Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Kó O Pàdánù Èrè Ọjọ́ Iwájú

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Kó O Pàdánù Èrè Ọjọ́ Iwájú

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fi ẹ̀bùn eré ìje náà dù yín.”​KÓL. 2:18.

ORIN: 122, 139

1, 2. (a) Èrè wo làwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń fojú sọ́nà fún? (b) Kí láá mú ká pọkàn pọ̀ sórí èrè ọjọ́ iwájú? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

BÍI ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró máa gba èrè kan, ìyẹn “ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè.” (Fílí. 3:14) Wọ́n ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù Kristi, tí wọ́n á sì mú kí aráyé di pípé. (Ìṣí. 20:6) Ẹ ò rí i pé èrè ńlá nìyẹn! Àwọn àgùntàn mìíràn náà ní ìrètí àgbàyanu tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún. Wọ́n ń retí ìgbà tí wọ́n máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ó dájú pé ìrètí àgbàyanu lèyí náà jẹ́.​—2 Pét. 3:13.

2 Kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lè jẹ́ olóòótọ́ dé òpin, kí wọ́n sì gba èrè náà, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa gbé èrò inú yín ka àwọn nǹkan ti òkè.” (Kól. 3:2) Ìyẹn ni pé kí wọ́n jẹ́ kí ìrètí àtigbé lọ́run máa wà lọ́kàn wọn nígbà gbogbo. (Kól. 1:​4, 5) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé yálà a ní ìrètí àtigbé lọ́run tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tá a bá ń ronú nípa àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí fún wa, ìyẹn á jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí èrè náà.​—1 Kọ́r. 9:24.

3. Ìkìlọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni?

 3 Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni yẹn nípa àwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n pàdánù èrè náà. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Kólósè pé kí wọ́n ṣọ́ra fáwọn èké Kristẹni. Àwọn èké Kristẹni yẹn gbà pé àwọn á rí ojúure Ọlọ́run táwọn bá ń pa Òfin Mósè mọ́ dípò káwọn lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù. (Kól. 2:​16-18) Pọ́ọ̀lù tún sọ nípa àwọn nǹkan míì tó lè mú káwa Kristẹni pàdánù èrè tá à ń fojú sọ́nà fún. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ̀rọ̀ nípa bí a ò ṣe ní gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè, bá a ṣe lè yanjú èdèkòyédè nínú ìjọ àti bá a ṣe lè yanjú ìṣòro nínú ìdílé. Ìmọ̀ràn tó fún àwọn Kristẹni nígbà yẹn ṣàǹfààní fáwa náà lónìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ nínú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kólósè.

MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÌFẸ́KÚFẸ̀Ẹ́ JỌBA LỌ́KÀN RẸ

4. Báwo ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ṣe lè mú ká pàdánù èrè náà?

4 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù rán àwọn arákùnrin rẹ̀ létí nípa ìrètí tí wọ́n ní, ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò.” (Kól. 3:5) Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ máa ń lágbára gan-an, ó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ó sì lè mú ká pàdánù èrè tá à ń fojú sọ́nà fún. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gba òun lọ́kàn débi tó fi ṣáko lọ. Lẹ́yìn tó pa dà sínú ìjọ, ó sọ pé: “Ìṣekúṣe wọ̀ mí lẹ́wù gan-an débi pé àtijáwọ́ nínú ẹ̀ wá ṣòro fún mi, ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà.”

5. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá bára wa láwọn ipò tó léwu?

5 Ó ṣe pàtàkì pé ká wà lójúfò pàápàá nígbà tá a bá bára wa láwọn ipò kan tó ti lè rọrùn láti ṣèṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, àtìbẹ̀rẹ̀ ló ti yẹ káwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà jíròrò ibi táwọn lè fìfẹ́ hàn síra wọn dé. Ó gba pé kí wọ́n kíyè sára tó bá dọ̀rọ̀ ìfẹnukonu, gbígbá ara wọn mọ́ra tàbí wíwà pa pọ̀ láwọn nìkan. (Òwe 22:3) Yàtọ̀ síyẹn, tí iṣẹ́ Kristẹni kan bá gba pé kó rìnrìn-àjò tàbí kó bá ẹ̀yà kejì ṣiṣẹ́, ó yẹ kó kíyè sára. (Òwe 2:​10-12, 16) Tó o bá bá ara rẹ nírú ipò yẹn, á dáa kó o jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, máa hùwà ọmọlúàbí, kó o sì rántí pé títage kì í bímọ re. Ó tún yẹ ká wà lójúfò nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn tàbí tá ò rẹ́ni fojú jọ. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká rẹ́ni fà wá mọ́ra. A sì lè máa wá ẹni tó máa tù wá nínú tàbí ẹni tó máa gba tiwa rò láìka ẹni yòówù kó jẹ́. Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé ká yíjú sí Jèhófà àtàwọn ará fún ìrànlọ́wọ́, ká má bàa ṣe ohun táá mú ká pàdánù èrè náà.​—Ka Sáàmù 34:18; Òwe 13:20.

6. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tó bá dọ̀rọ̀ eré ìnàjú tá a máa yàn?

6 Kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ má bàa jọba lọ́kàn wa, ó ṣe pàtàkì pé ká yẹra fáwọn eré ìnàjú tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ. Ọ̀pọ̀ lára àwọn eré ìnàjú tó gbòde kan lónìí ni ìṣekúṣe kún inú rẹ̀ bámú bíi ti Sódómù àti Gòmórà ayé ìgbàanì. (Júúdà 7) Àwọn tó ń gbé eré àtàwọn fíìmù jáde máa ń jẹ́ kó dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú ìṣekúṣe àti pé kò sóhun tó lè tẹ̀yìn irú ìwà bẹ́ẹ̀ yọ. Ó yẹ ká kíyè sára, ká sì fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò irú eré ìnàjú tá a máa gbádùn. Ká rí i pé a ò yan eré ìnàjú tó lè mú ká pàdánù èrè tá à ń fojú sọ́nà fún.​—Òwe 4:23.

Ẹ FI ÌFẸ́ ÀTI INÚURE “WỌ ARA YÍN LÁṢỌ”

7. Àwọn ìṣòro wo ló lè wáyé nínú ìjọ Kristẹni?

7 Gbogbo wa la gbà pé ìbùkún ńlá ló jẹ́ bá a ṣe wà nínú ìjọ Kristẹni. Bá a ṣe  ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípàdé àti bá a ṣe ń ran ara wa lọ́wọ́ máa ń jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí èrè náà. Àmọ́ nígbà míì, èdèkòyédè lè wáyé láàárín wa kó sì fa àìgbọ́ra-ẹni-yé. Tá ò bá tètè yanjú irú èdèkòyédè bẹ́ẹ̀, ó lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í di ara wa sínú.​—Ka 1 Pétérù 3:​8, 9.

8, 9. (a) Àwọn ànímọ́ wo láá jẹ́ ká rí èrè ọjọ́ iwájú gbà? (b) Kí la lè ṣe táá jẹ́ kí àlàáfíà jọba tí Kristẹni kan bá ṣẹ̀ wá?

8 Kí la lè ṣe tí èdèkòyédè kò fi ní jẹ́ ká pàdánù èrè tá à ń wọ̀nà fún? Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kólósè níyànjú pé: “Gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”​—Kól. 3:​12-14.

9 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tá a sì jẹ́ onínúure, á rọrùn fún wa láti dárí jì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá. Bí àpẹẹrẹ, tí Kristẹni kan bá sọ tàbí ṣe ohun kan tó dùn wá, á dáa káwa náà rántí ìgbà kan tá a sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tó dun àwọn míì. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn nígbà tí wọ́n fìfẹ́ gbójú fo àṣìṣe wa, tí wọ́n sì fi inúure hàn sí wa? (Ka Oníwàásù 7:​21, 22.) Ẹ wo bínú wa ṣe dùn tó pé Jésù fi inúure hàn sí wa, ó sì mú káwa olùjọsìn tòótọ́ wà níṣọ̀kan. (Kól. 3:15) À ń jọ́sìn Ọlọ́run kan náà, ìhìn rere kan náà là ń wàásù, ìṣòro wa sì jọra. Torí náà, tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará, tá à ń fi inúure hàn sí wọn, tá a sì ń dárí jì wọ́n, àá pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ, àá sì lè pọkàn pọ̀ sórí èrè ọjọ́ iwájú náà.

10, 11. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká maá jowú? (b) Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa jowú?

