Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  September 2016

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Káwọn Ọmọ Yín Nígbàgbọ́

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Káwọn Ọmọ Yín Nígbàgbọ́

“Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá . . . Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà.”SM. 148:12, 13.

ORIN: 88, 115

1, 2. (a) Iṣẹ́ tó nira wo làwọn òbí ní, ọ̀nà wo ni wọ́n sì lè gbà bójú tó iṣẹ́ náà? (b) Kókó mẹ́rin wo la máa jíròrò?

TỌKỌTAYA kan lórílẹ̀-èdè Faransé sọ pé: “Kéèyàn nígbàgbọ́ nínú Jèhófà kò ní káwọn ọmọ náà gba Jèhófà gbọ́. Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ogún téèyàn ń fi lé ọmọ lọ́wọ́. Báwọn ọmọ ṣe ń dàgbà ni wọ́n ń nígbàgbọ́.” Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Iṣẹ́ ńlá làwa òbí ní láti mú káwọn ọmọ wa nígbàgbọ́, mo gbà pé iṣẹ́ yìí ló nira jù lára iṣẹ́ wa. Gbogbo ọgbọ́n tá a bá ní ló yẹ ká dá. A lè dáhùn ìbéèrè wọn tán kínú wọn sì dùn, síbẹ̀ wọ́n tún lè béèrè ọ̀rọ̀ kan náà nígbà míì! Èsì tó o fún ọmọ kan lónìí tó tẹ́ ẹ lọ́rùn lè má fi bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn nígbà míì. Torí náà, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu pé àwọn ọ̀rọ̀ kan lè jẹ yọ lọ́pọ̀ ìgbà.”

2 Tó o bá ti bímọ, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò ní lè tọ́ àwọn ọmọ rẹ yanjú, kí wọ́n sì nígbàgbọ́? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, a ò lè dá a ṣe! (Jer. 10:23) Àmọ́, tá a bá gbára lé Jèhófà, àá ṣàṣeyọrí. Ẹ jẹ́ ká jíròrò nǹkan mẹ́rin tẹ́ ẹ lè ṣe káwọn ọmọ yín lè nígbàgbọ́: (1) Ẹ mọ àwọn ọmọ yín dáadáa. (2) Ẹ fọkàn sí ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ wọn. (3) Ẹ máa lo àwọn àpèjúwe tó bá a mu. (4) Ẹ máa ṣe sùúrù, kẹ́ ẹ sì máa gbàdúrà sí Jèhófà.

 MỌ ÀWỌN ỌMỌ RẸ DÁADÁA

3. Báwo làwọn òbí ṣe lè fara wé Jésù tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn ọmọ wọn?

3 Jésù máa ń fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. (Mát. 16:13-15) Á dáa kíwọ náà ṣe bíi ti Jésù. Ìgbà tí ara tu gbogbo yín ló dáa jù pé kó o ní kí wọ́n sọ tinú wọn. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kò sóhun tí wọn ò lè bá ẹ sọ, títí kan àwọn ohun tí kò dá wọn lójú. Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Dádì máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí mo gbà gbọ́, wọ́n sì máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀. Wọ́n á bi mí pé: ‘Kí ni Bíbélì sọ?’ ‘Ṣó o gbà pé òótọ́ ni Bíbélì sọ?’ ‘Kí nìdí tó o fi gbà bẹ́ẹ̀?’ Wọ́n máa ń fẹ́ kí n ṣàlàyé lọ́rọ̀ ara mi. Bí mo sì ṣe ń dàgbà sí i, wọ́n máa ń fẹ́ kí àlàyé mi túbọ̀ kún rẹ́rẹ́.”

4. Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn òbí ka ìbéèrè ọmọ wọn sí ọ̀rọ̀ ọmọdé? Sọ àpẹẹrẹ kan.

