Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  October 2016

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tó Dáa

Mo Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tó Dáa

Ìlú Colorado ni mo wà nígbà tí Izak Marais pè mí láti Patterson, ìpínlẹ̀ New York. Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ, mo bi í pé: “Ṣó o mọjọ́ orí mi ṣá?” Ó sì dáhùn pé: “Mo mọjọ́ orí ẹ dáadáa.” Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tó bí ọ̀rọ̀ yìí.

ÌLÚ WICHITA, ní ìpínlẹ̀ Kansas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí mi sí, ní December 10, 1936. Àwa mẹ́rin nìyá mi bí, èmi sì ni àkọ́bí. Orúkọ dádì mi ni William, ìyá mi sì ń jẹ́ Jean, Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn méjèèjì. Ìránṣẹ́ ìjọ ni dádì mi nígbà yẹn, ìyẹn orúkọ tí wọ́n máa ń pe ẹni tó ń múpò iwájú nínú ìjọ. Emma Wagner lorúkọ ìyà ìyá mi, àwọn ló sì kọ́ ìyá mi lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Lára wọn ni Gertrude Steele, tó ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì fún ọ̀pọ̀ ọdún lórílẹ̀-èdè Puerto Rico. * Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló yí mi ká tí mo lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.

MO RÁNTÍ ÀPẸẸRẸ ÀWỌN MÍÌ

Bàbá mi rèé níbi tí wọ́n ti ń fáwọn èèyàn níwèé ìròyìn

Nírọ̀lẹ́ Sátidé kan, èmi àti dádì mi wà lóde ẹ̀rí, à ń fáwọn èèyàn tó ń lọ tó ń bọ̀ ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! (tí wọ́n ń pè ní Consolation nígbà yẹn). Ọmọ ọdún márùn-ún péré ni mí. Lásìkò tí mò ń sọ yìí, wọ́n ń ja Ogun Àgbáyé Kejì lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè wa. Bá a ṣe ń fáwọn èèyàn níwèé ni dókítà kan tó ti mutí yó wá sọ́dọ̀ dádì mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bú wọn pé wọn ò lọ jagun, ó sọ pé ọ̀lẹ àti arógunsá ni wọ́n. Ó wá tọ́ dádì mi níjà, ó sì sọ pé, “O ò ṣe nà mí, ìwọ ọ̀lẹ burúkú yìí!” Ẹ̀rú bà mí gan-an, àmọ́ inú mi dùn sóhun tí dádì mi ṣe. Wọn ò tiẹ̀ dá a lóhùn, ṣe ni wọ́n kàn ń pín ìwé fáwọn èèyàn tó kóra jọ. Ẹnu ìyẹn ni wọ́n wà tí sójà kan kọjá. Bí dókítà yẹn ṣe rí sójà yẹn, ló bá ké sí sójà náà pé, “Ẹ wá gbé ọ̀lẹ afàjò yìí!” Sójà náà rí i pé ọkùnrin yẹn ti yó, ó wá sọ fún un pé, “O jẹ́ gbalé lọ kọ́tí lè dá lójú ẹ!” Báwọn méjèèjì ṣe lọ nìyẹn. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ṣọ́ọ̀bù dádì mi ni dókítà yẹn ti máa ń gẹrun torí pé ṣọ́ọ̀bù méjì ni dádì mi ní nílùú Wichita. Kò sígbà tí mo rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn tí mi kì í dúpẹ́ pé Jèhófà fún dádì mi nígboyà.

Èmi àtàwọn òbí mi rèé nígbà tá à ń lọ sípàdé àgbègbè kan nílùú Wichita, lọ́dún 1940

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́jọ, àwọn òbí mi ta ilé àtàwọn ṣọ́ọ̀bù wọn, wọ́n sì ra ọkọ̀ àfiṣelé kékeré kan, a wá kó lọ sílùú Colorado láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Ìtòsí àgbègbè kan tí wọ́n ń pè ní Grand Junction là ń gbé, àwọn òbí mi sì ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Kí wọ́n lè  gbọ́ bùkátà ìdílé, wọ́n ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, wọ́n sì ń sin ẹran. Jèhófà bù kún iṣẹ́ ìwàásù wọn torí pé ìjọ kan fìdí múlẹ̀ níbẹ̀. Nígbà tó di June 20, ọdún 1948, dádì mi ṣèrìbọmi fún mi nínú odò kan. Lára àwọn míì tí wọ́n tún ṣèrìbọmi fún ni Billie Nichols àti ìyàwó rẹ̀. Nígbà tó yá, tọkọtaya yìí di alábòójútó àyíká, ọmọ wọn ọkùnrin àti ìyàwó rẹ̀ náà sì tún di alábòójútó àyíká.

