Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Máa Fàánú Hàn, Kó O sì Máa Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Bíi Ti Jèhófà

Máa Fàánú Hàn, Kó O sì Máa Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Bíi Ti Jèhófà

“Ẹ fi ìdájọ́ òdodo tòótọ́ ṣe ìdájọ́ yín; kí ẹ sì máa bá a lọ ní ṣíṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”​—SEK. 7:9.

ORIN: 125, 88

1, 2. (a) Ọwọ́ wo ni Jésù fi mú Òfin Ọlọ́run? (b) Ọ̀nà wo làwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí gbà lọ́ Òfin lọ́rùn?

JÉSÙ nífẹ̀ẹ́ Òfin Mósè gan-an. Kò sì yani lẹ́nu torí pé Jèhófà ló ṣòfin náà, Òun sì lẹni tó ṣe pàtàkì jù sí Jésù láyé àti lọ́run. Kódà Sáàmù 40:8 sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run gan-an, ó ní: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, Òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” Jésù fi hàn lọ́rọ̀ àti níṣe pé Òfin Ọlọ́run jẹ́ pípé, ó ṣàǹfààní, gbogbo ohun tó wà nínú òfin náà ló sì máa ṣẹ.​—Mát. 5:​17-19.

2 Ẹ wo bó ṣe máa dun Jésù tó nígbà tó rí báwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí ṣe ń lọ́ Òfin Bàbá rẹ̀ lọ́rùn! Wọ́n ń pa àwọn òfin kéékèèké mọ́ dórí bíńtín, ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Ẹ ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá efinrin àti ewéko dílì àti ewéko kúmínì.” Kí wá nìṣòro wọn? Jésù sọ pé: “Ṣùgbọ́n ẹ ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.” (Mát. 23:23) Ó ṣe kedere pé arinkinkin mọ́ òfin làwọn Farisí. Àmọ́ Jésù ní tiẹ̀ lóye àwọn ìlànà tó wà nínú Òfin, ó sì mọ bí òfin kọ̀ọ̀kan ṣe gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 3 Àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè. (Róòmù 7:6) Síbẹ̀, Jèhófà rí i pé Òfin yẹn wà nínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀. Kò fẹ́ ká máa rin kinkin mọ́ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ inú Òfin yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fẹ́ ká lóye “àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ,” ìyẹn àwọn ìlànà tó rọ̀ mọ́ òfin náà, ó sì fẹ́ ká máa fi wọ́n sílò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìlànà wo ló ṣe kedere nínú ìṣètò tí Jèhófà ṣe nípa àwọn ìlú ààbò? Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí sọ àwọn ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú ìgbésẹ̀ tí ẹni tó ṣèèṣì pààyàn gbé. Ìṣètò yẹn tún kọ́ wa nípa Jèhófà àti bá a ṣe lè fìwà jọ ọ́. Torí náà, a máa dáhùn ìbéèrè mẹ́ta nínú àpilẹ̀kọ yìí: Báwo ni àwọn ìlú ààbò yẹn ṣe jẹ́ ká gbà pé aláàánú ni Jèhófà? Kí ló kọ́ wa nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí èèyàn? Báwo ló ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà? Bá a ṣe ń dáhùn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan, máa ronú ọ̀nà tó o lè gbà fara wé Baba wa ọ̀run.​—Ka Éfésù 5:1.

‘Ẹ YAN ÀWỌN ÌLÚ ŃLÁ TÍ Ó WỌ̀ FÚN ARA YÍN’

4, 5. (a) Kí ni wọ́n ṣe káwọn ìlú ààbò lè rọrùn dé, kí sì nìdí? (b) Kí nìyẹn kọ́ wa nípa Jèhófà?

