Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  March 2017

Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Tí Ọlá Tọ́ Sí

Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Tí Ọlá Tọ́ Sí

“Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni kí ìbùkún àti ọlá àti ògo àti agbára ńlá wà fún títí láé.”ÌṢÍ. 5:13.

ORIN: 9, 108

1. Kí nìdí tá a fi ń bọlá fáwọn èèyàn kan, kí la sì máa jíròrò báyìí?

TÁ A bá sọ pé a bọlá fún ẹnì kan, ó túmọ̀ sí pé a ka ẹni náà sí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, a sì bọ̀wọ̀ fún un. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń bọlá fún àwọn tó ṣe nǹkan àrà ọ̀tọ̀ tàbí àwọn tó wà nípò àṣẹ. Àmọ́ ó yẹ ká bi ara wa pé, ta ló yẹ ká bọlá fún, kí sì nìdí tó fi yẹ ká bọlá fún irú ẹni bẹ́ẹ̀?

2, 3. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká bọlá fún Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Ta ni ìwé Ìṣípayá 5:13 pè ní Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká bọlá fún un?

2 Ìwé Ìṣípayá 5:13 sọ pé ó yẹ ká bọlá fún “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Orí kẹrin ìwé Ìṣípayá jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká máa bọlá fún Jèhófà. Àwọn áńgẹ́lì ń pa ohùn wọn pọ̀, wọ́n sì ń yin Jéhófà “Ẹni tí ó wà láàyè títí láé àti láéláé.” Wọ́n ń sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”Ìṣí. 4:9-11.

3 Jésù Kristi ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, ìyẹn “Ọ̀dọ́ Àgùntàn  Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòh. 1:29) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ju gbogbo àwọn ọba tó tíì jẹ láyé yìí lọ títí kan àwọn tó wà lórí ìtẹ́ báyìí. Bíbélì pe Jésù ní “Ọba àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti Olúwa àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olúwa, ẹnì kan ṣoṣo tí ó ní àìkú, ẹni tí ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́, ẹni tí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí ó ti rí i tàbí lè rí i.” (1 Tím. 6:14-16) Ká sòótọ́, ọba míì wo ló ti yọ̀ǹda ẹ̀mí ara rẹ̀ kó lè rà wá pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀? Ǹjẹ́ kò wù ẹ́ pé kó o dara pọ̀ mọ́ àwọn áńgẹ́lì tó ń sọ pé: “Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí a fikú pa ni ó yẹ láti gba agbára àti ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti okun àti ọlá àti ògo àti ìbùkún.”Ìṣí. 5:12.

4. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé ká bọlá fún Jèhófà àti Kristi?

4 Ó pọn dandan pé ká bọlá fún Jèhófà àti Jésù, ìdí sì ni pé tá ò bá bọlá fún wọn, a lè pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 5:22, 23 jẹ́ kó ṣe kedere, ó ní: “Baba kì í ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni rárá, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe lé Ọmọ lọ́wọ́, kí gbogbo ènìyàn lè máa bọlá fún Ọmọ gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń bọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá bọlá fún Ọmọ kò bọlá fún Baba tí ó rán an.”Ka Sáàmù 2:7, 11.

5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọlá fún gbogbo èèyàn ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn dé ìwọ̀n àyè kan?

5 Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́n. 1:27) Èyí túmọ̀ sí pé àwa èèyàn lè fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run hàn, lọ́nà tó yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, àwa èèyàn lè fi ìfẹ́ hàn, ká fi inú rere hàn, ká sì fi ìyọ́nú hàn. Ọlọ́run tún fún àwa èèyàn ní ẹ̀rí ọkàn ká lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Róòmù 2:14, 15) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń nífẹ́ẹ̀ ohun tó bá mọ́ tó sì rẹwà, wọ́n sì máa ń fẹ́ gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì. Yálà wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀ àbí wọn ò mọ̀, wọ́n ń gbé ògo Jèhófà yọ, torí náà, dé ìwọ̀n àyè kan, ó yẹ ká bọlá fún wọn ká sì bọ̀wọ̀ fún wọn.Sm. 8:5.

BÓ ṢE YẸ KÁ MÁA BỌLÁ FÁWỌN MÍÌ

6, 7. Tó bá dọ̀rọ̀ ká máa bọlá fáwọn èèyàn, báwo làwa Kristẹni tòótọ́ ṣe yàtọ̀ sáwọn míì?

