Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  November 2016

‘Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú Lẹ́nì Kìíní-Kejì Lójoojúmọ́’

‘Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú Lẹ́nì Kìíní-Kejì Lójoojúmọ́’

“Bí ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí bá wà tí ẹ ní fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́.”ÌṢE 13:15.

ORIN: 121, 45

1, 2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa gbóríyìn fáwọn míì?

CRISTINA tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ pé: “Àwọn òbí mi kì í gbóríyìn fún mi àfi kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ sí mi ṣáá. Ọ̀rọ̀ wọn máa ń ká mi lára gan-an. [1] Wọ́n ní mò ń ṣe bí ọmọdé, pé mi ò gbọ́n rárá àti pé mo kàn sanra jọ̀kọ̀tọ̀ ni. Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn mú kí n gbà pé mi ò wúlò. Èyí máa ń mú kí n sunkún lọ́pọ̀ ìgbà, mi ò sì ní dá sí wọn.” Àbí ẹ ò rí i pé ayé lè súni tí wọ́n bá ń kàn wá lábùkù, tí wọn ò sì gbóríyìn fún wa.

2 Àwọn èèyàn máa ń sọ pé, yinniyinni, kẹ́ni lè ṣèmíì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Rubén fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ tó ti máa ń ṣe mí bíi pé mi ò wúlò. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, èmi àti alàgbà kan jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Alàgbà náà kíyè sí i pé inú mi ò dùn. Ó wá bi mí pé kí ló ṣẹlẹ̀, mo sọ tọkàn mi fún un, ó sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí mi. Lẹ́yìn náà, ó rán mi létí àwọn nǹkan dáadáa tí mo ti ń ṣe látọjọ́ yìí wá. Ó tún fi ọ̀rọ̀ Jésù tù mí nínú, pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa níye lórí ju ọ̀pọ̀ ẹyẹ ológoṣẹ́ lọ. Kò sígbà tí mo rántí ẹsẹ Bíbélì yìí, tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kì í wọ̀ mí lọ́kàn. Ọ̀rọ̀ tí alàgbà yẹn sọ mú kí ara mi túbọ̀ yá gágá.”Mát. 10:31.

3. (a) Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa fífúnni níṣìírí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 3 Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Bíbélì tẹnu mọ́ ọn pé ká máa gba ara wa níyànjú tàbí ká máa fún ara wa níṣìírí déédéé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè; ṣùgbọ́n ẹ máa bá a nìṣó ní gbígba ara yín níyànjú lẹ́nì kìíní-kejì lójoojúmọ́, . . . kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ẹnikẹ́ni nínú yín di aláyà líle.” (Héb. 3:12, 13) Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ti fún ẹ níṣìírí rí, tí ìṣírí náà sì gbé ẹ ró, ìwọ náà á gbà pé ó ṣe pàtàkì ká máa fún àwọn míì níṣìírí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fún àwọn míì níṣìírí? Kí la lè rí kọ́ lára ọ̀nà tí Jèhófà, Jésù àti Pọ́ọ̀lù gbà fún àwọn míì níṣìírí? Báwo la ṣe lè fáwọn míì níṣìírí táá sì gbé wọn ró?

GBOGBO WA LA NÍLÒ ÌṢÍRÍ

4. Àwọn wo ló nílò ìṣírí, àmọ́ kí ló dé táwọn èèyàn kì í sábà gbóríyìn fúnni mọ́?

4 Gbogbo wa la nílò ìṣírí, pàápàá jù lọ nígbà tá a wà lọ́mọdé. Olùkọ́ kan tó ń jẹ́ Timothy Evans sọ pé: ‘Bí àwọn ewéko ṣe nílò omi, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ nílò ìṣírí. Tá a bá ń gbóríyìn fáwọn ọmọ, inú wọn máa dùn, á sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a ka àwọn kún.’ Àmọ́ àwọn àkókò tó nira gan-an là ń gbé báyìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́. Torí náà, ọ̀pọ̀ kì í sábà gbóríyìn fúnni mọ́. (2 Tím. 3:1-5) Kódà, àwọn òbí kan kì í gbóríyìn fáwọn ọmọ wọn torí pé àwọn òbí tiwọn náà ò fìgbà kan gbóríyìn fún wọn. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí láàárín àwọn òṣìṣẹ́, débi pé àwọn òṣìṣẹ́ kan tiẹ̀ ń ráhùn pé àwọn ọ̀gá kì í rí tiwọn rò, ká má tíì sọ pé wọ́n á yìn wọ́n.