4 Ó rọrùn fáwọn èèyàn láti dé àwọn ìlú ààbò mẹ́fẹ̀ẹ̀fà náà. Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣètò ìlú ààbò mẹ́ta sí apá ọ̀tún Odò Jọ́dánì àti mẹ́ta míì sí apá òsì. Ìdí sì ni pé ó fẹ́ kó rọrùn fún ẹni tó ṣèèṣì pààyàn láti tètè dé ìlú ààbò tó sún mọ́ ọn jù. (Núm. 35:​11-14) Wọ́n máa ń bójú tó ọ̀nà tó lọ sáwọn ìlú ààbò náà dáadáa. (Diu. 19:3) Wọ́n sì máa ń gbé àwọn àmì sójú ọ̀nà láti tọ́ka síbi tí ìlú ààbò wà. Torí pé kò ṣòro láti dé àwọn ìlú ààbò yẹn, ẹni tó ṣèèṣì pààyàn ò ní sá lọ sórílẹ̀-èdè míì, kó má bàa di pé á dara pọ̀ mọ́ àwọn abọ̀rìṣà.

5 Rò ó wò ná: Jèhófà ló ní kí wọ́n pa ẹni tó mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn, òun náà ló sì ní kí wọ́n fàánú hàn sí ẹni tó ṣèèṣì pààyàn, kí wọ́n sì dáàbò bò ó. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Òfin yẹn ṣe kedere, ó rọrùn, kò sì nira láti tẹ̀ lé. Ó jẹ́ ká rí i pé aláàánú ni Ọlọ́run.” Jèhófà kì í ṣe òǹrorò, tí kò mọ̀ ju kó máa fìyà jẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú àánú.”​—Éfé. 2:4.

6. Kí ló fi hàn pé àwọn Farisí kò lójú àánú?

6 Àmọ́ àwọn Farisí ò lójú àánú rárá. Bí àpẹẹrẹ, ìtàn fi hàn pé tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wọ́n ní ẹ̀ṣẹ̀ kan náà ju ẹ̀ẹ̀mẹta lọ, wọn ò ní dárí ji onítọ̀hún mọ́. Jésù sọ àkàwé kan tó jẹ́ ká rí ojú táwọn Farisí fi ń wo àwọn tí wọ́n kà sí ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó ṣàkàwé Farisí kan tó ń gbàdúrà pé: “Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé èmi kò rí bí àwọn ènìyàn yòókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòdodo, panṣágà, tàbí bí agbowó orí yìí pàápàá,” ìyẹn agbowó orí kan tó ń fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fàánú hàn sí òun. Kí nìdí táwọn Farisí fi burú tó  bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé wọ́n “ka àwọn yòókù sí aláìjámọ́ nǹkan kan.”​—Lúùkù 18:​9-14.

Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ pé ó wù ẹ́ láti dárí jì wọ́n, ṣé ó sì máa ń rọrùn fáwọn tó ṣẹ̀ ẹ́ láti wá tọrọ àforíjì? Jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́ (Wo ìpínrọ̀ 4 sí 8)

7, 8. (a) Báwo lo ṣe lè fara wé Jèhófà tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ẹ́? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká tó lè dárí jini?

7 Jèhófà ni kó o fara wé, má ṣe fara wé àwọn Farisí. Torí náà, máa fi àánú hàn. (Ka Kólósè 3:13.) Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o jẹ́ kó rọrùn fáwọn èèyàn láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ. (Lúùkù 17:​3, 4) Torí náà bi ara rẹ pé: ‘Ṣó máa ń wù mí láti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ mí, títí kan àwọn tó ṣẹ̀ mí lọ́pọ̀ ìgbà? Tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ mí tàbí tó ṣàìdáa sí mi, ṣó máa ń yá mi lára láti yanjú ọ̀rọ̀ náà?’

8 Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, á rọrùn fún wa láti dárí ji àwọn èèyàn. Àwọn Farisí kì í dárí jini torí pé àwọn èèyàn ò já mọ́ nǹkan kan lójú wọn. Àmọ́ àwa Kristẹni lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a sì gbà pé “àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù” wá lọ, ó sì yẹ ká dárí jì wọ́n. (Fílí. 2:3) Ṣé wàá fara wé Jèhófà, kó o sì fi hàn pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ó wù ẹ́ láti dárí jì wọ́n, ìyẹn á sì mú kó rọrùn fáwọn náà láti wá tọrọ àforíjì. Má ṣe tètè máa bínú, kàkà bẹ́ẹ̀ máa mú sùúrù, kó o sì máa fàánú hàn.​—Oníw. 7:​8, 9.

