Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  November 2016

Wọ́n Bọ́ Lọ́wọ́ Ìsìn Èké

Wọ́n Bọ́ Lọ́wọ́ Ìsìn Èké

“Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi.”ÌṢÍ. 18:4.

ORIN: 101, 93

1. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn èèyàn Ọlọ́run máa bọ́ lọ́wọ́ Bábílónì Ńlá, àwọn ìbéèrè wo la sì máa jíròrò?

NÍNÚ àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé ìgbà kan wà táwọn Kristẹni tòótọ́ bára wọn nínú ohun tá a lè pè ní akóló Bábílónì. Àmọ́ inú wa dùn pé wọn ò ní wà níbẹ̀ títí lọ. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé Ọlọ́run pàṣẹ pé, “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi.” Ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni àṣẹ yẹn ì bá jẹ́ ká sọ pé kò sẹ́ni tó lè bọ́ lóko òǹdè Bábílónì Ńlá, ìyẹn ìsìn èké ayé yìí. (Ka Ìṣípayá 18:4.) Ó wù wá ká mọ ìgbà táwọn èèyàn Ọlọ́run bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ìsìn èké. Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́ ná, á dáa ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí: Kí làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nípa Bábílónì Ńlá láwọn ọdún tó ṣáájú 1914? Irú ọwọ́ wo làwọn ará wa fi mú iṣẹ́ ìwàásù lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní? Ṣé torí pé Ọlọ́run fẹ́ bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí ló ṣe jẹ́ kí wọ́n wà nígbèkùn Bábílónì lásìkò yẹn?

BÁBÍLÓNÌ ṢUBÚ

2. Kí làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nípa gbogbo ìsìn tí wọ́n kà sí ìsìn èké?

2 Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní, Arákùnrin Charles Taze Russell àtàwọn yòókù rẹ̀ rí i kedere pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Ìdí nìyẹn táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà fi pinnu pé àwọn ò ní ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú gbogbo ìsìn tí wọ́n kà sí ìsìn èké. Kódà, nínú ìwé ìròyìn  Zion’s Watch Tower tó jáde lóṣù November, 1879, wọ́n jẹ́ káyé mọ̀ pé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ làwọn rọ̀ mọ́. Wọ́n sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí tó bá sọ pé òun jẹ́ wúńdíá ìyàwó Kristi, àmọ́ tó wá ń ní àjọṣe pẹ̀lú ayé (ìyẹn ẹranko) tí ayé sì ń tì lẹ́yìn, kò sí orúkọ míì tá a lè pe irú ṣọ́ọ̀ṣì bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe orúkọ tí Ìwé Mímọ́ pè é, orúkọ náà ni aṣẹ́wó ṣọ́ọ̀ṣì,” ìyẹn Bábílónì Ńlá.—Ka Ìṣípayá 17:1, 2.

3. Kí làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe láti fi hàn pé wọ́n lóye ìdí tó fi yẹ kí wọ́n jáwọ́ nínú ìsìn èké? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

3 Àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin mọ ohun tó yẹ káwọn ṣe. Wọ́n mọ̀ pé táwọn bá máa rí ojúure Ọlọ́run, àwọn ò gbọ́dọ̀ ti ìsìn èké lẹ́yìn lọ́nàkọnà. Torí náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló kọ lẹ́tà sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọn pé àwọn ò ṣe mọ́. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń ka lẹ́tà ọ̀hún sétíìgbọ́ àwọn tó pé jọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Láwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí kò gbà pé kí wọ́n kà á, àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń fi ẹ̀dà lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí gbogbo ọmọ ìjọ. Wọ́n jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìsìn èké mọ́! Láwọn ìgbà kan, ẹni bá dán irú ẹ̀ wò á jẹyán ẹ̀ níṣu. Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 1870, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni ò gba tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì mọ́, ìjọba sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ̀yìn sí wọn. Pẹ̀lú bọ́rọ̀ ṣe rí yẹn, àwọn aráàlú wá lómìnira láti máa sọ̀rọ̀ nípa ìsìn bí wọ́n ṣe fẹ́, wọ́n sì lè bẹnu àtẹ́ lu àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà nígbà yẹn.

4. Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe nípa Bábílónì Ńlá lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní?

4 Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé ó dáa báwọn ṣe sọ fún tẹbí tọ̀rẹ́ àtàwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì wọn tẹ́lẹ̀ pé àwọn kì í ṣe ọmọ ìjọ wọn mọ́, àmọ́ wọ́n gbà pé ìyẹn nìkan ò tó. Gbogbo ayé ló gbọ́dọ̀ mọ̀ pé aṣẹ́wó amúnisìn ni Bábílónì Ńlá! Torí náà, láàárín December 1917 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1918 nìkan, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá ìwé àṣàrò kúkúrú táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pín fáwọn èèyàn. Bí ẹni sọ̀kò ìbànújẹ́ lu àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lọ̀rọ̀ inú ìwé náà torí pé àkòrí ìwé náà ni, “The Fall of Babylon,” ìyẹn, Bábílónì Ṣubú. Ẹ fojú inú wo bó ṣe máa rí lára àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, ṣe ni wọ́n fárígá. Àmọ́, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò tiẹ̀ wojú wọn, ṣe làwọn ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ ràì. Wọ́n pinnu pé àwọn “gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Kí wá la lè sọ níbi tọ́rọ̀ dé yìí? Kókó náà ni pé, dípò táwọn Kristẹni tòótọ́ yẹn ì bá fi dẹrú Bábílónì Ńlá lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní, ṣe ni wọ́n ń jára wọn gbà lọ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti dòmìnira.

WỌ́N FÌTARA WÀÁSÙ LÁSÌKÒ OGUN ÀGBÁYÉ KÌÍNÍ

5. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé àwọn ará fìtara wàásù lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní?

5 Láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, a gbà pé inú Jèhófà ò dùn sáwọn èèyàn rẹ̀ torí pé wọn ò fìtara wàásù lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní. A ṣàlàyé pé ohun tó fà á nìyẹn tí Jèhófà fi jẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ lọ sígbèkùn Bábílónì Ńlá fúngbà díẹ̀ lásìkò ogun yẹn. Àmọ́, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láàárín ọdún 1914 sí 1918 jẹ́ ká mọ̀ nígbà tó yá pé àwọn èèyàn Jèhófà lápapọ̀ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa wàásù ìhìn rere ní gbogbo ìgbà yẹn. Ẹ̀rí sì fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lóòótọ́. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn àwa èèyàn Ọlọ́run nígbà yẹn ti mú ká túbọ̀ lóye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú Bíbélì.

6, 7. (a) Ìṣòro wo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní? (b) Sọ àwọn ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn fìtara wàásù.

6 Ẹ̀rí fi hàn pé lásìkò Ogun Àgbáyé  Kìíní (tí wọ́n jà lọ́dún 1914 sí 1918), ọwọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nǹkan ò rọgbọ rárá fún wọn lásìkò yẹn, ó sì nídìí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó fà á tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀ pọ̀, àmọ́ ẹ jẹ́ ká sọ méjì lára wọn. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé, ọ̀nà kan táwọn ará wa ń lò jù láti wàásù nígbà yẹn ni pínpín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn. Torí bẹ́ẹ̀, nígbà táwọn ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé ìwé The Finished Mystery níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1918, ó nira díẹ̀ fún ọ̀pọ̀ àwọn ará láti wàásù. Wọn ò tíì mọ béèyàn ṣe lè máa fi Bíbélì nìkan wàásù, ìwé The Finished Mystery ló sábà máa ń gbẹnu sọ fún wọn. Ìdí kejì ni ti àrùn gágá tó jà lọ́dún 1918, tó sì pa àwọn èèyàn nípakúpa. Bí àrùn yẹn ṣe gbilẹ̀ mú kó ṣòro fáwọn ará láti wàásù bí wọ́n ṣe fẹ́. Láìka ìṣòro méjèèjì yìí àtàwọn ìṣòro míì sí, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lápapọ̀ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí i pé iṣẹ́ ìwàásù náà kò dúró.

