Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  September 2016

Ǹjẹ́ Ìmúra Rẹ Ń Fògo fún Ọlọ́run?

Ǹjẹ́ Ìmúra Rẹ Ń Fògo fún Ọlọ́run?

“Ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”1 KỌ́R. 10:31.

ORIN: 34, 61

1, 2. Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń wọ aṣọ tó bójú mu? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

NÍGBÀ tí ìwé ìròyìn kan lórílẹ̀-èdè Netherlands ń sọ nípa àpérò kan táwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ṣe, ó sọ pé: “Aṣọ tí àwọn èèyàn náà wọ̀ kò buyì kún àpérò náà rárá, pàápàá lásìkò ooru.” Ó wá fi kún un pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í múra bẹ́ẹ̀ nígbà àpéjọ wọn. . . . Àwọn ọkùnrin máa wọ kóòtù, wọ́n á tún fi táì sí i. Àwọn obìnrin sì máa ń wọ síkẹ́ẹ̀tì tó gùn dáadáa, tó wuyì, tó sì bójú mu.” Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń gbóríyìn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé a máa ń fi ‘aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wa lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, lọ́nà tí ó yẹ àwọn tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.’ (1 Tím. 2:9, 10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù darí ọ̀rọ̀ yìí sí, síbẹ̀ ìlànà yìí kan náà làwọn arákùnrin ń tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ ìmúra.

2 Ó ṣe pàtàkì káwa èèyàn Jèhófà máa wọ aṣọ tó bójú mu, ohun tí Ọlọ́run tá à ń sìn náà sì fẹ́ nìyẹn. (Jẹ́n. 3:21) Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa aṣọ àti ìmúra fi hàn pé Ọlọ́run ní àwọn ìlànà tó fẹ́ káwa olùjọsìn rẹ̀ máa tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ irú aṣọ tá a  máa wọ̀. Torí náà, tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀, kì í ṣohun tó wù wá nìkan ló yẹ ká máa rò. Ó tún yẹ ká máa ronú nípa ohun tó máa wu Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.

3. Kí la rí kọ́ nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìmúra?

3 Bí àpẹẹrẹ, Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ìṣekúṣe tó kúnnú àwọn ìlú tó yí wọn ká. Òfin yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà kórìíra àwọn ìmúra tí kì í jẹ́ ká dá ọkùnrin mọ̀ yàtọ̀ sí obìnrin, irú èyí tó lòde lónìí. (Ka Diutarónómì 22:5.) Nínú ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nípa ìmúra, a rí i kedere pé Ọlọ́run ò fẹ́ kí ọkùnrin máa múra bí obìnrin tàbí kí obìnrin máa múra bí ọkùnrin. Kò sì nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìmúra tí kì í jẹ́ kéèyàn mọ̀ bóyá ọkùnrin lẹnì kan tàbí obìnrin.

4. Kí ló lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó dáa tó bá dọ̀rọ̀ ìmúra?

4 Tó bá dọ̀rọ̀ ìmúra, Bíbélì ní àwọn ìlànà tó lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó dáa. Àwọn ìlànà yìí lè ràn wá lọ́wọ́ láìka ibi tá à ń gbé tàbí àṣà ìbílẹ̀ wa àti bójú ọjọ́ ṣe rí. A ò nílò òfin jàn-ràn-jan-ran nípa irú aṣọ tó yẹ ká wọ̀ àtèyí tí kò yẹ ká wọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìlànà Bíbélì là ń tẹ̀ lé bí kálukú wa ṣe ń yan irú aṣọ tó wù ú láti wọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé” tó bá dọ̀rọ̀ ohun tá a máa wọ̀.Róòmù 12:1, 2.

“A Ń DÁMỌ̀RÀN ARA WA FÚN ÌTẸ́WỌ́GBÀ GẸ́GẸ́ BÍ ÒJÍṢẸ́ ỌLỌ́RUN”

5, 6. Kí ló yẹ kí ìmúra wa mú káwọn èèyàn ṣe?

5 Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti ṣàkọsílẹ̀ ìlànà pàtàkì tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 6:4. (Kà á.) Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìrínisí ni ìsọnilọ́jọ̀. Òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn torí pé “ohun tí ó fara hàn sí ojú” ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń pinnu irú ẹni tá a jẹ́. (1 Sám. 16:7) Ìdí nìyẹn tí àwa tá a jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run fi gbà pé ìmúra kì í ṣe ọ̀rọ̀ ká wọ ohun tó kàn wù wá. Torí pé àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là ń tẹ̀ lé, a kì í wọ àwọn aṣọ tó fún mọ́ra pinpin, tó ṣí ara sílẹ̀ tàbí tó lè mú káwọn èèyàn máa ro èròkerò nípa wa. Bákan náà, a ò ní máa wọ àwọn aṣọ tí kò bo àwọn ibi kọ́lọ́fín ara tàbí tó gbé àwọn ibi kọ́lọ́fín ara yọ. Kò yẹ ká múra lọ́nà táá máa kọ àwọn míì lóminú tàbí táá mú kí wọ́n máa gbójú sẹ́gbẹ̀ẹ́ nígbà tí wọ́n bá rí wa.