KA Ẹ̀MÍ ÈÈYÀN SÍ PÀTÀKÌ, KÓ MÁ BÀA “SÍ Ẹ̀BI Ẹ̀JẸ̀ KANKAN LÓRÍ RẸ”

9. Báwo ni Jèhófà ṣe mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé ẹ̀mí èèyàn ṣe pàtàkì?

9 Ìdí pàtàkì tí Jèhófà fi ṣètò àwọn ìlú ààbò ni pé kò fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. (Diu. 19:10) Jèhófà ka ẹ̀mí sí pàtàkì, ó sì kórìíra “ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 6:​16, 17) Torí pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ àti onídàájọ́ òdodo, kì í gbójú fo ìpànìyàn, kódà kó jẹ́ èyí tó ṣèèṣì ṣẹlẹ̀. Lóòótọ́, wọ́n máa ń fàánú hàn sẹ́ni tó ṣèèṣì pààyàn, síbẹ̀ ó gbọ́dọ̀ ṣàlàyé bọ́rọ̀ náà ṣe wáyé fáwọn àgbà ọkùnrin. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló ṣèèṣì pààyàn, á wà nínú ìlú ààbò náà títí dìgbà tí àlùfáà àgbà bá kú. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibẹ̀ ló máa wà títí tóun alára fi máa kú. Ìṣètò yìí jẹ́ kó ṣe kedere sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ẹ̀mí èèyàn jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run. Torí náà, tí wọ́n bá máa fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá, wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun táá mú kí ẹ̀mí èèyàn tọwọ́ wọn bọ́.

10. Kí ni Jésù sọ tó fi hàn pé ẹ̀mí èèyàn ò jọ àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí lójú?

10 Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí ò fìwà jọ Jèhófà torí pé ẹ̀mí èèyàn ò jọ wọ́n lójú. Lọ́nà wo? Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ; ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé, àwọn tí wọ́n sì ń wọlé ni ẹ dí lọ́wọ́!” (Lúùkù 11:52) Àwọn ló yẹ kó máa ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́, ṣe ni wọ́n ń mú káwọn èèyàn náà kẹ̀yìn sí Jésù tó jẹ́ “Olórí Aṣojú ìyè,” wọ́n sì mú kí wọ́n máa tọ ọ̀nà ìparun. (Ìṣe 3:15) Agbéraga àti onímọtara-ẹni-nìkan làwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí, wọn ò sì bìkítà fáwọn Júù bíi tiwọn. Ẹ ò rí i pé ìkà àti aláìláàánú ni wọ́n!

11. (a) Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀mí lòun náà fi ń wò ó? (b) Kí láá jẹ́ ká máa fìtara wàásù bíi ti Pọ́ọ̀lù?

 11 Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà, ká má sì máa hùwà bí àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí? Ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká máa fojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí èèyàn wò ó. Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ ìwàásù fi hàn pé ó ka ẹ̀mí èèyàn sí pàtàkì. Abájọ tó fi sọ pé: “Ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo.” (Ka Ìṣe 20:​26, 27.) Síbẹ̀, kì í ṣe torí pé kí Pọ́ọ̀lù má bàa jẹ̀bi tàbí torí pé ó jẹ́ dandan ló ṣe ń wàásù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ẹ̀mí wọn sì ṣe pàtàkì sí i. (1 Kọ́r. 9:​19-23) Ohun tó sì yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn. Jèhófà “fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pét. 3:9) Ìwọ ńkọ́? Tó o bá jẹ́ kí àánú àwọn èèyàn máa ṣe ẹ́, wàá túbọ̀ máa fìtara wàásù, wàá sì máa láyọ̀ bó o ṣe ń ṣe é.