4 Tí ohun tó o kọ́ ọmọ rẹ kò bá dá a lójú, má kanra mọ́ ọn. Fara balẹ̀ ṣàlàyé fún un, kíwọ náà sì gbọ́ tiẹ̀. Bàbá kan sọ pé: “Má ṣe ka ìbéèrè ọmọ rẹ sí ọ̀rọ̀ ọmọdé. Má fojú kéré ọ̀rọ̀ rẹ̀, má sì dọ́gbọ́n yẹ ìbéèrè rẹ̀ sílẹ̀ torí pé o ò mọ bó o ṣe máa dáhùn.” Tí ọmọ rẹ bá ń béèrè ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, mọ̀ pé ṣe ló fẹ́ kó o tọ́ òun sọ́nà. Kódà nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, òun náà béèrè àwọn ìbéèrè gbankọgbì. (Ka Lúùkù 2:46.) Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Denmark sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, mo sọ fáwọn òbí mi pé mi ò rò pé ìsìn tòótọ́ là ń ṣe, dádì àti mọ́mì mi ò gba ọ̀rọ̀ mi sódì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ yẹn kọ wọ́n lóminú. Síbẹ̀, gbogbo ìbéèrè mi ni wọ́n fi Bíbélì dáhùn.”

5. Kí lẹ̀yin òbí lè ṣe táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ yín fẹsẹ̀ múlẹ̀?

5 Mọ àwọn ọmọ rẹ dáadáa, mọ ohun tí wọ́n ń rò, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn àtohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Má kàn gbà pé òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wọn kìkì torí pé wọ́n ń wá sípàdé, wọ́n sì ń bá ẹ lọ sóde ẹ̀rí. Ẹ jọ máa jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí lójoojúmọ́. Máa gbàdúrà fáwọn ọmọ rẹ, ẹ sì jọ máa gbàdúrà pọ̀. Sapá láti mọ ìgbà tí wọ́n ń kojú àdánwò, kó o sì ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ẹ FỌKÀN SÍ OHUN TẸ́ Ẹ̀ Ń KỌ́ WỌN

6. Tẹ́yin òbí bá ń bá Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde dọ́rẹ̀ẹ́, báwo nìyẹn ṣe máa ràn yín lọ́wọ́ tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn ọmọ yín?

6 Jésù mọ bá a ṣe ń kọ́ni dáadáa, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì máa ń wọni lọ́kàn torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. (Lúùkù 24:32; Jòh. 7:46) Irú ìfẹ́ yìí náà ló máa mú kí ọ̀rọ̀ àwọn òbí wọ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn. (Ka Diutarónómì 6:5-8; Lúùkù 6:45.) Torí náà, ẹ̀yin òbí, ẹ bá Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́ dáadáa. Ẹ máa kíyè sí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, kẹ́ ẹ sì máa lo àwọn ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá. (Mát. 6:26, 28) Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, òye tẹ́ ẹ ní á túbọ̀ jinlẹ̀, ẹ̀ẹ́ túbọ̀ mọyì Jèhófà, ìyẹn á sì jẹ́ kẹ́ ẹ lóhun púpọ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ yín.Lúùkù 6:40.

7, 8. Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá wà lọ́kàn ẹ̀yin òbí digbí, kí lẹ máa fẹ́ ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan.

7 Tí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá wà lọ́kàn ẹ̀yìn òbí digbí, ńṣe láá máa yá yín lára láti sọ ọ́ fáwọn ọmọ yín. Torí náà, ẹ má fi mọ sígbà tẹ́ ẹ bá ń múra ìpàdé tàbí nígbà Ìjọsìn Ìdílé nìkan. Síbẹ̀, ẹ má fipá mú wọn, ẹ jẹ́ kó máa wù wọ́n láti sọ tọkàn wọn, kó máa wà lára ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ jọ ń sọ lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, àsìkò tí tọkọtaya kan pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn bá ń wo àwọn ohun tí Ọlọ́run dá tàbí nígbà tí wọ́n bá ń jẹun ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Àwọn òbí náà sọ pé: “A máa ń fìyẹn rán àwọn ọmọ wa létí pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní àti ọgbọ́n rẹ̀ tí kò láfiwé ló mú kó fún wa láwọn nǹkan yẹn.” Àpẹẹrẹ míì ni tàwọn tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè South Africa tí wọ́n lọ́mọbìnrin méjì. Tí wọ́n bá jọ wà lóko, wọ́n máa ń fi àsìkò yẹn mú káwọn ọmọ wọn mọyì bí  irúgbìn ṣe ń hù tí wọ́n sì ń so èso. Àwọn òbí náà sọ pé: “A máa ń wá bá a ṣe máa mú káwọn ọmọ wa mọyì àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà dá.”