6 Tá a bá wọṣọ tó yẹ ọmọlúàbí, tí aṣọ wá mọ́, tó sì bójú mu, àwọn èèyàn máa yẹ́ wa sí, wọ́n á sì bọ̀wọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Èyí tiẹ̀ lè mú káwọn náà wá sin Jèhófà. Bákan náà, tí ìmúra wa bá bójú mu, àwọn èèyàn á fojú tó tọ́ wo ètò Ọlọ́run tá à ń ṣojú fún. Èyí sì lè mú kó yá wọn lára láti gbọ́ ìwàásù wa.

7, 8. Àwọn ìgbà wo ló ṣe pàtàkì gan-an pé ká múra lọ́nà tó bójú mu?

7 Ó yẹ ká múra lọ́nà táá fògo fún Ọlọ́run mímọ́ tá à ń sìn, lọ́nà táá buyì kún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, táá sì fi ìgbatẹnirò hàn sáwọn tá à ń wàásù fún. Yàtọ̀ síyẹn, irú ìmúra bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ káwọn èèyàn tẹ́tí sí ìwàásù wa. (Róòmù 13:8-10) Ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa múra lọ́nà tó bójú mu pàápàá nígbà tá a bá ń lọ́wọ́ nínú ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà, irú bí ìgbà tá a bá ń lọ sípàdé tàbí tá à ń lọ sóde ẹ̀rí. A gbọ́dọ̀ múra ‘lọ́nà tí ó yẹ àwọn tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.’ (1 Tím. 2:10) Òótọ́ kan ni pé aṣọ tó bójú mu níbì kan lè má bójú mu níbòmíì. Torí náà, àwa èèyàn Jèhófà máa  ń wo ohun tó bá àṣà ìbílẹ̀ ibi tá a wà mu, ká má bàa múra lọ́nà tó máa kọ àwọn èèyàn lóminú.

Ṣé ìmúra rẹ ń buyì kún Ọlọ́run tó ò ń ṣojú fún? (Wo ìpínrọ̀ 7 àti 8)

8 Ka 1 Kọ́ríńtì 10:31. Nígbà tá a bá ń lọ sí àpéjọ, a gbọ́dọ̀ múra lọ́nà tó bójú mu, tó sì yẹ ọmọlúàbí. Kò yẹ ká wọ àwọn aṣọ tó fún mọ́ra pinpin tàbí èyí tó ṣí ara sílẹ̀ irú èyí táyé ń gbé lárugẹ lónìí. Kódà, nígbà tá a bá wà níbi tá a dé sí tàbí tá à ń gbafẹ́ ṣáájú àpéjọ àti lẹ́yìn àpéjọ, kò yẹ ká múra wúruwùru tàbí ká kàn wọ ẹ̀wù kan ṣá. Tá a bá múra dáadáa, á yá wa lára láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àá sì lè wàásù nígbà tí àǹfààní rẹ̀ bá yọ.

9, 10. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú lórí ohun tó wà nínú Fílípì 2:4 tó bá kan ọ̀rọ̀ ìmúra?

9 Ka Fílípì 2:4. Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa ronú nípa àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà tá a bá ń pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀? Ìdí kan ni pé àwa èèyàn Jèhófà ń sapá láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo.” (Kól. 3:2, 5) A ò ní fẹ́ ṣe ohun táá mú kó ṣòro fáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn. Ìdí sì ni pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ oníṣekúṣe ṣì lè máa bá èròkerò jà lọ́kàn wọn. (1 Kọ́r. 6:9, 10) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun táá mú kí ọkàn irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tún máa fà sí ìṣekúṣe.

10 Nígbà tá a bá wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, ó yẹ ká múra lọ́nà tó bójú mu, tí ọkàn wọn kò  sì ní máa fà sí ìṣekúṣe. Yálà a wà nípàdé tàbí a lọ gbafẹ́, ó yẹ ká múra lọ́nà tó yẹ ọmọlúàbí. Òótọ́ ni pé gbogbo wa la lómìnira láti wọ ohun tó wù wá, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ múra lọ́nà táá mú kó rọrùn fáwọn ará wa láti jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà. A ò gbọ́dọ̀ múra lọ́nà táá mú kí wọ́n máa ro èròkerò tàbí kí wọ́n máa sọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ tàbí hùwàkiwà. (1 Pét. 1:15, 16) Bíbélì sọ pé ìfẹ́ tòótọ́ ‘kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í sì wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.’1 Kọ́r. 13:4, 5.

