“Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, . . . ẹ tẹ́wọ́ gbà á . . . gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—1 TẸS. 2:13.

ORIN: 114, 113

1-3. Kí ló ṣeé ṣe kó fa èdèkòyédè tó wáyé láàárín Yúódíà àti Síńtíkè, kí la lè ṣe tí irú ẹ̀ ò fi ní ṣẹlẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

ỌWỌ́ pàtàkì làwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi ń mú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Torí pé a jẹ́ aláìpé, kò sẹ́ni tí wọn ò lè fún ní ìmọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́. Tí wọ́n bá fún wa ní ìmọ̀ràn, kí la máa ṣe? Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni méjì tó ń jẹ́ Yúódíà àti Síńtíkè ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Èdèkòyédè wáyé láàárín àwọn obìnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró yìí. Àmọ́, Bíbélì ò sọ ohun tó fa èdèkòyédè náà. Síbẹ̀, kí nǹkan tá à ń sọ lè yé wa, ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná.

2 Ká sọ pé Yúódíà pe àwọn ará kan wá sílé rẹ̀ kí wọ́n lè gbádùn ara wọn, àmọ́ kò pe Síńtíkè. Tí Síńtíkè bá gbọ́ nípa ìkórajọ yìí, ó máa yà á lẹ́nu, ó sì lè máa ronú pé: ‘Ìyẹn ni pé Yúódíà lè pe àwọn èèyàn kó má sì pè mí. Mo sì rò pé ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni wá.’ Ìyẹn lè mú kí Síńtíkè bẹ̀rẹ̀ sí í fojú burúkú wo Yúódíà, kó sì máa fura sí i. Bí Síńtíkè náà ṣe ṣètò ìkórajọ tiẹ̀ nìyẹn, ó pe àwọn ará kan náà tí Yúódíà pè, àmọ́ kò pe Yúódíà. Ó ṣeé ṣe kí èdèkòyédè tó wáyé láàárín  wọn fa ìyapa nínú ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ibi tí ọ̀rọ̀ náà já sí fún wa, ó ṣeé ṣe káwọn arábìnrin yìí fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò.—Fílí. 4:2, 3.

3 Lónìí, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ. Àmọ́ tá a bá fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, irú èdèkòyédè yìí lè má ṣẹlẹ̀. Tírú ẹ̀ bá sì ṣẹlẹ̀, àá tètè yanjú rẹ̀ kó tó di wàhálà. Tá a bá fọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àá máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú rẹ̀.—Sm. 27:11.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ NÍ KÁ ṢE TÁWỌN ÈÈYÀN BÁ ṢẸ̀ WÁ

4, 5. Kí ni Bíbélì rọ̀ wá pé ká ṣe tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá?

4 Tí ẹnì kan bá fojú pa wá rẹ́ tàbí tí wọ́n rẹ́ wa jẹ, inú máa ń bí wa kì í sì í rọrùn láti pa á mọ́ra. Táwọn èèyàn bá ṣàìdáa sí wa torí ibi tá a ti wá tàbí torí àwọ̀ wa tàbí torí àwọn nǹkan míì, ó máa ń ká wa lára gan-an. Àmọ́, ó máa dùn wá gan-an tó bá jẹ́ pé àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni ló ṣe irú ẹ̀ sí wa. Ṣé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ tí àìpé bá mú káwọn èèyàn ṣe irú ẹ̀ sí wa?

5 Àtìgbà tí Jèhófà ti dá àwa èèyàn ló ti mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Ó mọ nǹkan tá a lè ṣe bí inú bá bí wa. Ó mọ̀ pé bí inú bá ń bí wa, a lè ṣi ọ̀rọ̀ sọ tàbí ká hùwà tá a máa kábàámọ̀ tó bá yá. Ìdí nìyẹn tó fi dáa ká máa fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé ká máa ṣe sùúrù, ká má sì tètè máa bínú. (Ka Òwe 16:32; Oníwàásù 7:9.) Kò yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan máa ká wa lára ju bó ṣe yẹ lọ, ká sì kọ́ bá a ṣe lè túbọ̀ máa dárí jini. Ìdí ni pé ọwọ́ kékeré kọ́ ni Jèhófà àti Jésù fi ń mú ọ̀rọ̀ dídárí jini. (Mát. 6:14, 15) Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé, ṣó yẹ kí n túbọ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń dárí jini? Ṣó sì yẹ kí n túbọ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń pa nǹkan mọ́ra?

6. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa dinú?

6 Àwọn tí kì í gbọ́kàn kúrò lórí ọ̀rọ̀ sábà máa ń kanra, wọ́n sì máa ń dinú. Èyí lè mú káwọn èèyàn máa yẹra fún wọn. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa sọ̀rọ̀ àwọn míì láìdáa, kíyẹn sì dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ. Ó lè máa ṣojú fúrú bíi pé kò sí nǹkan kan lọ́kàn rẹ̀ mọ́, àmọ́ bó pẹ́ bó yá èrò burúkú tó wà lọ́kàn rẹ̀ máa “tú síta nínú ìjọ.” (Òwe 26:24-26) Táwọn alàgbà bá kíyè sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, wọ́n á jẹ́ kó mọ̀ pé inú Ọlọ́run kì í dùn sáwọn tó ń di èèyàn sínú tàbí àwọn tó kórìíra àwọn míì tàbí àwọn tí kò lẹ́mìí ìdáríjì. Bíbélì tiẹ̀ jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run kórìíra irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀. (Léf. 19:17, 18; Róòmù 3:11-18) Ṣé ìwọ náà fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ?

BÍ JÈHÓFÀ ṢE Ń DARÍ WA

7, 8. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lónìí? (b) Sọ díẹ̀ lára àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé wọn?

7 Lónìí, Jèhófà ń bọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ń darí wọn. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni ó ń lò láti ṣe iṣẹ́ yìí, Kristi tó jẹ́ “orí ìjọ” ló sì ń darí wọn. (Mát. 24:45-47; Éfé. 5:23) Bíi ti ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ẹrú yìí gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú un. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:13.) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì tó ń ṣe wá láǹfààní?

8 Bíbélì sọ pé a gbọ́dọ̀ máa pé jọ sípàdé déédéé. (Héb. 10:24, 25) Ó tún sọ pé ìmọ̀ òtítọ́ tá a ní gbọ́dọ̀ ṣọ̀kan. (1 Kọ́r. 1:10) Bíbélì sọ fún wa pé Ìjọba Ọlọ́run la gbọ́dọ̀ fi sípò àkọ́kọ́ ní  ìgbésí ayé wa. (Mát. 6:33) Ìwé Mímọ́ tún jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ máa wàásù láti ilé dé ilé, ká sì máa kọ́ àwọn èèyàn láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí àti lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 5:42; 17:17; 20:20) Bíbélì sọ pé àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ mú kí ìjọ Ọlọ́run wà ní mímọ́. (1 Kọ́r. 5:1-5, 13; 1 Tím. 5:19-21) Jèhófà sì sọ pé gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí.—2 Kọ́r. 7:1.

9. Ọ̀nà kan ṣoṣo wo ni Jésù ń lò láti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wa lónìí?

9 Àwọn kan máa ń ronú pé àwọn lè lóye Bíbélì láyè ara wọn. Àmọ́, “ẹrú olóòótọ́” nìkan ni Jésù yàn pé kó máa fi ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wa. Láti ọdún 1919 ni Jésù ti ń lo ẹrú olóòótọ́ yìí láti mú káwọn èèyàn Ọlọ́run lóye Bíbélì, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni rẹ̀. Tá a bá a ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan máa wà nínú ìjọ, ìjọ sì máa jẹ́ mímọ́. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé mò ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Jésù ń fún wa nípasẹ̀ ẹrú olóòótọ́?’

ÈTÒ JÈHÓFÀ Ń TẸ̀ SÍWÁJÚ!

10. Báwo ni ìwé Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà?

10 Bíbélì jẹ́ ká mọ apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìran kan, wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run tó dúró fún apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà. (Ìsík. 1:4-28) Jèhófà ló wà lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin yìí, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ló sì fi ń darí kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà. Torí náà, apá ti ọ̀run yìí ló ń darí apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà. Ká sòótọ́, kẹ̀kẹ́ ẹṣin yìí ń bá eré lọ! Ìwọ ronú nípa àwọn àyípadà tó ti wáyé nínú ètò Ọlọ́run láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, má sì gbàgbé pé Jèhófà ló ń mú káwọn àyípadà náà wáyé. Bí Kristi àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ṣe ń gbára dì láti pa ayé búburú yìí run, kẹ̀kẹ́ ẹṣin Jèhófà túbọ̀ ń báṣẹ́ lọ kó lè sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, kó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run!

