Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ṣó Pọn Dandan Kó O Kọ́ Èdè Hébérù àti Gíríìkì?” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2009.

^ ìpínrọ̀ 5 Àtinú Bíbélì King James Version ni àwọn àkànlò èdè kan táwọn èèyàn máa ń lò lédè Gẹ̀ẹ́sì ti wá.