Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin àti Adé Kan Ń Dáàbò Bò Ẹ́

Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin àti Adé Kan Ń Dáàbò Bò Ẹ́

“Yóò sì ṣẹlẹ̀ láìkùnà bí ẹ bá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín.”​—SEK. 6:15.

ORIN: 17, 136

1, 2. Kí làwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù ń ṣe lẹ́yìn tí Sekaráyà rí ìran keje?

LẸ́YÌN tí Sekaráyà rí ìran keje, ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan láá máa rò. Jèhófà sọ pé òun máa fìyà jẹ àwọn olè àtàwọn tó ń hùwà àìṣòótọ́ míì nítorí ìwà burúkú wọn. Ó dájú pé ohun tí Jèhófà sọ yìí máa fún Sekaráyà lókun gan-an. Síbẹ̀, nǹkan ò yí pa dà, ṣe làwọn olè àtàwọn tó ń hùwà burúkú míì túbọ̀ ń gbilẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn náà ò rí ti tẹ́ńpìlì Jèhófà rò rárá. Ṣé ó dáa báwọn Júù yẹn ṣe pa iṣẹ́ tí Jèhófà fún wọn tì? Ṣé tìtorí iṣẹ́ tara wọn ni Jèhófà ṣe dá wọn nídè?

2 Sekaráyà mọ̀ pé ìgbàgbọ́ tó lágbára táwọn Júù yẹn ní ló mú kí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Àwọn ni “Ọlọ́run tòótọ́ ta ẹ̀mí [wọn] jí” kí wọ́n lè fi ilé wọn àti iṣẹ́ wọn ní Bábílónì sílẹ̀. (Ẹ́sírà 1:​2, 3, 5) Wọ́n fi ibi tí wọ́n gbé dàgbà sílẹ̀, wọ́n wá pa dà sílùú tí ọ̀pọ̀ wọn ò dé rí. Ká sọ pé iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà ò ṣe pàtàkì ni, ṣé àwọn Júù yẹn máa yááfì adúrú nǹkan bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì rin ìrìn-àjò nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan [1,000] máìlì gba àwọn òkè àtàwọn ọ̀nà tó rí gbágungbàgun?

3, 4. Àwọn ìṣòro wo làwọn Júù tó pa dà sí Jerúsálẹ́mù kojú?

 3 Kí ló ṣeé ṣe káwọn Júù yẹn máa rò bí wọ́n ṣe ń rìnrìn-àjò náà? Ó dájú pé wọ́n á máa ronú nípa bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa rí. Wọ́n ti gbọ́ nípa bí ìlú náà ṣe rẹwà tó nígbà kan. Ó sì ṣeé ṣe káwọn tó dàgbà láàárín wọn máa sọ bí tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe lẹ́wà tó. (Ẹ́sírà 3:12) Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà bá wọn rìnrìn-àjò yẹn, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ nígbà tó o bá kọ́kọ́ rí àwókù ìlú Jerúsálẹ́mù, tó o sì mọ̀ pé ibẹ̀ ni wàá máa gbé báyìí? Ṣé àyà rẹ ò ní já tó o bá rí àwọn ilé tó ti di àlàpà, tí igbó ti bò mọ́lẹ̀? Tó o bá ń rántí àwọn ògiri gìrìwò tó nípọn tó yí Bábílónì ká, ṣé ọkàn rẹ ò ní bà jẹ́ bó o ṣe ń wo àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù tó ti ya lulẹ̀? Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà ò jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Wọ́n ti rí bí Jèhófà ṣe dáàbò bò wọ́n nígbà ìrìn-àjò wọn pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Gbàrà tí wọ́n dé Jerúsálẹ́mù, ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n mọ pẹpẹ kan síbi tí tẹ́ńpìlì wà tẹ́lẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rúbọ sí Jèhófà lójoojúmọ́. (Ẹ́sírà 3:​1, 2) Téèyàn bá wo bí wọ́n ṣe fìtara bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà, ṣe ló dà bíi pé kò sóhun tó lè ṣí wọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí.

