DANIEL ÀTI MIRIAM ṣègbéyàwó ní September 2000 wọ́n sì ń gbé nílùú Barcelona lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Daniel sọ pé, “Iṣẹ́ wa ń mówó wọlé, a sì ń gbádùn ara wa. A máa ń lọ jẹun láwọn ilé ìtura tó lóókọ, a máa ń gbafẹ́ lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì, a sì máa ń wọṣọ gidi. A tún máa ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé.” Àmọ́ ohun kan mú kí wọ́n ṣàtúnṣe.

Àsọyé kan tí Daniel gbọ́ ní àpéjọ àgbègbè ọdún 2006 ló gún un ní kẹ́ṣẹ́. Nínú àsọyé náà, olùbánisọ̀rọ̀ béèrè pé: “Ǹjẹ́ à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn tó ń ‘ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sínú ìfikúpa’ lọ́wọ́ kí wọ́n lè bọ́ sójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun?” (Òwe 24:11) Olùbánisọ̀rọ̀ sọ pé ó ṣe pàtàkì ká kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà. (Ìṣe 20:26, 27) Daniel wá sọ pé, “Ṣe lọkàn mi ń sọ fún mi pé èmi gan-an ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀.” Olùbánisọ̀rọ̀ tún sọ pé èèyàn á túbọ̀ láyọ̀ téèyàn bá fi kún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Daniel alára gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ó ṣe tán, aṣáájú-ọ̀nà ni ìyàwó ẹ̀, ó sì ń láyọ̀.

Daniel sọ pé, “Mo pinnu pé màá ṣe àyípadà nígbèésí ayé mi.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dín àkókò tó fi ń ṣiṣẹ́ kù, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Yàtọ̀ síyẹn, ó ronú pé òun àti ìyàwó òun máa láyọ̀ gan-an táwọn bá lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀.

WỌ́N KỌ́KỌ́ KOJÚ ÌṢÒRO, WỌ́N WÁ GBA ÌRÒYÌN AYỌ̀

Ní May 2007, Daniel àti Miriam fi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì kó lọ sórílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti lọ rí, ìyẹn Panama. Àwọn erékùṣù Bocas del Toro tó wà láàárín agbami Òkun Caribbean ni ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, àwọn Ngabe tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ló sì pọ̀ ńbẹ̀. Daniel àti Miriam gbà pé táwọn bá ṣọ́wó ná, àwọn á lò tó oṣù mẹ́jọ níbẹ̀.

Wọ́n máa ń wọ ọkọ̀ ojú omi láti erékùṣù kan sí òmíì, wọ́n sì máa ń gun kẹ̀kẹ́ tí wọ́n bá ti dé àwọn erékùṣù náà. Wọn ò jẹ́ gbàgbé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n fi kẹ̀kẹ́ rin ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún [20] máìlì, lórí àwọn òkè gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, nínú oòrùn tó ń mú ganrínganrín. Ó rẹ Daniel gan-an, díẹ̀ ló kù kó dákú. Àmọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, pàápàá lẹ́yìn tí tọkọtaya náà kọ́ díẹ̀ nínù èdè ìbílẹ̀ wọn. Kò pẹ́ tí tọkọtaya náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn mẹ́tàlélógún [23] lẹ́kọ̀ọ́.

Bí eré bí eré, owó tán lọ́wọ́ wọn, ìbànújẹ́ wá sorí wọn kodò. Daniel sọ pé: “Ṣe lomi ń dà lójú wa pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ nígbà tá à ń ronú pé ká pa dà sílùú wa. Ó dùn wá gan-an pé a máa fi àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa sílẹ̀.” Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ lóṣù kan lẹ́yìn náà. Wọ́n gba lẹ́tà ayọ̀ kan. Miriam sọ pé: “Ètò Ọlọ́run sọ wá di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Inú wa dùn pé àá ṣì máa bá iṣẹ́ ìsìn wa lọ!”

OHUN TÓ FÚN WỌN LÁYỌ̀ JÙ

Lọ́dún 2015, ètò Ọlọ́run ṣe àwọn àtúntò kan, wọ́n sì ní kí tọkọtaya náà máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé dípò àkànṣe. Kí ni wọ́n wá ṣe? Wọ́n gbà pé ìlérí Jèhófà tó wà nínú Sáàmù 37:5 máa ṣẹ sáwọn lára, pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.” Wọ́n wá iṣẹ́ kékeré kan, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wọn lọ ní ìjọ kan tó wà ní Veraguas, lórílẹ̀-èdè Panama.

Daniel wá sọ pé: “Nígbà tá a máa kúrò ní Sípéènì, ẹ̀rù ń bà wá pé ṣé a máa lè gbé irú ìgbésí ayé yìí ṣáá. Ní báyìí, ohun tá à ń ṣe gan-an nìyẹn, a ò sì ṣaláìní àwọn nǹkan tó pọn dandan.” Kí lohun tó ń fún wọn láyọ̀ jù? Wọ́n sọ pé, “Bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà lohun tó ń fún wa láyọ̀, ayọ̀ tí ò lẹ́gbẹ́!”