Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  September 2017

“Jẹ́ Onígboyà . . . Kí O sì Gbé Ìgbésẹ̀”

“Jẹ́ Onígboyà . . . Kí O sì Gbé Ìgbésẹ̀”

“Jẹ́ onígboyà àti alágbára kí o sì gbé ìgbésẹ̀. Má fòyà tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà . . . wà pẹ̀lú rẹ.”​—1 KÍRÓ. 28:20.

ORIN: 60, 29

1, 2. (a) Iṣẹ́ ńlá wo ni Jèhófà gbé fún Sólómọ́nì? (b) Kí ló ń kọ Dáfídì lóminú nípa Sólómọ́nì?

JÈHÓFÀ gbéṣẹ́ ńlá kan fún Sólómọ́nì, ó ní kó bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn, ìyẹn kíkọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Bíbélì ròyìn pé ilé yẹn máa jẹ́ “ọlọ́lá ńlá lọ́nà títa yọ ré kọjá ní ti ìtayọ alẹ́wàlógo ní gbogbo àwọn ilẹ̀.” Ohun tó mú kí ilé náà túbọ̀ tayọ ni pé ó jẹ́ “ilé Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́.”​—1 Kíró. 22:1, 5, 9-11.

2 Ọba Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà máa ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn, àmọ́ ọ̀dọ́ ni Sólómọ́nì, kò sì ní ìrírí. Ṣó máa lè ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà yanjú? Àbí bó ṣe jẹ́ ọ̀dọ́ àti aláìnírìírí yẹn máa mú kó nira fún un? Ohun kan ni pé, bí Sólómọ́nì bá máa ṣe iṣẹ́ náà yanjú, ó ṣe pàtàkì pé kó nígboyà, kó sì gbé ìgbésẹ̀.

3. Kí ló mú kí Sólómọ́nì dẹni tó nígboyà?

3 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ìrírí bàbá rẹ̀ ni Sólómọ́nì ti kọ́ bó ṣe lè nígboyà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Dáfídì wà lọ́dọ̀ọ́, ó pa àwọn ẹranko ẹhànnà tó fẹ́ pa àgùntàn bàbá rẹ̀. (1 Sám. 17:34, 35) Bákan náà, ìgboyà tó ní ló mú kó lè kojú Gòláyátì tó jẹ́ òmìrán.  Jèhófà ran Dáfídì lọ́wọ́ tó fi jẹ́ pé òkúta kan péré ló fi mú ọkùnrin náà balẹ̀.​—1 Sám. 17:45, 49, 50.

4. Kí nìdí tí Sólómọ́nì fi nílò ìgboyà?

4 Abájọ tí Dáfídì fi rọ Sólómọ́nì pé kó jẹ́ onígboyà, kó sì kọ́ tẹ́ńpìlì náà. (Ka 1 Kíróníkà 28:20.) Bí Sólómọ́nì kò bá nígboyà, iṣẹ́ náà máa kà á láyà, kò sì ní lè ṣe é yanjú. Ẹ ò rí i pé ìyẹn á burú gan-an!

5. Kí nìdí tá a fi nílò ìgboyà?

5 Bíi ti Sólómọ́nì, àwa náà máa nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ká lè nígboyà, ká sì lè ṣe iṣẹ́ tó gbé fún wa yanjú. Torí náà, á dáa ká ronú nípa àwọn tí Bíbélì ròyìn pé wọ́n lo ìgboyà. Bákan náà, àá wo báwa náà ṣe lè lo ìgboyà ká sì ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yanjú.

ÀPẸẸRẸ ÀWỌN TÓ LO ÌGBOYÀ

6. Kí ló wú ẹ lórí nípa Jósẹ́fù?

6 Àpẹẹrẹ kan ni Jósẹ́fù. Ó lo ìgboyà nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì fẹ́ kó bá òun sùn. Jósẹ́fù mọ̀ pé ojú òun á rí màbo tóun ò bá ṣe ohun tí obìnrin náà fẹ́. Síbẹ̀ ó lo ìgboyà, dípò tó fi máa gbà láti bá obìnrin náà sùn, ṣe ló já ara rẹ̀ gbà mọ́ ọn lọ́wọ́ tó sì sá lọ.​—Jẹ́n. 39:10, 12.

