‘Mo béèrè pé kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi.’​—JÒH. 17:20, 21.

ORIN: 24, 99

1, 2. (a) Kí ni Jésù béèrè nínú àdúrà tó gbà kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀? (b) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Jésù fi bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìṣọ̀kan?

OHUN tó jẹ Jésù lọ́kàn lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ni bí wọ́n ṣe máa wà níṣọ̀kan. Ohun tó béèrè nínú àdúrà tó gbà pẹ̀lú wọn jẹ́ kó ṣe kedere pé ó wù ú pé káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan bí òun àti Bàbá òun ṣe jẹ́ ọ̀kan. (Ka Jòhánù 17:20, 21.) Tí wọ́n bá wà níṣọ̀kan, ó máa hàn gbangba pé Jèhófà ló rán Jésù wá sáyé kó lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìfẹ́ ló máa jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wà níṣọ̀kan, á sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wọ́n.​—Jòh. 13:34, 35.

2 Jésù tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wà níṣọ̀kan nígbà tí wọ́n ń jẹun pa pọ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn. Ìdí ni pé ẹnu wọn ò kò, wọn ò sì wà níṣọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, lórí ìjókòó níbẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn jiyàn “lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ,” kì í sì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tírú ẹ̀ máa wáyé nìyẹn. (Lúùkù 22:24-27; Máàkù 9:33, 34) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jákọ́bù àti Jòhánù sọ fún Jésù pé kó fi àwọn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì rẹ̀ nínú Ìjọba rẹ̀.​—Máàkù 10:35-40.

3. Àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe kó fà á táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò fi wà níṣọ̀kan, àwọn ìbéèrè wo la sì máa jíròrò?

 3 Lára ohun tí kò jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wà níṣọ̀kan ni pé wọ́n ń wá ipò ńlá fún ara wọn. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ẹ̀mí ìkórìíra àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tún gbilẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Káwọn ọmọlẹ́yìn tó lè wà níṣọ̀kan, àfi kí wọ́n fa ẹ̀mí burúkú yìí tu lọ́kàn wọn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Kí ni Jésù ṣe tí ẹ̀tanú àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ò fi jọba lọ́kàn rẹ̀? Báwo ló ṣe kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kò yẹ kí wọ́n máa ṣe ojúsàájú àti pé ó yẹ kí wọ́n wà níṣọ̀kan? Kí la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù táá mú ká wà níṣọ̀kan?

WỌ́N ṢE Ẹ̀TANÚ SÍ JÉSÙ ÀTÀWỌN ỌMỌLẸ́YÌN RẸ̀

4. Báwo làwọn èèyàn ṣe ṣẹ̀tanú sí Jésù?

4 Àwọn ìgbà kan wà táwọn èèyàn ṣe ẹ̀tanú sí Jésù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Fílípì sọ fún Nàtáníẹ́lì pé òun ti rí Mèsáyà, Nàtáníẹ́lì sọ pé: “Ohun rere kankan ha lè jáde wá láti Násárétì bí?” (Jòh. 1:46) Ó dájú pé Nàtáníẹ́lì mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Míkà 5:2, síbẹ̀ ó ronú pé kì í ṣe irú Násárétì yẹn ló yẹ kí Mèsáyà ti wá. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn ará Jùdíà máa ń fojú pa àwọn ará Gálílì rẹ́, kódà àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn ní Jùdíà tẹ́ńbẹ́lú Jésù torí pé Gálílì ló ti wá. (Jòh. 7:52) Àwọn Júù kan tiẹ̀ ń bú Jésù, wọ́n ń pè é ní ará Samáríà. (Jòh. 8:48) Àwọn ará Jùdíà àtàwọn ará Gálílì ò ka àwọn ará Samáríà séèyàn gidi, wọ́n sì máa ń yẹra fún wọn. Ìdí ni pé ẹ̀yà míì láwọn ará Samáríà, ẹ̀sìn wọn sì yàtọ̀ sí tàwọn Júù.​—Jòh. 4:9.

5. Ẹ̀tanú wo làwọn èèyàn ṣe sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù?

5 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù náà bẹnu àtẹ́ lu àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. Kódà, “ẹni ègún” làwọn Farisí kà wọ́n sí. (Jòh. 7:47-49) Lójú àwọn Farisí, ẹni tí kò bá lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì tàbí tí kò tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn kò ní láárí, gbáàtúù sì ni. (Ìṣe 4:13) Àwọn èèyàn ìgbà yẹn kórìíra àwọn tí ẹ̀sìn wọn, ipò wọn láwùjọ tàbí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí tiwọn, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi fojú tẹ́ńbẹ́lú Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Torí pé àárín àwọn èèyàn yẹn làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù náà dàgbà sí, àwọn náà lẹ́mìí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Torí náà, kí wọ́n tó lè wà níṣọ̀kan, wọ́n gbọ́dọ̀ fa èrò burúkú yìí tu lọ́kàn wọn.