A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé (Wo ìpínrọ̀ 11)

11, 12. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí ètò Ọlọ́run ń gbéṣe lónìí?

11 Ẹ jẹ́ ká ronú nípa iṣẹ́ tí apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run ń gbéṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Iṣẹ́ Ìkọ́lé. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ ló ń ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Warwick, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Kárí Ayé ló ń bójú tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé kárí ayé. Lára àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ni pé wọ́n ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, wọ́n sì ń mú àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa gbòòrò sí i. A mà dúpẹ́ o pé àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni yìí ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé yìí! Jèhófà sì ń bù kún gbogbo àwọn olóòótọ́ tó ń fowó ṣètìlẹyìn fún àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tá à ń ṣe kárí ayé.—Lúùkù 21:1-4.

 12 Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Onírúurú ilé ẹ̀kọ́ ni Jèhófà ti ń dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. (Aísá. 2:2, 3) Lára wọn ni Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà, Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run, Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Wọ Bẹ́tẹ́lì, Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Àyíká Àtàwọn Ìyàwó Wọn, Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Ìjọ, Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Àtàwọn Ìyàwó Wọn. Àbí ẹ ò rí i pé Jèhófà fẹ́ràn láti máa dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́! Bákan náà ni Ìkànnì wa, ìyẹn jw.org tún ń gbé ẹ̀kọ́ òtítọ́ lárugẹ torí pé ọ̀pọ̀ ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè ló wà níbẹ̀. Ìkànnì yìí ní abala àwọn ọmọdé àti abala tó wà fáwọn ìdílé, ó tún ní abala téèyàn ti lè rí àwọn ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́. Ṣé ìwọ náà ń lo Ìkànnì jw.org lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti nígbà ìjọsìn ìdílé yín?

JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ SÍ JÈHÓFÀ ÀTI ÈTÒ RẸ̀

13. Kì làwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ máa ṣe?

13 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní pé a wà nínú ètò Jèhófà! Torí pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, a sì mọ̀ pé ohun tó tọ́ la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè fi hàn pé Jèhófà la gbà pé ó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Ojoojúmọ́ layé yìí ń burú sí i, torí náà a gbọ́dọ̀ “kórìíra ohun búburú” bí Jèhófà náà ṣe kórìíra rẹ̀. (Sm. 97:10) A ò ní fara mọ́ èrò àwọn èèyàn inú ayé tí wọ́n gbà pé “ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára.” (Aísá. 5:20) Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń sapá láti jẹ́ mímọ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí, a sì máa ń yẹra fún ìwàkiwà torí pé a fẹ́ múnú Jèhófà dùn. (1 Kọ́r. 6:9-11) Àwọn ìlànà Bíbélì la máa ń tẹ̀ lé nígbèésí ayé wa torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà a sì fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, gbogbo ìgbà la máa ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí nínú ilé, nínú ìjọ, níbi iṣẹ́, níléèwé àti láwọn ibòmíì. (Òwe 15:3) Ẹ jẹ́ ká tún wo àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.

14. Báwo làwọn òbí Kristẹni ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?

14 Bá a ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wa. Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ń fi ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ wọn. Wọn kì í jẹ́ kí àṣà ìbílẹ̀ tó bá ta ko ìlànà Bíbélì nípa lórí bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn. Àwa Kristẹni kì í sì í fàyè gba ẹ̀mí ayé nínú ilé wa. (Éfé. 2:2) Kò yẹ kí bàbá kan tó ti ṣèrìbọmi máa ronú pé, ‘Nílùú wa, àwọn obìnrin ló máa ń kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́.’ Ìlànà Bíbélì ṣe kedere lórí kókó yìí, ó ní: “Ẹ̀yin baba, . . . ẹ máa bá a lọ ní títọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Àwọn òbí tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run máa ń fẹ́ káwọn ọmọ wọn dà bíi Sámúẹ́lì torí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀ bó ṣe ń dàgbà, ó sì dúró tì í.—1 Sám. 3:19.

15. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì?

