Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

“Ẹ Má Gbàgbé Aájò Àlejò”

“Ẹ Má Gbàgbé Aájò Àlejò”

“Ẹ má gbàgbé aájò àlejò.”HÉB. 13:2,

ORIN: 124, 79

1, 2. (a) Ìṣòro wo làwọn àjèjì máa ń ní lóde òní? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá, àwọn ìbéèrè wo la sì máa jíròrò?

Ó TI lé lọ́gbọ̀n [30] ọdún báyìí tí Osei [1] ti fi Gánà tí wọ́n ti bí i sílẹ̀ lọ sílùú òyìnbó.Àmọ́ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Ó sọ pé: “Mo rí i pé àwọn èèyàn ò rí tèmi rò. Ṣe ni gbogbo ibẹ̀ tutù ringindin, kò dà bí ilé rárá. Nígbà tí mo kúrò ní pápákọ̀ òfuurufú, òtútù yẹn wọ̀ mí lára gan-an, mi ò tíì rí irú rẹ̀ rí láyé mi, ṣe ni mo bú sẹ́kún.” Torí pé Osei ò fi bẹ́ẹ̀ gbédè ìlú tó wà, ó lé lọ́dún kan kó tó rí iṣẹ́ tó lè fi máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Ní báyìí tó ti jìnnà sílé, kò rẹ́ni fojú jọ, ọkàn rẹ̀ sì ń fà sílé.

2 Jẹ́ ká sọ pé ìwọ ni Osei, báwo ni wàá ṣe fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí ẹ? Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ táwọn ará bá kí ẹ tẹ̀ríntẹ̀rín ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láìwo ti orílẹ̀-èdè tó o ti wá tàbí àwọ̀ rẹ? Bíbélì rọ àwa Kristẹni pé: “Ẹ má gbàgbé aájò àlejò.” (Héb. 13:2) Torí náà, a máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn àjèjì? Tá a bá ní èrò tí kò tọ́ nípa àwọn àjèjì, kí nìdí tó fi yẹ ká yí èrò wa pa dà? Kí la  sì lè ṣe láti mú kára tu àwọn àjèjì tó ń wá sípàdé wa?

OJÚ TÍ JÈHÓFÀ FI Ń WO ÀWỌN ÀJÈJÌ

3, 4. Bó ṣe wà nínú Ẹ́kísódù 23:9, báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe sáwọn àjèjì, kí sì nìdí?

3 Lẹ́yìn tí Jèhófà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè nílẹ̀ Íjíbítì, ó fún wọn láwọn òfin kan táá jẹ́ kí wọ́n máa fojúure hàn sáwọn àjèjì tó wà láàárín wọn. (Ẹ́kís. 12:38, 49; 22:21) Torí pé nǹkan kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣẹnuure fáwọn àjèjì, Jèhófà fìfẹ́ ṣe àwọn ètò kan táá mú kí nǹkan rọrùn fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ṣètò pé kí wọ́n máa pèéṣẹ́ nínú oko àwọn míì.Léf. 19:9, 10.

4 Jèhófà ò fi dandan lé e pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì, ṣe ló rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ro tàwọn èèyàn náà mọ́ tiwọn. (Ka Ẹ́kísódù 23:9.) Ó ṣe tán, àwọn náà mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn bá jẹ́ àjèjì nílẹ̀ ibòmíì. Ilẹ̀ Íjíbítì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé kó tó di pé àwọn èèyàn náà sọ wọ́n dẹrú. Kódà ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ará Íjíbítì ò ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì séèyàn, torí wọ́n gbà pé àwọn dáa jù wọ́n lọ àti pé ẹ̀sìn wọn ò nítumọ̀. (Jẹ́n. 43:32; 46:34; Ẹ́kís. 1:11-14) Ojú pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gan-an nígbà yẹn, àmọ́ ní báyìí tí wọ́n ti wà nílẹ̀ tiwọn, Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n fojú pọ́n àwọn àjèjì tó wà láàárín wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fẹ́ kí wọ́n kà wọ́n sí “ọmọ ìbílẹ̀” wọn.Léf. 19:33, 34.