A máa ń bá àwọn ará tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kẹ́gbẹ́ gan-an, a sì jọ máa ń jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí, pàápàá jù lọ ìdílé Steele, ìyẹn Don àti Earlene, Dave àti Julia, pa pọ̀ pẹ̀lú Si àti Martha. Gbogbo wọn mú kí n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ gan-an. Wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé tí mo bá fi ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé mi, màá láyọ̀, ọkàn mi á sì balẹ̀ pé ohun tó dáa ni mo fayé mi ṣe.

MO ṢÍ LỌ SÍBÒMÍÌ

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], Arákùnrin Bud Hasty, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Dádì ní kí n wá bá òun níbi tóun wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ká lè jọ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Alábòójútó àyíká sọ fún wa pé ká lọ sílùú Ruston, ní ìpínlẹ̀ Louisiana, ká lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó wà níbẹ̀, torí pé àwọn akéde kan ti di aláìṣiṣẹ́mọ́. Alábòójútó àyíká náà sọ fún wa pé ká rí i dájú pé à ń ṣèpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ yálà àwọn èèyàn wá sípàdé tàbí wọn ò wá. A wá ibi tá a lè lò, a sì ṣàtúnṣe síbi tá a rí. Gbogbo ìpàdé là ń ṣe, àmọ́ àwọn ìgbà kan wà tó jẹ́ pé àwa méjèèjì nìkan la máa ń wà nípàdé. Tẹ́nì kan bá wà lórí pèpéle, ẹnì kejì á jókòó, á sì máa dáhùn gbogbo ìbéèrè. Tó bá sì jẹ́ pé apá tó ní àṣefihàn ni, àwa méjèèjì la jọ máa ṣe é láìsí ẹni kankan níjokòó. Nígbà tó yá, arábìnrin àgbàlagbà kan bẹ̀rẹ̀ sí í wá, àwọn mélòó kan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà sì tún ń wá, títí kan àwọn ará tó jẹ́ akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ tẹ́lẹ̀. Ká tó mọ̀, ẹsẹ̀ ti ń pọ̀ nípàdé, ìjọ sì fìdí múlẹ̀.

Lọ́jọ́ kan témi àti Arákùnrin Bud wà lóde ẹ̀rí, a bá Pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kan pàdé tó da ìbéèrè bò wá, ó tọ́ka sáwọn ẹsẹ Bíbélì kan tí mi ò lè ṣàlàyé. Ó ká mi lára pé mi ò lè dáhùn ìbéèrè rẹ̀, àmọ́ ìyẹn mú kí n sapá láti mú kóhun tí mo gbà gbọ́ túbọ̀ dá mi lójú. Torí náà, mo ṣèwádìí àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn látòru mọ́jú kí n lè mọ bí màá ṣe ṣàlàyé wọn. Ohun tí mo ṣe yẹn mú kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn mi, ó sì máa ń ṣe mí bíi pé kí n bá àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pàdé.

Kò pẹ́ sígbà yẹn, alábòójútó àyíká ní kí n lọ sílùú El Dorado, ní ìpínlẹ̀ Arkansas, láti ran ìjọ tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìjọba pè mí pé kí n wá sí àgọ́ àwọn sójà ní Colorado níbi tí wọ́n ti ń forúkọ àwọn èèyàn sílẹ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Lọ́jọ́ kan, èmi àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà kan jọ lọ sí àgọ́ yẹn, ọkọ̀ mi la sì gbé lọ. Ìgbà tá a máa dé ìlú Texas, ọkọ̀ náà jáàmù ó sì bà jẹ́ gan-an. La bá pe arákùnrin kan, arákùnrin náà sì gbé wa lọ sílé rẹ̀, a sì gbabẹ̀ lọ sípàdé wọn. Wọ́n  sọ fáwọn ará pé ọkọ̀ wa jáàmù, àwọn ará náà káàánú wa, wọ́n sì fún wa lówó. Nígbà tó yá, arákùnrin yẹn bá mi ta mọ́tò náà ní dọ́là mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25].