7. Ṣàlàyé bí Ráhábù ṣe fi hàn pé òun nígboyà. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

7 Ẹlòmíì tó lo ìgboyà ni Ráhábù. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ amí wá sílé rẹ̀ ní Jẹ́ríkò, ìbẹ̀rù lè mú kó sọ pé òun ò ní lè gbà wọ́n sílé. Àmọ́ torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó lo ìgboyà, ó dáàbò bo àwọn ọkùnrin náà, ó sì mú kí wọ́n pa dà sílé láìséwu. (Jóṣ. 2:4, 5, 9, 12-16) Ráhábù gbà pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, ìyẹn sì mú kó dá a lójú pé Jèhófà máa fi ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kò jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn kó jìnnìjìnnì bá òun, kódà kò bẹ̀rù ohun tí ọba Jẹ́ríkò àtàwọn èèyàn rẹ̀ lè ṣe fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbé ìgbésẹ̀ tó mú kí Jèhófà dá ẹ̀mí òun àti ìdílé rẹ̀ sí.​—Jóṣ. 6:22, 23.

8. Báwo ni ìgboyà tí Jésù ní ṣe ran àwọn àpọ́sítélì lọ́wọ́?

8 Àpẹẹrẹ míì ni tàwọn àpọ́sítélì Jésù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Wọ́n fojú ara wọn rí bí Jésù ṣe lo ìgboyà, ìyẹn sì mú káwọn náà nígboyà. (Mát. 8:28-32; Jòh. 2:13-17; 18:3-5) Bí àpẹẹrẹ, àwọn àpọ́sítélì ò jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n nígbà táwọn Sadusí halẹ̀ mọ́ wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ kọ́ni nípa Jésù mọ́.​—Ìṣe 5:17, 18, 27-29.

9. Ta ni 2 Tímótì 1:7 sọ pé ó lè fún wa ní ìgboyà?

9 Ìgboyà tí Jósẹ́fù, Ráhábù, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ní ló jẹ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ rere. Kì í ṣe torí pé wọ́n jọ ara wọn lójú ni wọ́n ṣe nígboyà, kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Onírúurú nǹkan làwa náà ń kojú tó máa gba pé ká nígboyà. Dípò tá a fi máa gbára lé ara wa, ṣe ni ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Ka 2 Tímótì 1:⁠7.) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò méjì lára àwọn ibi tá a ti nílò ìgboyà: (1) nínú ìdílé àti (2) nínú ìjọ.

ÀWỌN ÌGBÀ TÓ YẸ KÁ LO ÌGBOYÀ

10. Kí nìdí táwọn ọ̀dọ́ Kristẹni fi nílò ìgboyà?

10 Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ń kojú tó máa gba pé kí wọ́n lo ìgboyà kí wọ́n sì fi hàn pé Jèhófà làwọn ń sìn. Wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Sólómọ́nì tó fìgboyà ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nígbà tó ń kọ́ tẹ́ńpìlì. Ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ Kristẹni máa tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn òbí wọn, síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì káwọn fúnra wọn náà ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. (Òwe 27:11) Wọ́n nílò ìgboyà kí wọ́n lè pinnu àwọn tí wọ́n máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́ àti irú eré ìnàjú tí wọ́n máa ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n nílò ìgboyà kí wọ́n má  bàa lọ́wọ́ nínú ìwàkiwà, kí wọ́n sì pinnu ìgbà tí wọ́n máa ṣèrìbọmi. Kì í ṣe ohun tí Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run fẹ́ làwọn ọ̀dọ́ yìí ń ṣe, torí náà wọ́n nílò ìgboyà gan-an.

11, 12. (a) Àpẹẹrẹ wo ni Mósè fi lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn ní ìgboyà? (b) Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè fara wé Mósè?

