Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jósẹ́fù ará Arimatíà Lo Ìgboyà

Jósẹ́fù ará Arimatíà Lo Ìgboyà

JÓSẸ́FÙ ARÁ ARIMATÍÀ ò mọ̀ pé òun lè láyà láti lọ bá Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà. Ìdí ni pé àwọn èèyàn mọ gómìnà náà sí olóríkunkun ẹ̀dá. Síbẹ̀, tí wọ́n bá máa sin Jésù lọ́nà tó yẹ, ẹnì kan gbọ́dọ̀ lọ bá Pílátù kó lè yọ̀ǹda òkú Jésù. Nígbà tí Jósẹ́fù lọ bá Pílátù, ọ̀rọ̀ náà ò le tó bí Jósẹ́fù ṣe rò. Lẹ́yìn tí Pílátù rí àrídájú pé Jésù ti kú, ó yọ̀ǹda òkú rẹ̀ fún Jósẹ́fù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkàn Jósẹ́fù ṣì gbọgbẹ́, ṣe ló sáré pa dà síbi tí wọ́n ti pa Jésù.​— Máàkù 15:​42-45.

  • Ta ni Jósẹ́fù ará Arimatíà?

  • Kí ló pa òun àti Jésù pọ̀?

  • Kí lo lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí?

 Ọ̀KAN LÁRA ÌGBÌMỌ̀ SÀNHẸ́DÍRÌN

Ìwé Ìhìn Rere Máàkù sọ pé Jósẹ́fù jẹ́ “mẹ́ńbà kan tí ó ní ìsì rere nínú Àjọ Ìgbìmọ̀,” èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn. Àwọn ló máa ń bójú tó ẹjọ́ nílé ẹjọ́ gíga àwọn Júù, àwọn náà ló sì ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìlú. (Máàkù 15:​1, 43) Torí náà, ọ̀kan lára àwọn aṣáájú àwọn Júù ni Jósẹ́fù, èyí ló mú kó lè bá gómìnà náà sọ̀rọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ pé Jósẹ́fù jẹ́ ọlọ́rọ̀.​— Mát. 27: 57.

Ṣé ojú kì í tì ẹ́ láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni ẹ́?

Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ló kórìíra Jésù, àwọn náà ló sì gbìmọ̀ pọ̀ tí wọ́n fi pa á. Àmọ́ Bíbélì sọ pé Jósẹ́fù jẹ́ “ọkùnrin rere àti olódodo.” (Lúùkù 23:50) Jósẹ́fù ò dà bí ọ̀pọ̀ lára àwọn yòókù nínú ìgbìmọ̀ náà, olóòótọ́ èèyàn ni, kì í hu ìwàkiwà, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti pa òfin Ọlọ́run mọ́. Bíbélì tún sọ pé Jósẹ́fù ń “dúró de Ìjọba Ọlọ́run,” bóyá ìyẹn náà ló mú kó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Máàkù 15:43; Mát. 27:57) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó mú kí Jósẹ́fù nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Jésù ni pé òun fúnra rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo.

ỌMỌ Ẹ̀YÌN ÌKỌ̀KỌ̀

Jòhánù 19:38 sọ pé Jósẹ́fù “jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún àwọn Júù.” Kí ló ń ba Jósẹ́fù lẹ́rù? Ó mọ̀ pé àwọn Júù kórìíra Jésù, wọ́n sì ti pinnu pé àwọn máa lé ẹnikẹ́ni tó bá gba Jésù gbọ́ kúrò nínú sínágọ́gù. (Jòh. 7:​45-49; 9:22) Ojú burúkú ni wọ́n fi máa ń wo ẹni tí wọ́n bá lé kúrò ní sínágọ́gù, wọ́n sì máa ń ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí ẹni ẹ̀tẹ́ láwùjọ. Ìyẹn ló mú kó ṣòro fún Jósẹ́fù láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun gba Jésù gbọ́. Torí tí wọ́n bá mọ̀ pẹ́nrẹ́n, ṣe ni wọ́n máa yọ ọ́ nínú ìgbìmọ̀ náà.

