Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) November 2016

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti December26, 2016 sí January29, 2017 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlé Tó Ń Tuni Lára!

Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé wo ni Jésù lò táwọn èèyàn gbà pé ó ń tuni lára?

‘Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú Lẹ́nì Kìíní-Kejì Lójoojúmọ́’

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fún àwọn mí ì níṣìírí? Kí la rí kọ́ lára ọ̀nà tí Jèhófà, Jésù àti Pọ́ọ̀lù gbà fún àwọn mí ì níṣìírí? Báwo la ṣe lè fáwọn mí ì níṣìírí táá sì gbé wọn ró?

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Mú Ká Wà Létòletò

Olùṣètò tí kò láfiwé ni Jèhófà. Torí náà, a lè retí pé káwọn olùjọsìn rẹ̀ náà wà létòletò.

Ṣé Ọwọ́ Pàtàkì Lo Fi Ń Mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

A máa ń rí ìbùkún rẹpẹtẹ tá a bá ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà nínú rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń tẹ̀ lé ìdarí ètò rẹ̀.

“Iṣẹ́ Náà Pọ̀”

Ìwọ náà lè kópa nínú rẹ̀.

A Mú Wọn Jáde Kúrò Nínú Òkùnkùn

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹ̀yìn ikú àwọn àpọ́sítélì làwọn èèyàn Ọlọ́run lọ sígbèkùn Bábílónì? Ìgbà wo ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jáde nígbèkùn, báwo sì ni wọ́n ṣe jáde?

Wọ́n Bọ́ Lọ́wọ́ Ìsìn Èké

Ìgbà wo làwọn èèyàn Ọlọ́run bọ́ pátápátá nínú ìgbèkùn Bábílónì?

“Ẹ Jára Mọ́ṣẹ́, Ẹ̀yin Akéde Ìjọba Ọlọ́run Tó Wà Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì!!”

Iye àwọn èèyàn tó wá sínú ètò ọlọ́run nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láàárín ọdún mẹ́wàá kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan! Kí lohun tó wá mú káwọn èèyàn máa rọ́ wá sínú ètò Ọlọ́run?