Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Báwo Ni Ìbáwí Ṣe Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa?

Báwo Ni Ìbáwí Ṣe Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa?

“Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí.”​HÉB. 12:6.

ORIN: 123, 86

1. Báwo ni Bíbélì ṣe sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà ìbáwí?

KÍ LÓ máa wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí”? Ó ṣeé ṣe kọ́kàn ẹ lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ fìyà jẹ, àmọ́ ká fìyà jẹni nìkan kọ́ ni ìbáwí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà ìbáwí pẹ̀lú àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì, irú bí ìmọ̀, ọgbọ́n, ìfẹ́ àti ìwàláàyè. (Òwe 1:​2-7; 4:​11-13) Ìdí sì ni pé Ọlọ́run máa ń bá wa wí torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó fẹ́ ká wà láàyè títí láé. (Héb. 12:6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbáwí lè ní ìyà díẹ̀ nínú, síbẹ̀ Jèhófà kì í le koko jù tàbí kó fìyà jẹ wá ju bó ṣe yẹ lọ tó bá ń bá wa wí. Ká sòótọ́, ohun tí ìbáwí túmọ̀ sí ni pé ká kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn irú ẹ̀kọ́ tí òbí kan máa ń kọ́ ọmọ rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́.

2, 3. Báwo ni ìbáwí ṣe gba pé ká kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ká sì tún fìyà tó tọ́ jẹni? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

2 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí: Ọmọ kékeré kan tó ń jẹ́ Jídé ń gbá bọ́ọ̀lù nínú ilé. Ìyá rẹ̀ wá kìlọ̀ fún un pé: “Jídé, o mọ̀ pé kò yẹ kó o gbá bọ́ọ̀lù nínú ilé. Tó o bá lọ fọ́ nǹkan ńkọ́?” Àmọ́ kò gbọ́ràn, ṣe ló ń gbá bọ́ọ̀lù náà lọ títí tó fi fọ́ ìkòkò kan tó wà lórí tábìlì. Báwo ni ìyá rẹ̀ ṣe máa bá a wí? Ìbáwí náà lè gba pé kó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, kó sì tún fìyà díẹ̀ jẹ ẹ́. Tó bá fẹ́ kọ́ ọ, ó lè sọ  fún un pé ohun tó ṣe yẹn ò dáa. Á jẹ́ kó mọ̀ pé tó bá ń ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ̀ àǹfààní tiẹ̀ náà ló máa jẹ́. Kí ọmọ náà lè wá mọ̀ pé ohun tóun ṣe ò dáa rárá, ìyá rẹ̀ lè fìyà tó tọ́ jẹ ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ìyá rẹ̀ lè gba bọ́ọ̀lù náà, kó sì sọ fún un pé òun ò fẹ́ rí bọ́ọ̀lù lẹ́sẹ̀ rẹ̀ mọ́ fáwọn àkókò kan. Ìyẹn á jẹ́ kọ́mọ náà mọ̀ pé téèyàn bá ṣàìgbọràn, á jìyà ẹ̀.

3 Lónìí, bá a ṣe wà nínú ìjọ Kristẹni ti mú ká di ara ìdílé Ọlọ́run. (1 Tím. 3:15) Torí náà, a gbà pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti fún wa ní ìtọ́ni àti pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti fìfẹ́ bá wa wí tá a bá ṣàìgbọràn. Bákan náà, tá a bá hùwà tí kò dáa, tá a sì jìyà ẹ̀, á jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ṣègbọràn sí Baba wa ọ̀run. (Gál. 6:7) Ká sòótọ́, Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kò sì fẹ́ ká máa jìyà.​—1 Pét. 5:​6, 7.

4. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa tọ́ àwọn ọmọ wa àtàwọn míì sọ́nà? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì tọ́ àwọn ọmọ wa àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ sọ́nà, ìyẹn á mú kí wọ́n sapá láti di ọmọlẹ́yìn Kristi. Bíbélì ló yẹ ká máa fi kọ́ni torí pé ó máa jẹ́ ká lè ‘báni wí nínú òdodo.’ Tá a bá ń lo Bíbélì, àá lè ran àwọn ọmọ wa àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ káwọn náà lè máa ‘pa gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ fún wa mọ́.’ (2 Tím. 3:16; Mát. 28:​19, 20) Jèhófà máa bù kún wa tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á sì mú káwọn náà sapá láti ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọmọlẹ́yìn Kristi. (Ka Títù 2:​11-14.) Ẹ jẹ́ ká wá gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta yìí yẹ̀ wò: (1) Báwo ni ìbáwí Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa? (2) Kí la lè kọ́ lára àwọn tí Jèhófà bá wí láyé àtijọ́? (3) Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ tá a bá ń báni wí?

ỌLỌ́RUN MÁA Ń FÌFẸ́ BÁ WA WÍ

5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa nígbà tó bá ń tọ́ wa sọ́nà?

5 Jèhófà máa ń tọ́ wa sọ́nà, ó sì máa ń kọ́ wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ó fẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ òun, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Jòh. 4:16) Jèhófà kì í kàn wá lábùkù, tàbí kó máa nà wá lẹ́gba ọ̀rọ̀ débi pé á máa ṣe wá bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan. (Òwe 12:18) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọyì wa, àwọn ibi tá a dáa sí ló sì máa ń wò. Kódà ó fún wa lómìnira láti yan ohun tá a fẹ́. Ǹjẹ́ ìwọ náà gbà pé ìfẹ́ ló ń mú kí Jèhófà lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìtẹ̀jáde wa, àwọn òbí wa tó jẹ́ Kristẹni àtàwọn alàgbà láti tọ́ wa sọ́nà, kí wọ́n sì bá wa wí? Nígbà míì, a lè “ṣi ẹsẹ̀ gbé” tàbí ká ṣàṣìṣe láìmọ̀, àwọn alàgbà máa ń fara wé Jèhófà nígbà tí wọ́n bá fi sùúrù àti ìfẹ́ tọ́ wa sọ́nà.​—Gál. 6:1.

6. Tí wọ́n bá bá ẹnì kan wí tó sì pàdánù àwọn àǹfààní kan nínú ìjọ, báwo nìyẹn ṣe ń fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?

6 Nígbà míì, ìbáwí lè gba pé kí wọ́n ká ẹnì kan lọ́wọ́ kò. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè pàdánù àwọn àǹfààní kan nínú ìjọ. Kódà tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, irú ìbáwí yẹn ṣì fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá pàdánù àwọn àǹfààní tó ní nínú ìjọ, ìyẹn á jẹ́ kó rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, kó máa ṣàṣàrò, kó sì máa gbàdúrà. Nípa bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Sm. 19:7) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó lè pa dà wá ní àwọn àǹfààní míì nínú ìjọ. Kódà tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ìyẹn náà fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa torí pé ìwà burúkú yẹn ò ní ran àwọn míì nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:​6, 7, 11) Bákan náà, torí pé Jèhófà máa ń báni wí dé ìwọ̀n tó tọ́, ìyẹn á jẹ́ kẹ́ni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ mọ̀ pé ohun tóun ṣe burú  gan-an, ó sì lè mú kó ronú pìwà dà.​—Ìṣe 3:19.

ÌBÁWÍ JÈHÓFÀ ṢE WỌ́N LÁǸFÀÀNÍ

7. Ta ni Ṣébínà, àṣìṣe wo ló sì ṣe?

7 Ká lè rí àǹfààní tí ìbáwí máa ń mú wá, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ àwọn méjì tí Jèhófà bá wí yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́ ni Ṣébínà tó gbáyé nígbà ìṣàkóso Ọba Hesekáyà, ẹnì kejì sì ni Graham, arákùnrin kan lóde òní. Ṣébínà ni “ẹni tí ń ṣe àbójútó ilé” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ti Ọba Hesekáyà, torí náà ipò àṣẹ ló wà. (Aísá. 22:15) Àmọ́ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, ó sì ń wá ògo fún ara rẹ̀. Kódà, ó gbẹ́ ibojì ńlá kan fún ara rẹ̀, ó sì ń gun “àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ògo.”​—Aísá. 22:​16-18.

Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá a sì ṣàtúnṣe, Jèhófà máa bù kún wa (Wo ìpínrọ̀ 8 sí 10)

8. Báwo ni Jèhófà ṣe bá Ṣébínà wí, kí ni Ṣébínà sì ṣe?

8 Torí pé Ṣébínà ń wá ògo fún ara rẹ̀, Ọlọ́run lé e ‘kúrò ní ipò rẹ̀,’ ó sì fi Élíákímù rọ́pò rẹ̀. (Aísá. 22:​19-21) Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà fẹ́ gbógun ja Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó yá, Senakéríbù rán àwọn kan tó wà nípò gíga nínú ìjọba rẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá kí wọ́n lè ṣẹ̀rù ba àwọn Júù, kí wọ́n sì mú kí Hesekáyà túúbá fún wọn. (2 Ọba 18:​17-25) Hesekáyà wá rán Élíákímù pé kó lọ rí àwọn tí Senakéríbù rán wá, Élíákímù àtàwọn méjì míì ni wọ́n sì jọ lọ. Ọ̀kan nínú wọn ni Ṣébínà tó ti wá di akọ̀wé báyìí. Ǹjẹ́ èyí kì í ṣe ẹ̀rí pé Ṣébínà gba ìbáwí tí Jèhófà fún un? Kò ráhùn, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fìrẹ̀lẹ̀ gba iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ tí wọ́n fún un. Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ mẹ́ta tá a lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí.

9-11. (a) Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ṣébínà? (b) Kí lo rí kọ́ nípa Jèhófà nínú ọ̀nà tó gbà bá Ṣébínà wí?

9 Àkọ́kọ́, Ṣébínà pàdánù ipò rẹ̀. Èyí jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni ìkìlọ̀ Bíbélì tó sọ pé, “ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.” (Òwe 16:18) Tíwọ náà bá láwọn àǹfààní kan nínú ìjọ, tí àǹfààní náà sì ń mú káwọn míì máa kan sárá sí ẹ, ṣé wàá sapá láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Ṣé wàá gbà pé Jèhófà ló mú kó o ṣe àwọn àṣeyọrí tó o ṣe àti pé òun ló fún ẹ láwọn ẹ̀bùn tó o ní? (1 Kọ́r. 4:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro.”​—Róòmù 12:3.

10 Èkejì, bí Jèhófà ṣe bá Ṣébínà wí fi hàn pé Jèhófà kò wo Ṣébínà bí ẹni tí kò lè ṣàtúnṣe mọ́. (Òwe 3:​11, 12) Ẹ̀kọ́  pàtàkì nìyẹn jẹ́ fáwọn tó bá pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní nínú ìjọ lónìí. Dípò kí wọ́n máa bínú tàbí kí wọ́n máa fapá jánú, ó yẹ kí wọ́n sapá láti ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n bá lè ṣe nínú ìjọ, kí wọ́n sì gbà pé torí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn ló ṣe bá wọn wí. Ká rántí pé tá a bá rẹ ara wa sílẹ̀, Jèhófà máa san wá lẹ́san. (Ka 1 Pétérù 5:​6, 7.) Jèhófà máa ń fi ìbáwí onífẹ̀ẹ́ mọ wá, torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ ara wa di amọ̀ rírọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.

11 Ẹ̀kẹta, táwọn òbí tàbí àwọn alàgbà bá fẹ́ báni wí, wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá Ṣébínà wí. Lọ́nà wo? Bí Jèhófà ṣe bá Ṣébínà wí fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan dá ló kórìíra, kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ náà. Tíwọ náà bá fẹ́ báni wí, á dáa kó o fara wé Jèhófà. O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá sapá láti wá ibi tẹ́ni náà dáa sí, kó o sì jẹ́ kó mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó dá lo kórìíra, kì í ṣe òun fúnra rẹ̀.​—Júúdà 22, 23.

12-14. (a) Kí làwọn kan máa ń ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá bá wọn wí? (b) Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran arákùnrin kan lọ́wọ́ láti yíwà pa dà, àǹfààní wo ló sì rí?