8 Bàbá kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà mú ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́wàá lọ síbi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí. Ìdí sì ni pé ó fẹ́ kí ìgbàgbọ́ ọmọ rẹ̀ túbọ̀ lágbára, kó sì mọyì àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Bàbá náà sọ pé: “A rí àwọn ìṣáwùrú àtàwọn ẹran omi kéékèèké míì tó ti wà rí láyé gbọ́nhan, àmọ́ tí wọn ò sí mọ́. Ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tá a rí òkú àwọn ẹran omi ayé ọjọ́un yẹn. Ẹní bá rí wọn á mọ̀ pé nígbà tí wọ́n ṣì wà, wọ́n á dùn wò, àgbàyanu sì ni wọ́n. Kódà, wọn ò yàtọ̀ sóhun tá à ń rí lónìí. Tó bá jẹ́ òótọ́ lohun táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ pé àtinú ohun tí kò jọni lójú tó wà láyé gbọ́nhan làwọn ohun àgbàyanu tó wà lóde òní ti jáde, báwo wá ni tàwọn ohun àgbàyanu ayé gbọ́nhan ṣe jẹ́? Mi ò jẹ́ gbàgbé àwọn ohun tí mo rí yẹn, mo sì jẹ́ kí ẹ̀kọ́ yìí ṣe kedere sí ọmọ mi.”

MÁA LO ÀPÈJÚWE TÓ BÁ A MU

9. Kí nìdí tó fi dáa káwọn òbí máa lo àpèjúwe? Sọ àpẹẹrẹ kan.

9 Jésù máa ń lo àpèjúwe gan-an, ìyẹn sì máa ń mú káwọn èèyàn ronú jinlẹ̀, kọ́rọ̀ rẹ̀ wọ̀ wọ́n lọ́kàn, kí wọ́n sì rántí ohun tó kọ́ wọn. (Mát. 13:34, 35) Àwọn ọmọdé kì í gbàgbé àwòrán, yálà èyí tí wọ́n fojú rí tàbí èyí tá a ṣàpèjúwe rẹ̀. Torí náà, ẹ̀yin òbí, ẹ máa lo àwòrán àti àpèjúwe dáadáa tẹ́ ẹ bá ń kọ́ wọn. Ohun tí ìyá kan lórílẹ̀-èdè Japan tó ní ọmọkùnrin méjì ṣe nìyẹn. Nígbà tí èyí àgbà wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, téyìí àbúrò sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ, ìyá wọn ṣàlàyé bójú ọ̀run ṣe rí fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló jẹ́ kó fara balẹ̀ ṣe ojú ọ̀run bẹ́ẹ̀. Kọ́rọ̀ náà lè yé wọn, ó ní kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn po tíì fún òun, ó sì fún wọn ní mílíìkì, ṣúgà àti tíì. Ìyá náà wá sọ pé: “Àwọn méjèèjì fara balẹ̀ po tíì náà. Mo wá bi wọ́n pé kí nìdí tí wọ́n fi fara balẹ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ po tíì náà bí mo ṣe máa ń fẹ́ gan-an, kó má ṣàn jù, kó má sì ki jù. Mo wá ṣàlàyé fún wọn pé bí Ọlọ́run ṣe fara balẹ̀ ṣe ojú ọ̀run nìyẹn káyé lè dùn gbé fún wa.” Ó dájú pé àpèjúwe yẹn máa yé àwọn ọmọ náà. Àbájọ táwọn ọmọ náà kò fi gbàgbé ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́!

