Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  September 2016

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Mú Kí Ìgbàgbọ́ Yín Túbọ̀ Lágbára

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Mú Kí Ìgbàgbọ́ Yín Túbọ̀ Lágbára

“Ìgbàgbọ́ ni . . . ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.”HÉB. 11:1.

ORIN: 41, 69

1, 2. Àwọn nǹkan wo làwọn ọ̀dọ́ wa ń kojú, kí sì ni wọ́n lè ṣe kí ìgbàgbọ́ wọn nínú Ẹlẹ́dàá lè túbọ̀ lágbára?

NÍLẸ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ọmọ kan sọ fún ọmọ Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jọ wà níléèwé pé: “Kì í ṣe irú ẹ ló yẹ kí wọ́n tàn jẹ pé Ọlọ́run wà.” Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Àwọn tíṣà mi gbà pé ìtàn àròsọ lásán làwọn àkọ́sílẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá tó wà nínú Bíbélì. Wọ́n gbà pé ohun tó yẹ káwa akẹ́kọ̀ọ́ gbà gbọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nílẹ̀ Faransé sọ pé: “Ó máa ń ya àwọn tíṣà iléèwé mi lẹ́nu pé àwa akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣì wà tá a gba ohun tó wà nínú Bíbélì gbọ́.”

2 Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọ wa àtẹ̀yin ọ̀dọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà nìyẹn? Ṣé àwọn ọmọ iléèwé rẹ náà máa ń fẹ́ kó o tẹ̀ síbi táyé tẹ̀ sí, kó o gbà pé ẹfolúṣọ̀n ló mú káwọn nǹkan wà dípò Ẹlẹ́dàá? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe táá mú kí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ẹlẹ́dàá túbọ̀ lágbára. Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o lo làákàyè rẹ torí pé ó “máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.” Kò ní jẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀kọ́ ayé yìí ba ìgbàgbọ́ rẹ jẹ́.Ka Òwe 2:10-12.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Kó o tó lè nígbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, o gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. (1 Tím. 2:4) Torí náà, tó o bá ń ka Bíbélì tàbí àwọn ìwé wa, má kàn máa wò wọ́n gààràgà, ṣe ni kó o fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ wọn.  Máa ronú lé ohun tó ò ń kà, kó o lè lóye rẹ̀. (Mát. 13:23) Tó o bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́, wàá túbọ̀ rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan àti pé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Bíbélì. Ní báyìí, a máa jíròrò bó o ṣe lè máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀.Héb. 11:1.

BÓ O ṢE LÈ MÚ KÍ ÌGBÀGBỌ́ RẸ TÚBỌ̀ LÁGBÁRA

4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó kan ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ yálà èèyàn gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan tàbí pé ipasẹ̀ ẹfolúṣọ̀n ni wọ́n fi wà? Kí ló gba pé kéèyàn ṣe?

4 Ǹjẹ́ ẹnì kan ti sọ fún ẹ rí pé òun gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ torí pé ẹ̀rí wà nínú sáyẹ́ǹsì pé òótọ́ ni, ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, àfi kéèyàn ṣáà ti gbà á gbọ́? Ohun táwọn kan gbà gbọ́ nìyẹn. Àmọ́ ohun kan rèé tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Yálà ẹfolúṣọ̀n lẹnì kan gbà tàbí Ọlọ́run, déwọ̀n àyè kan ó kan ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Kò sẹ́nì kan nínú wa tó rí Ọlọ́run rí, bẹ́ẹ̀ la ò sí níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn nǹkan. (Jòh. 1:18) Bákan náà ni kò sí ẹnì kankan láyé yìí, títí kan àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó lè sọ pé òun rí aláǹgbá tó di àmọ̀tẹ́kùn tàbí ọ̀nì tó di erin. (Jóòbù 38:1, 4) Torí náà, ó gba pé kí gbogbo wa gbé ẹ̀rí tó wà nílẹ̀ wò, ká ronú lé e lórí ká sì dórí ìpinnu. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, ó sọ pé: “Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní àwíjàre.”Róòmù 1:20.

Máa lo àwọn ohun tí ètò Jèhófà fún wa tó wà lédè rẹ nígbà tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 5)

5. Àwọn nǹkan wo ni ètò Ọlọ́run fún wa ká lè fòye mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan?

