Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) November 2017

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti December 25, 2017 sí January 28, 2018, ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí

Máa Fi Ayọ̀ Kọrin!

Tí ojú bá ń tì ẹ́ láti kọrin nípàdé, kí lo lè ṣe tí wàá fi lè máa kọrin sókè yin Jèhófà?

Ṣé Ò Ń Sá Di Jèhófà?

Àwọn ìlú ààbò tí Jèhófà ṣètò fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ kọ́ wa pé Jèhófà máa ń dárí jini pátápátá.

Máa Fàánú Hàn, Kó O sì Máa Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Bíi Ti Jèhófà

Báwo ni àwọn ìlú ààbò ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé aláàánú ni Jèhófà? Kí ló kọ́ wa nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí èèyàn? Báwo ló ṣe jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà?

A Ó Bù Kún Ẹni Tí Ó Jẹ́ Ọ̀làwọ́

A lè lo okun wa, àkókò wa àtàwọn nǹkan mí ì tá a ni láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run máa gbòòrò sí i.

Má Ṣe Fàyè Gba Èrò Ayé

A gbọ́dọ̀ kíyè sára kó má di pé à ń ronú bí ayé ṣe ń ronú. Wo márùn-ún lára èrò tí ayé ń gbé lárugẹ.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Kó O Pàdánù Èrè Ọjọ́ Iwájú

Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti rán àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ létí nípa ìrètí àgbàyanu tí wọ́n ní, ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ṣọ́ra fáwọn nǹkan kan.

Bí Ara Ẹ Ṣe Lè Mọlé Nínú Ìjọ Tó O Wà Báyìí

Ó ṣeé ṣe kí àyà ẹ máa já tó bá di dandan pé kó o kó lọ sí ìjọ mí ì. Kí láá jẹ́ kí ara rẹ tètè mọlé?