6 Ó yẹ ká ṣọ́ra ká má lọ máa gbé àwọn èèyàn gẹ̀gẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn bọlá fáwọn míì bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, àmọ́ ẹ̀mí ayé Sátánì ti mú káwọn èèyàn sọ àwọn kan di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Lára àwọn táráyé ń gbógo fún ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, àwọn olóṣèlú, àwọn eléré ìdárayá, àwọn tó ń ṣe eré orí ìtàgé, àwọn olórin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n ti sọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ di ọlọ́run. Torí náà, tèwe tàgbà ló máa ń ṣe bíi tiwọn, kódà wọ́n máa ń káṣà bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, bí wọ́n ṣe ń múra àti bí wọ́n ṣe ń hùwà.

7 Àwa Kristẹni tòótọ́ kì í gbé àwọn èèyàn gẹ̀gẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Nínú gbogbo àwọn tó ti gbé ayé rí, Kristi nìkan ló fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé. (1 Pét. 2:21) Inú Ọlọ́run kò ní dùn tá a bá ń bọlá fáwọn èèyàn kọjá bó ṣe yẹ. Òótọ́ kan tó yẹ ká máa rántí ni pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Torí náà, kò sídìí láti sọ èèyàn èyíkéyìí di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ.

8, 9. (a) Báwo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa ń ṣe sáwọn aláṣẹ? (b) Ibo ló yẹ ká bọ̀wọ̀ fún wọn dé?

8 Nínú ayé lónìí, àwọn kan wà nípò àṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba máa ń rí i pé àwọn èèyàn pa òfin àti àṣẹ ìlú mọ́, wọ́n máa ń bójú tó àwọn aráàlú,  gbogbo èèyàn ló sì máa ń jàǹfààní látinú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n fi ara wọn sábẹ́ “àwọn aláṣẹ onípò gíga.” Ó wá fún wọn ní ìtọ́ni pé: “Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí; . . . ẹni tí ó béèrè fún ọlá, ẹ fún un ní irúfẹ́ ọlá bẹ́ẹ̀.”Róòmù 13:1, 7.

9 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin ìjọba máa ń yàtọ̀ láti ibì kan sí òmíì, síbẹ̀ a máa ń tẹ̀ lé òfin tí wọ́n bá là sílẹ̀. Àmọ́ tí òfin tí wọ́n fún wa bá ta ko ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, a ò ní tẹ̀ lé e. A ò ní torí pé a fẹ́ bọ̀wọ̀ fún wọn ká wá tẹ òfin Ọlọ́run lójú tàbí ká ṣe ohun tó máa ba ẹ̀rí ọkàn wa jẹ́ tàbí ká lọ́wọ́ sóhun tí kò yẹ ká lọ́wọ́ sí.Ka 1 Pétérù 2:13-17.

10. Àpẹẹrẹ wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ bíbọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?

10 Tó bá dọ̀rọ̀ bíbọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ayé àtijọ́. Nígbà tí ìjọba Róòmù sọ pé káwọn èèyàn wá fi orúkọ sílẹ̀, Jósẹ́fù àti Màríà náà lọ forúkọ sílẹ̀. Wọ́n rìnrìn-àjò lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù bó tilẹ̀ jẹ́ pé oyún Màríà ti ga gan-an, ó sì máa tó bímọ. (Lúùkù 2:1-5) Nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn èké kan Pọ́ọ̀lù, ó gbèjà ara rẹ̀ níwájú Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà àti Fẹ́sítọ́ọ̀sì tó jẹ́ gómìnà Róòmù tó ń ṣàkóso Jùdíà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.Ìṣe 25:1-12; 26:1-3.

11, 12. (a) Kí nìdí tí ọ̀wọ̀ tá à ń fún àwọn aláṣẹ fi yàtọ̀ sí èyí tá à ń fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ẹlẹ́rìí kan fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fún olóṣèlú kan?

11 Bákan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ga, bí wọ́n bá tiẹ̀ ń retí pé ká ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹlẹ́sìn èké kì í kọ́ni ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run, wọn kì í sì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Torí náà, a kì í bọlá àrà ọ̀tọ̀ fún wọn, bá a ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn yòókù náà ló yẹ ká máa ṣe sí wọn. Ẹ jẹ́ ká tún rántí pé Jésù bẹnu àtẹ́ lu àwọn aṣáájú ẹ̀sìn nígbà ayé rẹ̀, ó pè wọ́n ní alágàbàgebè àti afọ́jú afinimọ̀nà. (Mát. 23:23, 24) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ, ó lè sèso rere.

