Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Ṣe Ìfẹ́ Rẹ̀

Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Ṣe Ìfẹ́ Rẹ̀

Nígbà tí wọ́n bi èmi àtọkọ mi pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n mi àtìyàwó rẹ̀ bóyá a ṣe tán láti gba iṣẹ́ tuntun kan, gbogbo wa fohùn ṣọ̀kan, a sì dáhùn pé, “A ṣe tán láti lọ!” Kí nìdí tá a fi pinnu láti gba iṣẹ́ tuntun yìí, báwo sì ni Jèhófà ṣe bù kún wa? Ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ ìtàn ara mi fún yín.

ÌLÚ Hemsworth lórílẹ̀-èdè England ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1923. Mo ní ẹ̀gbọ́n ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bob. Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, bàbá mi gba àwọn ìwé kan tó tú àṣírí ẹ̀sìn èké. Ohun tí Bàbá mi kà nínú ìwé yẹn wú wọn lórí gan-an torí pé wọ́n kórìíra àgàbàgebè tó wà nínú ẹ̀sìn. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, Bob Atkinson wá sí ilé wa, ó sì mú ká gbọ́ ọ̀kan lára àwọn àsọyé Arákùnrin Rutherford lórí ẹ̀rọ giramafóònù. A wá rí i pé àwọn tó ṣe ìwé tí bàbá mi kà náà ló sọ àsọyé yìí. Làwọn òbí mi bá sọ fún Arákùnrin Atkinson pé kó wá máa jẹun lọ́dọ̀ wa lálaalẹ́ kó lè máa dáhùn àwọn ìbéèrè tá a ní nínú Bíbélì. Arákùnrin yẹn sọ pé á dáa tá a bá lè máa wá sí ìpàdé nílé arákùnrin kan tí kò jìnnà púpọ̀ sí wa. Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé nìyẹn, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi dá ìjọ kan sílẹ̀ ní Hemsworth. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í gba àwọn ìránṣẹ́ àyíká sílé wa, (alábòójútó àyíká là ń pè wọ́n báyìí) a sì máa ń pe àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ń gbé tòsí pé kí wọ́n wá jẹun lọ́dọ̀ wa. Bí wọ́n ṣe ń wá sílé wa mú kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Nígbà tó yá, ìdílé wa dá okòwò kan sílẹ̀, àmọ́ bàbá mi sọ fún ẹ̀gbọ́n mi pé, “A máa pa iṣẹ́ yìí tì tó o bá pinnu pé wàá ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.” Bob gbà, ó fi ilé sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́mọ ọdún mọ́kànlélógún [21]. Lẹ́yìn ọdún méjì, èmi náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16]. Yàtọ̀ sí òpin ọ̀sẹ̀, mo sábà máa ń dá ṣiṣẹ́, káàdì ìjẹ́rìí àti ẹ̀rọ giramafóònù ni mo sì fi ń wàásù. Jèhófà bù kún iṣẹ́ ìsìn mi gan-an torí pé mo ní ẹnì kan tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, tó sì ṣèrìbọmi. Nígbà tó yá, ọ̀pọ̀ nínú ìdílé rẹ̀ ló wá sínú òtítọ́. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ètò Ọlọ́run sọ èmi àti Arábìnrin Mary Henshall di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì rán wa lọ sí ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni ní àgbègbè Cheshire.

Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́ nígbà yẹn, ìjọba sì sọ pé kí àwọn obìnrin kọ́wọ́ ti ogun náà. Torí pé òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni wá, a ronú pé ó yẹ kí ìjọba yọ̀ǹda wa torí pé wọ́n máa ń yọ̀ǹda àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ ilé ẹjọ́ ò gbà, wọ́n sì rán mi lọ sí ẹ̀wọ̀n ọjọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31]. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e nígbà tí mo pé ọmọ  ọdún mọ́kàndínlógún [19], mo ní kí wọ́n forúkọ mi kún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n gbé mi lọ sí ilé ẹjọ́, àmọ́ ilé ẹjọ́ dá mi láre nínú ẹjọ́ méjèèjì. Ní gbogbo àkókò tí nǹkan nira yìí, ẹ̀mí mímọ́ ràn mí lọ́wọ́, ó sì dà bíi pé ṣe ni Jèhófà dì mí lọ́wọ́ mú, ó sì fún mi lókun kí n lè dúró gbọin-in.​—Aísá. 41:​10, 13.