4 Yàtọ̀ sí iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì, àwọn Júù yẹn tún gbọ́dọ̀ tún ìlú wọn kọ́. Wọ́n máa tún àwọn ilé wọn kọ́, wọ́n á ṣiṣẹ́ lóko, wọ́n á sì gbọ́ bùkátà ara wọn. (Ẹ́sírà 2:70) Ká sòótọ́, iṣẹ́ náà lè kà wọ́n láyà. Ẹnu ìyẹn ni wọ́n wà táwọn tó yí wọn ká tún bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wọ́n. Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] làwọn èèyàn yẹn fi ta kò wọ́n, èyí sì mú káwọn Júù náà bẹ̀rẹ̀ sí í dẹwọ́ díẹ̀díẹ̀. (Ẹ́sírà 4:​1-4) Gbogbo nǹkan wá dojú rú lọ́dún 522 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí ọba Páṣíà ṣòfin pé wọn ò gbọ́dọ̀ kọ́ ilé kankan mọ́ ní Jerúsálẹ́mù. Ṣe ló dà bíi pé wọn ò ní lè kọ́ Jerúsálẹ́mù mọ́.​—Ẹ́sírà 4:​21-24.

5. Kí ni Jèhófà ṣe káwọn èèyàn rẹ̀ lè pa dà sẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà?

5 Ó dájú pé Jèhófà mọ ohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi fi ìran kẹjọ han Sekaráyà káwọn Júù náà lè mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì mọyì gbogbo akitiyan wọn. Ìràn náà tún jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà máa dáàbò bò wọ́n tí wọ́n bá pa dà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Táwọn Júù yẹn bá pa dà sẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà, Jèhófà jẹ́ kó dá wọn lójú pé iṣẹ́ náà á yọrí sí rere, ó ṣèlérí pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ láìkùnà bí ẹ bá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín.”​—Sek. 6:15.

KẸ̀KẸ́ ẸṢIN ÀWỌN ỌMỌ OGUN Ọ̀RUN

6. (a) Kí ni Sekaráyà kọ́kọ́ rí nínú ìran kẹjọ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí nìdí tí àwọ̀ àwọn ẹṣin náà fi yàtọ̀ síra?

6 Ìran kẹjọ tó kẹ́yìn ló fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun jù. (Ka Sekaráyà 6:​1-3.) Nínú ìran náà, Sekaráyà rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin mẹ́rin tó dira ogun tí wọ́n ń jáde “láti àárín òkè ńlá méjì, àwọn òkè ńlá náà sì jẹ́ òkè ńlá bàbà.” Àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà ní àwọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, èyí sì jẹ́ ká lè fìyàtọ̀ sáàárín àwọn tó gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà. Sekaráyà wá béèrè pé: “Kí ni ìwọ̀nyí?” (Sek. 6:4) Ó yẹ káwa náà mọ ohun tí èyí túmọ̀ sí torí pé ìran náà kàn wá.

Jèhófà ṣì ń lo àwọn áńgẹ́lì láti fún àwa èèyàn rẹ̀ lókun kí wọ́n sì dáàbò bò wá

7, 8. (a) Kí làwọn òkè méjèèjì náà ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí nìdí táwọn òkè náà fi jẹ́ bàbà?

7 Nínú Bíbélì, òkè ńlá sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ ìjọba tàbí ìṣàkóso. Òkè méjì tí Sekaráyà rí jọra pẹ̀lú òkè méjì tí wòlíì Dáníẹ́lì rí nínú ìran. Ọ̀kan lára òkè náà ṣàpẹẹrẹ ìṣàkóso Jèhófà láyé àti lọ́run, àkóso náà yóò sì wà títí láé. Òkè kejì ṣàpẹẹrẹ Ìjọba Mèsáyà lábẹ́ àkóso Jésù. (Dán. 2:​35, 45) Àtìgbà tí Jésù ti gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914 làwọn òkè méjèèjì yìí ti  ń kó ipa pàtàkì láti mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé.

8 Kí nìdí táwọn òkè náà fi jẹ́ bàbà? Ohun kan ni pé báwọn èèyàn ṣe mọyì góòlù náà ni wọ́n ṣe mọyì bàbà. Jèhófà pàṣẹ pé kí wọ́n lo bàbà nígbà tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn àti nígbà tí wọ́n ń kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́kís. 27:​1-3; 1 Ọba 7:​13-16) Torí náà, bí àwọn òkè náà ṣe jẹ́ bàbà jẹ́ ká rí i pé ìṣàkóso Jèhófà àti Ìjọba Mèsáyà kò láfiwé, èyí sì máa mú àlàáfíà àti ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún aráyé.