Jósẹ́fù nìkan kọ́ ló n bẹ̀rù àtijẹ́wọ́ Jésù. Jòhánù 12:42 sọ pé, “ọ̀pọ̀ lára àwọn olùṣàkóso pàápàá ní ìgbàgbọ́ nínú [Jésù] ní ti gidi, ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisí wọn kì í jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má bàa lé wọn jáde kúrò nínú sínágọ́gù.” Lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Nikodémù tóun náà jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn.​— Jòh. 3:​1-10; 7:​50-52.

Àmọ́ ọmọ ẹ̀yìn ni Jósẹ́fù ní tiẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀. Nǹkan ńlá nìyẹn tá a bá rántí ohun tí Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ níní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi níwájú àwọn ènìyàn, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò jẹ́wọ́ níní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi níwájú àwọn ènìyàn, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mát. 10:​32, 33) Kì í kúkú ṣe pé Jósẹ́fù sẹ́ Jésù, àmọ́ kò fẹ́ káwọn  èèyàn mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù lòun. Ìwọ ńkọ́?

Síbẹ̀, Bíbélì sọ nǹkan dáadáa tí Jósẹ́fù ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kò bá wọn lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù. (Lúùkù 23:51) Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé Jósẹ́fù ò sí níbẹ̀ nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ Jésù. Èyí ó wù kó jẹ́, ó dájú pé ó máa dun Jósẹ́fù gan-an nígbà tó rí bí wọ́n ṣe dájọ́ Jésù láìtọ́, àmọ́ kò sóhun tó lè ṣe sí i.

Ó PA DÀ ṢÈPINNU

Nígbà tí Jésù fi máa kú, Jósẹ́fù ò bẹ̀rù mọ́, ó sì ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ́wọ́. Máàkù 15:43 sọ ohun tó ṣe, ó ní: “Ó lo ìgboyà láti wọlé síwájú Pílátù, ó sì béèrè fún òkú Jésù.”

Ó ṣeé ṣe kí Jósẹ́fù wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù kú. Kódà, kí Pílátù tó mọ̀ pé Jésù ti kú lòun ti mọ̀. Ìdí nìyẹn tí Pílátù fi “ṣe kàyéfì bóyá [Jésù] ti kú” nígbà tí Jósẹ́fù béèrè fún òkú rẹ̀. (Máàkù 15:44) Ẹ jẹ́ ká gbà pé Jósẹ́fù rí bí Jésù ṣe ń jẹ̀rora lórí òpó igi oró. Ṣó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyẹn ló mú kó pinnu pé òun ò ní bẹ̀rù láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù lòun? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ bẹ́ẹ̀. Èyí ó wù kó jẹ́, Jósẹ́fù ti gbé ìgbésẹ̀ láìfi ti ẹnikẹ́ni pè, ó sì jẹ́ kó hàn pé òun kì í ṣe ọmọ ẹ̀yìn ìkọ̀kọ̀ mọ́.

JÓSẸ́FÙ SIN ÒKÚ JÉSÙ

Àwọn Júù kì í fi òkú ọ̀daràn sílẹ̀ dọjọ́ kejì, òfin sọ pé kí oòrùn tó wọ̀ ni kí wọ́n ti sin ín. (Diu. 21:​22, 23) Ńṣe làwọn ọmọ Róòmù máa ń fi òkú ọ̀daràn sílẹ̀ sórí òpó títí á fi jẹrà tàbí kí wọ́n jù ú sínú sàréè  kan ṣáá. Àmọ́ Jósẹ́fù ò fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí Jésù. Jósẹ́fù ní ibojì kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ́ sínú àpáta nítòsí ibi tí wọ́n ti pa Jésù. Ti pé wọn ò sin ẹnikẹ́ni sínú ibojì yìí rí fi hàn pé kò pẹ́ tí Jósẹ́fù kó wá sí Jerúsálẹ́mù láti Arimatíà, * ibẹ̀ ló sì fẹ́ kí wọ́n sin òun àti ìdílé òun sí. (Lúùkù 23:53; Jòh. 19:41) Inúure ńlá ni Jósẹ́fù ṣe bó ṣe sin Jésù sínú ibojì tó fẹ́ kí wọ́n sin òun sí. Yàtọ̀ síyẹn, èyí mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ tó sọ pé wọ́n máa sin Mèsáyà pẹ̀lú àwọn “ọlọ́rọ̀.”​— Aísá. 53:​5, 8, 9.