5 Ohun téèyàn ò rí dáadáa tàbí téèyàn ń wò lọ́ọ̀ọ́kán la sábà máa ń fi òye mọ̀. (Héb. 11:3) Torí náà, olóye èèyàn máa ń ronú jinlẹ̀, láfikún sí ohun tó fojú rí àtohun tó fetí gbọ́. Ètò Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀ ìwádìí, wọ́n sì ti ṣàkójọ àwọn ìwádìí náà kó lè ràn wá lọ́wọ́. Àwọn nǹkan yìí ń jẹ́ ká lè máa fojú ìgbàgbọ́ rí Ẹlẹ́dàá wa. (Héb. 11:27) Lára ohun tí ètò Ọlọ́run fún wa làwọn ìtẹ̀jáde bíi fídíò The Wonders of Creation Reveal God’s Glory, àwọn ìwé pẹlẹbẹ tá a pè ní Was Life Created? àti The Origin of Life—Five Questions Worth Asking, òmíràn ni ìwé Is There a Creator Who Cares About  You? Yàtọ̀ sáwọn yìí, àwọn àpilẹ̀kọ tó ń múni ronú jinlẹ̀ tún ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn wa. A tún máa ń kà nípa àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn míì nínú ìwé ìròyìn Jí! tí wọ́n ṣàlàyé ohun tó mú kí wọ́n wá gbà pé Ọlọ́run wà. Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan àràmàǹdà tó yí wa ká. Ó ṣe tán, àwọn nǹkan àràmàǹdà tó yí wa ká yìí làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń wò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe jáde, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

6. Sọ díẹ̀ lára àwọn àǹfààní táwọn kan ti rí bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ìtẹ̀jáde tí ètò Ọlọ́run fún wa. Àǹfààní wo nìwọ ti rí?

6 Ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́dún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ bó ṣe ń gbádùn ìwé pẹlẹbẹ méjì tá a sọ lẹ́ẹ̀kan, ó ní: “Mi ò jẹ́ fàwọn ìwé yẹn ṣeré. Àkàtúnkà ni mo fi ṣe, ó ti tó ẹ̀ẹ̀mejìlá tí mo ti kà á.” Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Faransé sọ pé: “Kò sígbà táwọn àpilẹ̀kọ ‘Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?’ kì í yà mí lẹ́nu! Wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé kò sí bí ẹnjiníà kan ṣe gbóná tó, iwájú láá máa bá Ẹlẹ́dàá.” Lórílẹ̀-èdè South Africa, tọkọtaya kan tó ní ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kan sọ pé: “Ibi tọ́mọ wa kọ́kọ́ máa ń kà nínú Jí! ni apá tí wọ́n pè ní ‘Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.’ ” Ìwọ ńkọ́? Ṣé o máa ń jadùn àwọn ohun tí ètò Ọlọ́run ń fún wa? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ ẹ á dà bí igi tó ta gbòǹgbò gan-an. O sì mọ̀ pé igi tó ta gbòǹgbò kì í bẹ̀rù ìjì, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ tìẹ náà ṣe máa dúró digbí lójú ẹ̀kọ́ èké.Jer. 17:5-8.

ṢÉ O GBÀ PÉ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN NI BÍBÉLÌ?

7. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fẹ́ ká máa lo làákàyè wa?

7 Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa béèrè bóyá ìwé Ọlọ́run ni Bíbélì? Ó bọ́gbọ́n mu dáadáa! Jèhófà fẹ́ ká lo làákàyè wa kí ohun tá a gbà gbọ́ lè dá wa lójú. Kò fẹ́ ká gba ohun kan gbọ́ torí pé àwọn míì gba ohun náà gbọ́. Torí náà, máa ronú jinlẹ̀ kóhun tó ò ń kọ́ lè dá ẹ lójú. Tí ohun tó o kọ́ yìí bá ti dá ẹ lójú, á mú kó o ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. (Ka Róòmù 12:1, 2; 1 Tímótì 2:4.) Ohun kan tó o lè ṣe ni pé kó o dìídì ṣètò àwọn kókó kan tó o fẹ́ ṣèwádìí nípa rẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an.

8, 9. (a) Àwọn nǹkan wo la lè ṣèwádìí nípa rẹ̀? (b) Àǹfààní wo làwọn kan ti rí torí pé wọ́n ronú lé ohun tí wọ́n kà?