A rẹ́ni gbé wa lọ sílùú Wichita, níbi tí ọ̀rẹ́ dádì mi kan ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, E. F. McCartney lorúkọ rẹ̀. Àtikékeré lèmi àtàwọn ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ìbejì ti ń ṣọ̀rẹ́ bọ̀, Frank àti Francis lorúkọ àwọn méjèèjì. Wọ́n ní àlòkù mọ́tò kan tí wọ́n tà fún mi ní dọ́là mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Àbí ẹ ò rí nǹkan, iye tí mo ta mọ́tò mi tó jáàmù gan-an nìyẹn! Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tó ṣe kedere sí mi pé Jèhófà fún mi lóhun tí mo nílò torí pé ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ni mo fi sípò àkọ́kọ́ láyé mi. Àsìkò tí mo wà pẹ̀lú àwọn McCartney yẹn ni wọ́n mú mi mọ arábìnrin onítara kan, tó ń jẹ́ Bethel Crane. Màmá rẹ̀ tó ń jẹ́ Ruth nítara gan-an, ìlú Wellington ní ìpínlẹ̀ Kansas ni màmá yẹn ń gbé, ibẹ̀ ló ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà títí tó fi lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún. Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tá a pàdé, ìyẹn lọ́dún 1958, èmi àti Bethel ṣègbéyàwó, a sì jọ ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ nílùú El Dorado.

IṢẸ́ ALÁYỌ̀

Torí pé àwọn òbí wa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, àwa méjèèjì pinnu pé a ṣe tán láti lọ síbikíbi tí ètò Ọlọ́run bá ti fẹ́ lò wá. Wọ́n sọ wá di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì ní ká lọ máa sìn nílùú Walnut Ridge, ní ìpínlẹ̀ Arkansas. Lọ́dún 1962, wọ́n pè wá sí kíláàsì kẹtadínlógójì [37] ti Ìlé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Inú wa dùn nígbà tá a dé ọ̀hún, tá a wá rí i pé àwa àti Don Steele la jọ wà ní kíláàsì. Lọ́jọ́ tá a gbàwé ẹ̀rí, wọ́n ní ká lọ máa sìn ní Nairobi, lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Ẹ̀rù bà wá gan-an lọ́jọ́ tá a kúrò nílùú New York, àmọ́ ọkàn wa balẹ̀ nígbà tá a rí àwọn ará tó wá pàdé wa ní pápákọ̀ òfúúrufú nílùú Nairobi.

Èmi àtìyàwó mi rèé lóde ẹ̀rí nílùú Nairobi, pẹ̀lú Mary àti Chris Kanaiya

Kò pẹ́ tá a dé orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà tára wa fi mọlé, tá a sì ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù wa. Chris àti Mary Kanaiya làwọn tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Wọ́n ṣì ń bá iṣẹ́ alákòókò kíkún lọ dòní olónìí ní Kẹ́ńyà. Lẹ́yìn tá a lo ọdún kan ní Kẹ́ńyà, ètò Ọlọ́run gbé wa lọ sílùú Kampala, lórílẹ̀-èdè Uganda. Àwa ni míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tó sìn lórílẹ̀-èdè yẹn. A mà gbádùn iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè yẹn o! Ńṣe làwọn èèyàn ń pè wá lọ́tùn-ún lósì pé ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà, ọ̀pọ̀ wọn ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, lẹ́yìn ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tá a ti wà nílẹ̀ Áfíríkà, a pa dà sí Amẹ́ríkà ká lè ní ìdílé tiwa. Lọ́jọ́ tá a fẹ́ pa dà, àárò àwọn ará sọ wá gan-an, kódà ó ju tìgbà tá a kúrò ní Amẹ́ríkà lọ. Ìdí sì ni pé ọwọ́ ti wọwọ́ pẹ̀lú àwọn ará nílẹ̀ Áfíríkà, a sì gbà pé a máa pa dà wá lọ́jọ́ kan.