MO NÍ ALÁBÀÁṢIṢẸ́ TUNTUN

Lọ́dún 1946, mo pàdé Arthur Matthews. Arákùnrin yìí nítara gan-an, àmọ́ torí pé kò wọṣẹ́ ológun, ìjọba rán an lọ sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta. Nígbà tó dé, ó wá sí Hemsworth níbi tí àbúrò rẹ̀ tó ń jẹ́ Dennis ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Àtikékeré làwọn méjèèjì ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́dọ̀ bàbá wọn, ọ̀dọ́ sì ni wọ́n nígbà tí wọ́n ṣèrìbọmi. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ètò Ọlọ́run rán Dennis lọ sí orílẹ̀-èdè Ireland, ló bá ku Arthur nìkan ní Hemsworth. Àwọn òbí mi fẹ́ràn Arthur gan-an torí pé aṣáájú-ọ̀nà tó ń ṣiṣẹ́ kára ni, ó sì níwà ọmọlúàbí. Torí náà, wọ́n ní kó wá máa gbé lọ́dọ̀ àwọn. Tí n bá lọ kí àwọn òbí mi nílé, èmi àti Arthur la máa ń fọ abọ́ lẹ́yìn tá a bá jẹun tán. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà síra wa. Nígbà tó dọdún 1948, ìjọba tún ju Arthur sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta. Nígbà tó di January 1949, a ṣègbéyàwó, a sì pinnu pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà la máa fayé wa ṣe. A máa ń ṣọ́wó ná, Jèhófà sì bù kún wa gan-an. Bákan náà, a máa ń lo àkókò ìsinmi tá a bá ní láti bá àwọn tó ń kórè èso ṣiṣẹ́ ká lè rí owó díẹ̀, èyí mú ká lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wa lọ.

Ní Hemsworth lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó lọ́dún 1949

Kò tó ọdún méjì lẹ́yìn ìgbà yẹn ni ètò Ọlọ́run rán wa lọ sí Northern Ireland. Wọ́n kọ́kọ́ ní ká lọ sílùú Armagh, lẹ́yìn náà ìlú Newry, àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ló sì pọ̀ jù láwọn ìlú méjèèjì. Àtiwàásù ò rọrùn rárá níbẹ̀, a sì máa ń ṣọ́ra gan-an tá a bá fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Ilé tọkọtaya kan la ti máa ń ṣèpàdé, ibẹ̀ sì jìn tó máìlì mẹ́wàá síbi tá à ń gbé. Àwa bíi mẹ́jọ la máa ń pàdé níbẹ̀. Tí àwọn tọkọtaya náà bá ní ká sun ọ̀dọ̀ àwọn mọ́jú, ilẹ̀ la máa ń sùn, tó bá sì di àárọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n máa ń se oúnjẹ aládùn fún wa. Inú wa dùn pé àwọn ará ti pọ̀ gan-an lágbègbè yẹn báyìí.

“A ṢE TÁN LÁTI LỌ!”

