Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Adití, Mò Ń Kọ́ Àwọn Mí ì Lẹ́kọ̀ọ́

Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Adití, Mò Ń Kọ́ Àwọn Mí ì Lẹ́kọ̀ọ́

Ọdún 1941 ni mo ṣèrìbọmi, àmọ́ ọdún 1946 ni mo tó lóye òtítọ́ Bíbélì dáadáa. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ara mi fún yín.

NÍ NǸKAN bí ọdún 1910, àwọn òbí mi ṣí kúrò nílùú Tbilisi lórílẹ̀-èdè Georgia, wọ́n sì kó lọ sórílẹ̀-èdè Kánádà. Wọ́n wá ń gbé ní oko kan tó wà nítòsí abúlé Pelly, ìpínlẹ̀ Saskatchewan, ní apá ìwọ̀ oòrùn Kánádà. Ọdún 1928 ni wọ́n bí mi, èmi sì ni àbíkẹ́yìn nínú ọmọ mẹ́fà táwọn òbí mi bí. Oṣù mẹ́fà kí wọ́n tó bí mi ni bàbá mi kú, ìkókó sì ni mí nígbà tí màmá mi náà kú. Lucy ni ọmọbìnrin táwọn òbí mi kọ́kọ́ bí, kò sì pẹ́ tóun náà fi kú lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17]. Torí náà, àbúrò màmá mi kan tó ń jẹ́ Nick gba gbogbo wa tọ́.

Lọ́jọ́ kan, àwọn ará ilé mi rí i tí mò ń fa ìrù akọ ẹṣin tó wà lóko wa, mo ṣì kéré gan-an nígbà yẹn. Àyà wọn já, wọ́n rò pé ẹṣin náà máa ta mí nípàá, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé kí n kúrò níbẹ̀, àmọ́ mi ò dáhùn. Ẹ̀yìn ni mo kọ sí wọn, mi ò sì gbọ́ gbogbo ariwo wọn. A dúpẹ́ pé ẹṣin náà ò ṣe mí léṣe, àmọ́ ọjọ́ yẹn làwọn ará ilé mi mọ̀ pé adití ni mí.

Ọ̀rẹ́ Bọ̀dá Nick kan sọ pé kí wọ́n mú mi lọ sílé ẹ̀kọ́ tó wà fáwọn adití. Torí náà, Bọ̀dá Nick mú mi lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn adití tó wà nílùú Saskatoon ìpínlẹ̀ Saskatchewan. Ibẹ̀ jìn gan-an sílé wa, ẹ̀rù sì bà mí torí pé ọmọ ọdún márùn-ún péré ni mí nígbà yẹn. Ìgbà ọlidé nìkan ni mo máa ń lọ sílé. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo kọ́ èdè àwọn adití, mo sì ń gbádùn kí n máa bá àwọn ọmọ tó kù ṣeré.

BÍ MO ṢE KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́

Lọ́dún 1939, Bill Danylchuck fẹ́ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Marion, wọ́n sì mú èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Frances sọ́dọ̀. Àwọn ló kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ìdílé wa. Tí n bá wá sílé nígbà ọlidé, wọ́n máa ń sapá gan-an láti ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì fún mi. Kí n sòótọ́, kò rọrùn fún wọn torí pé wọn ò gbọ́ èdè àwọn adití. Àmọ́ wọ́n rí i pé mo nífẹ̀ẹ́ ohun tí wọ́n ń kọ́ mi. Èmi náà sì rí i pé ohun tí wọ́n  ń kọ́ nínú Bíbélì náà ni wọ́n ń hù níwà, torí náà mo máa ń bá wọn lọ sóde ẹ̀rí. Kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí pé kí n ṣèrìbọmi, torí náà ní September 5, 1941, Bill ṣèrìbọmi fún mi nínú àgbá ńlá kan tí wọ́n pọn omi kànga sí. Omi náà tutù gan-an!

Èmi àtàwọn míì tó jẹ́ adití ní àpéjọ àgbègbè kan nílùú Cleveland, Ohio, lọ́dún 1946

Nígbà tí mo wá sílé nígbà ọlidé lọ́dún 1946, a lọ sí àpéjọ àgbègbè kan nílùú Cleveland ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ náà, àwọn ẹ̀gbọ́n mi ló ń kọ ohun tí wọ́n ń sọ fún mi kí n lè máa fọkàn bá àpéjọ náà lọ. Àmọ́ nígbà tó di ọjọ́ kejì, inú mi dùn gan-an láti rí àwùjọ àwọn adití kan ní àpéjọ náà, ẹnì kan sì ń túmọ̀ ohun tí wọ́n ń sọ sí èdè àwọn adití. Èyí mú kí n gbádùn àpéjọ náà dọ́ba, ìgbà yẹn ni òtítọ́ Bíbélì tí mo ti ń kọ́ látọjọ́ yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé mi dáadáa.