Ó dájú pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn fìtara wàásù! (Wo ìpínrọ̀ 6 àti 7)

7 Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1914 nìkan, ìwọ̀nba àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà nígbà yẹn fi sinimá “Photo-Drama of Creation” [ìyẹn, Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] han àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án. Sinimá yẹn ní àwọn àwòrán ara ògiri nínú, ó sì tún ní ohùn tó ń dún lábẹ́lẹ̀, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìtàn aráyé, bẹ̀rẹ̀ látinú ọgbà Édẹ́nì títí dé ìparí ẹgbẹ̀rún ọdún tí Kristi á fi ṣàkóso. Ohun táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ṣe ya àwọn èèyàn lẹ́nu gan-an torí pé kò sírú ẹ̀ nígbà yẹn. Ẹ tiẹ̀ wò ó ná. Iye èèyàn tó wo fídíò yẹn lọ́dún 1914 nìkan ju àròpọ̀ iye àwa akéde Ìjọba Ọlọ́run tó ń wàásù ní gbogbo ayé lónìí! Ìròyìn tún jẹ́ ká mọ̀ pé lọ́dún 1916, àwọn tó pé jọ sípàdé tá a ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ lọ [809,393], nígbà tó sì di ọdún 1918, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan [949,444]. Ǹjẹ́ kò ṣe kedere pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn fìtara wàásù? Ó dájú pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀!

8. Báwo làwọn ará ṣe ń rí okun tẹ̀mí gbà lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní?

8 Ní gbogbo àsìkò tí wọ́n ń ja Ogun Àgbáyé Kìíní, oúnjẹ tẹ̀mí ò yé dé ọ̀dọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi gbogbo. Àwọn ará sì ń tipa bẹ́ẹ̀ rí okun gbà láti máa báṣẹ́ ìwàásù lọ. Arákùnrin Richard H. Barber tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń fìtara wàásù lásìkò yẹn sọ pé: “A rí i  dájú pé à ń rán àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò mélòó kan sáwọn ìjọ, à ń pín ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kiri, kódà a tún ń fi ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè Kánádà níbi tí ìjọba ti ka ìwé ìròyìn náà léèwọ̀. Mo fi ìwé The Finished Mystery tá a ṣe ní ẹ̀dà kékeré tó ṣe é kì bàpò ránṣẹ́ sáwọn ará tí ìjọba ti gba èyí tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Arákùnrin Rutherford ní ká ṣètò àwọn àpéjọ àgbègbè láwọn ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lápá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, a sì rán àwọn olùbánisọ̀rọ̀ síbẹ̀ kí wọ́n lè fún àwọn ará níṣìírí tó bá ti lè ṣeé ṣe tó.”

WỌ́N NÍLÒ ÌYỌ́MỌ́

9. (a) Kí nìdí táwọn èèyàn Ọlọ́run fi nílò ìbáwí láwọn ọdún 1914 sí 1919? (b) Kí nìyẹn ò wá túmọ̀ sí?

9 Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo ohun táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe láwọn ọdún 1914 sí 1919 ló bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu délẹ̀délẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ inú làwọn ará wa fi ń ṣe nǹkan lásìkò yẹn, wọn ò mọ ibi tó yẹ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ mọ. (Róòmù 13:1) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n dá sí ọ̀rọ̀ ogun. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pàṣẹ pé káwọn èèyàn ya May 30, 1918, sọ́tọ̀ láti gbàdúrà fún àlàáfíà, ètò Ọlọ́run sọ nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ pé káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà dara pọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ará kan lọ yáwó kí wọ́n lè fowó ti ogun náà lẹ́yìn, nígbà táwọn mélòó kan tiẹ̀ wọṣẹ́ ológun tí wọ́n sì gbébọn lójú ogun. Àmọ́ o, a ò lè sọ pé àṣìṣe táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ṣe ló fà á tí wọ́n fi lọ sígbèkùn Bábílónì kí wọ́n lè gba ìbáwí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ó yẹ káwọn yẹra pátápátá fún ìsìn èké, ó sì ṣe kedere pé lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní, wọn ò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìsìn èké ayé yìí.—Ka Lúùkù 12:47, 48.