5. Báwo la ṣe lè fún àwọn míì níṣìírí?

5 Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dáa, tá a sì gbóríyìn fún un, à ń fún un níṣìírí nìyẹn. A lè fún àwọn míì níṣìírí tá a bá ń jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ànímọ́ tó dáa tí wọ́n ní, a sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń tu àwọn tó soríkọ́ nínú. (1 Tẹs. 5:14) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ‘gbà níyànjú’ túmọ̀ sí “fífa ẹnì kan mọ́ra.” Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a máa ń láǹfààní láti sọ̀rọ̀ ìṣírí fún wọn. (Ka Oníwàásù 4:9, 10.) Ṣó o máa ń wá àkókò tó dáa láti jẹ́ káwọn míì mọ ìdí tó o fi nífẹ̀ẹ́ wọn àti ìdí tó o fi mọyì wọn? Kó o tó dáhùn ìbéèrè yìí, á dáa kó o ronú lórí òwe kan tó sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò mà dára o!’Òwe 15:23.

6. Kí nìdí tí Èṣù fi máa ń fẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì? Sọ àpẹẹrẹ kan.

6 Sátánì Èṣù máa ń fẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì torí ó mọ̀ pé ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Sátánì mú kí onírúurú àjálù dé bá Jóòbù, ó sì tún fi ẹ̀sùn èké kàn án kí Jóòbù lè rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. (Jóòbù 2:3; 22:3; 27:5) Táwa náà bá ń fún àwọn tá a jọ wà nínú ìdílé níṣìírí, tá a sì ń gbóríyìn fáwọn tó wà nínú ìjọ, Èṣù ò ní rọ́wọ́ mú. Èyí máa mú kí ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wà nínú ìdílé àti nínú ìjọ.

ÀPẸẸRẸ ÀWỌN TÓ FÚNNI NÍṢÌÍRÍ NÍNÚ BÍBÉLÌ

7, 8. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé Jèhófà máa ń fúnni níṣìírí? (b) Báwo làwọn òbí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

7 Jèhófà. Onísáàmù kan kọrin pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sm. 34:18) Nígbà tí ẹ̀rù ń ba Jeremáyà tó sì rẹ̀wẹ̀sì, Jèhófà fún un  nígboyà. (Jer. 1:6-10) Ẹ tún wo bó ṣe máa rí lára wòlíì Dáníẹ́lì tó ti dàgbà nígbà tí Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan sí i kó lè fún un lókun. Áńgẹ́lì náà pe Dáníẹ́lì ní ọkùnrin “fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.” (Dán. 10:8, 11, 18, 19) Ṣé ìwọ náà lè fún àwọn míì níṣìírí, irú bí àwọn akéde, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tàbí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti dàgbà, tí wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ lókun mọ́?

8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà àti Jésù ti jọ ṣiṣẹ́ fún àìlóǹkà ọdún kí Jésù tó wá sáyé, síbẹ̀ Jèhófà gbóríyìn fún un, ó sì fún un níṣìírí nígbà tó wà láyé. Ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù gbọ́ tí Bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀run pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mát. 3:17; 17:5) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run gbóríyìn fún Jésù, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé inú òun dùn sí ohun tó ń ṣe. Ó dájú pé inú Jésù máa dùn nígbà tí Bàbá rẹ̀ gbóríyìn fún un lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àkọ́kọ́ ni ìgbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ìkejì sì ni ọdún tó lò kẹ́yìn láyé. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Jésù wà nínú ìdààmú lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan láti fún un lókun. (Lúùkù 22:43) Ẹ̀yin òbí, ẹ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, kẹ́ ẹ máa fún àwọn ọmọ yín níṣìírí, kẹ́ ẹ sì máa gbóríyìn fún wọn tí wọ́n bá ṣe dáadáa. Tí wọ́n bá sì ń kojú àdánwò níléèwé, ẹ máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí àdánwò náà.