12 Àpẹẹrẹ kan ni ti olóṣẹ̀lú orílẹ̀-èdè Austria kan tó ń jẹ́ Heinrich Gleissner. Nígbà ogun àgbáyé kejì, ìjọba Násì jù ú sẹ́wọ̀n torí pé ọ̀rọ̀ wọn ò wọ̀ mọ́. Wọ́n wá fi í sínú ọkọ̀ ojú irin kan, ibẹ̀ ló sì ti pàdé Ẹlẹ́rìí onítara kan tó ń jẹ́ Leopold Engleitner tó wá láti orílẹ̀-èdè Austria. Ìjọba Násì fàṣẹ ọba mú òun náà, wọ́n sì rán an lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà nílùú Buchenwald. Nínú ọkọ̀ ojú irin yẹn, Arákùnrin Engleitner fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fún Gleissner, òun náà sì tẹ́tí sí i dáadáa. Nígbà tí ogun àgbáyé kejì parí, léraléra ni Gleissner gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè Austria. Ìwọ náà lè rántí àwọn àbájáde rere tá a máa ń ní tá a bá bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ, tá a sì ń fún wọn ní ọ̀wọ̀ tí Bíbélì sọ pé ká máa fún wọn.

ÀWỌN MÍÌ TÓ YẸ KÁ BỌ̀WỌ̀ FÚN

13. Àwọn wo gan-an ló yẹ ká máa bọlá fún, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀?

13 Ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ ká sì tún máa bọlá fáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, pàápàá jù lọ àwọn alàgbà tó ń múpò iwájú. (Ka 1 Tímótì 5:17.) A máa ń bọ̀wọ̀  fáwọn arákùnrin yìí láìka ibi tí wọ́n ti wá, bí wọ́n ṣe kàwé tó, bí wọ́n ṣe gbajúmọ̀ tó láwùjọ tàbí bí wọ́n ṣe lówó lọ́wọ́ sí. Bíbélì pè wọ́n ní “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn.” Wọ́n wà lára àwọn tí Jèhófà ṣètò pé kó máa bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀. (Éfé. 4:8) Ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà ìjọ, àwọn alábòójútó àyíká, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fáwọn tó ń múpò iwájú, ohun táwa náà sì ń ṣe lónìí nìyẹn. A kì í sọ àwọn aṣojú tí ètò Ọlọ́run ń lò di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, tá a bá sì wà pẹ̀lú wọn, a ò ní máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀ bíi pé áńgẹ́lì ni wọ́n. Síbẹ̀, a máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn arákùnrin yìí torí iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ní, a sì máa ń bọlá fún wọn.Ka 2 Kọ́ríńtì 1:24; Ìṣípayá 19:10.

14, 15. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn alàgbà àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn?

14 Olùṣọ́ àgùntàn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ la mọ àwọn alàgbà yìí sí. Torí pé wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọn kì í gbà káwọn èèyàn máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀ bí àwọn gbajúgbajà. Wọ́n yàtọ̀ sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn òde òní àtàwọn tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí Jésù sọ nípa wọn pé: “Wọ́n fẹ́ ibi yíyọrí ọlá jù lọ níbi oúnjẹ alẹ́ àti àwọn ìjókòó iwájú nínú àwọn sínágọ́gù, àti ìkíni ní àwọn ibi ọjà.”Mát. 23:6, 7.

15 Àwọn alàgbà tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń ṣe ohun tí Jésù sọ pé: “Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni kí a má pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi. Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ òjíṣẹ́ yín. Ẹnì yòówù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ẹnì yòówù tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.” (Mát. 23:8-12) Torí pé àwọn alàgbà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, inú àwọn ará níbi gbogbo láyé máa ń dùn láti bọlá fún wọn, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.

Torí pé àwọn alàgbà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, inú àwọn ará máa ń dùn láti bọlá fún wọn, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an (Wo ìpínrọ̀ 13 sí 15)

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bíbọlá fúnni, ká sì máa fi í sílò?