11 Ó ṣe pàtàkì káwọn ọ̀dọ́ pinnu bí wọn ṣe máa lo ìgbésí ayé wọn. Láwọn ilẹ̀ kan, ṣe ni wọ́n máa ń fúngun mọ́ àwọn ọ̀dọ́ pé kí wọ́n lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, kí wọ́n sì wá iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé. Láwọn ilẹ̀ míì, ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ ti mú káwọn ọ̀dọ́ máa ronú àtiforí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n lè pèsè jíjẹ mímu fún ìdílé wọn. Tó bá jẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ nìyẹn, o lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Mósè. Ọmọbìnrin Fáráò ló tọ́ Mósè dàgbà, torí náà ó máa rọrùn fún un láti di gbajúmọ̀, kó sì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ẹ wo báwọn ìdílé Fáráò, àwọn olùkọ́ rẹ̀ àtàwọn agbaninímọ̀ràn rẹ̀ á ṣe máa fúngun mọ́ ọn pé ohun tó yẹ kó ṣe nìyẹn! Àmọ́ kàkà kí Mósè ṣèyẹn, ṣe ló yàn láti sin Jèhófà. Lẹ́yìn tí Mósè fi gbogbo ọrọ̀ Íjíbítì sílẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. (Héb. 11:24-26) Ohun tó ṣe yìí ló mú kí Jèhófà bù kún un nígbà yẹn, ó sì dájú pé ìbùkún tí Jèhófà máa fún un lọ́jọ́ iwájú á jùyẹn lọ.

12 Bákan náà lónìí, Jèhófà máa bù kún àwọn ọ̀dọ́ tó bá ń fi Ìjọba Ọlọ́run síwájú nígbèésí ayé wọn, tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nínú ètò rẹ̀. Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò. Àpẹẹrẹ gidi ni Tímótì tó gbé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní jẹ́ fún ẹ̀yin ọ̀dọ́ tó bá di pé kẹ́ ẹ gbájú mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín. *​—Ka Fílípì 2:19-22.

Ṣé wàá jẹ́ onígboyà ní gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ? (Wo ìpínrọ̀ 13-17)

13. Báwo ni ìgboyà tí ọ̀dọ́bìnrin kan ní ṣe mú kọ́wọ́ rẹ̀ tẹ ohun tó pinnu láti ṣe?

13 Arábìnrin kan nílùú Alabama, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ bó ṣe nígboyà, tíyẹn sì mú kó tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Mo máa ń tijú gan-an nígbà tí mo wà ní kékeré. Mi ò kì í lè bá àwọn tá a jọ ń ṣèpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba sọ̀rọ̀, ká má tíì sọ pé kí n bá ẹni tí mi ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí.” Àmọ́ àwọn ará nínú ìjọ àtàwọn òbí rẹ̀ ràn án lọ́wọ́ débi pé ọwọ́ rẹ̀ tẹ ohun tó pinnu láti ṣe, ìyẹn láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ó wá sọ pé: “Ohun tí ayé Sátánì fẹ́ kéèyàn máa lé ni ilé ẹ̀kọ́ gíga, iyì, owó àtàwọn nǹkan ìní tara. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, ọwọ́ wọn kì í tẹ ohun tí wọ́n ń lé, ìyẹn máa ń tán wọn lókun, ó sì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Àmọ́ bí mo ṣe ń fayé mi sin Jèhófà ti mú kí n láyọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́, ohun tó dáa jù tí mo lè fayé mi ṣe náà nìyẹn.”

14. Àwọn ìgbà wo lẹ̀yin òbí nílò ìgboyà?

14 Ẹ̀yin òbí náà nílò ìgboyà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gá yín níbi iṣẹ́ lè ní kẹ́ ẹ máa fi ojoojúmọ́ ṣe àṣekún iṣẹ́, títí kan òpin ọ̀sẹ̀. Kò sí àní-àní pé ìyẹn sì máa dí ìjọsìn ìdílé yín lọ́wọ́, títí kan òde ẹ̀rí àti ìpàdé. Ó gba ìgboyà kẹ́ ẹ tó lè sọ fún ọ̀gá yín pé ẹ ò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀. Tẹ́ ẹ bá dúró lórí ìpinnu yín, àpẹẹrẹ tó dáa lẹ̀ ń fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ yín. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn òbí kan nínú ìjọ fàyè gba àwọn ọmọ wọn láti ṣe àwọn nǹkan tẹ́yin ò gbà láyè fáwọn ọmọ yín. Àwọn òbí bẹ́ẹ̀ lè béèrè ìdí tẹ́ ò fi jẹ́ káwọn ọmọ yín lọ́wọ́ sí nǹkan táwọn ọmọ tiwọn ń ṣe. Ṣé wàá lè fìgboyà ṣàlàyé fún wọn, láìkàn wọ́n lábùkù?