8 Lára ohun táwọn kan ṣèwádìí nípa rẹ̀ ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì, wọ́n tún wá ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ làwọn ìtàn inú Bíbélì, àti bí sáyẹ́ǹsì àtàwọn awalẹ̀pìtàn ṣe ti Bíbélì lẹ́yìn. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan téèyàn á fẹ́ ṣèwádìí nípa rẹ̀ ni Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Ẹsẹ yìí ló jẹ́ ká mọ àkòrí Bíbélì lódindi, ìyẹn ni pé Jèhófà máa lo Ìjọba rẹ̀ láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, á sì jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn lo èdè àpèjúwe láti jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe máa dá aráyé nídè kúrò lọ́wọ́ ìyà táráyé ti ń jẹ látọjọ́ Ádámù. Ọ̀nà wo lo lè gbà ṣèwádìí nípa Jẹ́nẹ́sísì 3:15? Ọ̀nà kan ni pé kó o ṣàkọsílẹ̀ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì ṣe wáyé. Bó o ṣe ń ṣèwádìí, máa kíyè sí àwọn ibi tí Bíbélì ti tọ́ka sí àwọn tọ́rọ̀ kàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, àti bó ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ. Kọ àwọn ẹsẹ yẹn sílẹ̀, wàá wá rí i pé ńṣe làwọn ẹsẹ yẹn so kọ́ra, ọ̀kan tẹ̀lé èkejì, á sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé òótọ́ ni pé ẹ̀mí mímọ́ ló darí àwọn wòlíì àtàwọn míì tó kọ Bíbélì.2 Pét. 1:21.

9 Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ni Bíbélì sọ látìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, nǹkan bí ogójì [40] ọkùnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló kọ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ wọn ò gbé níbì kan náà, wọn ò sì gbáyé lásìkò kan náà.” Àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa àjọyọ̀ Ìrékọjá nínú Ilé Ìṣọ́ December 15, 2013, ló wú arábìnrin kan  lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà lórí. Àpilẹ̀kọ náà sọ bí àjọyọ̀ yẹn ṣe kan àsọtẹ́lẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì 3:15 àti bí Mèsáyà ṣe máa fara rẹ̀ rúbọ. Arábìnrin yẹn sọ pé: “Àpilẹ̀kọ yẹn mú kí n túbọ̀ gbà pé Jèhófà ò láfiwé. Ìyàlẹ́nu gbáà ni pé, àjọyọ̀ Ìrékọjá tó dìídì ṣètò torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà ló tún wá dèyí tí Jésù mú ṣẹ! Nígbà tí mo ka àpilẹ̀kọ náà débì kan, mo dúró, mo wá ronú lọ gbári, pé àjọyọ̀ ọjọ́sí ni Jésù wá mú ṣẹ yìí, ó ga o!” Kí ló mú kọ́rọ̀ yìí wọ arábìnrin náà lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀? Ó ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó kà, ó sì lóye rẹ̀. Ohun tó ṣe yẹn mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára, ó sì jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.Mát. 13:23.

10. Kí ni sísọ táwọn tó kọ Bíbélì sòótọ́ mú kó túbọ̀ dá ẹ lójú nípa Bíbélì?

10 Ohun míì tó tún lè mú kí ìgbàgbọ́ ẹni lágbára ni pé kó máa ronú lórí báwọn tó kọ Bíbélì ṣe lo ìgboyà, tí wọn ò sì fi dúdú pe funfun. Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín àwọn tó kọ Bíbélì àtàwọn òǹkọ̀wé míì láyé ọjọ́un. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òǹkọ̀wé míì láyé ọjọ́un máa ń pọ́n àwọn aṣáájú wọn ju bó ṣe yẹ lọ, wọ́n sì máa ń gbógo fún orílẹ̀-èdè wọn. Àmọ́, ní ti àwọn wòlíì Jèhófà, bọ́rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ ni wọ́n máa ń sọ. Wọn ò daṣọ bo àṣìṣe àwọn èèyàn wọn, títí kan tàwọn ọba wọn. (2 Kíró. 16:9, 10; 24:18-22) Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò bo àṣìṣe tiwọn àti tàwọn míì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. (2 Sám. 12:1-14; Máàkù 14:50) Ọ̀dọ́kùnrin kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Kò sí òótọ́ lẹ́nu àwọn èèyàn ayé. Báwọn tó kọ Bíbélì ṣe sòótọ́ mú kó túbọ̀ dá mi lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.”