AṢỌ TÓ BÓJÚ MU

11, 12. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn bá a ṣe ń ronú ohun tá a máa wọ̀?

11 Nígbà tá a bá fẹ́ pinnu ohun tá a máa wọ̀, àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run mọ̀ pé ohun gbogbo ni àkókò wà fún. (Oníw. 3:1, 17) Òótọ́ ni pé a máa ń wo bójú ọjọ́ ṣe rí ká tó pinnu ohun tá a máa wọ̀. A tún máa ń ronú lórí ibi tá à ń lọ àti bí nǹkan ṣe rí níbẹ̀. Àmọ́, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn ìlànà Jèhófà kì í yí pa dà bójú ọjọ́ ṣe ń yí pa dà.Mál. 3:6.

12 Lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn, ó lè ṣòro láti wọ aṣọ tó bójú mu, tó sì bo ara dáadáa torí ooru. Àmọ́, ara máa tu àwọn ará tí a kò bá wọ aṣọ tó fún pinpin tàbí tó ṣí ara sílẹ̀. (Jóòbù 31:1) Bákan náà, tá a bá lọ gbafẹ́ létíkun tàbí tá a lọ wẹ̀ lódò, ó yẹ ká wọ aṣọ tó bójú mu. (Òwe 11:2, 20) Nínú ayé, táwọn èèyàn bá lọ wẹ̀ lódò wọ́n sábà máa ń bọ́ra sí ìhòòhò, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì sáwa tá à ń sin Jèhófà ni bí ìmúra wa ṣe máa fògo fún Ọlọ́run mímọ́ tá à ń sìn.

13. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú lórí ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:32, 33 ká tó pinnu ohun tá a máa wọ̀?

13 Ohun pàtàkì míì wà tó yẹ ká ronú lé ká tó pinnu ohun tá a máa wọ̀. Ó yẹ ká ronú nípa ẹ̀rí ọkàn àwọn míì yálà, wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:32, 33.) Kò yẹ ká wọ aṣọ èyíkéyìí tó lè kọ àwọn míì lóminú. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí olúkúlùkù wa máa ṣe bí ó ti wu aládùúgbò rẹ̀ nínú ohun rere fún gbígbé e ró.” Ó wá fi kún un pé: “Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” (Róòmù 15:2, 3) Jésù máa ń fi ire àwọn míì ṣáájú tiẹ̀, ó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kóun máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tóun bá máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwa náà lè ṣe bíi ti Jésù, ká má ṣe máa wọ àwọn aṣọ tá a nífẹ̀ẹ́ sí àmọ́ tí kò ní jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ ìwàásù wa.

14. Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa múra lọ́nà tó ń fògo fún Ọlọ́run?

14 Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ fi ìlànà Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ wọn. Lára ohun tí wọ́n ní láti ṣe ni pé kí wọ́n rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn àtàwọn alára ń múnú Jèhófà dùn nípa mímúra lọ́nà tó bójú mu. (Òwe 22:6; 27:11) Tẹ́yin òbí bá ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ yín, tẹ́ ẹ sì ń fìfẹ́ tọ́ wọn sọ́nà, ẹ̀ẹ́ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Á dáa kẹ́ ẹ kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń ra aṣọ tó bójú mu àti ibi tí wọ́n ti lè rí irú aṣọ bẹ́ẹ̀ rà. Kẹ́ ẹ kọ́ wọn pé kì í ṣe ohun tó wù wọ́n nìkan ni kí wọ́n rà, àmọ́ kí wọ́n ra ohun táá jẹ́ kí wọ́n lè fira wọn hàn bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.

MÁ ṢI ÒMÌNIRA RẸ LÒ

15. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀?

15 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó ṣeé múlò tó sì máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa fògo fún Ọlọ́run. Síbẹ̀, a lómìnira láti yan ohun tó wù wá láti wọ̀. Ohun tí kálukú wa nífẹ̀ẹ́  sí yàtọ̀, bẹ́ẹ̀ sì làpò wa ò dọ́gba. Síbẹ̀, ó yẹ kí aṣọ tá a bá wọ̀ wà ní mímọ́ tónítóní, kó jẹ́ ti ọmọlúàbí, kó bá ibi tá a wà mu, kó má sì kọ àwọn míì lóminú.

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè wọ aṣọ tó bójú mu?