15. Báwo ni Sáàmù 37:25 àti Hébérù 13:5 ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́?

15 Ó gba ìgboyà ká tó lè ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run síwájú  láyé wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí kan kì í gba àwọn ọmọ wọn níyànjú pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, kí wọ́n lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, kí wọ́n lọ sí Bẹ́tẹ́lì tàbí kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kọ́ ibi ìjọsìn wa. Àwọn òbí bẹ́ẹ̀ máa ń bẹ̀rù pé àwọn ọmọ àwọn kò ní lè tọ́jú àwọn lọ́jọ́ ogbó. Àmọ́ àwọn òbí tó gbọ́n máa ń lo ìgboyà, wọ́n sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa bójú tó àwọn. (Ka Sáàmù 37:25; Hébérù 13:5.) Tẹ́ ẹ bá nígboyà, tẹ́ ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àwọn ọmọ yín náà máa ṣe bẹ́ẹ̀.​—1 Sám. 1:27, 28; 2 Tím. 3:14, 15.

16. Kí làwọn òbí kan ṣe tí àwọn ọmọ wọn fi jẹ́ kí ìjọsìn Jèhófà gba iwájú láyé wọn? Àǹfààní wo nìyẹn sì ti ṣe fún àwọn ọmọ náà?

16 Tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà mú káwọn ọmọ wọn fi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wọn. Bàbá àwọn ọmọ náà sọ pé: “Káwọn ọmọ wa tó mọ̀rọ̀ sọ la ti máa ń sọ fún wọn nípa ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àti kéèyàn ṣiṣẹ́ sin àwọn ará nínú ìjọ. Ìyẹn ni wọ́n sì fi ṣe àfojúsùn wọn bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Ní báyìí tí ọwọ́ wọn ti tẹ àfojúsùn wọn, èyí ti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé yìí, wọ́n sì ti wá ní ojúlówó ayọ̀.” Arákùnrin kan tó ní ọmọ méjì sọ pé: “Àwọn òbí kan máa ń náwó nára káwọn ọmọ wọn lè mókè lẹ́nu ẹ̀kọ́ wọn, nínú eré ìnàjú àti nínú eré ìdárayá. Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé kí àwọn òbí náwó nára kí àwọn ọmọ wọn lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Gbogbo ìgbà tá a bá ń rí àwọn ọmọ wa ni inú wa máa ń dùn, torí pé ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú láyé wọn, a sì máa ń fún wọn níṣìírí nígbà gbogbo.” Ohun kan tó dájú ni pé Jèhófà máa bù kún àwọn òbí tó ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wọn.

BÓ O ṢE LÈ LO ÌGBOYÀ NÍNÚ ÌJỌ

17. Sọ bí àwọn tó wà nínú ìjọ ṣe lè lo ìgboyà.

17 Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa lo ìgboyà nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alàgbà nílò ìgboyà tí wọ́n bá ń bójú tó ẹjọ́ tàbí tí wọ́n bá ń ṣèrànwọ́ fún ẹnì kan tó ń ṣàìsàn tó lè gbẹ̀mí rẹ̀. Bákan náà, àwọn alàgbà kan  máa ń ṣèbẹ̀wò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kí wọ́n lè kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ṣé àwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ náà nílò ìgboyà? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ló wà fún wọn báyìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n lè lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, wọ́n lè ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ, wọ́n sì lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn kan lára wọn tiẹ̀ ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì.