9. Kí la rí kọ́ lára Jésù nípa bó ṣe bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lò?

9 Jésù. Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù dá ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀, ó rí i pé àwọn àpọ́sítélì òun ń gbéra ga. Jésù fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn nígbà tó fọ ẹsẹ̀ wọn, síbẹ̀ wọ́n ṣì ń bára wọn jiyàn lórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. Yàtọ̀ síyẹn, Pétérù tún dá ara rẹ̀ lójú jù. (Lúùkù 22:24, 33, 34) Àmọ́, Jésù ò ro ìyẹn, ńṣe ló gbóríyìn fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé wọ́n dúró ti òun nígbà ìṣòro. Ó tiẹ̀ tún sọ fún wọn pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ tó ju tòun lọ, ó sì fi dá wọn lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. (Lúùkù 22:28; Jòh. 14:12; 16:27) Àwa náà lè ṣe bíi ti Jésù, ká máa gbóríyìn fáwọn ọmọ wa àtàwọn míì tí wọ́n bá ṣe dáadáa, dípò ká máa ṣọ́ àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn.

10, 11. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé ó yẹ ká máa fún àwọn míì níṣìírí?

10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Pọ́ọ̀lù máa ń gbóríyìn fáwọn ará nínú àwọn lẹ́tà tó kọ. Òun àtàwọn mélòó kan lára wọn ti jọ rìnrìn-àjò fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ó sì dájú pé ó mọ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn, síbẹ̀ àwọn nǹkan rere tí wọ́n ṣe ló mẹ́nu bà. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé Tímótì jẹ́ ọmọ òun “olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa,” ẹni tó máa fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ará. (1 Kọ́r. 4:17; Fílí. 2:19, 20) Àpọ́sítélì náà tún ròyìn Títù fún àwọn ará tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì pé ó jẹ́ “alájọpín pẹ̀lú [òun] àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ire” wọn. (2 Kọ́r. 8:23) Ó dájú pé inú Tímótì àti Títù máa dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa wọn.

11 Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fẹ̀mí ara wọn wewu bí wọ́n ṣe pa dà lọ sáwọn ìlú tí wọ́n ti ṣe inúnibíni sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, láìka àtakò tó le tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kojú ní ìlú Lísírà, wọ́n pa dà síbẹ̀ kí wọ́n lè fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dọmọ ẹ̀yìn níṣìírí kí ìgbàgbọ́ wọn lè fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Ìṣe 14:19-22) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní Éfésù, àwọn èèyàn ìlú náà kóra jọ wọ́n sì da rúgúdù sílẹ̀. Ìwé Ìṣe 20:1, 2 sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Lẹ́yìn tí ìrọ́kẹ̀kẹ̀ náà ti rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn, nígbà tí ó sì ti fún wọn ní ìṣírí, tí ó sì ti dágbére fún wọn pé ó dìgbà kan ná, ó jáde lọ láti rin ìrìn àjò lọ sí Makedóníà. Lẹ́yìn líla àwọn ibi wọnnì já, tí ó sì ń fún àwọn tí ń bẹ níbẹ̀ ní ìṣírí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀, ó wá sí ilẹ̀ Gíríìkì.” Ẹ ò rí i pé ọwọ́ pàtàkì ni Pọ́ọ̀lù fi mú fífún àwọn èèyàn níṣìírí.

 BÁ A ṢE Ń RÍ ÌṢÍRÍ GBÀ LÓNÌÍ

12. Báwo la ṣe ń fún ara wa níṣìírí láwọn ìpàdé wa?

12 Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí Baba wa ọ̀run fi ṣètò pé ká máa pé jọ déédéé ni pé ká lè fún àwọn ará níṣìírí, káwa náà sì lè rí ìṣírí gbà. (Ka Hébérù 10:24, 25.) Bíi tàwọn Kristẹni àtijọ́, àwa náà máa ń pé jọ pọ̀ ká lè kẹ́kọ̀ọ́ ká sì tún rí ìṣírí gbà. (1 Kọ́r. 14:31) Cristina tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Ohun tí mo máa ń gbádùn jù nípàdé ni ìṣírí tí mo máa ń rí gbà. Tí mo bá dé Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbà míì, inú mi kì í dùn, àmọ́ àwọn arábìnrin máa ń wá bá mi, wọ́n á gbá mi mọ́ra, wọ́n á sì sọ fún mi pé mo rẹwà gan-an. Wọ́n máa ń sọ fún mi pé àwọn nífẹ̀ẹ́ mi àti pé inú àwọn máa ń dùn báwọn ṣe ń rí i tí mò ń tẹ̀ síwájú. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí máa ń mú inú mi dùn gan-an ni.” Ẹ ò rí i pé ara máa tu gbogbo wa tá a bá ń fún ara wa níṣìírí lẹ́nì kìíní kejì.—Róòmù 1:11, 12.