11. Kí ló máa mú káwọn ọ̀dọ́ túbọ̀ mọyì àwọn ìlànà Bíbélì?

11 Torí pé àwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣe wá láǹfààní làwọn kan ṣe gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. (Ka Sáàmù 19:7-11.) Ọ̀dọ́bìnrin kan lórílẹ̀-èdè Japan sọ pé: “Inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń fi ìlànà Bíbélì sílò ní ìdílé wa. Àlàáfíà wà láàárín wa, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan sì jọba nílé wa.” Ó ṣe kedere pé àwọn ìlànà Bíbélì ń dáàbò bò wá torí pé a kì í lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké àtàwọn àṣà tó ń mú àwọn èèyàn lẹ́rú. (Sm. 115:3-8) Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn tó gbà pé kò sí Ọlọ́run máa ń ní èrò tí kò tọ́? Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ti fi nǹkan míì pe Ọlọ́run, wọn ò sì fún Jèhófà ní ògo tó yẹ ẹ́. Àwọn tó sọ pé kò sí Ọlọ́run gbà pé bí ayé yìí bá máa dáa, ọwọ́ àwa èèyàn ló wà. Àmọ́, pẹ̀lú bí nǹkan ṣe rí láyé báyìí, ó ṣe kedere pé kò sí báwa èèyàn ṣe lè mú ìgbà ọ̀tun bá ayé.Sm. 146:3, 4.

BÓ O ṢE LÈ ṢÀLÀYÉ OHUN TÓ O GBÀ GBỌ́

12, 13. Báwo lo ṣe lè fọgbọ́n ṣàlàyé fáwọn ọmọléèwé rẹ, àwọn olùkọ́ rẹ àtàwọn míì pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan àti pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì?

12 Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé fáwọn èèyàn pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan àti pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, má ṣe ronú pé o mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àwọn kan sọ pé àwọn gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́, síbẹ̀ wọ́n tún gbà pé Ọlọ́run wà. Èrò wọn ni pé ẹfolúṣọ̀n ni Ọlọ́run lò láti dá àwọn nǹkan. Àwọn míì sì gbà pé ẹfolúṣọ̀n ní láti jóòótọ́ torí pé bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wọn ò ní máa fi kọ́ni níléèwé. Ìwàkiwà tó kúnnú ìsìn ló mú káwọn míì gbà pé kò sí Ọlọ́run. Torí náà, kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé, á dáa kó o kọ́kọ́ bi ẹni náà ní ìbéèrè táá jẹ́ kó o mọ ohun tó gbà gbọ́. Tó o bá fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ, ó ṣeé ṣe kóun náà fetí sí ẹ.Títù 3:2.

13 Tẹ́nì kan bá ń ta kò ẹ́ pé kì í ṣe Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan, o lè fọgbọ́n lo ìbéèrè láti mú kẹ́ni náà ṣàlàyé ara rẹ̀. Ní kó ṣàlàyé báwọn nǹkan ṣe dáyé tó bá dá a lójú pé kò sí Ẹlẹ́dàá. Òótọ́ kan ni pé tí ohun tó kọ́kọ́ dáyé kò bá ní pa run, ó di dandan kó mú irú ara rẹ̀ jáde. Ògbógi kan nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé kíyẹn tó lè wáyé, ó pọn dandan kí ohun tó kọ́kọ́ dáyé náà (1) ní ohun  kan tó dà bí awọ táá lè dáàbò bò ó, (2) ní agbára láti mú irú ara rẹ̀ jáde, (3) ní èròjà táá jẹ́ kó lè mú irú ara rẹ̀ jáde, àti pé (4) kò gbọ́dọ̀ mú ohun tó yàtọ̀ sí òun alára jáde, torí pé ẹní bíni làá jọ. Ògbógi náà wá sọ pé: “Àwámáridìí làwọn nǹkan tó yí wa ká, títí kan àwọn nǹkan kéékèèké.”

14. Kí lo lè ṣe tó ò bá mọ bó o ṣe máa ṣàlàyé fáwọn èèyàn pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kò tọ̀nà?