12. Kí nìdí táwa èèyàn Ọlọ́run fi ń fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ààbò?

12 Tá a bá ń fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ààbò, à ń fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí làwa náà fi ń wò ó. Kò yẹ ká máa wakọ̀ níwàkuwà, ó sì yẹ ká fọwọ́ gidi mú ọ̀rọ̀ ààbò níbiṣẹ́ àti láwọn ìgbà míì, títí kan ìgbà tá a bá ń kọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa tàbí nígbà tá a bá ń ṣàtúnṣe sí wọn. Ó tún yẹ kọ́rọ̀ ààbò jẹ wá lọ́kàn tá a bá ń lọ sípàdé tàbí àwọn àpéjọ wa. Kò yẹ ká fọwọ́ kékeré mú ọ̀rọ̀ ààbò àti ìlera wa torí ká lè tètè parí iṣẹ́ wa tàbí torí owó tá a máa rí nídìí rẹ̀. Ìgbà gbogbo ni Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tó tọ́ àtohun tó yẹ, ó sì yẹ ká fara wé e. Ó yẹ káwọn alàgbà máa rí i pé kò sóhun tó lè fi ẹ̀mí tiwọn tàbí tàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sínú ewu. (Òwe 22:3) Bí alàgbà kan bá rán ẹ létí pé kó o yẹra fún ohun tó lè wu ẹ̀mí rẹ léwu, tètè fi ìmọ̀ràn náà sílò. (Gál. 6:1) Torí náà, ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí èèyàn ni kó o fi máa wò ó, kó má bàa “sí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kankan lórí rẹ.”

“ṢE ÌDÁJỌ́ . . . NÍ ÌBÁMU PẸ̀LÚ ÀWỌN ÌDÁJỌ́ WỌ̀NYÍ”

13, 14. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì láti máa ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà?

13 Jèhófà pàṣẹ fáwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa ṣèdájọ́ òdodo bíi tòun. Ohun àkọ́kọ́ ni pé kí wọ́n wádìí bóyá ẹnì kan mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn ni àbí ó ṣèèṣì. Lẹ́yìn náà, wọ́n á rí i pé àwọn lóye ohun tó mú kí ẹ̀mí èèyàn tọwọ́ rẹ̀ bọ́, bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀, àti irú ẹni tó jẹ́ látẹ̀yìnwá, èyí á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá káwọn fàánú hàn sí i tàbí káwọn má ṣe bẹ́ẹ̀. Kí wọ́n lè ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ bóyá ẹni tó pààyàn náà ṣe bẹ́ẹ̀ “láti inú ìkórìíra” àti pé ṣe ló “lúgọ dè é kí ó bàa lè kú.” (Ka Númérì 35:​20-24.) Tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá ṣojú àwọn míì, ó kéré tán ẹni méjì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí i bóyá ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ pa ẹni náà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.​—Núm. 35:30.

14 Lẹ́yìn táwọn àgbà ọkùnrin bá ti rí òkodoro ọ̀rọ̀, wọ́n á fún ẹni náà láfiyèsí dípò ohun tó ṣe. Èyí gba pé kí wọ́n lo ìjìnlẹ̀ òye, kí wọ́n wo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà àtohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ hàn sójútáyé. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wọ́n nílò ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà kí wọ́n lè lo ìjìnlẹ̀ òye àti àánú, kí wọ́n sì ṣèdájọ́ òdodo.​—Ẹ́kís. 34:​6, 7.

15. Báwo ni ojú tí Jésù fi wo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe yàtọ̀ sí tàwọn Farisí?

15 Ìwà àìtọ́ tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan hù làwọn Farisí máa ń gbájú mọ́, kì í ṣe irú ẹni tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà jẹ́. Nígbà táwọn Farisí rí Jésù níbi ìkórajọ kan nílé Mátíù, wọ́n bi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé olùkọ́ yín ń jẹun pẹ̀lú àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀?” Jésù fèsì pé: “Àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀. Ẹ lọ, nígbà náà, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí èyí túmọ̀ sí, ‘Àánú ni èmi fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ.’ Nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” (Mát. 9:​9-13) Ṣéyẹn wá  túmọ̀ sí pé Jésù gba ìwàkíwà láyè? Kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, apá pàtàkì lára ìwàásù Jésù ni pé káwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ronú pìwà dà. (Mát. 4:17) Jésù fòye mọ̀ pé àwọn kan lára “àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀” máa yí pa dà. Kì í ṣe torí oúnjẹ nìkan ni wọ́n ṣe wá sílé Mátíù, kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé, ‘ọ̀pọ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í tọ Jésù lẹ́yìn.’ (Máàkù 2:15) Àmọ́, àwọn Farisí kò rí ohun tí Jésù rí nípa àwọn èèyàn náà. Ìwà àwọn Farisí yàtọ̀ pátápátá sí ti Ọlọ́run aláàánú àti onídàájọ́ òdodo tí wọ́n sọ pé àwọn ń sìn, torí pé ṣe ni wọ́n ka àwọn míì sí ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò lè yí pa dà láé.

