Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) September 2017

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti October 23 sí November 26, 2017, ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Máa Kó Ara Rẹ Níjàánu

Báwo làwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì ṣe lè mú ká ní ìkóra-ẹni-níjàánu, ká sì máa lò ó? Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni ní ìkóra-ẹni-níjàánu?

Máa Fàánú Hàn Bíi Ti Jèhófà

Ìgbà kan wà tí Jèhófà polongo orúkọ rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ fún Mósè. Ohun tí Jèhófà kọ́kọ́ mẹ́nu kàn ni bóun ṣe jẹ́ aláàánú. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ aláàánú? Kí nìdí tó fi yẹ kó o jẹ́ aláàánú?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Inú Mi Dùn Pé Mo Bá Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ṣiṣẹ́

David Sinclair sọ bí inú rẹ̀ ṣe dùn tó pé ó bá àwọn adúróṣinṣin lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣiṣẹ́ láwọn ọdún 61 tó ti lò ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yóò Wà Títí Láé

Bíbélì ṣì ni ìwé táwọn èèyàn ní lọ́wọ́ jù lọ láìka pé ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ ọ́ tàbí bí èdè ṣe ń yí pa dà. Bíbélì tún là á já láìka ìyípadà tó wáyé lágbo òṣèlú àti bí àwọn kan ṣe tako iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì.

“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára”

Ọ̀pọ̀ ló ti yí ìgbésí ayé wọn pa dà torí pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí Bíbélì sa agbára láyé wa?

“Jẹ́ Onígboyà . . . Kí O sì Gbé Ìgbésẹ̀”

Kí nìdí tá a fi nílò ìgboyà, báwo sì la ṣe lè ní in?