O lè tọ́ka sí àwọn nǹkan tọ́mọ rẹ sábà máa ń rí kó lè gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan (Wo ìpínrọ̀ 10)

10, 11. (a) Àpèjúwe wo lo lè lò láti mú kọ́mọ rẹ nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Àwọn àpèjúwe wo lo ti lò, tó sì ti ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́?

10 O tún lè lo àpèjúwe oúnjẹ sísè láti mú kí ọmọ rẹ nígbàgbọ́. Báwo lo ṣe lè lò ó? O lè jẹ́ kó mọ̀ pé bí ẹni tí kò ṣe kéèkì rí bá fẹ́ ṣe é, ó lè wo àkọsílẹ̀ nípa béèyàn ṣe ń ṣe kéèkì. Lẹ́yìn náà, fún ọmọ rẹ ní èso ápù, kó o wá bi í pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ápù yìí náà ní àkọsílẹ̀?” Gé ápù náà sí méjì, kó o sì fún un ní kóró inú rẹ̀. Ṣàlàyé fún un pé, kóró tí kò ju bíńtín lọ yẹn ló hù, tó wá dàgbà di igi tó ń so èso ápù tá à ń gbádùn, tó sì ń ṣara lóore.” Wá bi í pé: “Tó bá jẹ́nì kan ló ṣàkọsílẹ̀ bá a ṣe máa ṣe kéèkì, ṣé kóró bíńtín tó di igi máa wà láìsí ẹni tó dá a?” Tọ́mọ rẹ bá ti tójú bọ́,  jẹ́ kó mọ̀ pé ohun tó ń mú kí kóró bíńtín yẹn di igi tó ń so èso ápù ti wà lákọọ́lẹ̀ nínú ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pè ní DNA. Ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ tiẹ̀ lè jọ wo àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ The Origin of Life—Five Questions Worth Asking, ojú ìwé 10 sí 20.

11 Àwọn òbí kan máa ń lo àpilẹ̀kọ “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” tó máa ń jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! láti kọ́ àwọn ọmọ wọn. Nígbà míì, wọ́n máa ń lo àwọn àpilẹ̀kọ yẹn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kéékèèké láwọn ẹ̀kọ́ tí kò ṣòro lóye. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè Denmark fi ọkọ̀ òfuurufú wé ẹyẹ. Wọ́n sọ pé: “Lóòótọ́ ọkọ̀ òfuurufú jọ ẹyẹ, àmọ́ ẹyẹ máa ń yé ẹyin, ó sì máa ń pamọ, ṣé ọkọ̀ òfuurufú lè bí ọkọ̀ òfuurufú míì? Kò síbi tẹ́yẹ ò lè bà sí, àmọ́ ṣé ibikíbi ni ọkọ̀ òfuurufú lè bà sí bíi ti ẹyẹ? Ǹjẹ́ a lè sọ pé ariwo ọkọ̀ òfuurufú àti orin aládùn tí ẹyẹ máa ń kọ jọra? Ta ni a lè sọ pé ọgbọ́n rẹ̀ pọ̀ jù, ṣé ẹni tó ṣe ọkọ̀ òfuurufú ni àbí Ẹlẹ́dàá tó dá ẹyẹ?” Ó dájú pé àpèjúwe yìí, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání máa mú kí ọmọ rẹ ronú jinlẹ̀, á sì jẹ́ kó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.Òwe 2:10-12.