18. Báwo làwọn àgbà obìnrin ṣe lè lo ìgboyà?

18 Iṣẹ́ ribiribi làwọn àgbà obìnrin ń ṣe nínú ìjọ. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà fi àwọn arábìnrin yìí jíǹkí wa! Lóòótọ́ agbára wọn lè má fi bẹ́ẹ̀ gbé ohun tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà, síbẹ̀ wọ́n ṣì ń fi ìgboyà ṣe ohun tágbára wọn gbé. (Ka Títù 2:3-5.) Bí àpẹẹrẹ, ó gba ìgboyà tí wọ́n bá ní kí àgbà obìnrin kan bá ọ̀dọ́bìnrin kan sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe ń múra. Àgbà obìnrin náà kò ní kàn án lábùkù, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa gbà á níyànjú pé kó ṣàtúnṣe káwọn míì lè kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀. (1 Tím. 2:​9, 10) Táwọn àgbà obìnrin bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á gbé ìjọ ró.

19. (a) Báwo làwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi ṣe lè lo ìgboyà? (b) Báwo ni Fílípì 2:13 àti 4:13 ṣe lè mú káwọn arákùnrin nígboyà?

19 Ó tún ṣe pàtàkì kí àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi jẹ́ onígboyà, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀. Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run làwọn arákùnrin tó nígboyà, tí wọ́n sì ṣe tán láti ṣiṣẹ́ sìn nínú ìjọ. (1 Tím. 3:1) Àmọ́, àwọn kan kì í fẹ́ gba àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ. Wọ́n lè ti ṣe àṣìṣe nígbà kan rí, kí wọ́n wá máa ronú pé àwọn ò yẹ lẹ́ni tó ń di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Àwọn arákùnrin míì sì lè máa ronú pé àwọn ò ní lè ṣe iṣẹ́ náà bí iṣẹ́. Tó bá jẹ́ pé ohun tó ò ń rò nìyẹn, Jèhófà á mú kó o nígboyà. (Ka Fílípì 2:13; 4:13.) Rántí pé ìgbà kan wà tí Mósè náà rò pé òun ò ní lè ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. (Ẹ́kís. 3:11) Síbẹ̀ Jèhófà ràn án lọ́wọ́, nígbà tó sì yá Mósè dẹni tó nígboyà tó sì ṣe iṣẹ́ náà yanjú. Àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi náà lè nígboyà tí wọ́n bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, tí wọ́n sì ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ àwọn tó lo ìgboyà nínú Bíbélì. Wọ́n lè fìrẹ̀lẹ̀ bẹ àwọn alàgbà pé kí wọ́n dá àwọn lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì jẹ́ káwọn alàgbà mọ̀ pé àwọn ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá wà. A rọ gbogbo ẹ̀yin arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi pé kẹ́ ẹ jẹ́ onígboyà, kẹ́ ẹ sì múra tán láti ṣiṣẹ́ nínú ìjọ!

“JÈHÓFÀ . . . WÀ PẸ̀LÚ RẸ”

20, 21. (a) Ìdánilójú wo ni Dáfídì fún Sólómọ́nì? (b) Kí ló dá àwa náà lójú?

20 Ọba Dáfídì rán Sólómọ́nì létí pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú rẹ̀ títí tó fi máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí. (1 Kíró. 28:20) Ó ṣe kedere pé Sólómọ́nì fi àwọn ọ̀rọ̀ yẹn sọ́kàn. Láìka pé ọ̀dọ́ ni tí kò sì nírìírí, ó lo ìgboyà, ó gbé iṣẹ́ ṣe, Jèhófà sì ràn án lọ́wọ́ tó fi parí iṣẹ́ náà ní ọdún méje àtààbọ̀.

21 Bí Jèhófà ṣe ran Sólómọ́nì lọ́wọ́, ó máa ran àwa náà lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tó gbé fún wa yanjú, nínú ìdílé àti nínú ìjọ. (Aísá. 41:10, 13) Tá a bá ń lo ìgboyà nínú ìjọsìn Jèhófà, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún wa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, “jẹ́ onígboyà . . . kí o sì gbé ìgbésẹ̀.”

^ ìpínrọ̀ 12 Wàá rí àwọn nǹkan tó o lè ṣe táá jẹ́ kó o fi Ìjọba Ọlọ́run síwájú nígbèésí ayé rẹ nínú àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Fi Àwọn Ohun Tó Ò Ń Lé Nípa Tẹ̀mí Yin Ẹlẹ́dàá Rẹ Lógo,” nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2004.