12 Ó ṣeni láàánú pé lẹ́yìn tí wọ́n bá àwọn kan wí, ṣe ni wọ́n bínú fi Jèhófà àti ètò rẹ̀ sílẹ̀. (Héb. 3:​12, 13) Àmọ́ ṣé ọ̀rọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti kọjá àtúnṣe ni? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Graham tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ nígbà kan, nígbà tó yá wọ́n gbà á pa dà, àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn ló di aláìṣiṣẹ́mọ́. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, alàgbà kan sapá láti di ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì ní kí alàgbà náà máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

13 Alàgbà náà sọ pé: “Ìgbéraga nìṣòro Graham. Ṣe ló ń ṣàríwísí àwọn alàgbà tó bójú tó ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Torí náà, mo jẹ́ kí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ mélòó kan tá a ṣe lẹ́yìn yẹn dá lórí àwọn Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí kò fi yẹ ká máa gbéra ga. Graham wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara rẹ̀ wò, ó sì rí i pé àfi kóun ṣàtúnṣe. Kíá ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe! Ó rí i pé ìgbéraga ni ò jẹ́ kóun gba ìbáwí táwọn alàgbà fún òun, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í yíwà pa dà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé déédéé, ó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, kò sì fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré. Yàtọ̀ síyẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í múpò iwájú nínú ìdílé rẹ̀ tó bá kan ọ̀rọ̀ ìjọsìn, ìyẹn sì mú kí inú ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ dùn gan-an.”​—Lúùkù 6:​41, 42; Ják. 1:​23-25.

14 Alàgbà yẹn tún sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, Graham sọ nǹkan kan fún mi tó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ó ní: ‘Ọjọ́ pẹ́ tí mo ti wà nínú òtítọ́, kódà mo ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà rí. Àmọ́ ìsinsìnyí ni mo tó lè sọ pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.’ Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n sọ fún un pé kó máa gbé makirofóònù nípàdé, ó sì mọyì àǹfààní yẹn gan-an. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Graham jẹ́ kí n mọ̀ lóòótọ́ pé tẹ́nì kan bá rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ tó sì gba ìbáwí Jèhófà, ìbùkún tó máa rí á kọjá àfẹnusọ.”

FARA WÉ JÈHÓFÀ ÀTI JÉSÙ TÓ O BÁ Ń BÁNI WÍ

15. Ká tó lè lẹ́nu ọ̀rọ̀ láti báni wí, kí ló yẹ ká ṣe?

15 Tẹ́nì kan bá fẹ́ jẹ́ olùkọ́ tó dáa, òun fúnra ẹ̀ gbọ́dọ̀ gbẹ̀kọ́ dáadáa. (1 Tím. 4:​15, 16) Torí náà, ó yẹ káwọn tí Jèhófà fún láṣẹ láti máa báni wí lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ìyẹn àwọn òbí àtàwọn alàgbà, kí wọ́n sì jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ àwọn sọ́nà. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ káwọn míì bọ̀wọ̀ fún wọn, wọ́n á sì lẹ́nu ọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ tàbí tí wọ́n bá fẹ́ bá a wí. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ lára Jésù.

16. Kí la rí kọ́ lára Jésù tó bá di pé ká báni wí tàbí ká kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?

16 Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀, kódà ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tí kò  bá tiẹ̀ rọrùn pàápàá. (Mát. 26:39) Ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àtọ̀dọ̀ Jèhófà ni ẹ̀kọ́ tóun ń kọ́ wọn ti wá, Jèhófà náà ló sì fún òun lọ́gbọ́n tóun ní. (Jòh. 5:​19, 30) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní àti bó ṣe máa ń ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ mú kó jẹ́ olùkọ́ tó láàánú tó sì ń tuni lára, ìyẹn sì mú káwọn èèyàn sún mọ́ ọn. (Ka Lúùkù 4:22.) Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìtura bá àwọn tó dà bí òwú àtùpà tó ń jó lọ́úlọ́ú, ìyẹn àwọn tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. (Mát. 12:20) Kódà nígbà táwọn èèyàn ṣe ohun tó dùn ún, kàkà kó bínú sí wọn, ṣe ló fìfẹ́ bá wọn lò. Èyí hàn nínú bó ṣe fìfẹ́ bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wí nígbà tí wọ́n ń bá ara wọn fa ọ̀rọ̀ ẹni tó tóbi jù láàárín wọn.​—Máàkù 9:​33-37; Lúùkù 22:​24-27.