5. Kí láá jẹ́ ká máa fojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn àjèjì wò wọ́n?

5 Ó dájú pé bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì láyé ìgbà yẹn náà ló ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn lóde òní, pàápàá jù lọ àwọn tó ń wá sípàdé wa. (Diu. 10:17-19; Mál. 3:5, 6) Tá a bá mọ àwọn ìṣòro táwọn àjèjì máa ń ní, àá máa fìfẹ́ hàn sí wọn, àá sì máa gba tiwọn rò. Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ gbédè ibi tí wọ́n wà, àwọn èèyàn sì máa ń fojú pa wọ́n rẹ́.1 Pét. 3:8.

ṢÉ OJÚ TÓ TỌ́ LO FI Ń WO ÀWỌN ÀJÈJÌ?

6, 7. Kí ló fi hàn pé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní kò jẹ́ kí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà dá ìyapa sílẹ̀ láàárín wọn?

6 Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní rí i pé ó pọn dandan káwọn má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó wà láàárín àwọn Júù dá ìyapa sílẹ̀ láàárín wọn. Nígbà ayẹyẹ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣàjọpín ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn àjèjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni. (Ìṣe 2:5, 44-47) Báwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn ará wọn tó tilẹ̀ míì wá fi hàn pé wọ́n mọ̀ pé ó yẹ káwọn máa ṣe “aájò àlejò,” tàbí lédè míì, káwọn máa “ṣe inúure sí àwọn tí wọn ò mọ̀ rí.”

7 Báwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ìgbà yẹn ṣe ń pọ̀ sí i, ó jọ pé àwọn kan láàárín wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì ń ṣàròyé pé wọn ò bójú tó àwọn opó wọn. (Ìṣe 6:1) Nígbà tọ́rọ̀ náà dé etí àwọn àpọ́sítélì, wọ́n yan àwọn ọkùnrin méje kí wọ́n lè rí i dájú pé gbogbo opó tó wà nínú ìjọ la bójú tó. Orúkọ Gíríìkì làwọn ọkùnrin méje náà ń jẹ́, tó fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì fẹ́ kára tu gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, kó má sì tún sọ́rọ̀ kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà mọ́ láàárín wọn.Ìṣe 6:2-6.

8, 9. (a) Báwo la ṣe máa mọ̀ bóyá a ti ń fojú tí kò tọ́ wo àwọn tí èdè tàbí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa? (b) Èrò wo ló yẹ ká sapá láti yí pa dà? (1 Pét. 1:22)

8 Yálà a mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí a ò mọ̀, gbogbo wa pátá ni àṣà ìbílẹ̀ wa máa ń mú ká ronú tàbí hùwà lọ́nà kan. (Róòmù 12:2) Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe káwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn tá a jọ wà níléèwé máa pẹ̀gàn àwọn tí àwọ̀ wọn, àṣà wọn tàbí èdè wọn yàtọ̀ sí tiwọn. Ṣé irú ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà bẹ́ẹ̀ kò tíì ràn wá? Báwo ló sì ṣe máa ń rí lára wa táwọn èèyàn bá fi èdè wa, àṣà wa tàbí ìlú wa ṣe yẹ̀yẹ́, bóyá tí wọ́n tiẹ̀ bẹnu àtẹ́ lù wá?

9 Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Pétérù ní èrò tí kò tọ́ nípa àwọn tí kì í ṣe Júù bíi tiẹ̀, àmọ́  nígbà tó yá ó borí èrò yẹn. (Ìṣe 10:28, 34, 35; Gál. 2:11-14) Lọ́nà kan náà, tá a bá kíyè sí i pé àwa náà máa ń fojú tí kò tọ́ wo àwọn tí èdè tàbí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa, á dáa ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yí èrò wa pa dà. (Ka 1 Pétérù 1:22.) Ká máa rántí pé kò sẹ́ni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìgbàlà, torí pé aláìpé ni gbogbo wa, láìka ìlú tàbí orílẹ̀-èdè tá a ti wá sí. (Róòmù 3:9, 10, 21-24) Torí náà, kí nìdí tẹ́nì kan á fi máa rò pé òun sàn ju ẹlòmíì lọ? (1 Kọ́r. 4:7) Ojú tí Pọ́ọ̀lù fi wo àwọn èèyàn ló yẹ káwa náà fi máa wo àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bíi tiẹ̀ pé wọn ‘kì í ṣe àjèjì àti àtìpó mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà agbo ilé Ọlọ́run.’ (Éfé. 2:19) Tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa fojú tó tọ́ wo àwọn tí èdè tàbí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa, àá fìwà jọ Ọlọ́run.Kól. 3:10, 11.