MO KỌ́ ÀWỌN MÍÌ LẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́

Nígbà yẹn, Ogun Àgbáyé Kejì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ni, àwọn èèyàn sì ń gbé orílẹ̀-èdè wọn gẹ̀gẹ̀. Nígbà tí mo pa dà síléèwé lẹ́yìn àpéjọ yẹn, mo pinnu pé mi ò ní jẹ́ kí ohunkóhun ba ìgbàgbọ́ mi jẹ́. Torí náà, mi ò tún bá wọn kọ orin orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni mi ò kí àsíá mọ́. Bákan náà, mi ò bá wọn lọ́wọ́ sáwọn ọdún àtàwọn ayẹyẹ míì mọ́, títí kan àwọn ààtò ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe níléèwé wa. Inú àwọn tó ń bójú tó wa níléèwé ò dùn sí mi, torí náà wọ́n halẹ̀ mọ́ mi, wọ́n sì tún pa onírúurú irọ́ kí n lè yí ìpinnu mi pa dà. Èyí mú káwọn ọmọléèwé mi dẹnu bò mí, àmọ́ mo lo àǹfààní yẹn láti wàásù fún wọn. Lára àwọn tí mo bá sọ̀rọ̀ tí wọ́n wá di Ẹlẹ́rìí ni Larry Androsoff, Norman Dittrick àti Emil Schneider, gbogbo wọn ló ń sin Jèhófà dòní olónìí.

Ní gbogbo ìgbà tí mo bá lọ sílùú míì, mo máa ń wá àwọn adití kí n lè wàásù fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, mo bá ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Eddie Tager pàdé níbì kan táwọn adití máa ń kóra jọ sí nílùú Montreal, mo sì wàásù fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọọ̀ta ni tẹ́lẹ̀, ní báyìí ó ti di Ẹlẹ́rìí, ó sì dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití nílùú Laval, ní ìpínlẹ̀ Quebec títí tó fi kú lọ́dún tó kọjá. Mo tún wàásù fún ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Juan Ardanez. Ó máa ń ṣe bíi tàwọn ará Bèróà tí wọ́n máa ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ohun tí wọ́n ń kọ́ jóòótọ́. (Ìṣe 17:10, 11) Òun náà di Ẹlẹ́rìí, ó di alàgbà, ó sì fòótọ́ sin Jèhófà nílùú Ottawa, ní ìpínlẹ̀ Ontario títí tó fi kú.

Mò ń wàásù ní òpópónà láwọn ọdún 1950

Lọ́dún 1950, mo kó lọ sílùú Vancouver. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo nífẹ̀ẹ́ kí n máa wàásù fáwọn adití, àmọ́ mi ò jẹ́ gbàgbé ìgbà kan tí mo pàdé obìnrin kan tí kì í ṣe adití lójú ọ̀nà tí mo sì wàásù fún un. Chris Spicer lorúkọ obìnrin náà, ó tẹ́tí sí mi, ó sì gbà láti san àsansílẹ̀ ká lè máa fi ìwé ìròyìn ránṣẹ́ sí i. Ó tún fẹ́ kí n bá ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Gary sọ̀rọ̀. Torí náà mo lọ sílé wọn, a sì jọ sọ̀rọ̀ gan-an, wọ́n á kọ ìbéèrè wọn sínú ìwé, èmi náà  á sì kọ ìdáhùn sínú ìwé fún wọn. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, a ò ríra fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́ ó yà mí lẹ́nu pé lọ́jọ́ kan, tọkọtaya náà rí mi láàárín èrò ní àpéjọ àgbègbè kan nílùú Toronto, ìpínlẹ̀ Ontario. Ọjọ́ yẹn gan-an ni Gary fẹ́ ṣèrìbọmi. Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn tún jẹ́ kí n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká má dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù torí pé a ò mọ ẹni tó máa tẹ́wọ́ gba òtítọ́, a ò sì mọ ibi tá a ti lè bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ pàdé.

Nígbà tó yá, mo pa dà sílùú Saskatoon. Mo pàdé obìnrin kan níbẹ̀ tó ní kí n máa kọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ tó jẹ́ ìbejì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jean àti Joan Rothenberger lorúkọ wọn, ilé ẹ̀kọ́ àwọn adití tí mo lọ làwọn náà ń lọ. Kò pẹ́ táwọn méjèèjì fi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì fáwọn ọmọ kíláàsì wọn. Èyí mú kí márùn-ún lára àwọn ọmọ kíláàsì wọn di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀kan lára wọn ni Eunice Colin. Ìgbà tí mo fẹ́ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn adití ni mo kọ́kọ́ pàdé Eunice. Ó fún mi ní súìtì kan, ó sì bi mí bóyá a lè jọ jọ́rẹ̀ẹ́.