15 Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu. Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé wa, á dáa ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ètò rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ náà ká lè fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ kan tó kan ọ̀pọ̀ òbí. Àwọn kan máa ń ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè míì kí nǹkan lè túbọ̀ rọ̀ṣọ̀mù fún wọn. Tí àwọn kan lára wọn bá bímọ, wọ́n máa ń fi ọmọ náà ránṣẹ́ sáwọn mọ̀lẹ́bí wọn nílé kí wọ́n lè bá wọn tọ́ ọ. Àwọn á sì máa bá iṣẹ́ tiwọn lọ kówó lè máa wọlé. Lóòótọ́, ọwọ́ wa ni ìpinnu yẹn wà, àmọ́ ó yẹ ká rántí pé a máa jíhìn fún ìpinnu èyíkéyìí tá a bá ṣe.  (Ka Róòmù 14:12.) Torí náà, ó yẹ ká kọ́kọ́ ronú nípa ohun tí Bíbélì sọ ká tó ṣèpinnu tó máa kan àwọn ará ilé wa tàbí iṣẹ́ tá a fẹ́ ṣe. Ìdí ni pé Baba wa ọ̀run ló gbọ́dọ̀ máa tọ́ wa sọ́nà torí pé a ò lè darí ara wa.—Jer. 10:23.

16. Nígbà tí obìnrin kan bímọ, ìpinnu wo ló ní láti ṣe, kí ló sì ràn án lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́?

16 Lẹ́yìn tí obìnrin kan tó ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè míì bímọ, ó pinnu láti fi ọmọ náà ránṣẹ́ sáwọn òbí rẹ̀ àgbà nílé, kí wọ́n lè bá a tọ́ ọ. Ìgbà tí obìnrin yẹn bímọ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti tọ́ ọmọ òun kì í ṣe ẹlòmíì, òun sì gbọ́dọ̀ kọ́ ọmọ náà láti sin Jèhófà. (Sm. 127:3; Òwe 22:6) Obìnrin yìí gbàdúrà sí Jèhófà bí Bíbélì ṣe ní ká máa ṣe. (Sm. 62:7, 8) Ó sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn míì nínú ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń fúngun mọ́ ọn pé kó fi ọmọ náà ránṣẹ́ sílé, síbẹ̀ ó kọ̀, torí ó mọ̀ pé kò yẹ kóun ṣe bẹ́ẹ̀. Inú ọkọ rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó rí bí àwọn ará ṣe dúró ti ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ wọn, bóun náà ṣe gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ nìyẹn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé pẹ̀lú ìyàwó àti ọmọ rẹ̀. Ẹ ò rí i pé inú obìnrin yìí máa dùn nígbà tó rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà rẹ̀.

17. Ìtọ́ni wo ni ètò Ọlọ́run fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

17 Bá a ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́ni. Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ni pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tá à ń rí gbà látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run fún wa láwọn àbá nípa bó ṣe yẹ ká máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ètò Ọlọ́run sọ ohun tó yẹ ká máa ṣe tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí i fi ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, ó yẹ ká jẹ́ kẹ́ni náà mọ púpọ̀ sí i nípa ètò Ọlọ́run. A lè lo fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? àti ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? Ètò Ọlọ́run dábàá pé tá a bá ti parí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni pẹ̀lú ẹni tá à ń kọ́, ká tún kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ pẹ̀lú ẹni náà kódà tó bá ti ṣèrìbọmi pàápàá. Ètò Ọlọ́run fún wa ní ìtọ́ni yìí kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun lè “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Kól. 2:7) Ṣé ìwọ náà ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa yìí?

18, 19. Sọ díẹ̀ lára àwọn ìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.

18 Tá a bá ní ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún gbogbo ohun tó ti ṣe fún wa, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Òun ló fún wa lẹ́mìí, ó sì ń dá wa sí. (Ìṣe 17:27, 28) Ó tún fún wa ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ìyẹn Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bíi tàwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà, àwa náà gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì a sì fọwọ́ pàtàkì mú un.—1 Tẹs. 2:13.

19 Bíbélì ti mú ká sún mọ́ Jèhófà, òun náà sì ti sún mọ́ wa. (Ják. 4:8) Àǹfààní ńlá ni Baba wa ọ̀run fún wa bó ṣe mú ká wà nínú ètò rẹ̀. A sì mọyì àwọn ìbùkún tá à ń rí gbà. Onísáàmù náà sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nígbà tó kọrin pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere: Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sm. 136:1) Ìgbà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] ni ọ̀rọ̀ náà “inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” fara hàn nínú ìwé Sáàmù 136. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ yẹn máa ṣẹ sí wa lára torí a máa wà láàyè títí láé!