A GBA IṢẸ́ TUNTUN

Ìlú Colorado, níbi táwọn òbí mi ń gbé la pa dà sí. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, a bí Kimberly ọmọbìnrin wa àkọ́kọ́. Ní nǹkan bí ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn náà, a tún bí Stephany àbúrò rẹ̀. Ọwọ́ gidi la fi mú ọ̀rọ̀ títọ́ àwọn ọmọ wa, a sì rí i pé a kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Yàtọ̀ síyẹn, bíi tàwọn òbí wa, a tún fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn. Àmọ́, ohun kan ni pé kí òbí fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀, ohun ọ̀tọ̀ gbáà ni pé káwọn ọmọ tẹ̀lé àpẹẹrẹ wọn, kí wọ́n sì sin Jèhófà tọkàntọkàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àbúrò mi méjì ló kúrò nínú òtítọ́. Àmọ́, àdúrà wa ni pé kí wọ́n pa dà sínú ètò Jèhófà kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà táwọn òbí wa fi lélẹ̀ fún wa.

Inú wa ń dùn báwọn ọmọ wa ṣe ń fohun tá à ń kọ́ wọn sílò, a sì jọ máa ń wọ́nà àtiṣe nǹkan pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, torí pé ilé wa ò jìn sí àgbègbè Aspen, nílùú Colorado, gbogbo wa kọ́ béèyàn ṣe ń yọ̀ tẹ̀rẹ́ lórí yìnyín. Ìdí tá a fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká lè jọ máa ṣeré lórí yìnyín lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àkókò tá a fi jọ máa ń ṣeré yẹn máa ń jẹ́ ká lè bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ dáadáa. Nígbà míì, a  máa ń lọ sínú igbó lọ pàgọ́, àá dáná, àá jókòó yíká iná náà, àá sì jọ máa tàkúrọ̀sọ. Lóòótọ́ ọmọdé ni wọ́n, àmọ́ ìbéèrè wọn máa ń ju tọmọdé lọ. Lára ìbéèrè wọn ni pé: “Kí làwọn máa ṣe táwọn bá dàgbà?” àti “Irú ọkùnrin wo làwọn máa fẹ́?” Èmi àtìyá wọn sapá láti mú kí wọ́n máa ronú ohun tí wọ́n á fayé wọn ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. A jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé á dáa kí wọ́n ṣe iṣẹ́ alákòókò kíkún, kí wọ́n sì fẹ́ arákùnrin tí wọ́n jọ ní àfojúsùn kan náà. A jẹ́ kí wọ́n rí i pé á ṣe wọ́n láǹfààní tí wọn ò bá tètè lọ́kọ. A sábà máa ń sọ̀rọ̀ kan bí eré bí àwàdà, pé “Ẹ fara balẹ̀ kẹ́ ẹ pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kẹ́ ẹ tó lọ́kọ.”

Bíi tàwọn òbí wa, àwa náà ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè jọ máa lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí déédéé. A máa ń ṣètò pé káwọn ará tó wà nínú iṣẹ́ alákòókò kíkún dé sílé wa. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń sọ àwọn ìrírí tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì fún wọn. A máa ń sọ fún wọn pé lágbára Jèhófà, lọ́jọ́ kan àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin á jọ lọ sílẹ̀ Áfíríkà. Kò síjọ́ tá a sọ bẹ́ẹ̀ tí kì í wu àwọn ọmọ wa bíi pé ká ti lọ.

Bákan náà, a kì í fọ̀rọ̀ Ìjọsìn Ìdílé ṣeré, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń ṣe àṣefihàn àwọn nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ níléèwé. Àá ní káwọn ọmọbìnrin wa ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àá wá máa béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn. Bá a ṣe ń kọ́ wọn yìí ń dùn mọ́ wọn gan-an, ó sì jẹ́ kí wọ́n nígboyà láti wàásù fáwọn èèyàn. Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà sí i, nígbà míì kì í yá wọn lára láti ṣe Ìjọsìn Ìdílé. Kódà lọ́jọ́ kan tínú bí mi, mo ní kí wọ́n kọjá lọ síyàrá wọn, pé a ò ní ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tọjọ́ yẹn mọ́. Ohun tí mo ṣe yẹn yà wọ́n lẹ́nu gan-an, wọn ò mọ̀ pé mo lè sọ bẹ́ẹ̀, ni wọ́n bá bú sẹ́kún, wọ́n wá ń bẹ̀bẹ̀ pé ká ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ìgbà yẹn la wá mọ̀ pé gbogbo làálàá wa láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ò já sásán. A ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí wọ́n lè máa gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kódà a máa ń jẹ́ kí wọ́n sọ tinú wọn dáadáa. Nígbà míì tí wọ́n bá sọ pé àwọn ò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ kan nínú Bíbélì, ṣe làyà wa máa ń là gààràgà. Síbẹ̀, a máa ń fara balẹ̀ gbọ́ èrò wọn nípa ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn ìyẹn, àá bá wọn fèròwérò, wọ́n sì máa ń gbà pé èrò Jèhófà ló tọ̀nà.