Ká tó dé Northern Ireland ni ẹ̀gbọ́n mi àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Lottie ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe níbẹ̀. Nígbà tó dọdún 1952, àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ sí ìpàdé àgbègbè kan nílùú Belfast. Arákùnrin kan ló gba gbogbo wa sílé, pa pọ̀ pẹ̀lú Pryce Hughes tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà yẹn. Lálẹ́ ọjọ́ kan, gbogbo wa ń sọ̀rọ̀ nípa ìwé kékeré tí ètò Ọlọ́run mú jáde ní àpéjọ náà, orúkọ ìwé náà ni God’s Way Is Love, àwọn tó ń gbé ní Ireland ni wọ́n sì dìídì ṣe é fún. Arákùnrin Hughes sọ bó ṣe nira tó láti wàásù fáwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó wà ní Ireland. Àwọn àlùfáà máa ń mú káwọn èèyàn lé àwọn arákùnrin wa kúrò nílé, wọ́n sì máa ń mú káwọn jàǹdùkú gbéjà kò wá. Arákùnrin Hughes sọ pé: “A nílò àwọn tọkọtaya tó ní mọ́tò táá dara pọ̀ mọ́ wa láti pín ìwé yìí ní orílẹ̀-èdè náà.” * Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la dáhùn pé, “A ṣe tán láti lọ!” Ohun tó bí ọ̀rọ̀ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ ìtàn yìí nìyẹn.

Àwa àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà míì nínú ọ̀kadà kan tí wọ́n so kẹ̀kẹ́ mọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́

 Ibì kan táwa aṣáájú-ọ̀nà sábà máa ń dé sí nílùú Dublin ni ilé Ma Rutland. Ọjọ́ pẹ́ tí arábìnrin yìí ti ń fòótọ́ sin Jèhófà. Lẹ́yìn tá a lo àkókò díẹ̀ lọ́dọ̀ arábìnrin yìí, a ta díẹ̀ nínú àwọn ẹrù wa, làwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin bá kó sínú ọ̀kadà Bob tí wọ́n so kẹ̀kẹ́ mọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, à ń wá ibi tá a ti lè rí mọ́tò rà. A rí àlòkù mọ́tò kan rà, a sì sọ fún ẹni tó tà á fún wa pé kó bá wa gbé e wá sílé torí pé kò sẹ́ni tó mọ mọ́tò wà nínú wa. Mo rántí pé lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ṣe ni ọkọ mi jókòó sórí bẹ́ẹ̀dì tó ń ju ọwọ́ síwá sẹ́yìn bí ẹni tó ń ju jíà ọkọ̀. Nígbà tí ọkọ mi ń gbìyànjú láti gbé mọ́tò náà jáde láàárọ̀ ọjọ́ kejì, Arábìnrin Mildred Willett tó jẹ́ míṣọ́nnárì yà lọ́dọ̀ wa (arábìnrin yìí ni Arákùnrin John Barr fẹ́.) Inú wa dùn pé arábìnrin náà mọ mọ́tò wà, bó ṣe kọ́ wa ní mọ́tò nìyẹn, làwa náà bá gbìyànjú ẹ̀ wò fúngbà díẹ̀. Nígbà tó yá, a bọ́ sọ́nà.

Mọ́tò wa àti ilé alágbèérìn wa

Ní báyìí tá a ti ní mọ́tò, ó wá ku bá a ṣe máa rí ilé. Wọ́n kìlọ̀ fún wa pé ká má gbé inú ilé alágbèérìn torí pé àwọn jàǹdùkú lè sọná sí i. Àmọ́ a wá ilé títí, a ò rílé, torí náà lálẹ́ ọjọ́ yẹn, inú mọ́tò làwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sùn mọ́jú. Nígbà tó dọjọ́ kejì tá a wá ilé títí tá ò rí, a ra ilé alágbèérìn kékeré kan tó láwọn bẹ́ẹ̀dì tá a lè sùn, a sì sọ ọ́ dilé. Inú wa dùn pé a rí àwọn àgbẹ̀ tó gbà wá láyè láti páàkì ilé alágbèérìn wa sórí ilẹ̀ wọn. Tá a bá lọ wàásù, a máa lọ sáwọn ibi tó jìn tó máìlì mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ibi tá a páàkì sí. Lẹ́yìn tá a bá gbé ilé alágbèérìn wa lọ sí ibòmíì, àá wá pa dà wá síbi tá a páàkì sí tẹ́lẹ̀, ká lè wàásù fún wọn.

