Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) March 2017

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti May 1 sí 28, 2017 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Bá Àwọn Ọlọ́gbọ́n Rìn, Mo sì Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Wọn

William Samuelson dojú kọ ìṣòro, ó sì tún rí àwọn ohun tó fún un láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Tí Ọlá Tọ́ Sí

Ta ló yẹ ká bọlá fún, kí sì nìdí? Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?

Lo Ìgbàgbọ́—Kó O Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání!

Àwọn ìpinnu kan lè nípa lórí rẹ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ. Kí ló máa jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání?

Fi Ọkàn Pípé Pérépéré Sin Jèhófà!

Àwọn ọba Júdà náà Ásà, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà, àti Jòsáyà ṣàṣìṣe. Síbẹ̀ Ọlọ́run sọ pé wọ́n sin òun pẹ̀lú ọkàn pípé pérépéré. Kí nìdí?

Ṣé Wàá Fọkàn sí Àwọn Ohun Tá A Ti Kọ Sílẹ̀?

O lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe àwọn mí ì, títí kan àwọn èyí tí wọ́n kọ sínú Bíbélì.

Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Gidi Tí Àárín Ìwọ àti Ọ̀rẹ́ Rẹ Bá Fẹ́ Dàrú

Ọ̀rẹ́ rẹ lè níṣòro tó máa gba pé kó o ràn án lọ́wọ́ láti kọ́fẹ pa dà. Kí lo lè ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀?

Orúkọ Bíbélì Kan Tó Wà Lára Ìkòkò

Ní 2012, àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí àfọ́kù ìkòkò amọ̀ kan tó ti tó 3,000 ọdún. Àfọ́kù ìkòkò yìí ti wá di ìran àpẹ́wò fáwọn olùṣèwádìí. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ẹ̀?