“A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀, tí ẹ sì fi ara yín hàn ní ọmọ ẹ̀yìn mi.”​JÒH. 15:8.

ORIN: 53, 60

1, 2. (a) Kí ni Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú lórí ìdí tá a fi ń wàásù? (d) Kí la máa jíròrò?

NÍ ALẸ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ó bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Ó tún sọ àpèjúwe kan fún wọn nípa àjàrà, bá a ṣe gbé e yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Jésù lo àpèjúwe yìí kó lè fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níṣìírí láti máa “bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀,” ìyẹn ni pé kí wọ́n máa fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.​—Jòh. 15:8.

2 Àmọ́ kì í ṣe ohun tí wọ́n máa ṣe nìkan ni Jésù sọ fún wọn, ó tún sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwa náà ronú lórí àwọn nǹkan tí Jésù sọ? Tá a bá ń ronú lórí ìdí tó fi yẹ ká máa wàásù, ó máa jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa fara dà á bá a ṣe ń ‘jẹ́rìí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.’ (Mát. 24:​13, 14) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ìdí mẹ́rin tí Bíbélì sọ tó fi yẹ ká máa wàásù. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa jíròrò ẹ̀bùn mẹ́rin tí Jèhófà fún wa ká lè máa fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

 À Ń YIN JÈHÓFÀ LÓGO

3. (a) Bó ṣe wà ní Jòhánù 15:​8, kí nìdí tá a fi ń wàásù? (b) Kí ni èso àjàrà inú àpèjúwe Jésù dúró fún, kí sì nìdí tí àfiwé yẹn fi bá a mu wẹ́kú?

3 Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tá a fi ń wàásù ni pé, à ń yin Jèhófà lógo, a sì ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. (Ka Jòhánù 15:​1, 8.) Nínú àpèjúwe àjàrà yẹn, Jésù fi Baba rẹ̀ wé aroko tó ń gbin àjàrà. Ó sì fi ara rẹ̀ wé àjàrà tàbí igi àjàrà, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sì ni ẹ̀ka. (Jòh. 15:5) Ó ṣe kedere pé èso àjàrà yẹn ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń wàásù. Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀.” Ó dájú pé tí igi àjàrà kan bá mú èso àtàtà jáde, inú ẹni tó gbin èso náà máa dùn. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà, ṣe là ń mú ìyìn àti ògo wá fún Jèhófà Ọlọ́run wa.​—Mát. 25:​20-23.

4. (a) Àwọn ọ̀nà wo la gbà ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́? (b) Báwo ló ṣe rí lára rẹ pé o láǹfààní láti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́?

4 Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́? A ò lè ṣe ohunkóhun láti túbọ̀ sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Torí mímọ́ ni, kò sì lábùkù kankan bó ti wù kó kéré mọ. Ṣùgbọ́n, ẹ kíyè sí ohun tí wòlíì Aísáyà sọ, ó ní: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun​—òun ni Ẹni tí ó yẹ kí ẹ kà sí mímọ́.” (Aísá. 8:13) Lára ọ̀nà tá a lè gbà sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ ni pé, ká gbà pé kò sí orúkọ míì bíi tiẹ̀, ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́ kí àwọn náà lè kà á sí mímọ́. (Mát. 6:9) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà fáwọn èèyàn àtàwọn ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé, ṣe là ń fi hàn pé afọ̀rọ̀-èké-bani-jẹ́ ni Sátánì àti pé irọ́ gbuu ló pa mọ́ Jèhófà. (Jẹ́n. 3:​1-5) Bákan náà, à ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ tá a bá ń jẹ́ káwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mọ̀ pé Jèhófà ni gbogbo “ògo àti ọlá àti agbára” tọ́ sí. (Ìṣí. 4:11) Rune tó ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún mẹ́rìndínlógún [16] sọ pé: “Inú mi máa ń dùn pé mo láǹfààní láti máa sọ nípa Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run fáwọn èèyàn, ohun tí ò sì jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù sú mi nìyẹn.”

A NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ ÀTI ỌMỌ RẸ̀

5. (a) Kí ni Jòhánù 15:​9, 10 sọ tó fi hàn pé ó yẹ ká máa wàásù? (b) Báwo ni Jésù ṣe tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní ìfaradà?

5 Ka Jòhánù 15:​9, 10. Ìdí pàtàkì míì tá a fi ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù látọkàn wá. (Máàkù 12:30; Jòh. 14:15) Jésù ò kàn sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n nínú ìfẹ́ òun, àmọ́ ó ní kí wọ́n “dúró nínú ìfẹ́ [òun].” Kí nìdí? Ìdí ni pé, ó gba ìfaradà ká tó lè máa bá a lọ láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù láti ọdún dé ọdún. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “dúró” nínú Jòhánù 15:​4-10 kó lè tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní ìfaradà.

6. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Kristi?

6 Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Kristi, ká sì rí ojú rere rẹ̀? A gbọ́dọ̀ máa pa àwọn àṣẹ Jésù mọ́. Ohun tí Jésù fúnra rẹ̀ sì ṣe nìyẹn, ó ní: ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.’ Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa.​—Jòh. 13:15.

7. Báwo ni ìgbọràn àti ìfẹ́ ṣe tan mọ́ra?

7 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbọràn àti ìfẹ́ tan mọ́ra nígbà tó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ní àwọn àṣẹ mi, tí ó sì ń pa wọ́n mọ́, ẹni yẹn ni ó nífẹ̀ẹ́ mi.” (Jòh. 14:21) Torí pé àtọ̀dọ̀ Jèhófà ni àṣẹ tí Jésù pa ti wá, tá a bá pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká máa wàásù, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Mát. 17:5; Jòh. 8:28) Tá a  bá ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù, àwọn náà máa jẹ́ ká dúró nínú ìfẹ́ wọn, wọn ò sì ní fi wá sílẹ̀ láé.

À Ń KÌLỌ̀ FÁWỌN ÈÈYÀN

8, 9. (a) Kí nìdí míì tá a fi ń wàásù? (b) Báwo ni ohun tí Jèhófà sọ nínú Ìsíkíẹ́lì 3:​18, 19 àti 18:23 ṣe ń jẹ́ ká tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù?

8 Ìdí míì tá a fi ń wàásù ni pé, à ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn. Àpẹẹrẹ ẹnì kan tó ṣe bẹ́ẹ̀ ni Nóà tí Bíbélì pè ní “oníwàásù.” (Ka 2 Pétérù 2:5.) Ṣáájú Ìkún Omi, Nóà wàásù fáwọn èèyàn, ó sì dájú pé ó kìlọ̀ fún wọn nípa ìparun tó ń bọ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Jésù sọ pé: “Nítorí bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” (Mát. 24:​38, 39) Láìka pé àwọn èèyàn ò kọbi ara sí ìwàásù rẹ̀, Nóà ò jẹ́ kó sú òun, ṣe ló ń bá a lọ láti máa kéde ìkìlọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn.

9 Lónìí, à ń wàásù ìhìn rere káwọn èèyàn lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Bíi ti Jèhófà, ó wù wá gan-an káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kí wọ́n lè “máa wà láàyè” nìṣó. (Ìsík. 18:23) Lẹ́sẹ̀ kan náà, bá a ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé àti níbi térò pọ̀ sí, ṣe là ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó pa ayé búburú yìí run.​—Ìsík. 3:​18, 19; Dán. 2:44; Ìṣí. 14:​6, 7.

A NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÈÈYÀN

10. (a) Bó ṣe wà ní Mátíù 22:​39, kí nìdí míì tá a fi ń wàásù? (b) Sọ bí Pọ́ọ̀lù àti Sílà ṣe ran ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan lọ́wọ́ nílùú Fílípì.

10 Ìdí pàtàkì míì tún wà tí kò fi yẹ ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ìdí náà sì ni pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. (Mát. 22:39) Ìfẹ́ tá a ní fáwọn èèyàn ló ń jẹ́ ká fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ náà. Nígbà míì, nǹkan lè yí pa dà fáwọn tí kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa tẹ́lẹ̀, kíyẹn sì mú kí wọ́n tẹ́tí sí ìhìn rere. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù àti Sílà nílùú Fílípì. Àwọn alátakò jù wọ́n sẹ́wọ̀n, àmọ́ nígbà tó dòru, ìmìtìtì ilẹ̀ kan wáyé, gbogbo ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n náà sì ṣí sílẹ̀ gbayawu. Nígbà tí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ronú pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ti sá lọ, ló bá fa idà yọ kó lè pa ara rẹ̀. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ké jáde pé: “Má ṣe ara rẹ lọ́ṣẹ́!” Ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà tí ìdààmú ọkàn ti bá wá béèrè pé: “Kí ni kí n ṣe láti rí ìgbàlà?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Gba Jésù Olúwa gbọ́, ìwọ yóò sì rí ìgbàlà.”​—Ìṣe 16:​25-34.

À ń wàásù torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a nífẹ̀ẹ́ Jésù, a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn (Wo ìpínrọ̀ 5 àti 10)

11, 12. (a) Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn ṣe ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn lónìí? (b) Kí ló yẹ ká múra tán láti ṣe fáwọn èèyàn?