Èmi àti Eunice lọ́dún 1960 àti lọ́dún 1989

Nígbà tí màmá Eunice rí i pé ó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lọ bá ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ wọn, ó sì ní kó má jẹ́ kí Eunice kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́. Ni ọ̀gá náà bá gba àwọn ìwé tó fi ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́ Eunice pinnu pé kò sóhun tó máa ní kóun má kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Nígbà tó fẹ́ ṣèrìbọmi, àwọn òbí rẹ̀ sọ fún un pé, “Tó o bá mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo fẹ́ ṣe, wàá kó jáde nílé yìí!” Wọ́n lé Eunice jáde lóòótọ́ lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sì fìfẹ́ gbà á sílé. Ó ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ, ó sì ṣèrìbọmi. Eunice pa dà wá dẹni pàtàkì nígbèésí ayé mi, torí pé òun ni mo fi ṣaya. Nígbà témi àti ẹ̀ ṣègbéyàwó lọ́dún 1960, àwọn òbí rẹ̀ kò wá síbi ìgbéyàwó wa. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mọyì wa torí ohun tá a gbà gbọ́ àti bá a ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wa.

 JÈHÓFÀ BÓJÚ TÓ MI

Nicholas ọmọ mi àti Deborah ìyàwó rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní London

Ọmọkùnrin méje la bí, kò sì sí èyí tó jẹ́ adití nínú wọn. Àtitọ́ wọn ò rọrùn rárá, àmọ́ a rí i dájú pé a kọ́ wọn lédè àwọn adití ká lè jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa, ká sì lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn ará nínú ìjọ sì ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, òbí kan kọ ìwé pélébé kan sí wa pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ wa ń sọ̀rọ̀kọ́rọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Èyí mú ká lè bójú tó ọ̀rọ̀ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Mẹ́rin nínú àwọn ọmọ mi, ìyẹn, James, Jerry, Nicholas, àti Steven ló ń sin Jèhófà tọkàntọkàn pẹ̀lú ìdílé wọn. Alàgbà làwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin níjọ tí wọ́n wà. Yàtọ̀ síyẹn, Nicholas àti Deborah ìyàwó rẹ̀ wà lára àwọn tó ń túmọ̀ èdè àwọn adití ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Bákan náà, Steven àti Shannan ìyàwó rẹ̀ náà ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń túmọ̀ èdè àwọn adití ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Àwọn ọmọ mi James, Jerry àti Steven pẹ̀lú àwọn ìyàwó wọn ń lo èdè àwọn adití lónírúurú ọ̀nà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà

Ó dùn mí gan-an pé àrùn jẹjẹrẹ tí Eunice ń bá pò ó ló pàpà wá gbẹ̀mí rẹ̀ ní oṣù kan ká tó ṣe àyájọ́ ogójì ọdún tá a ṣègbéyàwó. Kò kárísọ ní gbogbo àsìkò tó fi ń ṣàìsàn torí ó gbà gbọ́ pé tóun bá kú Jèhófà máa jí òun dìde. Mò ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ náà tí màá tún fojú kàn án.

Faye àti James, Jerry àti Evelyn, Shannan àti Steven

Ní February ọdún 2012, mo ṣubú, itan mi sì yẹ̀. Ó wá pọn dandan pé màá nílò ẹni táá máa ràn mí lọ́wọ́. Torí náà, ọ̀kan lára àwọn ọmọ mi ní kí n wá máa gbé lọ́dọ̀ àwọn. Mo wá ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití nílùú Calgary, mo sì jẹ́ alàgbà níbẹ̀. Á yà yín lẹ́nu tí mo bá sọ fún yín pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí màá wà ní ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití. Ẹ lè máa wò ó pé báwo ni mo ṣe wá ń gbádùn ìpàdé ní gbogbo ìgbà tí mo fi wà níjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì látọdún 1946? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa tọ́jú àwọn ọmọ aláìníbaba, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ fún mi. (Sm. 10:14) Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ti dúró tì mí, àwọn tó ń kọ ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé fún mi, àwọn tó tìtorí tèmi kọ́ èdè àwọn adití àtàwọn tó ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ràn mí lọ́wọ́.

Mo lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà (ASL) nígbà tí mo wà lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79]

Kí n sòótọ́, àwọn ìgbà kan wà tí nǹkan tojú sú mi débi tó fi ń ṣe mí bíi kí n bọ́hùn torí pé mi ò gbọ́ ohun táwọn èèyàn ń sọ. Nígbà míì ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn èèyàn ò mọ bí nǹkan ṣe rí lára mi. Láwọn àsìkò yẹn, ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ fún Jésù ni mo máa ń rántí, pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:66-68) Bíi tàwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tá a jọ dàgbà pọ̀ tí wọ́n jẹ́ adití, èmi náà ti rí i pé ó dáa kéèyàn ní sùúrù. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí n dúró de Jèhófà àti ètò rẹ̀, èyí sì ti ṣe mí láǹfààní gan-an! Ní báyìí, a ti wá ní ọ̀pọ̀ yanturu ìtẹ̀jáde lédè àwọn adití, mo sì ń gbádùn àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ lédè àwọn adití. Kò sí àní-àní, mo ti gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi gan-an, mo sì láyọ̀ pé mò ń sin Jèhófà Ọba ayé àtọ̀run.