Ọgbọ́n tá a dá nìyẹn tá a fi lè wàásù ní gbogbo apá gúúsù orílẹ̀-èdè Ireland láìsí wàhálà púpọ̀. A pín àwọn ìwé kékeré tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún [20,000], a sì forúkọ àwọn tó fìfẹ́ hàn ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Inú wa dùn gan-an pé ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ló wà níbẹ̀ báyìí.

A PA DÀ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ ENGLAND, LẸ́YÌN NÁÀ SÍ SCOTLAND

Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run ní ká lọ máa wàásù ní gúúsù ìlú London. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, wọ́n pe Arthur láti ẹ̀ka ọ́fíìsì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pé ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká lọ́jọ́ kejì! Lẹ́yìn tá a ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀sẹ̀ kan, a lọ sí àyíká tá a ti máa ṣiṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Scotland. Kò rọrùn torí pé ọkọ mi ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè múra àwọn àsọyé rẹ̀ dáadáa, síbẹ̀ bó ṣe gbà láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún un lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà wú mi lórí gan-an. A gbádùn iṣẹ́ alábòójútó àyíká gan-an. A ti lo ọdún mélòó kan ní ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni, àmọ́ ní báyìí inú wa dùn pé a wà láàárín ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

Lọ́dún 1962, ètò Ọlọ́run ní kí ọkọ mi wá gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ olóṣù mẹ́wàá ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, á sì ku èmi nìkan nílé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wa, síbẹ̀ a pinnu pé á dáa kó lọ. Torí pé èmi nìkan ló kù nílé, ètò Ọlọ́run ní kí n pa dà sílùú Hemsworth, kí n lọ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Nígbà tí ọkọ mi pa dà dé lẹ́yìn ọdún kan, wọ́n ní ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àgbègbè, èyí máa ń mú ká rìnrìn-àjò láti orílẹ̀-èdè Scotland lọ dé àríwá England títí dé orílẹ̀-èdè Northern Ireland.

A GBA IṢẸ́ TUNTUN NÍ IRELAND

Lọ́dún 1964, Arthur gba iṣẹ́ tuntun, ètò Ọlọ́run sọ ọ́ di ìránṣẹ́ ẹ̀ka ní ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Ireland. Kò  kọ́kọ́ wù mí láti lọ torí pé a ti ń gbádùn iṣẹ́ arìnrìn-àjò wa gan-an. Àmọ́ tí n bá ronú pa dà, ṣe ni mo máa ń dúpẹ́ pé ètò Ọlọ́run fún mi láǹfààní láti ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Ká tiẹ̀ sọ pé iṣẹ́ tí Jèhófà fún ẹ ò kọ́kọ́ wù ẹ́, ohun tó dá mi lójú ni pé, tó o bá gbà á, Jèhófà máa bù kún ẹ. Ọwọ́ mi máa ń dí gan-an, mo máa ń ṣiṣẹ́ ọ́fíìsì, ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ìwé ni mo máa ń tò tàbí kí n máa dáná, kí n sì máa ṣiṣẹ́ ìmọ́tótó. A tún máa ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àgbègbè láwọn ìgbà míì, èyí ti mú ká dojúlùmọ̀ àwọn ará wa jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Bá a ṣe ń mọ àwọn ará sí i, tá a sì ń rí báwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń tẹ̀ síwájú, ṣe ni ìdè tó so wá pọ̀ túbọ̀ ń lágbára. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìbùkún yìí!

ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ MÁNIGBÀGBÉ

Ọdún 1965 la ṣe àpéjọ àgbáyé àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè Ireland, ìlú Dublin la sì ti ṣe é. * Láìka àtakò táwọn èèyàn ṣe, àpéjọ náà kẹ́sẹ járí. Àwọn tó pé jọ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [3,948], àwọn márùndínláàádọ́rin [65] ló sì ṣèrìbọmi. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500] ló wá láti orílẹ̀-èdè míì fún àpéjọ náà, gbogbo àwọn tó gbà wọ́n sílé ni ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ lẹ́tà ìdúpẹ́ sí, àwọn náà sì mọrírì ìwà rere àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n gbà sílé. Àtìgbà yẹn ni nǹkan ti yí pa dà ní Ireland.