9. Àwọn wo ló ń gun àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà, iṣẹ́ wo sì ni Jèhófà fún wọn?

9 Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí Sekaráyà rí. Kí ni àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àtàwọn tó gùn wọ́n ṣàpẹẹrẹ? Wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ àwùjọ àwùjọ ni wọ́n wà. (Ka Sekaráyà 6:​5-8.) Wọ́n ń jáde lọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà “Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé,” wọ́n sì ní iṣẹ́ pàtàkì kan tí wọ́n fẹ́ lọ ṣe. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà fún wọn? Ó rán wọn lọ sáwọn ibì kan kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run, pàápàá lọ́wọ́ Bábílónì tí Bíbélì pè ní “ilẹ̀ àríwá.” Jèhófà máa rí i dájú pé Bábílónì ò ní kó àwọn èèyàn òun lẹ́rú mọ́. Kò sí àní-àní pé ìran tí Sekaráyà rí yìí máa fi àwọn Júù tó ń kọ́ tẹ́ńpìlì lọ́kàn balẹ̀. Wọn ò ní bẹ̀rù pé àwọn ọ̀tá máa dí àwọn lọ́wọ́ mọ́.

10. Kí làwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àtàwọn tó gùn wọ́n mú kó dá wa lójú?

10 Bíi tọjọ́ Sekaráyà, Jèhófà ń lo àwọn áńgẹ́lì láti dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀, kí wọ́n sì fún wa lókun. (Mál. 3:6; Héb. 1:​7, 14) Látìgbà tí Ísírẹ́lì tẹ̀mí ti kúrò nígbèkùn Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919, ìjọsìn mímọ́ túbọ̀ ń gbèrú láìka àtakò gbígbóná janjan táwọn ọ̀tá ń ṣe. (Ìṣí. 18:4) Torí pé àwọn áńgẹ́lì ń dáàbò bò wá, a mọ̀ pé Bábílónì Ńlá ò ní lágbára lórí wa mọ́. (Sm. 34:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkàn wa balẹ̀ pé àwa èèyàn Ọlọ́run á túbọ̀ máa gbèrú nípa tẹ̀mí. Torí náà, ìran tí Sekaráyà rí mú kó dá wa lójú pé àwọn òkè méjèèjì náà ń dáàbò bò wá.

11. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù nígbà táwọn ọ̀tá bá gbéjà kò wá?

11 Láìpẹ́, àwọn alákòóso ayé Sátánì máa kóra jọ láti pa àwa èèyàn Jèhófà run. (Ìsík. 38:​2, 10-12; Dán. 11:​40, 44, 45; Ìṣí. 19:19) Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ ogun yìí máa dà bí àwọsánmà tó bo ilẹ̀, wọ́n á sì máa gun ẹṣin bọ̀ tìbínú-tìbínú kí wọ́n lè pa wá run. (Ìsík. 38:​15, 16) * Ṣó yẹ ká bẹ̀rù? Rárá o! Ìdí ni pé àwọn ọmọ ogun ọ̀run wà lẹ́yìn wa. Nígbà táwọn alákòóso ayé Sátánì bá gbéjà kò wá nígbà ìpọ́njú ńlá, àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ ogun Jèhófà máa kóra jọ, wọ́n á dáàbò bo àwa èèyàn Ọlọ́run, wọ́n á sì pa gbogbo àwọn tó ń ta ko ìṣàkóso Jèhófà. (2 Tẹs. 1:​7, 8) Ọjọ́ ńlá lọjọ́ yẹn máa jẹ́! Àmọ́, ta ló máa ṣáájú àwọn ọmọ ogun Jèhófà?

JÈHÓFÀ DÉ ỌBA ÀTI ÀLÙFÁÀ RẸ̀ LÁDÉ

12, 13. (a) Kí ni Jèhófà ní kí Sekaráyà ṣe? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ni Èéhù náà ṣàpẹẹrẹ?