10. Kí làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe tó fi hàn pé wọ́n ka ẹ̀mí sí pàtàkì?

10 Lóòótọ́, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ò lóye gbogbo ohun tó wé mọ́ kéèyàn má ṣe jẹ́ apá kan ayé bí àwa ṣe lóye rẹ̀ lónìí, síbẹ̀ ohun kan wà tí wọ́n mọ̀ dunjú, wọ́n mọ̀ pé Bíbélì sọ pé a ò gbọ́dọ̀ pààyàn. Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn mélòó kan lára wọn wọṣẹ́ ológun tí wọ́n sì lọ sójú ogun nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wọn ò kọjú ìbọn sẹ́nikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò pààyàn. Torí pé àwọn ará ò gbà láti pààyàn, wọ́n kó wọn lọ síbi tógun ti le káwọn ọ̀tá lè pa wọ́n dànù.

11. Báwo ló ṣe rí lára àwọn aláṣẹ nígbà táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pinnu pé àwọn ò ní jà lójú ogun?

11 Inú Èṣù ò dùn rárá pé àwọn ará ò pààyàn lójú ogun, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ṣe ṣì kù díẹ̀ káàtó. Ìdí nìyẹn tí Sátánì fi wá fi “àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n.” (Sm. 94:20) Nígbà tí Ọ̀gágun James Franklin Bell tó jẹ́ ọ̀gá ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Arákùnrin J. F. Rutherford àti W. E. Van Amburgh, ó sọ pé Ẹ̀ka Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìdájọ́ Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fẹ́ kí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ṣe òfin pé tí ẹnikẹ́ni bá sọ pé òun ò ní jà lójú ogun, ṣe ni kí wọ́n pa onítọ̀hún. Ó sì dájú pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ní lọ́kàn. Bọ́rọ̀ náà ṣe ká Ọ̀gágun Bell lára tó, ó fìbínú sọ fún Arákùnrin Rutherford pé: “Ẹ jọlá pé Wilson [ìyẹn ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà] ò fọwọ́ sí òfin yẹn, àmọ́ o, kẹ́ ẹ fò kẹ́ ẹ dẹyẹ, ọwọ́ wa máa tẹ̀ yín!”

12, 13. (a) Kí nìdí tí wọ́n fi fàwọn arákùnrin mẹ́jọ sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ? (b) Ṣé ìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn ará yẹn mú kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà? Ṣàlàyé.

12 Ohun táwọn aláṣẹ yẹn sọ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Ká tó wí ká tó fọ̀, wọ́n fàṣẹ ọba mú Arákùnrin Rutherford àti  Arákùnrin Van Amburgh pẹ̀lú àwọn mẹ́fà míì. Nígbà tí adájọ́ máa dá ẹjọ́ náà, ó sọ pé: “Ohun táwọn èèyàn yìí gbà gbọ́ tí wọ́n sì ń polongo mú kí wọ́n burú ju àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì tá à ń bá jà . . . Wọ́n ń fojú di àwọn agbófinró orílẹ̀-èdè yìí àtàwọn ológun wa, ìyẹn nìkan kọ́, wọ́n tún bẹnu àtẹ́ lu gbogbo àwọn àlùfáà tó wà láwọn ṣọ́ọ̀ṣì. Ṣe ló yẹ ká fimú wọn fọn fèrè.” (Ìwé Faith on the March, tí Arákùnrin A. H. Macmillan kọ, ojú ìwé 99) Ohun tí wọ́n sì ṣe gan-an nìyẹn. Wọ́n ju àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́jọ yẹn sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ tó wà nílùú Atlanta, Georgia, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́ nígbà tógun yẹn parí, wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n sì fagi lé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