A TÚN GBA ÀWỌN IṢẸ́ TUNTUN MÍÌ

Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, àwọn ọmọ wa ti dàgbà. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti ètò rẹ̀ tó ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Inú wa dùn pé nígbà táwọn ọmọ wa ṣe tán níléèwé girama, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n sì kọ́ iṣẹ́ tí wọ́n á fi máa gbọ́ bùkátà ara wọn. Àwọn àtàwọn arábìnrin méjì míì ṣí lọ sílùú Cleveland, ìpínlẹ̀ Tennessee láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. A ṣàárò wọn gan-an, àmọ́ inú wa dùn pé iṣẹ́ alákòókò kíkún ni wọ́n ń fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Èmi àti Bethel ìyàwó mi tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wa pa dà, a sì tún rí àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì tó fún wa láyọ̀. A ṣe adelé alábòójútó àyíká, a sì tún máa ń ṣèrànwọ́ láwọn àpéjọ àgbègbè.

Káwọn ọmọ wa tó lọ síbi tí àìní gbé pọ̀, wọ́n lọ ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà nílùú London lórílẹ̀-èdè England. Ibẹ̀ ni Stephany ti pàdé Paul Norton, tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] ni Stephany nígbà yẹn. Ẹ̀ẹ̀kejì tí wọ́n ṣèbẹ̀wò ni Kimberly rí ọ̀rẹ́ Paul kan tóun náà ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, Brian Llewellyn lorúkọ rẹ̀. Bó ṣe di pé gbogbo ẹ̀ tò nìyẹn o. Nígbà tí Stephany fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23], òun àti Paul ṣègbéyàwó. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Brian àti Kimberly ṣègbéyàwó nígbà tóun náà pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Torí náà, àwọn méjèèjì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún kí wọ́n tó lọ sílé ọkọ. Inú wa dùn gan-an sáwọn arákùnrin tí wọ́n yàn láti fẹ́.

Èmi àti ìyàwó mi rèé pẹ̀lú Paul, Stephany, Kimberly àti Brian ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Màláwì, lọ́dún 2002

Àwọn ọmọ wa sọ fún wa pé àpẹẹrẹ wa àti tàwọn òbí wọn àgbà ló jẹ́ káwọn náà máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́ nígbèésí ayé àwọn, kódà nígbà tí nǹkan nira. (Mát. 6:33) Ní April ọdún 1998, ètò Ọlọ́run pe Paul àti Stephany wá sí kíláàsì karùnlélọ́gọ́rùn-ún [105] ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ní kí wọ́n lọ sìn lórílẹ̀-èdè Màláwì, nílẹ̀ Áfíríkà. Ètò Ọlọ́run tún pe Brian àti Kimberly wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà nílùú London, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n ní kí wọ́n lọ máa sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Màláwì. Inú wa dùn gan-an torí a mọ̀ pé ohun tó dáa jù táwọn ọ̀dọ́ lè fayé wọn ṣe ni pé kí wọ́n lò ó nínú iṣẹ́ Ọlọ́run.

WỌ́N TÚN FÚN WA LÁǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌSÌN MÍÌ

Ní January ọdún 2001, Arákùnrin Marais pè mí lórí fóònù bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Òun ni alábòójútó Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtumọ̀, ó sọ fún mi pé ètò Ọlọ́run ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa dá àwọn atúmọ̀ èdè  tó wà láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ lóye èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lásìkò tá à ń sọ yìí, mo ti dẹni ọgọ́ta ọdún ó lé mẹ́rin [64], wọ́n sì fẹ́ kí n wà lára àwọn tó máa kọ́ wọn. Torí náà, èmi àtìyàwó mi fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, a sì fi tó àwọn màmá wa létí, ká lè mọ èrò wọn nípa ẹ̀. Wọn ò tiẹ̀ rò ó pé ẹ̀ẹ̀mejì tí wọ́n fi gbà pé ká lọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò ní sí nítòsí wọn mọ́. Bí mo ṣe pe Arákùnrin Marais pa dà nìyẹn pé a ṣe tán láti yọ̀ǹda ara wa.