12. Báwo lo ṣe lè lo àpèjúwe láti mú kí ọmọ rẹ gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì?

12 Àpèjúwe tó gbéṣẹ́ tún lè mú kó túbọ̀ dá ọmọ rẹ lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jóòbù 26:7. (Kà á.) Kí lo lè ṣe láti mú kọ́mọ rẹ gbà pé Jèhófà ló mí sí Jóòbù láti sọ̀rọ̀ yẹn? O kàn lè sọ fún un pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣáà ni. Dípò bẹ́ẹ̀, o ò ṣe wọ́nà àtimú kọ́rọ̀ náà túbọ̀ yé ọmọ rẹ? Rán an létí pé ìgbà tí kò sí awò téèyàn fi ń wo sánmà tàbí ọkọ̀ òfuurufú ni Jóòbù gbáyé. Ní kí ọmọ rẹ ṣàlàyé bó ti rọrùn tó fáwọn èèyàn ìgbà yẹn láti gbà pé bí ayé yìí ṣe tóbi tó, ṣe ló rọ̀ dirodiro láìsí ohun tó gbé e dúró. Wá sọ fún un pé kó wò ó bóyá bọ́ọ̀lù tàbí òkúta kan lè dá dúró sójú òfuurufú láìsí ohun tó dì í mú. Síbẹ̀, òótọ́ lohun tí ẹsẹ yẹn sọ, ayé ò dúró sórí ohunkóhun. Àpèjúwe yìí máa jẹ́ kí ọmọ rẹ gbà pé Jèhófà ló jẹ́ kí Jóòbù mọ òótọ́ yẹn, torí pé ó pẹ́ káwọn èèyàn tó wá mọ̀ pé kò sí ohun tó gbé ayé dúró.Neh. 9:6.

JẸ́ KÍ WỌ́N MỌ̀ PÉ ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ ṢÀǸFÀÀNÍ

13, 14. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè mú káwọn ọmọ yín gbà pé ìlànà Bíbélì ń ṣeni láǹfààní?

13 Ó tún ṣe pàtàkì gan-an pé kó o kọ́ àwọn ọmọ rẹ pé ayé wọn á dùn bí oyin bí wọ́n bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. (Ka Sáàmù 1:1-3.) Onírúurú ọ̀nà lo lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní kí wọ́n wò ó bíi pé àwọn fẹ́ lọ gbé níbi àdádó kan, táwọn míì á sì máa bá wọn gbé níbẹ̀. Wá bi wọ́n pé: “Tẹ́ ẹ bá fẹ́ máa wà ní àlàáfíà, irú ìwà wo lẹ máa fẹ́ káwọn tẹ́ ẹ jọ ń gbé máa hù?” Lẹ́yìn náà, ẹ jọ jíròrò irú àwọn ànímọ́ tó yẹ káwa Kristẹni ní bó ṣe wà nínú Gálátíà 5:19-23.

14 Tó o bá ń kọ́ wọn bẹ́ẹ̀, ó kéré tán àwọn ọmọ rẹ á kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì. Àkọ́kọ́, wọ́n á mọ̀ pé tá a bá ń fi ìlànà Ọlọ́run sílò, àá wà lálàáfíà, àá sì wà níṣọ̀kan. Ìkejì, á ṣe kedere sí wọn pé bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ lónìí, ńṣe ni Jèhófà ń múra wa sílẹ̀ láti gbénú ayé tuntun. (Aísá. 54:13; Jòh. 17:3) O lè wá lo àwọn ìrírí tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa láti mú kí ẹ̀kọ́ yìí wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, o lè lo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà,” tó wà nínu ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Tàbí kẹ̀, tẹ́nì kan bá wà níjọ yín tó ṣe àwọn àyípadà tó lágbára kó tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè ní kónítọ̀hún sọ ìrírí rẹ̀ fún yín. Àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn rí i pé ìlànà Bíbélì ń ṣeni láǹfààní gan-an!Héb. 4:12.