13. Kí nìdí tí àwọn tó nírìírí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run fi nílò ìṣírí?

13 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó nírìírí náà nílò ìṣírí. Àpẹẹrẹ kan ni ti Jóṣúà. Jóṣúà ti ń sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ Jèhófà ní kí Mósè fún un níṣìírí. Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Fàṣẹ yan Jóṣúà, kí o sì fún un ní ìṣírí, kí o sì fún un lókun, nítorí pé òun ni ẹni tí yóò lọ níwájú àwọn ènìyàn yìí, òun sì ni ẹni tí yóò mú kí wọ́n jogún ilẹ̀ tí ìwọ yóò rí.” (Diu. 3:27, 28) Iṣẹ́ ńlá ni Jèhófà gbé lé Jóṣúà lọ́wọ́ yìí, òun ló máa kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sójú ogun kí wọ́n lè gba Ilẹ̀ Ìlérí. Ó máa ní ìjákulẹ̀, ìgbà kan sì máa wà táwọn ọ̀tá máa ṣẹ́gun rẹ̀. (Jóṣ. 7:1-9) Abájọ tí Jèhófà fi sọ fún Mósè pé kó fún un níṣìírí, kó sì fún un lókun. Lónìí, ó yẹ ká máa fún àwọn alàgbà níṣìírí, ká sì máa gbóríyìn fáwọn alábòójútó àyíká torí pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó agbo Ọlọ́run. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:12, 13.) Alábòójútó àyíká kan sọ pé: “Àwọn ará kan máa ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí wa. Wọ́n máa ń sọ bí wọ́n ṣe mọyì iṣẹ́ wa àti bí wọ́n ṣe gbádùn ìbẹ̀wò wa tó. A máa ń tọ́jú àwọn lẹ́tà náà, a sì máa ń kà wọ́n nígbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì. Àwọn lẹ́tà náà máa ń fún wa lókun gan-an.”

Àwọn ọmọ wa máa ṣe dáadáa tá a bá ń gbóríyìn fún wọn (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn tá a bá fẹ́ fún ní ìmọ̀ràn?

14 Àwọn alàgbà àtàwọn òbí gbà pé téèyàn bá fẹ́ gbani nímọ̀ràn látinú Bíbélì, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n gbóríyìn fẹ́ni náà, kí wọ́n sì fún un níṣìírí. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fáwọn ará ní Kọ́ríńtì torí pé wọ́n tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó fún wọn, ó dájú pé á yá wọn lára láti túbọ̀ máa ṣe ohun tó tọ́. (2 Kọ́r. 7:8-11) Arákùnrin Andreas tó lọ́mọ méjì sọ pé: “Tá a bá ń gbóríyìn fáwọn ọmọ, ó máa jẹ́ kí wọ́n dàgbà dénú, kí wọ́n sì tẹ̀  síwájú nínú ìjọsìn wọn. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ fún àwọn ọmọ yín nímọ̀ràn, tẹ́ ẹ sì fẹ́ kí wọ́n fi í sílò, á dáa kẹ́ ẹ gbóríyìn fún wọn. Lóòótọ́, àwọn ọmọ wa lè mọ ohun tó tọ́, àmọ́ tá a bá fẹ́ kí wọ́n máa ṣe ohun tó tọ́, ó ṣe pàtàkì ká máa yìn wọ́n.”

