Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) March 2018

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti April 30 sí June 3, 2018 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ìrìbọmi​—Ohun Tó Yẹ Kí Gbogbo Kristẹni Ṣe

Kí ni Bíbélì sọ nípa ìrìbọmi? Kí làwọn nǹkan téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi? Tí Kristẹni kan bá ń kọ́ ẹnì kan tàbí ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí nìdí tó fi yẹ kó máa rántí pé ìrìbọmi ṣe pàtàkì?

Ẹ̀yin Òbí, Ṣé Ẹ̀ Ń Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi?

Kí ló yẹ káwọn òbí Kristẹni rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn mọ̀ kí wọ́n tó ṣèrìbọmi?

ÌBÉÈRÈ LÁTI ỌWỌ́ ÀWỌN ÒǸKÀWÉ

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń yàwòrán Pọ́ọ̀lù bí ẹni tó pá lórí tàbí bí ẹni tó nírun díẹ̀?

Aájò Àlejò Ṣe Pàtàkì Gan-An

Kí nìdí tí Ìwé Mímọ́ fi ní ká ṣe ara wa lálejò? Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn? Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti gba ara wa lálejò, báwo la sì ṣe lè borí wọn?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Ò Já Mi Kulẹ̀ Rí

Erika Nöhrer Bright ti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti míṣọ́nnárì. Ó sọ bí Jèhófà ṣe fún òun lókun, tó sì dúró ti òun ní gbogbo ọdún tóun fi wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Báwo Ni Ìbáwí Ṣe Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa?

Kí la rí kọ́ lára àwọn tí Jèhófà bá wí nígbà àtijọ́? Báwo la sì ṣe lè fara wé Jèhófà tá a bá ń báni wí?

‘Fetí sí Ìbáwí Kó O sì Di Ọlọ́gbọ́n’

Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń kọ́ wa ní ìkóra-ẹni-níjàánu? Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìbáwí tí wọ́n bá fún wa nínú ìjọ?