17. Táwọn alàgbà bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ àbójútó tí Ọlọ́run gbé fún wọn lọ́nà tó tọ́, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe?

17 Táwọn alàgbà bá fẹ́ báni wí, á dáa kí wọ́n fara wé Jésù, kí wọ́n sì gbé ọ̀rọ̀ wọn ka Bíbélì. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé wọ́n fẹ́ kí Jèhófà àti Jésù máa darí àwọn. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pét. 5:​2-4) Táwọn alàgbà bá ń fi ara wọn sábẹ́ ìdarí Ọlọ́run àti Kristi tó jẹ́ orí ìjọ, wọ́n á ṣe ara wọn láǹfààní, wọ́n á sì tún ṣe ìjọ náà láǹfààní.​—Aísá. 32:​1, 2, 17, 18.

18. (a) Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn òbí ṣe? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe wọn?

18 Kí ló máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti bá àwọn ọmọ wọn wí lọ́nà tó yẹ? Bíbélì sọ fáwọn olórí ìdílé pé: “Ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe ṣe pàtàkì tó? Òwe 19:18 jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìyè àti ikú ni bíbá ọmọ wí. Torí náà, tí òbí kan bá fẹ́ kọ́mọ rẹ̀ máa wà láàyè, àfi kó máa bá a wí. Àmọ́ tí òbí kan ò bá bá ọmọ rẹ̀ wí lọ́nà tó yẹ, kó sì tọ́ ọ sọ́nà, irú òbí bẹ́ẹ̀ máa jíhìn fún Jèhófà. (1 Sám. 3:​12-14) Kò rọrùn, síbẹ̀ táwọn òbí bá ń fìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà, tí wọ́n ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ àwọn sọ́nà, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí àwọn, Jèhófà máa fún wọn ní ọgbọ́n àti okun tí wọ́n nílò láti ṣe ojúṣe wọn.​—Ka Jákọ́bù 1:5.

À Ń KỌ́ BÁ A ṢE LÈ MÁA GBÉ PỌ̀ NÍ ÀLÀÁFÍÀ TÍTÍ LÁÉ

19, 20. (a) Àwọn ìbùkún wo la máa rí tá a bá ń gba ìbáwí Jèhófà? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

19 Ká sòótọ́, a ò lè kaye ìbùkún tá a máa rí tá a bá ń gba ìbáwí Jèhófà, tá a sì ń fara wé Jèhófà àti Jésù táwa náà bá ń báni wí. Lára ẹ̀ ni pé, ìdílé wa máa tòrò, àlàáfíà sì máa wà nínú ìjọ. Ọkàn gbogbo wa máa balẹ̀, ara á tù wá, àá sì nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú. Ìtọ́wò lásán lèyí tá a bá fi wé àwọn nǹkan tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun. (Sm. 72:7) Kò sí àní-àní pé ìbáwí Jèhófà ń kọ́ wa bá a ṣe lè máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà títí láé, ká sì wà níṣọ̀kan bí ìdílé kan lábẹ́ àbójútó Baba wa ọ̀run. (Ka Aísáyà 11:9.) Tá a bá ń fojú tó tọ́ wo ìbáwí Jèhófà, ìyẹn á jẹ́ ká mọyì ìbáwí rẹ̀, ká sì gbà pé lóòótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

20 Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ púpọ̀ sí i nípa ìbáwí nínú ìdílé àti nínú ìjọ. A tún máa jíròrò bí ìbáwí ṣe tan mọ́ ìkóra-ẹni-níjàánu àti ohun kan tó burú ju ẹ̀dùn ọkàn téèyàn máa ń ní tí wọ́n bá bá a wí.