BÁ A ṢE LÈ FI HÀN PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÀJÈJÌ

10, 11. Kí ni Bóásì ṣe tó fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn àjèjì lòun náà fi wo Rúùtù tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Móábù?

10 Ó ṣe kedere pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn àjèjì ni Bóásì náà fi wo Rúùtù tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Móábù. Nígbà tí Bóásì wá sóko láti wá wo bíṣẹ́ ìkórè ṣe ń lọ, ó kíyè sí obìnrin àjèjì kan tó ń lo gbogbo okun rẹ̀ láti pèéṣẹ́ tàbí ṣa ohun táwọn olùkórè ṣẹ́ kù. Ó wú Bóásì lórí nígbà tó gbọ́ pé Rúùtù tọrọ àyè kó tó pèéṣẹ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ láìgbàṣẹ. Torí náà, Bóásì ní kí àwọn olùkórè yọ sílẹ̀ lára ṣírí ọkà tí wọ́n ti kórè fún Rúùtù.Ka Rúùtù 2:5-7, 15, 16.

11 Ọ̀rọ̀ tí Bóásì bá Rúùtù sọ fi hàn pé ọ̀rọ̀ Rúùtù jẹ ẹ́ lọ́kàn gan-an, ìdí sì ni pé ó lóye àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ torí pé àjèjì ni. Torí náà, ó sọ fún un pé àwọn obìnrin ni kó máa bá ṣiṣẹ́ káwọn ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ nínú oko má bàa yọ ọ́ lẹ́nu. Kódà, Bóásì rí i pé Rúùtù rí oúnjẹ jẹ dáadáa, ó sì rómi mu bíi tàwọn òṣìṣẹ́ yòókù. Yàtọ̀ síyẹn, Bóásì ò fọ̀rọ̀ gún Rúùtù lára, kàkà bẹ́ẹ ṣe ló ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un.Rúùtù 2:8-10, 13, 14.

12. Tá a bá fojúure hàn sáwọn àjèjì, kí ló máa mú kí wọ́n ṣe?

12 Bóásì mọyì bí Rúùtù ṣe ń tọ́jú Náómì ìyá ọkọ rẹ̀, ó sì tún gbóríyìn fún un torí pé ó ti di ìránṣẹ́ Jèhófà. Bóásì ṣojúure sí Rúùtù torí pé Jèhófà náà nífẹ̀ẹ́ obìnrin yìí àti pé ó ti ‘wá ìsádi lábẹ́ ìyẹ́ apá Ọlọ́run Ísírẹ́lì.’ (Rúùtù 2:12, 20; Òwe 19:17) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, tá a bá fojúure hàn sí “gbogbo onírúurú ènìyàn,” wọ́n lè wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n á sì rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn.1 Tím. 2:3, 4.

Ṣé a máa ń kí àwọn àjèjì tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tẹ̀rín tọ̀yàyà? (Wo ìpínrọ̀ 13 àti 14)

13, 14. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká rí i pé a kí àwọn àjèjì tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba? (b) Kí lo lè ṣe tójú bá ń tì ẹ́ tàbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ yá ẹ lára láti bá àwọn tí kì í ṣe ọmọ ìlú rẹ sọ̀rọ̀?

13 Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣojúure sáwọn àjèjì tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ni pé ká kí wọn tẹ̀rín tọ̀yàyà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ojú  máa ń ti àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ìlú onílùú, wọ́n sì sábà máa ń dá wà. Torí pé ibi tí wọ́n dàgbà sí yàtọ̀ àti pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rẹ́ni fojú jọ báyìí, ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò tẹ́gbẹ́. Torí náà, á dáa kó jẹ́ àwa la máa kọ́kọ́ sún mọ́ wọn, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Tí èdè ẹni yẹn bá wà lórí ètò ìṣiṣẹ́ JW Language, o lè fi kọ́ bí wàá ṣe kí ẹni náà lédè rẹ̀.Ka Fílípì 2:3, 4.

14 Ojú lè máa tì wá tàbí kó má fi bẹ́ẹ̀ yá wa lára láti bá àwọn tí kì í ṣe ọmọ ìlú wa sọ̀rọ̀. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á dáa kó o sọ nǹkan kan fún wọn nípa ara rẹ. O lè wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ fi jọra, àti pé àṣà kọ̀ọ̀kan ló ní dáadáa tiẹ̀.

