Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Látinú Àpamọ́ Wa

“Ẹ Jára Mọ́ṣẹ́, Ẹ̀yin Akéde Ìjọba Ọlọ́run Tó Wà Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì!!”

“Ẹ Jára Mọ́ṣẹ́, Ẹ̀yin Akéde Ìjọba Ọlọ́run Tó Wà Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì!!”

ÀPILẸ̀KỌ kan tó jáde nínú ìwé tá a wá mọ̀ sí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa dà bí ìpè tó ń dún kíkankíkan fáwọn ará wa nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó ní: “Ẹ Jára Mọ́ṣẹ́, Ẹ̀yin Akéde Ìjọba Ọlọ́run Tó Wà Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì!!” (Ìwé Informant, December 1937, ẹ̀dá tá a ṣe fáwọn ará nílùú London) Ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ kan nínú àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Iye Àwọn Èèyàn Tó Wá Sínú Ètò Ọlọ́run Láàárín Ọdún Mẹ́wàá Kò Tó Nǹkan.” Àtẹ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdún mẹ́wàá, ìyẹn láti ọdún 1928 sí 1937, tí wọ́n tẹ̀ síwájú ìwé náà fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.

ṢÉ ÀWỌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ PỌ̀ JÙ NI?

Kí ló fà á tí nǹkan fi rí bẹ́ẹ̀ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà yẹn? Ó jọ pé àwọn ará ò fi bẹ́ẹ̀ jára mọ́ṣẹ́ ìwàásù torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ló ti dà bíi pé àwọn ará ti ń fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú iṣẹ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì ti sọ pé ìwọ̀nba ọgọ́rùn méjì [200] àwọn aṣáájú-ọ̀nà nìkan ló lè ṣiṣẹ́ láwọn àgbègbè àdádó tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wá sọ fáwọn tó bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pé níwọ̀n bí kò ti síbi tí wọ́n ti lè sìn nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, á dáa kí wọ́n kọjá lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ Yúróòpù. Àwọn ará dáhùn pa dà lọ́nà tó wúni lórí gan-an, torí pé ṣe làwọn aṣáájú-ọ̀nà ń fi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀ tí wọ́n sì ń lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì bí ilẹ̀ Faransé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè wọn.

“Ẹ JÁRA MỌ́ṢẸ́”

Ìwé Informant, December 1937 yẹn sọ ohun kan láti sún àwọn ará sẹ́nu iṣẹ́, ó ní: A fẹ́ ṣe mílíọ̀nù kan wákàtí lọ́dún 1938! Àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé bí akéde kọ̀ọ̀kan bá ṣe wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lóṣù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, táwọn aṣáájú-ọ̀nà náà bá ṣe àádọ́fà [110] wákàtí lóṣù, wẹ́rẹ́ ni mílíọ̀nù kan yẹn máa pé. Wọ́n wá dábàá pé kí ìjọ ṣètò àwọn ọjọ́ mélòó kan táwọn akéde á lè lo wákàtí márùn-ún lóde ẹ̀rí, kí wọ́n sì rí i pé àwọn ń ṣe ìpadàbẹ̀wò lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀.

Àwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara ṣiṣẹ́ kárakára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù

Ohun tí ìwé yẹn sọ wú àwọn ará lórí gan-an. Arábìnrin Hilda Padgett * sọ pé, “Oríléeṣẹ́ ni wọ́n ti rọ̀ wá pé ká tẹra mọ́ṣẹ́, ohun tá a sì fẹ́ gan-an nìyẹn, àwa náà ò sì jáfara, kíá iṣẹ́ ti ṣe.” Arábìnrin míì tó ń jẹ́ E. F. Wallis sọ pé: “Àbá tí wọ́n fún wa pé ká máa lo wákàtí márùn-ún láwọn ọjọ́ mélòó kan láàárín ọ̀sẹ̀ mú kí iṣẹ́ náà yá! Ẹ gbọ́ ná, kí ló lè múnú ẹni dùn bíi pé kéèyàn wà lẹ́nu iṣẹ́ Olúwa látàárọ̀ ṣúlẹ̀? . . . Lóòótọ́, ó lè ti rẹ̀ wá tá a bá fi máa pa dà sílé, àmọ́ inú wa máa ń dùn gan-an ni. Àsọdùn ò sí ńbẹ̀!” Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Stephen Miller gbọ́ ìpè yẹn, ó sọ pé àáyá bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré. Ó gbà pé kò sóhun míì tóun lè fi eegun ọ̀dọ́ òun ṣe tó dáa ju pé kóun wàásù! Ó rántí pé òun àtàwọn kan máa ń gun kẹ̀kẹ́ káàkiri láti lọ wàásù látàárọ̀ ṣúlẹ̀, tó bá sì dọwọ́ ìrọ̀lẹ́ lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn máa ń jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ àsọyé tí wọ́n ti gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n tún máa wá fìtara yan kiri pẹ̀lú àkọlé gàdàgbà tí wọ́n gbé sókè láti fi polongo ìpàdé, wọ́n sì máa ń pín ìwé ìròyìn láwọn òpópónà.