12 Sekaráyà nìkan ló rí ìran mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tí Jèhófà fi hàn án. Jèhófà wá ní kó ṣe  ohun kan tó máa fún àwọn tó ń kọ́ tẹ́ńpìlì náà lókun. (Ka Sekaráyà 6:​9-12.) Jèhófà sọ fún un pé kó gba góòlù àti fàdákà lọ́wọ́ àwọn kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti Bábílónì, ìyẹn Hélídáì, Tóbíjà àti Jedáyà. Ó sì ní kó fi góòlù àti fàdákà náà ṣe “adé títóbi lọ́lá” kan. (Sek. 6:11) Ṣé Gómìnà Serubábélì ti ẹ̀yà Júdà tó sì tún jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì ni Jèhófà ní kí Sekaráyà dé ládé náà? Rárá o. Ó dájú pé ẹnu máa ya àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn nígbà tó dé Jóṣúà Àlùfáà Àgbà ládé.

13 Ṣé bí Sekaráyà ṣe dé Jóṣúà Àlùfáà Àgbà ládé wá túmọ̀ sí pé Jóṣúà ti di ọba? Kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Jóṣúà kì í ṣe àtọmọdọ́mọ Dáfídì, torí náà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jọba. Àpẹẹrẹ ni ohun tí Sekaráyà ṣe yẹn, ó jẹ́ ká mọ̀ pé lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa yan ẹnì kan tó máa jẹ́ ọba àti àlùfáà títí láé. Bíbélì wá pe àlùfáà àgbà tí Sekaráyà dé ládé náà ní Ìrújáde tàbí Èéhù. Ìwé Mímọ́ mú kó ṣe kedere pé Jésù ni Èéhù náà.​—Aísá. 11:1; Mát. 2:23. *

14. Iṣẹ́ wo ni Jésù tó jẹ́ Ọba àti Àlùfáà Àgbà máa ṣe?

14 Jésù ni Ọba àti Àlùfáà Àgbà, òun sì tún ni aṣáájú àwọn ọmọ ogun Jèhófà. Torí náà, Jésù ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó lè dáàbò bo àwa èèyàn Jèhófà nínú ayé Sátánì yìí. (Jer. 23:​5, 6) Láìpẹ́, ó máa ṣáájú àwọn ọmọ ogun Jèhófà láti dáàbò bo àwa èèyàn Ọlọ́run, á sì ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè kó lè fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. (Ìṣí. 17:​12-14; 19:​11, 14, 15) Àmọ́ kí Jésù tó gbé ìgbésẹ̀ yìí, ó ṣì ní iṣẹ́ pàtàkì kan láti ṣe.

JÉSÙ KỌ́ TẸ́ŃPÌLÌ

15, 16. (a) Iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò àti ìyọ́mọ́ wo ló wáyé láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run, ta ló sì ṣe iṣẹ́ náà? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

15 Yàtọ̀ sí pé Jésù jẹ́ Ọba àti Àlùfáà Àgbà, Jèhófà tún yàn án pé kó “kọ́ tẹ́ńpìlì” òun. (Ka Sekaráyà 6:13.) Lóde òní, lára iṣẹ́ ìkọ́lé tí Jésù ń ṣe ni bó ṣe dá àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà nídè kúrò nígbèkùn Bábílónì Ńlá, tó sì mú ìjọ Kristẹni pa dà bọ̀ sípò lọ́dún 1919. Ó tún yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” sípò láti máa bójú tó iṣẹ́ táwa èèyàn Jèhófà ń ṣe ní apá ti ilẹ̀ ayé nínú tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí. (Mát. 24:45) Kódà, ohun tí Jésù ń ṣe báyìí ni pé ó ń yọ́ àwa èèyàn Jèhófà mọ́ kí ìjọsìn wa lè túbọ̀ jẹ́ mímọ́.​—Mál. 3:​1-3.

16 Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, òun àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa mú káwọn olóòótọ́ di pípé. Lẹ́yìn ìyẹn, kìkì àwọn tó ń fòótọ́ inú sin Jèhófà nìkan ló máa kù nínú ayé tuntun. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìjọsìn tòótọ́ á wá gbilẹ̀!