16 Ó ṣe kedere pé tá a bá fi àwọn kókó tá a jíròrò tán yìí sílò, àá lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu nípa ìmúra wa. Àmọ́, ká sòótọ́, kì í rọrùn láti rí aṣọ tó bójú mu rà lọ́jà. Ìdí ni pé àwọn aṣọ táyé ń gbé lárugẹ ló kúnnú ọjà lónìí. Torí náà, ó lè gbà wá lákòókò, ká sì fẹ́rẹ̀ẹ́ rin inú ọjà tán ká tó rí síkẹ́ẹ̀tì àti búláòsì àtàwọn aṣọ míì tí kò fún mọ́ra pinpin tó sì yẹ ọmọlúàbí. Síbẹ̀, inú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà máa dùn tí wọ́n bá rí i pé aṣọ wa rẹwà, ó sì buyì kúnni. Ó dájú pé tá a bá ń múra lọ́nà tó ń fògo fún Jèhófà Baba wa ọ̀run, ayọ̀ tá a máa ní á ju gbogbo wàhálà tá a ṣe láti rí aṣọ náà rà.

17. Kí ló lè mú kí arákùnrin kan pinnu bóyá kóun dá irùngbọ̀n sí tàbí kóun má ṣe bẹ́ẹ̀?

17 Ǹjẹ́ ó yẹ káwọn arákùnrin máa dá irùngbọ̀n sí? Láyé àtijọ́, Òfin Mósè fi dandan lé e pé àwọn ọkùnrin gbọ́dọ̀ dá irùngbọ̀n sí. Àmọ́, àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè. (Léf. 19:27; 21:5; Gál. 3:24, 25) Láwọn ilẹ̀ kan, kò sóhun tó burú téèyàn bá ní irùngbọ̀n tó ṣe rẹ́múrẹ́mú, ìyẹn ò sì ní káwọn èèyàn má ṣe gbọ́ ìwàásù. Kódà, àwọn arákùnrin kan tá a yàn sípò nínú ìjọ láwọn ilẹ̀ yẹn ní irùngbọ̀n. Síbẹ̀, àwọn arákùnrin kan nírú àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè pinnu pé àwọn ò ní dá irùngbọ̀n sí. (1 Kọ́r. 8:9, 13; 10:32) Àmọ́ láwọn ilẹ̀ míì, kò bójú mu rárá fáwọn Kristẹni láti dá irùngbọ̀n sí. Kódà, tí arákùnrin kan bá dá irùgbọ̀n sí láwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìrísí rẹ̀ máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò sì ní lórúkọ rere láwùjọ.Róòmù 15:1-3; 1 Tím. 3:2, 7.

18, 19. Báwo ni Míkà 6:8 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe ń sapá láti múra lọ́nà tó máa múnú Jèhófà dùn?

18 Inú wa dùn pé Jèhófà ò fún wa ní òfin jàn-ràn-jan-ran nípa irú aṣọ tó yẹ ká máa wọ̀ àti bó ṣe yẹ ká máa múra. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún wa lómìnira láti yan ohun tó bọ́gbọ́n mu. Torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìlànà Bíbélì máa tọ́ wa sọ́nà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu. Kódà, nínú ọ̀nà tá à ń gbà múra pàápàá àti aṣọ tá à ń wọ̀, a lè fi hàn pé a jẹ́ ‘ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rìn.’Míkà 6:8.

19 A mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ a sì gbà pé ìlànà Jèhófà ló dára jù lọ fún wa. Torí náà, tá a bá jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, tá a sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ìlànà rẹ̀ la ó máa tẹ̀ lé nígbà gbogbo. Ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà tún máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò tó bá fẹ́ ṣèpinnu. Torí náà, à ń fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà bá Ọlọ́run rìn tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, tá a sì ń ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tiwa.

20. Tá a bá ń múra lọ́nà tó bójú mu, kí ló máa mú káwọn èèyàn ṣe?

20 Ó yẹ kó ṣe kedere nínú ọ̀nà tá à ń gbà múra pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. Àwọn ará wa àtàwọn tó wà ládùúgbò gbọ́dọ̀ rí i nínú ọ̀nà ìmúra wa pé Ọlọ́run mímọ́ là ń ṣojú fún. Ọlọ́run ní àwọn ìlànà tó fẹ́ ká máa tẹ̀ lé, inú wa sì máa ń dùn láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà. A gbóríyìn fún ẹ̀yin arákùnrin àtẹ̀yin arábìnrin wa pé ẹ̀ ń múra lọ́nà tó bójú mu ẹ sì ń hùwà tó yẹ Kristẹni. Ìyẹn ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n lè rí ìyè. À ń tipa bẹ́ẹ̀ fògo fún Jèhófà, a sì ń múnú rẹ̀ dùn. Ó dájú pé tá a bá ń múra lọ́nà tó bójú mu, àá máa mú ìyìn àti ògo bá Jèhófà, Ẹni tó ‘fi iyì àti ọlá ńlá wọ ara rẹ̀ láṣọ.’Sm. 104:1, 2.