14 Tó ò bá mọ bó o ṣe máa ṣàlàyé fáwọn èèyàn pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kò tọ̀nà, á dáa kó o lo àfiwé tí Pọ́ọ̀lù lò. Ó sọ pé: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Héb. 3:4) Wò ó ná, ṣé a rẹ́ni tó máa sọ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀? Tó bá jẹ́ pé ilé kan ò lè wà láìsí ẹni tó kọ́ ọ, mélòómélòó làwọn nǹkan tó jẹ́ àwámáridìí tó yí wa ká! O sì tún lè fún àwọn tó o bá sọ̀rọ̀ ní ìtẹ̀jáde tó bá ọ̀rọ̀ yín mu. Arábìnrin kan fún ọ̀dọ́kùnrin kan láwọn ìwé pẹlẹbẹ tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan. Ọ̀dọ́kùnrin yẹn sọ pé ẹfolúṣọ̀n lòun gbà, òun ò gbà pé Ọlọ́run wà. Kò pẹ́ sígbà yẹn, ọ̀dọ́kùnrin náà sọ pé: “Mo ti wá gbà pé Ọlọ́run wà lóòótọ́.” Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, ká má fọ̀rọ̀ gùn, ọ̀dọ́kùnrin náà ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

15, 16. Ọ̀nà míì wo lo tún lè gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, kí ló sì yẹ kó o máa rántí?

15 O tún lè lo àwọn ọ̀nà yìí tó bá jẹ́ pé ẹni tẹ́ ẹ jọ ń sọ̀rọ̀ sọ pé òun ò gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Ní kó sọ ohun tó gbà gbọ́ gan-an àtohun tó nífẹ̀ẹ́ sí. (Òwe 18:13) Tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ sáyẹ́ǹsì, jẹ́ kó mọ̀ pé Bíbélì sọ àwọn nǹkan kan tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu, ó ṣeé ṣe kíyẹn wú u lórí. Àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣẹ àti pé àwọn ìtàn inú rẹ̀ jóòótọ́ ló máa mú káwọn míì nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Bákan náà, o lè sọ díẹ̀ lára àwọn ìlànà tó ṣeé mú lò nígbèésí ayé, bí èyí tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè.

16 Àmọ́ o, máa rántí pé kó o lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lo ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, kì í ṣe torí kó o lè jiyàn. Torí náà, máa fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ. Máa béèrè àwọn ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání, pọ́n àwọn èèyàn náà lé, kó o sì fi pẹ̀lẹ́tù sọ̀rọ̀, pàápàá tó bá jẹ́ àgbàlagbà lò ń bá sọ̀rọ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè gbà pẹ̀lú rẹ. Wọ́n á rí i pé ohun tó ò ń sọ dá ẹ lójú. Wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ọ̀dọ́ ló lè ṣe ohun tó ò ń ṣe. Bó ti wù kó rí, àwọn kan wà tí wọn ò ṣe tán àtiyí èrò wọn pa dà, wọ́n sì lè jẹ́ àwọn tó fẹ́ràn àtimáa fèèyàn ṣe yẹ̀yẹ́. Tó bá jẹ́ irú wọn lo bá pàdé, má ṣe fi àkókò rẹ ṣòfò lọ́dọ̀ wọn.Òwe 26:4.

SỌ ÒTÍTỌ́ DI TÌẸ

17, 18. (a) Kí ló máa jẹ́ kó o sọ òtítọ́ di tìẹ? (b) Ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 Ẹ̀kọ́ oréfèé nínú Bíbélì kò tó láti mú kéèyàn nígbàgbọ́ tó lágbára. Torí náà, máa walẹ̀ jìn tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ìgbà téèyàn ń wá ìṣúra tá a fi pa mọ́. (Òwe 2:3-6) Máa lo àwọn ohun tí ètò Jèhófà fún wa tó wà lédè rẹ. Lára wọn ni àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn Watchtower Library on DVD, òmíì ni ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower, àtàwọn ìwé bí Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bákan náà, ṣètò láti ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin. O tiẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín ọdún kan. Kò sírọ́ ńbẹ̀, téèyàn bá ń ka Bíbélì, èèyàn á nígbàgbọ́. Nígbà tí alábòójútó àyíká kan rántí ohun tó fi ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ṣe, ó ní: “Ohun tó jẹ́ kí n gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ni pé mo kà á láti páálí dé páálí. Ìgbà yẹn làwọn ìtàn Bíbélì tí wọ́n kọ́ mi ní kékeré wá túbọ̀ jẹ́ gidi sí mi. Èyí wá mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.”

18 Ẹ̀yin òbí, iṣẹ́ ńlá lẹ ní láti mú káwọn ọmọ yín nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì pinnu láti jọ́sìn rẹ̀. Kí lẹ lè ṣe táá jẹ́ kí wọ́n nígbàgbọ́ tó lágbára? Kókó yìí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.