16 Lóòótọ́, ó lè má rọrùn fún wa láti mọ àwọn tó yẹ ká bọlá fún àti dé ìwọ̀n àyè tó yẹ ká bọlá fún wọn. Irú  ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni ayé àtijọ́ náà. (Ìṣe 10:22-26; 3 Jòh. 9, 10) Síbẹ̀, ó yẹ ká sapá láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bíbọlá fúnni, ká sì máa fi í sílò. Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá ń bọlá fúnni bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

ÀǸFÀANÍ TÓ WÀ NÍNÚ BÍBỌLÁ FÚNNI BÓ ṢE TỌ́ ÀTI BÓ ṢE YẸ

17. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń bọlá fáwọn tó wà nípò àṣẹ?

17 Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà nípò àṣẹ, ó ṣeé ṣe kí wọ́n túbọ̀ máa gbèjà ẹ̀tọ́ tá a ní láti wàásù. Èyí sábà máa ń mú káwọn èèyàn fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ ìwàásù wa. Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, aṣáájú-ọ̀nà kan lórílẹ̀-èdè Jámánì tó ń jẹ́ Birgit lọ sí ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ọmọ rẹ̀ nílé ìwé. Àwọn olùkọ́ ibẹ̀ wá sọ fún un pé ohun tí àwọn ti rí láti ọdún yìí wá ni pé àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń hùwà tó dáa. Wọ́n ní ojútì gbáà ló máa jẹ́ táwọn ò bá lọ́mọ Ẹlẹ́rìí kankan nílé ìwé àwọn. Birgit wá sọ pé, “A máa ń kọ́ àwọn ọmọ wa pé kí wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, a sì máa ń kọ́ wọn pé kí wọ́n máa bọlá fáwọn olùkọ́ wọn.” Olùkọ́ kan sọ pé, “Ká sọ pé gbogbo ọmọ ló dà bí ọmọ yín, iṣẹ́ olùkọ́ kàn máa dà bí ẹni ń fi ẹran jẹ̀kọ ni.” Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ náà lọ sí àpéjọ àgbègbè tá a ṣe nílùú Leipzig.

18, 19. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa gbé àwọn alàgbà gẹ̀gẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ?

18 Tá a bá fẹ́ máa bọlá fáwọn alàgbà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. (Ka Hébérù 13:7, 17.) Ó yẹ ká máa gbóríyìn fún wọn torí iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe, ká sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n ń fún wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á mú kí wọ́n máa fi ìdùnnú bá iṣẹ́ wọn lọ. Àmọ́ o, èyí ò túmọ̀ sí pé ká wá máa káṣà bí alàgbà kan táwọn èèyàn kà sí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ṣe ń múra àti bó ṣe ń sọ̀rọ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa dà bíi pé òun là ń tẹ̀ lé. Ó yẹ ká rántí pé aláìpé làwọn alàgbà, àpẹẹrẹ Kristi nìkan ló sì yẹ ká máa tẹ̀ lé.

19 Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, tá ò sì máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀ bí àwọn gbajúgbajà, ṣe là ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìdí ni pé, kò ní jẹ́ kí wọ́n máa gbéra ga tàbí kí wọ́n máa rò pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ tàbí pé àwọn nìkan làwọn mọ nǹkan ṣe.

20. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń bọlá fáwọn míì?

20 Tó bá ti mọ́ wa lára láti máa bọlá fáwọn míì, a ò ní máa ro tara wa nìkan. Kò ní jẹ́ ká jọ ara wa lójú táwọn èèyàn bá ń bọlá fún wa. Bákan náà, á jẹ́ ká máa fara wé ètò Jèhófà tó bá di pé ká bọlá fáwọn èèyàn. Ètò Jèhófà kì í bọlá fáwọn èèyàn kọjá bó ṣe yẹ yálà Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n àbí wọn kí í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, kò ní jẹ́ ká ṣìwà hù tí ẹnì kan tá à ń bọlá fún bá ṣe ohun tó dùn wá.

21. Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa bọlá fúnni bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ?

21 Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa bọlá fúnni bó ṣe yẹ ni pé àá máa múnú Jèhófà dùn. A jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run torí pé ohun tó fẹ́ ká ṣe là ń ṣe. Èyí sì ń mú kí Jèhófà fún ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣáátá rẹ̀ lésì. (Òwe 27:11) Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bọlá fúnni. A mà dúpẹ́ o pé a mọ bá a ṣe lè máa bọlá fúnni lọ́nà tí Jèhófà fẹ́.