10 Àpẹẹrẹ àwọn tó jowú nínú Bíbélì jẹ́ ká rí i pé owú jíjẹ lè mú kéèyàn pàdánù èrè ọjọ́ iwájú. Ẹ rántí pé owú ló mú kí Kéènì pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀. Bákan náà, Kórà, Dátánì àti Ábírámù jowú Mósè, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n ta kò ó. Àpẹẹrẹ míì ni ti Ọba Sọ́ọ̀lù tó jowú Dáfídì torí pé ó ṣàṣeyọrí, ó sì ń wá bó ṣe máa pa á. Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé: “Níbi tí owú àti ẹ̀mí asọ̀ bá wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti gbogbo ohun búburú wà.”​—Ják. 3:16.

11 Tá a bá jẹ́ onínúure, tá a sì ń fìfẹ́ bá àwọn míì lò, a ò ní máa jowú wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú.” (1 Kọ́r. 13:4) Tá a bá ń fojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ará wa wò wọ́n, tá a sì gbà pé ọmọ ìyá ni gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ, a ò ní máa jowú wọn. Ìyẹn á mú ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, àá sì máa fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, tó sọ pé: “Bí a bá ṣe ẹ̀yà ara kan lógo, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a yọ̀.” (1 Kọ́r. 12:​16-18, 26) Torí náà, ṣe ló yẹ ká máa bá ẹni tó ṣàṣeyọrí yọ̀ dípò ká máa jowú rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jónátánì ọmọ Ọba Sọ́ọ̀lù. Kò jowú nígbà tí Jèhófà yan Dáfídì láti jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fún Dáfídì níṣìírí. (1 Sám. 23:​16-18) Ṣé àwa náà lè máa fìfẹ́ àti inú rere hàn bíi ti Jónátánì?

OHUN TÁÁ MÚ KÍ ÌDÍLÉ RÍ ÈRÈ NÁÀ GBÀ

12. Ìmọ̀ràn Bíbélì wo ló máa ran ìdílé lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí èrè ọjọ́ iwájú gbà?

12 Táwọn tó wà nínú ìdílé bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò, ìdílé wọn á tòrò, àlàáfíà á  jọba, wọn ò sì ní pàdánù èrè ọjọ́ iwájú. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù gba àwọn ìdílé Kristẹni tó wà ní Kólósè? Ó ní: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa. Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.” (Kól. 3:​18-21) Kò sí àní-àní pé táwọn ọkọ, àwọn aya àtàwọn ọmọ bá ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò, á ṣe wọ́n láǹfààní.

13. Kí ni arábìnrin kan lè ṣe táá mú kí ọkọ rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́?

13 Tó bá jẹ́ pé ọkọ rẹ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé ìwà tó ń hù sí ẹ kò dáa tó, kí ni wàá ṣe? Tó bá jẹ́ pé ìwà rẹ̀ tó kù díẹ̀ káàtó lò ń ránnu mọ́ ṣáá, ṣéyẹn á mú kó yíwà pa dà? Tíyẹn bá tiẹ̀ mú kó ṣe ohun tó o fẹ́, ǹjẹ́ o rò pé ìyẹn á mú kó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́? Kò jọ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ tó o bá ń bọ̀wọ̀ fún un, ìyẹn á jẹ́ kí ìdílé yín tòrò, á sì mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà. Kódà, ó lè mú kí ọkọ rẹ wá ṣe ìsìn tòótọ́, kí ẹ̀yin méjèèjì sì tipa bẹ́ẹ̀ rí èrè ọjọ́ iwájú gbà.​—Ka 1 Pétérù 3:​1, 2.

14. Kí ló yẹ kí ọkọ kan ṣe tí ìyàwó rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kò bá bọ̀wọ̀ fún un?

 14 Tó bá jẹ́ pé ìyàwó rẹ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé kì í bọ̀wọ̀ fún ẹ tó, kí ni wàá ṣe? Tó o bá ń pariwo mọ́ ọn kó lè mọ̀ pé ìwọ ni olórí, ṣéyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ẹ? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Ọlọ́run fẹ́ kó o fìfẹ́ lo ipò orí rẹ kó o sì fìwà jọ Jésù. (Éfé. 5:23) Jésù tó jẹ́ orí ìjọ máa ń fìfẹ́ hàn, ó sì máa ń mú sùúrù. (Lúùkù 9:​46-48) Tí ọkọ kan bá ń fara wé Jésù, ìyẹn lè mú kí ìyàwó rẹ̀ wá ṣe ìsìn tòótọ́.