13 Kódà ní gbogbo ìgbà táwọn arákùnrin mẹ́jọ yẹn fi wà lẹ́wọ̀n, ohun tí Bíbélì sọ ni wọ́n rọ̀ mọ́. Nínú lẹ́tà kan tí wọ́n kọ sí ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tí wọ́n fi ń rọ̀ ọ́ pé kó dá sọ́rọ̀ àwọn, wọ́n sọ pé: “Àṣẹ tí Olúwa pa fáwọn èèyàn rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ni pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn.’ Torí náà, bí ẹnikẹ́ni lára àwa Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì [ìyẹn, International Bible Students Association] tá a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Olúwa bá mọ̀ọ́mọ̀ tàpá sí àṣẹ Olúwa, irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa rí ìbínú Ọlọ́run, ó sì lè pa run. Ìdí nìyẹn tí èyíkéyìí lára wa ò fi ní lọ́wọ́ nínú ogun, bẹ́ẹ̀ la ò sì ní pààyàn.” Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ akin nìyẹn! Kò sí àní-àní pé àwọn ará yẹn rọ̀ mọ́ ìpinnu wọn láti ṣègbọràn sí Jèhófà!

ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN DÒMÌNIRA NÍGBẸ̀YÌNGBẸ́YÍN!

14. Fi Bíbélì ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914 sí 1919.

14 Málákì 3:1-3 ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919, pé Ọlọ́run máa yọ́ àwọn ẹni àmì òróró “ọmọ Léfì” mọ́. (Kà á.) Láwọn ọdún yẹn, “Olúwa tòótọ́,” ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run wá sí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí pẹ̀lú Jésù Kristi tí Bíbélì pè ní “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà” láti wá wo àwọn tó ń sìn nínú tẹ́ńpìlì náà. Lẹ́yìn tí Jèhófà ti bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí tó sì ti yọ́ wọn mọ́, ó mú kí wọ́n gbára dì láti gba àfikún iṣẹ́. Abájọ tó fi jẹ́ pé lọ́dún 1919, Jèhófà yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pé kó máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fáwọn ará ilé ìgbàgbọ́. (Mát. 24:45) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn èèyàn Ọlọ́run bọ́ pátápátá lọ́wọ́ Bábílónì Ńlá. Jèhófà fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sáwọn èèyàn rẹ̀, àtìgbà yẹn ló sì ti mú kí wọ́n túbọ̀ máa lóye ìfẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Baba wọn ọ̀run. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ń bù kún àwa èèyàn rẹ̀! [1]

15. Ní báyìí tá a ti bọ́ lọ́wọ́ Bábílónì Ńlá, kí ló yẹ ká ṣe?

15 Inú wa mà dùn o pé àwa èèyàn Jèhófà ò sí lábẹ́ ìgbèkùn Bábílónì Ńlá mọ́! Pàbó ni gbogbo akitiyan Sátánì láti pa àwa Kristẹni tòótọ́ run já sí. Àmọ́ o, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé ìdí tí Jèhófà fi dá wa sílẹ̀ lómìnira. (2 Kọ́r. 6:1) Ọ̀pọ̀ èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ṣì wà nínú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìsìn èké. Wọ́n ń retí ẹni tó máa tú wọn sílẹ̀. Jèhófà ti fi kọ́kọ́rọ́ ẹ̀ lé wa lọ́wọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe bíi tàwọn ará wa nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe káwọn èèyàn náà lè jàjà bọ́ lọ́wọ́ ìsìn èké!

^ [1] (ìpínrọ̀ 14) Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù tó lọ sígbèkún fún àádọ́rin [70] ọdún jọra pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì kú tí ìpẹ̀yìndà sì bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, kò jọ pé lílọ táwọn Júù lọ sígbèkùn jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni. Kókó kan ni pé, ọdún tí àwùjọ kọ̀ọ̀kan fi wà nígbèkùn yàtọ̀ síra. Torí náà, kò sídìí tó fi yẹ ká máa wá kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ìgbèkùn àwọn Kristẹni ṣe jọra pẹ̀lú tàwọn Júù, bí ẹni pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù ní láti bá ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹni àmì òróró mu láwọn ọdún yẹn títí di ọdún 1919.