KÓPA NÍNÚ IṢẸ́ ÌKỌ́LÉ NÁÀ

17. Kí ni Jèhófà tún fi dá àwọn Júù lójú, kí nìyẹn sì mú kí wọ́n ṣe?

17 Àǹfààní wo ni ọ̀rọ̀ Sekaráyà ṣe àwọn Júù ìgbà ayé rẹ̀? Jèhófà mú kó dá wọn lójú pé òun máa dáàbò bò wọ́n àti pé wọ́n máa kọ́ ilé náà parí. Ó dájú pé ohun tí Sekaráyà sọ fún wọn yẹn fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ṣùgbọ́n, báwo làwọn kéréje yẹn ṣe máa ṣe iṣẹ́ ńlá yìí? Ọ̀rọ̀ tí Sekaráyà sọ lẹ́yìn ìyẹn mú kó dá wọn lójú pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ náà yọrí. Jèhófà sọ fún wọn pé láfikún sáwọn olóòótọ́ bíi Hélídáì, Tóbíjà àti Jedáyà, àwọn èèyàn púpọ̀ ṣì máa “wá, . . . wọn yóò sì kọ́ lára  tẹ́ńpìlì Jèhófà.” (Ka Sekaráyà 6:15.) Níwọ̀n bó ti dá àwọn Júù yẹn lójú pé Jèhófà wà lẹ́yìn àwọn, kíá ni wọ́n pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé náà láìfi àtakò pè. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Jèhófà sọ ìṣòro tó dà bí òkè di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Wọ́n mú òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ náà kúrò, wọ́n sì parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà lọ́dún 515 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Ẹ́sírà 6:22; Sek. 4:​6, 7) Àmọ́, ọ̀rọ̀ Jèhófà kọjá ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, ó kan ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò wa yìí.

Jèhófà kò ní gbàgbé ìfẹ́ tá a ní fún un láé! (Wo ìpínrọ̀ 18 àti 19)

18. Báwo lọ̀rọ̀ inú Sekaráyà 6:15 ṣe ń nímùúṣẹ lónìí?

18 Lóde òní, ẹgbàágbèje àwọn èèyàn ló ń wá sínú ètò Ọlọ́run, tinútinú ni wọ́n sì ń lo ‘àwọn ohun ìní wọn tí ó níye lórí’ láti ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń lo àkókò wọn, okun wọn àtàwọn ohun ìní wọn fún ìtìlẹ́yìn tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí. (Òwe 3:9) Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì àwọn ohun tá à ń fi ṣètìlẹyìn? Ẹ rántí pé Hélídáì, Tóbíjà àti Jedáyà ló mú àwọn ohun tí Sekaráyà fi ṣe adé náà wá. Adé yẹn wá dà bí “ìrántí” táwọn èèyàn fi ń rántí ohun tí wọ́n ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Sek. 6:14) Lọ́nà kan náà, Jèhófà kò ní gbàgbé ìfẹ́ wa àti iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. (Héb. 6:10) Títí láé ni Jèhófà á máa rántí àwọn ohun tá a ṣe.

19. Kí ló yẹ kí àwọn ìran tí Sekaráyà rí sún wa láti ṣe lónìí?

19 Gbogbo ohun tá à ń gbé ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí fi hàn pé Jèhófà ń bù kún wa àti pé Kristi ló ń darí wa. Inú ètò tí mìmì kan ò lè mì, tó sì máa wà títí láé la wà. Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn nípa ìjọsìn tòótọ́ máa ṣẹ dandan. Torí náà, jẹ́ kí inú rẹ máa dùn pé o wà lára àwọn èèyàn Jèhófà, kó o sì máa “fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run [rẹ].” Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá wà lábẹ́ ààbò Ọba àti Àlùfáà Àgbà wa àti lábẹ́ ààbò àwọn ọmọ ogun ọ̀run tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà. Torí náà, máa sa gbogbo ipá rẹ láti ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà àwọn ọmọ ogun máa bójú tó ẹ, á sì dáàbò bò ẹ́ jálẹ̀ ayé búburú yìí àti títí láé!

^ ìpínrọ̀ 11 Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2015, ojú ìwé 29 àti 30.

^ ìpínrọ̀ 13 Ọ̀rọ̀ náà “ará Násárétì” wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “èéhù.”