Arthur ń kí Arákùnrin Nathan Knorr bó ṣe ń dé sí àpéjọ tá a ṣe lọ́dún 1965

Arthur mú Ìwé Ìtàn Bíbélì jáde lédè Gaelic lọ́dún 1983

Lọ́dún 1966, ètò Ọlọ́run so àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Ireland méjèèjì pa pọ̀ lábẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Dublin. Ìṣọ̀kan yìí wúni lórí torí pé ńṣe ni erékùṣù méjèèjì yapa síra wọn ní ti ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ẹ̀sìn. Inú wa dùn gan-an láti rí bí ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ṣe ń wá sínú òtítọ́, tí wọ́n sì ń sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì.

ÌYÍPADÀ MÍÌ

Nǹkan tún yí pa dà fún wa lọ́dún 2011 nígbà tí ètò Ọlọ́run so ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Ireland pa pọ̀, wọ́n sì ní ká lọ máa ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú London. Lásìkò tá à ń sọ yìí, nǹkan ò dẹrùn fún mi torí pé ara ọkọ mi ò yá rárá. Àwọn dókítà sọ pé ó ní àrùn Parkinson tó máa ń mú kí ọwọ́ àtẹsẹ̀ gbọ̀n. Nígbà tó di May 20, 2015, ọkọ mi ọ̀wọ́n ṣaláìsí lẹ́yìn ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] tá a ti jọ wà pa pọ̀.

Láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn ni mo ti máa ń ní ìsoríkọ́ àti ẹ̀dùn ọkàn, mo sì máa ń ro àròkàn. Kò sí bí mo ṣe lè gbàgbé ọkọ mi torí pé bí ìgbín bá fà, ìkarahun á tẹ̀ lé e la jọ máa ń ṣe. Àárò rẹ̀ máa ń sọ mí gan-an. Àmọ́ nírú àwọn àsìkò yìí, ṣe ni mo túbọ̀ máa ń sún mọ́ Jèhófà. Bákan náà, inú mi máa ń dùn táwọn èèyàn bá ń sọ bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ Arthur. Ṣe làwọn ọ̀rẹ́ wa ní Ireland, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà máa ń kọ lẹ́tà ìṣírí sí mi. Ìtùnú táwọn lẹ́tà yìí fún mi kọjá àfẹnusọ, bẹ́ẹ̀ sì ni àbúrò ọkọ mi tó ń jẹ́ Dennis àti Mavis ìyàwó rẹ̀ ò fi mí sílẹ̀, àwọn àtàwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tó ń jẹ́ Ruth àti Judy dúró tì mí gan-an.

Ẹsẹ Bíbélì kan tó máa ń tù mí nínú ni Aísáyà 30:​18, tó sọ pé: “Jèhófà yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún fífi ojú rere hàn sí yín, nítorí náà, yóò dìde láti fi àánú hàn sí yín. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.” Ọkàn mi balẹ̀ bí mo ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń fi sùúrù dúró de ìgbà tó máa yanjú àwọn ìṣòro wa, táá sì fún wa níṣẹ́ tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun.

Tí mo bá ronú pa dà sẹ́yìn, mo máa ń rí bí Jèhófà ṣe darí iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè Ireland àti bó ṣe bù kún iṣẹ́ náà. Mo dúpẹ́ pé Jèhófà fún mi láǹfààní láti ṣe ìwọ̀nba díẹ̀ nínú iṣẹ́ yìí. Òótọ́ pọ́ńbélé ni pé téèyàn bá ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, Jèhófà máa rọ̀jò ìbùkún lé e lórí.

^ ìpínrọ̀ 12 Wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 1988, ojú ìwé 101 àti 102 lédè Gẹ̀ẹ́sì.

^ ìpínrọ̀ 22 Wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 1988, ojú ìwé 109 sí 112 lédè Gẹ̀ẹ́sì.