11 Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn ṣe ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn lónìí? Ẹ kíyè sí i pé lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà wáyé ni ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà tó tẹ́tí sí ìhìn rere. Bó sì ṣe rí lónìí náà nìyẹn, àwọn kan lè má nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere tẹ́lẹ̀, àmọ́ nǹkan lè ṣàdédé yí pa dà fún wọn,  kíyẹn sì mú kí wọ́n tẹ́tí sí ìhìn rere. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ lè ṣàdédé bọ́ lọ́wọ́ àwọn kan tàbí kí ìgbéyàwó wọn túká láìrò tẹ́lẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé àìsàn burúkú kan ló ṣàdédé mú ẹlòmíì tàbí kéèyàn wọn kan ṣàdédé fò ṣánlẹ̀, kó sì kú lọ́sàn kan òru kan. Àwọn tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí máa ń ní ìdààmú ọkàn, èyí sì lè mú káyé sú wọn. Àwọn míì tiẹ̀ lè máa béèrè pé, ‘Kí ni màá ṣe tí Ọlọ́run á fi kó mi yọ?’ Nígbà tá a bá rí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, wọ́n lè tẹ́tí sí ìwàásù wa fúngbà àkọ́kọ́ láyé wọn.

12 Torí náà, tá ò bá dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, a máa wà ní ìmúratán láti sọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀ gan-an. (Aísá. 61:1) Charlotte tó ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún méjìdínlógójì [38] sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ayé yìí ò yé àwọn èèyàn mọ́, ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí wọ́n gbọ́ ìhìn rere.” Ejvor tó ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] sọ pé: “Nǹkan ti tojú sú ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí, ó sì máa ń wù mí kí n ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìyẹn ló máa ń mú kí n tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù náà.” Ká sòótọ́, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a ò ní dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

ÀWỌN Ẹ̀BÙN TÓ Ń JẸ́ KÁ MÁA BÁ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ NÌṢÓ

13, 14. (a) Ẹ̀bùn wo ni Jòhánù 15:11 mẹ́nu kàn? (b) Báwo la ṣe lè ní irú ayọ̀ tí Jésù ní? (d) Kí ni ayọ̀ tá à ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù máa ń fún wa?

13 Nígbà tí Jésù ń bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ̀rọ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé, ó mẹ́nu kan àwọn ẹ̀bùn kan táá jẹ́ kí wọ́n lè fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn ẹ̀bùn wo nìyẹn, àǹfààní wo sì làwọn ẹ̀bùn náà máa ṣe wá?

14 Ìdùnnú. Ǹjẹ́ àṣẹ tí Jésù pa pé ká máa wàásù ṣòro láti pa mọ́? Rárá o. Nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa àjàrà náà, ó sọ pé àwọn tó ń wàásù ìhìn rere máa ní ayọ̀. (Ka Jòhánù 15:11.) Kódà, ó fi dá wa lójú pé ìdùnnú òun máa di tiwa. Lọ́nà wo? Bá a ṣe sọ ṣáájú, Jésù fi ara rẹ̀ wé igi àjàrà, ó sì fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wé ẹ̀ka igi. Igi ló máa ń gbé ẹ̀ka igi ró, torí náà tí ẹ̀ka kan bá ṣì wà lára igi, á máa rí omi àtàwọn èròjà míì tó nílò látara igi náà. Lọ́nà kan náà, táwa náà bá wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, tá a sì ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí, a máa ní irú ayọ̀ tí Jésù ní bó ṣe ń ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. (Jòh. 4:34; 17:13; 1 Pét. 2:21) Hanne tó ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó lé ní ogójì [40] ọdún sọ pé, “Inú mi máa ń dùn lẹ́yìn tí mo bá dé láti òde ẹ̀rí, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó wù mí láti máa wàásù nìṣó.” Kò sí àní-àní pé ayọ̀ tá à ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù máa ń fún wa lókun, ìyẹn sì ń jẹ́ ká lè máa bá iṣẹ́ náà lọ kódà táwọn kan ò bá fẹ́ gbọ́ wa.​—Mát. 5:​10-12.

15. (a) Ẹ̀bùn wo ni Jòhánù 14:27 mẹ́nu kàn? (b) Báwo ni àlàáfíà ṣe ń mú ká máa so èso?