16. Kí làwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ onídàájọ́ gbọ́dọ̀ fòye mọ̀?

16 Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn fara wé Jèhófà tó jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Sm. 37:28) Wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ‘ṣe àyẹ̀wò, kí wọ́n sì wádìí kínníkínní,’ bóyá lóòótọ́ lẹnì kan hùwà àìtọ́. Tí onítọ̀hún bá ti hùwà àìtọ́, wọ́n á bójú tó ọ̀rọ̀ náà níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́. (Diu. 13:​12-14) Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ onídàájọ́ gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ wo ọ̀rọ̀ náà, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì náà ronú pìwà dà lóòótọ́. Kì í sábà rọrùn láti mọ̀ bóyá ẹnì kan ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Ó gba pé kí wọ́n mọ ojú tónítọ̀hún fi wo ẹ̀ṣẹ̀ tó dá àti bọ́rọ̀ náà ṣe dùn ún tó. (Ìṣí. 3:3) Ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà kó tó lè rí àánú gbà. *

17, 18. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fòye mọ̀ bóyá ẹnì kan ronú pìwà dà tọkàntọkàn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

17 Àwọn alàgbà kò dà bíi Jèhófà àti Jésù tó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn. Tó o bá jẹ́ alàgbà, báwo lo ṣe lè fòye mọ̀ bóyá ẹnì kan ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Àkọ́kọ́, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n àti ìfòyemọ̀. (1 Ọba 3:9) Ìkejì, ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ẹrú olóòótọ́ kó o lè mọ ìyàtọ̀ láàárín “ìbànújẹ́ ti ayé” àti ojúlówó ìrònúpìwàdà, tí Bíbélì pè ní “ìbànújẹ́ ní ọ̀nà ti Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 7:​10, 11) Fara balẹ̀ wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn tó ronú pìwà dà àtàwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ni Bíbélì sọ nípa bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn, ojú tí wọ́n fi wo ìwà àìtọ́ tí wọ́n hù àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an?

18 Paríparí rẹ̀, mọ irú ẹni tí oníwà àìtọ́ náà jẹ́ gan-an. Ronú lórí ipò àtilẹ̀wá rẹ̀, ohun tó mú kó hùwà àìtọ́ àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní. Nígbà tí Bíbélì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù tó jẹ́ orí ìjọ Kristẹni, ó sọ pé: “Kì yóò sì ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́. Yóò sì fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀, yóò sì fi ìdúróṣánṣán fúnni ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà nítorí àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé.” (Aísá. 11:​3, 4) Olùṣọ́ àgùntàn tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Jésù lẹ̀yin alàgbà, ó máa ràn yín lọ́wọ́ láti ṣèdájọ́ òdodo bíi tiẹ̀. (Mát. 18:​18-20) Ó dájú pé a mọrírì àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n ń sapá láti máa ṣèdájọ́ òdodo, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? A mọyì bi wọ́n ṣe ń sapá láti máa fàánú hàn àti bí wọ́n ṣe ń ṣèdájọ́ òdodo!

19. Kí lo rí kọ́ nínú ìjíròrò wa nípa àwọn ìlú ààbò?

19 Òfin Mósè ṣàgbéyọ “kókó ìmọ̀ àti ti òtítọ́” nípa Jèhófà àtàwọn ìlànà òdodo rẹ̀. (Róòmù 2:20) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìlú ààbò kọ́ àwọn alàgbà nípa bí wọ́n ṣe lè máa “fi ìdájọ́ òdodo tòótọ́ ṣe ìdájọ́,” ó sì jẹ́ kí gbogbo wa mọ bá a ṣe lè máa ṣe “inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú sí ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì.” (Sek. 7:9) Òótọ́ ni pé a ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, àmọ́ Jèhófà kò yí pa dà, ó ṣì jẹ́ Ọlọ́run aláàánú àti onídàájọ́ òdodo. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni pé à ń jọ́sìn Ọlọ́run tó dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, torí náà a lè fìwà jọ ọ́, ká sì rí ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀!

^ ìpínrọ̀ 16 Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́, September 15, 2006, ojú ìwé 30.