BÁ A ṢE LÈ FÁWỌN MÍÌ NÍṢÌÍRÍ TÁÁ SÌ GBÉ WỌN RÓ

15. Sọ ọ̀nà kan tá a lè gbà fún àwọn míì níṣìírí.

15 Fi hàn pé o mọyì ìsapá táwọn ará ń ṣe àtàwọn ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní. (2 Kíró. 16:9; Jóòbù 1:8) Jèhófà àti Jésù mọyì ohun tí kálukú wa ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa, kódà tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba lagbára wa gbé torí ipò wa. (Ka Lúùkù 21:1-4; 2 Kọ́ríńtì 8:12.) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará kan tó jẹ́ àgbàlagbà máa ń sapá gan-an kí wọ́n lè máa wá sípàdé déédéé, wọn ò sì gbẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ṣé kò yẹ ká máa gbóríyìn fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ká sì máa fún wọn níṣìírí?

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo àǹfààní tá a ní láti fáwọn míì níṣìírí?

16 Máa lo àwọn àǹfààní tó o ní láti fún àwọn míì níṣìírí. Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó wú wa lórí, ó yẹ ká gbóríyìn fún un. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ sí Áńtíókù ní Písídíà. Àwọn alága sínágọ́gù tó wà níbẹ̀ sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, bí ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí bá wà tí ẹ ní fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́.” Pọ́ọ̀lù wá sọ àsọyé kan tó fakíki. (Ìṣe 13:13-16, 42-44) Táwa náà bá ní ọ̀rọ̀ ìṣírí tá a lè sọ fáwọn ará, ǹjẹ́ kò yẹ ká sọ ọ́? Tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa fáwọn èèyàn níṣìírí, àwọn náà á máa fún wa níṣìírí.—Lúùkù 6:38.

17. Kí ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọyì ìṣírí tá a bá fún wọn?

17 Sọ àwọn nǹkan pàtó tẹ́ni náà ṣe, kó o sì jẹ́ kó tọkàn ẹ wá. Ó dáa ká máa gbóríyìn fáwọn míì ká sì máa fún wọn níṣìírí. Àmọ́ tá a bá wo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà, a máa rí i pé Jésù yìn wọ́n fún ohun pàtó tí wọ́n ṣe. (Ka Ìṣípayá 2:18, 19.) Tó o bá jẹ́ òbí, o lè jẹ́ káwọn ọmọ rẹ mọ àwọn nǹkan pàtó tó wú ẹ lórí nípa bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. A sì lè jẹ́ kí ìyá kan tó ń dá tọ́mọ mọ̀ pé inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń kíyè sí ọ̀nà tó ń gbà tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ láìka bí nǹkan ò ṣe rọrùn. Irú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí bẹ́ẹ̀ máa ń sèso rere.

18, 19. Báwo la ṣe lè máa gbé àwọn míì ró?

18 Jèhófà kò ní ti ọ̀run máa sọ ẹni tá a máa fún níṣìírí tàbí ọ̀rọ̀ tá a máa sọ fún ẹni náà bó ṣe ní kí Mósè fún Jóṣúà níṣìírí kó sì fún un lókun. Síbẹ̀, inú Ọlọ́run máa ń dùn tá a bá ń fún àwọn ará wa àtàwọn míì níṣìírí. (Òwe 19:17; Héb. 12:12) Bí àpẹẹrẹ, a lè sọ fún alásọyé kan nípa ohun tá a gbádùn nínú àsọyé rẹ̀ tàbí bí àsọyé náà ṣe jẹ́ ká lóye ẹsẹ Bíbélì kan. Arábìnrin kan kọ̀wé sí olùbánisọ̀rọ̀ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán wá sí àpéjọ kan tó lọ, ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ́jú díẹ̀ la fi sọ̀rọ̀, ẹ rí i pé mo ní ẹ̀dùn ọkàn, àmọ́ ọ̀rọ̀ yín tù mí nínú, ó sì fi mí lọ́kàn balẹ̀. Mo fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé bẹ́ ẹ ṣe ń sọ̀rọ̀ tútù látorí pèpéle àti bẹ́ ẹ ṣe bá mi sọ̀rọ̀ jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà ló rán yín sí mi.”

19 Ó dájú pé a máa rí onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà fún àwọn míì níṣìírí tá a bá pinnu láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wa pé: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nì kìíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe ní tòótọ.” (1 Tẹs. 5:11) Gbogbo wa máa múnú Jèhófà dùn tá a bá ń “bá a nìṣó ní gbígba ara [wa] níyànjú lẹ́nì kìíní-kejì lójoojúmọ́.”

^ [1] (ìpínrọ̀ 1) A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.