Ìwé Informant tún rọ àwọn ará pé: “A nílò àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó tó ẹgbẹ̀rún.” Ìlànà tuntun kan mú kó ṣeé ṣe fáwọn aṣáájú-ọ̀nà láti máa bá ìjọ ṣiṣẹ́ kí wọ́n sì máa gbé àwọn ará ìjọ ró, dípò tó fi jẹ́ pé àgbègbè àdádó nìkan ni wọ́n á ti máa ṣiṣẹ́. Arábìnrin Joyce Ellis (tórúkọ̀ bàbá rẹ̀ ń jẹ́ Barber) sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló wá rí i pé  ó yẹ káwọn ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ju ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] lọ nígbà yẹn, ó wà lọ́kàn mi pé kémi náà ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.” Nígbà tó sì di July 1940, ó di aṣáájú-ọ̀nà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Nígbà tí Arákùnrin Peter, tó wá di ọkọ Joyce náà gbọ́ ìpè náà pé kí wọ́n “Jára Mọ́ṣẹ́,” ṣe lòun náà “bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé á dáa kóun di aṣáájú-ọ̀nà.” Ní June 1940, lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], ó gun kẹ̀kẹ́ lọ sílùú Scarborough tó wà ní kìlómítà márùnlélọ́gọ́rùn-ún [105] (tàbí máìlì 65) síbi tó ń gbé, láti máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Lára àwọn tó yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà ni tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Cyril àti Kitty Johnson. Wọ́n ta ilé àtàwọn ohun ìní wọn kí wọ́n lè rówó lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn. Cyril tó jẹ́ ọkọ fiṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, nígbà tó sì fi máa doṣù tó tẹ̀ lé e, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Arákùnrin náà sọ pé: “A ò jáyà rárá, a gbà pé a máa lè ṣe é. Tinútinú la fi gbaṣẹ́ náà, a sì ń láyọ̀.”

WỌ́N GBA ILÉ FÁWỌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ

Kò pẹ́ tí iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà fi pọ̀ gan-an, àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú wá ronú bí wọ́n ṣe lè mú kíṣẹ́ náà rọrùn fáwọn aṣáájú-ọ̀nà. Arákùnrin Jim Carr, tó jẹ́ ìránṣẹ́ ìpínlẹ̀ agbègbè lọ́dún 1938 (tá à ń pè ní alábòójútó àyíká báyìí), ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run dábàá, wọ́n sì gba ilé fáwọn aṣáájú-ọ̀nà láwọn ìlú ńláńlá. Wọ́n rọ àwọn aṣáájú-ọ̀nà pé kí wọ́n mú ara wọn ní àwùjọ-àwùjọ, kí wọ́n jọ máa ṣiṣẹ́ kí wọ́n sì jọ máa gbé pọ̀, kí wọ́n bàa lè dín ìnáwó kù. Nílùú Sheffield, wọ́n gba ilé ńlá kan, wọ́n sì ní kí arákùnrin kan jẹ́ alábòójútó ilé náà. Ìjọ tó wà nílùú náà kó àga, tábìlì àtàwọn ohun èlò míì lọ síbẹ̀, wọ́n sì tún fún wọn lówó. Arákùnrin Jim sọ pé: “Gbogbo àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà fọwọ́ sowọ́ pọ̀, nǹkan sì ń lọ mẹ̀lọmẹ̀lọ.” Àwọn aṣáájú-ọ̀nà mẹ́wàá ló ń gbénú ilé náà, wọn ò sì fi nǹkan tẹ̀mí ṣeré. Bí àpẹẹrẹ, láràárọ̀ wọ́n máa ń ka ẹsẹ ojúmọ́ tí wọ́n bá fẹ́ jẹun, lẹ́yìn náà olúkúlùkù wọn á gba ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ̀ lọ níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílùú náà.

Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tuntun ya bo pápá iṣẹ́ ìwàásù nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Àwọn akéde àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà jára mọ́ṣẹ́ bí ìpè náà ṣe sọ, nígbà tí ọdún 1938 sì fi máa parí, wọ́n dé ojú ìlà mílíọ̀nù kan wákàtí tí wọ́n ń lé. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ wákàtí nìkan làwọn ará ti fakọ yọ, gbogbo apá iṣẹ́ ìsìn ni wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́dún márùn-ún lẹ́yìn náà, iye akéde tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti fi ìlọ́po mẹ́ta ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Báwọn ará ṣe fi kún ìtara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run mú kí wọ́n lókun láti fàyà rán ìṣòro tó wáyé nígbà ogun tó bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà.

Lónìí, iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tún ti légbá kan. Láwọn ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọdọọdún niye àwọn aṣáájú-ọ̀nà ń pọ̀ sí i. Nígbà tó fi máa di October 2015, wọ́n ti di ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá ó lé ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́rìnlélógún [13,224]. Ó ṣe kedere pé àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí gbà pé kò sóhun míì téèyàn lè fayé ẹ̀ ṣe tó dà bíi kéèyàn ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

^ ìpínrọ̀ 8 Ìtàn ìgbésí ayé Arábìnrin Padgett wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà October 1, 1995, ojú ìwé 19 sí 24.