15 Àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn. (Ka Jòhánù 14:27.) Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Mo fi àlàáfíà mi fún yín.” Báwo ni ẹ̀bùn yìí ṣe ń mú ká máa so èso? Bá a ṣe ń fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ọkàn wa máa ń balẹ̀ torí a mọ̀ pé inú Jèhófà àti Jésù ń dùn sí ohun tá à ń ṣe. (Sm. 149:4; Róòmù 5:​3, 4; Kól. 3:15) Ulf tó ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún márùndínláàádọ́ta [45] sọ pé, “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ mí tí mo bá dé láti òde ẹ̀rí, síbẹ̀ ọkàn mi máa ń balẹ̀ torí pé ohun tó dáa jù ni mò ń fayé mi ṣe.” A mà dúpẹ́ o pé iṣẹ́ ìwàásù ń mú kí ọkàn wa balẹ̀, ká sì ní àlàáfíà!

16. (a) Ẹ̀bùn wo ni Jòhánù 15:15 mẹ́nu kàn? (b) Kí ló yẹ káwọn àpọ́sítélì ṣe tí wọ́n bá fẹ́ máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù nìṣó?

 16 Àǹfààní láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù. Lẹ́yìn tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun fẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀, ó ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì ṣe tán láti fara wọn jìn fáwọn míì. (Jòh. 15:​11-13) Lẹ́yìn náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Mo pè yín ní ọ̀rẹ́.” Àbí ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù! Àmọ́ kí làwọn àpọ́sítélì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù nìṣó? Wọ́n gbọ́dọ̀ ‘máa bá a lọ láti máa so èso.’ (Ka Jòhánù 15:​14-16.) Ní nǹkan bí ọdún méjì ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’ ” (Mát. 10:7) Torí náà, lálẹ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn, ó ní kí wọ́n máa fara dà á nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Mát. 24:13; Máàkù 3:14) Lóòótọ́ kò rọrùn láti máa bá iṣẹ́ náà lọ láìṣàárẹ̀, àmọ́ wọ́n lè ṣàṣeyọrí, kí wọ́n sì máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù nìṣó. Kí ló máa jẹ́ kí wọ́n lè fara dà á? Ẹ̀bùn míì ló máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀.

17, 18. (a) Ẹ̀bùn wo ni Jòhánù 15:16 mẹ́nu kàn? (b) Báwo ni ẹ̀bùn yìí ṣe ṣàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù láǹfààní? (d) Àwọn ẹ̀bùn wo ló ń fún wa lókun?

17 Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa. Jésù sọ pé: ‘Ohunkóhun yòówù tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, ó máa fi í fún yín.’ (Jòh. 15:16) Ó dájú pé ìlérí yìí máa fáwọn àpọ́sítélì lókun gan-an! * Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì yé wọn nígbà yẹn pé Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wọn máa tó kú, síbẹ̀ Jèhófà ò ní fi wọ́n sílẹ̀. Jèhófà ṣe tán láti dáhùn àdúrà wọn, kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ. Kò sì pẹ́ rárá táwọn fúnra wọn fi rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà tí wọ́n gbà pé kó ran àwọn lọ́wọ́.​—Ìṣe 4:​29, 31.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa dáhùn àwọn àdúrà wa (Wo ìpínrọ̀ 18)

18 Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Tá ò bá dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àá máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù nìṣó. Yàtọ̀ síyẹn, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìṣòro èyíkéyìí tá a bá kojú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Fílí. 4:13) A mà dúpẹ́ o, pé a láǹfààní láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù àti pé Jèhófà ń dáhùn àdúrà wa! Àwọn ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa yìí ló ń fún wa lókun ká lè máa so èso.​—Ják. 1:17.

19. (a) Kí nìdí tá a fi ń bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó? (b) Kí ló máa jẹ́ ká lè parí iṣẹ́ tí Jèhófà fún wa?

19 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti rí ìdí mẹ́rin tá a fi ń bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó. Àkọ́kọ́, à ń fògo fún Jèhófà, a sì ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Ìkejì, a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù. Ìkẹta, a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ìkẹrin, a fẹ́ kìlọ̀ fáwọn èèyàn. A tún ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹ̀bùn mẹ́rin táá mú ká lè parí iṣẹ́ tí Jèhófà fún wa, ìyẹn sì ni ìdùnnú, àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn, àǹfààní láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù àti bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wa. Inú wa mà dùn o pé Jèhófà ń rí gbogbo bá a ṣe ń sapá láti máa so èso, ó sì dájú pé á san wá lẹ́san!

^ ìpínrọ̀ 17 Nígbà tí Jésù ń bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló fi dá wọn lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wọn.​—Jòh. 14:13; 15:​7, 16; 16:23.