15. Báwo ni ọkọ kan ṣe lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìyàwó òun?

15 Bíbélì gba àwọn ọkọ níyànjú pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” (Kól. 3:19) Tí ọkọ kan bá ń tẹ́tí sí ìyàwó rẹ̀, tó sì jẹ́ kó dáa lójú pé òun mọyì rẹ̀, ṣe ni irú ọkọ bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìyàwó òun, òun sì bọ̀wọ̀ fún un. (1 Pét. 3:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tí ìyàwó kan bá sọ ni ọkọ rẹ̀ máa ṣe, síbẹ̀ tí ọkọ kan bá ń fọ̀rọ̀ lọ ìyàwó rẹ̀, ìpinnu tó bá ṣe máa nítumọ̀. (Òwe 15:22) Ọkọ tó bá nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ kò ní fi dandan sọ pé kí ìyàwó òun bọ̀wọ̀ fún òun, kàkà bẹ́ẹ̀ tó bá mọyì ìyàwó rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ á túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún un. Tí ọkọ kan bá nífẹ̀ẹ́ ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀, ìyẹn á mú kí gbogbo wọn túbọ̀ máa fayọ̀ sin Jèhófà, wọ́n á sì rí èrè ọjọ́ iwájú náà gbà.

Kí la lè ṣe tí àwọn ìṣòro inú ìdílé ò fi ní mú ká pàdánù èrè ọjọ́ iwájú? (Wo ìpínrọ̀ 13 sí 15)

Ẹ̀YIN Ọ̀DỌ́, Ẹ MÁ ṢE JẸ́ KÍ OHUNKÓHUN MÚ KẸ́ Ẹ PÀDÁNÙ ÈRÈ NÁÀ

16, 17. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa bínú sáwọn òbí rẹ tí wọ́n bá bá ẹ wí?

16 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òbí rẹ kò mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ tàbí pé wọ́n ti le koko jù, kí ni wàá ṣe? Inú lè bẹ̀rẹ̀ sí í bí ẹ, kó o sì máa ṣiyèméjì bóyá kó o sin Jèhófà tàbí kó o má sìn ín. Àmọ́ tó o bá bínú fi Jèhófà sílẹ̀, bópẹ́bóyá wàá rí i pé kò sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ rẹ tó àwọn òbí rẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà.

17 Tó bá jẹ́ pé àwọn òbí rẹ kì í bá ẹ wí rárá, ǹjẹ́ o ò ní bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ? (Héb. 12:8) Ó lè jẹ́ pé ọ̀nà tí àwọn òbí rẹ ń gbà bá ẹ wí ló máa ń bí ẹ nínú. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, dípò kó o máa bínú torí ọ̀nà tí wọ́n gbà bá ẹ wí, á dáa kó o ronú nípa ìdí tí wọ́n fi bá ẹ wí. Torí náà, ṣe sùúrù, má ṣe máa fapá jánú tí wọ́n bá ń bá ẹ wí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀, ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.” (Òwe 17:27) Torí náà, sapá kó o lè máa hùwà àgbà, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mọ bó o ṣe lè fi sùúrù gba ìbáwí àti bó o ṣe lè jàǹfààní nínú ìbáwí náà láìbínú sí ọ̀nà tí wọ́n gbà bá ẹ wí. (Òwe 1:8) Ìbùkún ńlá ni téèyàn bá láwọn òbí tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà, ó sì dájú pé wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gba èrè tá à ń fojú sọ́nà fún.

18. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá pọkàn pọ̀ sórí èrè ọjọ́ iwájú náà?

18 Ká sòótọ́, èrè àgbàyanu là ń fojú sọ́nà fún, yálà ìyè àìleèkú ní ọ̀run tàbí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ìrètí tá a ní yìí dájú torí pé Ẹlẹ́dàá wa fúnra rẹ̀ ló ṣèlérí rẹ̀ fún wa. Ọlọ́run sọ nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé pé: “Ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà.” (Aísá. 11:9) Gbogbo àwọn tó bá ń gbé láyé nígbà yẹn ni Jèhófà máa kọ́. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ mà nìyẹn o! Torí náà, pọkàn pọ̀ sórí ohun tí Jèhófà ṣèlérí, kó o sì pinnu pé o ò ní jẹ́ kí ohunkóhun mú kó o pàdánù èrè ọjọ́ iwájú.