15. Kí ló yẹ kẹ́yin òbí máa fi sọ́kàn tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn ọmọ yín?

15 Kókó kan rèé: Má ṣe máa kọ́ wọn lọ́nà kan ṣáá, kó má bàa sú wọn. Máa ronú àwọn  ọ̀nà míì tó o tún lè lò. Béèrè àwọn ìbéèrè táá mú wọn ronú jinlẹ̀, má sì sọ ohun tí kò ní yé wọn. Mú kí ìjíròrò náà lárinrin, kó sì gbé wọn ró. Bàbá kan sọ pé: “Máa ronú onírúurú ọ̀nà tó o lè gbà ṣàlàyé ohun tó o ti ṣàlàyé fún wọn tẹ́lẹ̀, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ.”

JẸ́ OLÓÒÓTỌ́, MÁA ṢE SÙÚRÙ, KÓ O SÌ MÁA GBÀDÚRÀ

16. Kí nìdí tó fi yẹ kẹ́yin òbí máa ṣe sùúrù tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn ọmọ yín? Sọ àpẹẹrẹ kan.

16 Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń mú kéèyàn nígbàgbọ́. (Gál. 5:22, 23) Bí èso ni ìgbàgbọ́ rí, ó máa ń gba àkókò kó tó dàgbà. Torí náà, ẹ̀yin òbí ní láti máa ṣe sùúrù tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ má sì jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú yín. Bàbá kan lórílẹ̀-èdè Japan tó lọ́mọ méjì sọ pé: “Ohun témi àtìyàwó mi ṣe ni pé a máa ń wá àyè fáwọn ọmọ wa. Mo máa ń fi ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lójoojúmọ́ látìgbà tí wọ́n ti wà ní kékeré, àyàfi ọjọ́ tá a bá ń lọ sípàdé. Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ò pọ̀ jù fún wa, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ga wọ́n lára.” Alábòójútó àyíká kan sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló wà lọ́kàn mi tí mi ò lè béèrè tán. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yẹn nípàdé, ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ìgbà Ìjọsìn Ìdílé tàbí ìgbà tí mò ń dá kẹ́kọ̀ọ́ ni màá rí àwọn ìdáhùn náà. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kẹ́yin òbí máa kọ́ àwọn ọmọ yín.”

Kó o tó lè kọ́ ọmọ rẹ dáadáa, ìwọ alára gbọ́dọ̀ fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ́kàn (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn òbí fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn, báwo làwọn tọkọtaya kan ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn ọmọbìnrin wọn?

17 Ohun míì ni pé kó o fi àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tìẹ kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Àwọn ọmọ rẹ máa kíyè sí ohun tí ìwọ fúnra rẹ ń ṣe, àwọn náà á sì máa ṣe bíi tìẹ. Torí náà, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára. Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ rí i pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ohun tí tọkọtaya kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Bermuda máa ń ṣe tí wọ́n bá ní ìdààmú ọkàn ni pé, wọ́n á pe àwọn ọmọ wọn, wọ́n á sì jọ gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà. Wọ́n tún máa ń rọ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà láyè ara wọn. Àwọn tọkọtaya náà sọ pé: “A máa ń sọ fún ọmọbìnrin wa àgbà pé, ‘Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, máa lo ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, má sì máa ṣàníyàn ju bó ti yẹ lọ.’ Nígbà tóun náà bá wá rí bí nǹkan ṣe pa dà rí fún wa, ó máa ń gbà pé Jèhófà ló ràn wá lọ́wọ́. Èyí ti mú kí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára, ó sì túbọ̀ dá a lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.”

18. Kí lẹ̀yin òbí gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn?

18 Òótọ́ kan ni pé ọmọ kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe máa lágbára tó. Àmọ́ ẹ̀yin òbí lè gbin ohun tó dáa sọ́kàn wọn, kẹ́ ẹ sì bomi rin ín. A mọ̀ pé Ọlọ́run nìkan ló lè mú kí irúgbìn náà dàgbà. (1 Kọ́r. 3:6) Torí náà, gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́, kó o sì sapá gan-an láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Ọlọ́run máa bù kún ìsapá rẹ.Éfé. 6:4.