Ṣé ohunkóhun wà tó o kà sí pàtàkì ju àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà?

Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ròyìn pé lẹ́yìn tí wọ́n gbé òkú Jésù sọ̀kalẹ̀ látorí òpó, Jósẹ́fù fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì. (Mát. 27:​59-61; Máàkù 15:​46, 47; Lúùkù 23:​53, 55; Jòh. 19:​38-40) Ẹnì kan ṣoṣo tí Bíbélì mẹ́nu kàn pé ó ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ ni Nikodémù, torí Bíbélì sọ pé òun ló mú èròjà atasánsán wá tí wọ́n fi di òkú náà. Tá a bá wo ipò Jósẹ́fù àti Nikodémù láwùjọ, kò dájú pé àwọn méjèèjì ló fúnra wọn gbé òkú Jésù. Ó lè jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ wọn ló gbé òkú náà, tí wọ́n sì lọ sin ín. Èyí ó wù kó jẹ́, iṣẹ́ ńlá làwọn ọkùnrin méjèèjì yẹn ṣe, torí pé ẹnikẹ́ni tó bá fọwọ́ kan òkú máa jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, gbogbo ohun tó bá sì fara kàn máa jẹ́ aláìmọ́. (Núm. 19:11; Hág. 2:13) Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé kò ní lè sún mọ́ àwọn èèyàn, kò sì ní lè bá wọn ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá àtàwọn ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe fún odindi ọ̀sẹ̀ kan. (Núm. 9: 6) Ó ṣeé ṣe káwọn tó kù nínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn pẹ̀gàn Jósẹ́fù torí pé ó sin òkú Jésù. Síbẹ̀, kò fìyẹn pè, ó sin Jésù lọ́nà tó yẹ, ó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù lòun.

IBI TÍ ÌTÀN JÓSẸ́FÙ PARÍ SÍ

Lẹ́yìn tí wọ́n sin Jésù, Bíbélì ò mẹ́nu kan Jósẹ́fù ará Arimatíà mọ́. Èyí lè mú ká máa ronú pé: Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí i? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, a ò mọ̀. Àmọ́ tá a bá wo ohun tá a jíròrò tán yìí, kò sí àní-àní pé Jósẹ́fù jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ti di Kristẹni. Ó ṣe tán, lásìkò tí nǹkan le koko gan-an, kàkà kó bẹ̀rù, ṣe ló fi hàn pé òun nígbàgbọ́, ó sì lo ìgboyà. Ẹ̀rí tó lágbára nìyẹn jẹ́ pé ó di Kristẹni.

Ohun kan wà nínú ìtàn yìí tó yẹ kí gbogbo wa ronú jinlẹ̀ lé lórí. Ṣé ohunkóhun wà tá a kà sí pàtàkì ju àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà? Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn nǹkan tá a kà sí pàtàkì jù ni ipò wa láwùjọ, iṣẹ́ wa, àwọn ohun ìní wa, ìfẹ́ tá a ní fún ìdílé wa tàbí òmìnira tá à ń gbádùn?

^ ìpínrọ̀ 18 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Arimatíà náà ni Rámà, táwọn èèyàn wá mọ̀ lónìí sí Rentis tàbí Rantis. Rámà ni wọ́n bí wòlíì Sámúẹ́lì sí, ó sì fi nǹkan bíi máìlì méjìlélógún [22] jìn sí Jerúsálẹ́mù.​— 1 Sám. 1:​19, 20.