JẸ́ KÁRA TÙ WỌ́N

15. Kí la lè ṣe táá mú kára tu àwọn tó wá láti ìlú míì?

15 Ohun kan wà tó o lè ṣe láti mú kára tu àwọn àjèjì tó wà níjọ yín. O lè bi ara rẹ pé: ‘Ká sọ pé ìlú onílùú lèmi náà wà, báwo ni màá ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe sí mi?’ (Mát. 7:12) Máa ṣe sùúrù fún wọn torí pé ara wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọlé ni. Ìwà wọn lè kọ́kọ́ ṣàjèjì sí wa, àmọ́ dípò ká máa retí pé kí wọ́n kọ́ àṣà wa, á dáa ká mọyì àṣà wọn.Ka Róòmù 15:7.

16, 17. (a) Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn àjèjì tó wà láàárín wa? (b) Báwo la ṣe lè ran àwọn àjèjì tó wà ní ìjọ wa lọ́wọ́?

16 Tá a bá kà nípa ibi táwọn àjèjì tó wà níjọ wa ti wá àti àṣà wọn, àá túbọ̀ lóye wọn. Nígbà Ìjọsìn Ìdílé wa, a lè ṣèwádìí nípa àwọn àjèjì tó wà níjọ wa tàbí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Ohun míì táá jẹ́ ká túbọ̀ mọwọ́ ara wa ni pé ká ní kí wọ́n wá sílé wa, ká sì jọ jẹun. Torí pé Jèhófà “ti ṣí ilẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè,” ṣé kò yẹ káwa náà ṣí ilẹ̀kùn wa fáwọn àjèjì tó “bá wa tan nínú  ìgbàgbọ́”?Ìṣe 14:27; Gál. 6:10; Jóòbù 31:32.

Ṣé a máa ń gba àwọn àjèjì tó wà láàárín wa lálejò? (Wo ìpínrọ̀ 16 àti 17)

17 Tá a bá ń wáyè láti wà pẹ̀lú àwọn àjèjì tó wà láàárín wa, àá túbọ̀ mọyì ìsapá tí wọ́n ń ṣe láti kọ́ àṣà wa. A lè wá rí i pé wọ́n máa nílò ìrànlọ́wọ́ láti kọ́ èdè wa. Yàtọ̀ síyẹn, a tún lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá ilé tó dáa tí wọ́n lè gbé, a sì lè bá wọn wáṣẹ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ara wọn á túbọ̀ mọlé, ọkàn wọn á sì balẹ̀.Òwe 3:27.

18. Àpẹẹrẹ wo làwọn àjèjì lè tẹ̀ lé?

18 Òótọ́ kan ni pé á dáa káwọn tó jẹ́ àjèjì ṣe gbogbo ohun tí àwọn náà lè ṣe kára wọn lè mọlé. Wọ́n lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Rúùtù. Lákọ̀ọ́kọ́, Rúùtù ò fojú pa àṣà ilẹ̀ tó wà rẹ́ torí pé ó tọrọ àyè kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í pèéṣẹ́. (Rúùtù 2:7) Kò ronú pé òun ṣáà lẹ́tọ̀ọ́ láti pèéṣẹ́, kó wá wọnú oko olóko láìgbàṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún dúpẹ́ fún inú rere tí wọ́n fi hàn sí i. (Rúùtù 2:13) Táwọn àjèjì náà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á túbọ̀ níyì lójú àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ àtàwọn ará ìlú.

19. Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kára tu àwọn àjèjì tó wà láàárín wa?

19 A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ṣojúure sí onírúurú èèyàn, ó sì ń mú kí wọ́n gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí dara pọ̀ mọ́ àwa èèyàn Jèhófà nílùú wọn. Àmọ́ ní báyìí tí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ wa, ṣé kò ní dáa ká ṣe ohun táá jẹ́ kára tù wọ́n? Yálà a ní lọ́wọ́ tàbí a ò fi bẹ́ẹ̀ ní, tá a bá ń fojúure hàn sí wọn, ńṣe là ń fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Torí pé àpẹẹrẹ Jèhófà là ń tẹ̀ lé, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kára lè tù wọ́n.Éfé. 5:1, 2.

^ [1] (ìpínrọ̀ 1) A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.