Ẹ̀yìn ìyẹn ni dókítà sọ pé màámi ní àrùn jẹjẹrẹ. Mo bá sọ fún màámi pé á dáa ká dúró ká lè ṣèrànwọ́ fún Linda àbúrò mi tó ń tọ́jú wọn. Párá tí màámi máa dáhùn, wọ́n ní: “Kò sóhun tó jọ ọ́, tẹ́ ò bá lọ, ẹ̀ẹ́ dá kún àìsàn tó ń ṣe mí.” Ohun kan náà ni Linda sọ. A ò mọ bá a ṣe lè dúpẹ́ tó lọ́wọ́ wọn, a sì mọyì ìtìlẹ́yìn àwọn ará tí wọ́n jọ wà níjọ! Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tá a kúrò nílé lọ sí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní Patterson, Linda pè wá, ó sì sọ pé màámi ti kú. Ikú màámi dùn wá gan-an, àmọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ ká ṣe náà la ṣe, a tara bọ iṣẹ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà náà.

Ǹjẹ́ ẹ mọbi tí wọ́n kọ́kọ́ rán wa lọ? Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Màláwì ni, níbi táwọn ọmọ wa àtàwọn ọkọ wọn ti ń sìn. Inú wa dùn gan-an pé a tún jọ wà níbì kan náà! Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n rán wa lọ sórílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè, nígbà tá a kúrò níbẹ̀, a lọ sórílẹ̀-èdè Sáńbíà. Lẹ́yìn tá a ti fọdún mẹ́ta àtààbọ̀ kọ́ àwọn atúmọ̀ èdè lẹ́kọ̀ọ́, ètò Ọlọ́run ní ká pa dà sí Màláwì. Wọ́n ní ká ṣàkójọ ìrírí àwọn ará tó fojú winá inúnibíni lórílẹ̀-èdè yẹn, tí wọ́n sì di ìgbàgbọ́ wọn mú. *

A wà lóde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ wa

Lọ́dún 2005, a pa dà sí Amẹ́ríkà. Bíi tọjọ́sí, àárò àwọn ará yìí tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ wá. Ìlú Basalt, ní ìpínlẹ̀ Colorado la pa dà sí, à sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wa lọ. Kò pẹ́ sígbà yẹn, lọ́dún 2006, Brian àti Kimberly kó wá sítòsí wa kí wọ́n lè tọ́ àwọn ọmọbìnrin wọn méjèèjì, ìyẹn Mackenzie àti Elizabeth. Paul àti Stephany ṣì wà ní Màláwì, níbi tí Paul ti ń ṣiṣẹ́ sìn nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Ní báyìí, àgbà ti dé, mo sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọgọ́rin [80] ọdún. Bí mo bá ń rántí àwọn arákùnrin tó kéré sí mi lọ́jọ́ orí tá a ti jọ ṣiṣẹ́ láwọn ọdún yìí wá, tí wọ́n ń bójú tó iṣẹ́ tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀, ṣe ni inú mi máa ń dùn. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tó túbọ̀ ń mú kínú wa máa dùn ni àpẹẹrẹ àtàtà táwọn òbí wa àtàwọn míì fi lélẹ̀ fún wa, táwa náà sì fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ wa àtàwọn ọmọ wọn.

^ ìpínrọ̀ 5 Wo ìwé ìròyìn Ile-Iṣọ Na May 1, 1956, ojú ìwé 269 sí 272, (lédè Gẹ̀ẹ́sì) àti Ile-Iṣọ Na October 15, 1971, ojú ìwé 630 sí 634, kó o lè kà nípa iṣẹ́ míṣọ́nnárì táwọn ìdílé Steele ṣe.

^ ìpínrọ̀ 30 Àpẹẹrẹ kan ni ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Trophim Nsomba tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2015, ojú ìwé 14 sí 18.