6. Sọ àwọn ìrírí tó fi hàn pé ẹ̀tanú àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà lè ràn wá.

6 Ẹ̀tanú àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ló kúnnú ayé lónìí. Àwọn èèyàn lè máa ṣe ẹ̀tanú sí wa tàbí kó jẹ́ pé àwa là ń ṣe ẹ̀tanú sáwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ti di aṣáájú-ọ̀nà báyìí lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Inú máa ń bí mi tí mo bá ń rántí báwọn aláwọ̀ funfun ṣe fìyà jẹ àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Ọsirélíà nígbà àtijọ́ àti títí di báyìí. Tí mo bà sì rántí bí wọ́n ṣe hùwà ìkà sí mi, ńṣe ni inú wọn túbọ̀ máa ń bí mi.” Arákùnrin kan láti ilẹ̀ Kánádà sọ pé nígbà kan rí òun kórìíra àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, ó ní: “Lọ́kàn mi, mo gbà pé àwa tá à ń sọ èdè Faransé la dáa jù, torí náà mo kórìíra àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì.”

7. Kí ni Jésù ṣe tí ẹ̀tanú àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ò fi jọba lọ́kàn rẹ̀?

7 Ẹ̀tanú àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tètè máa ń jọba lọ́kàn ẹni, kì í sì í rọrùn láti fà tu. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí nígbà ayé Jésù, àmọ́ kí ni Jésù ṣe tí èrò yìí ò fi jọba lọ́kàn rẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, kò fàyè gba èrò yìí rárá, kò sì ṣe ojúsàájú. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo èèyàn ni Jésù máa ń wàásù fún, ì báà jẹ́ olówó tàbí tálákà, Farisí tàbí ará Samáríà, kódà ó wàásù fáwọn agbowó orí àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ìkejì, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ máa fura òdì tàbí kí wọ́n máa ṣẹ̀tanú sáwọn míì.

 ÌFẸ́ ÀTI Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀ MÁA JẸ́ KÁ BORÍ Ẹ̀TANÚ

8. Ìlànà pàtàkì wo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó máa jẹ́ ká wà níṣọ̀kan? Ṣàlàyé ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀.

8 Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìlànà pàtàkì kan táá jẹ́ ká wà níṣọ̀kan. Ó sọ pé: “Arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.” (Ka Mátíù 23:8, 9.) Ọ̀nà kan tí gbogbo wa gbà jẹ́ “arákùnrin” ni pé àtọ̀dọ̀ Ádámù la ti ṣẹ̀ wá. (Ìṣe 17:26) Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ o, Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé arákùnrin àti arábìnrin ni gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ torí wọ́n gbà pé Jèhófà ni Baba wọn ọ̀run. (Mát. 12:50) Bákan náà, gbogbo wọn ti di ìdílé ńlá kan nípa tẹ̀mí torí pé ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ wọn ti mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé táwọn àpọ́sítélì bá ń kọ lẹ́tà sáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn, wọ́n sábà máa ń sọ pé, ‘ẹ̀yin ará.’​—Róòmù 1:13; 1 Pét. 2:17; 1 Jòh. 3:13.

9, 10. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn Júù máa gbéra ga nítorí ẹ̀yà wọn? (b) Báwo ni Jésù ṣe kọ́ wọn pé kò yẹ kí wọ́n máa fojú pa àwọn ẹ̀yà míì rẹ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

9 Lẹ́yìn tí Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé arákùnrin àti arábìnrin ni gbogbo wa, ó tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (Ka Mátíù 23:11, 12.) Ká rántí pé ìgbéraga wà lára ohun tí kò jẹ́ káwọn àpọ́sítélì yẹn wà níṣọ̀kan. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn Júù máa ń gbéra ga nítorí ẹ̀yà wọn. Ọ̀pọ̀ wọn gbà pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ torí pé àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ni wọ́n. Àmọ́ Jòhánù Oníbatisí sọ fún wọn pé: “Ọlọ́run ní agbára láti gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù láti inú òkúta wọ̀nyí.”​—Lúùkù 3:8.

10 Jésù jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká máa gbéra ga torí ẹ̀yà tá a ti wá. Ó jẹ́ kí kókó yìí ṣe kedere nígbà tí akọ̀wé òfin kan bi í pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Jésù wá fi àpèjúwe kan dáhùn ìbéèrè yẹn, ó sọ nípa Júù kan táwọn olè lù nílùkulù. Nígbà táwọn Júù kan tó ń kọjá lọ rí ọkùnrin yẹn, ṣe ni wọ́n kàn bá tiwọn lọ. Àmọ́ nígbà tí ọkùnrin kan tó jẹ́ ará Samáríà rí i, àánú ṣe é, ó sì tọ́jú ọkùnrin náà. Jésù wá sọ fún akọ̀wé òfin náà pé á dáa kó fìwà jọ ará Samáríà yẹn. (Lúùkù 10:25-37) Jésù jẹ́ káwọn Júù rí i pé wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ará Samáríà tó bá di pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn.

11. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fa ẹ̀mí ìgbéraga àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu lọ́kàn wọn, báwo sì ni Jésù ṣe tẹ kókó yìí mọ́ wọn lọ́kàn?

11 Kí Jésù tó lọ sọ́run, ó pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wàásù “ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó lè ṣe iṣẹ́ yìí, wọ́n gbọ́dọ̀ fa ẹ̀mí ìgbéraga àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu lọ́kàn wọn. Kí Jésù lè múra wọn sílẹ̀ láti wàásù fún onírúurú èèyàn, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń sọ ohun tó dáa nípa àwọn tí kì í ṣe Júù. Bí àpẹẹrẹ, ó yin ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan tí kì í ṣe Júù torí pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ tayọ. (Mát. 8:​5-10) Ní Násárétì ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, Jésù ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe fi ojúure hàn sí àwọn tí kì í ṣe Júù bí opó Sáréfátì tó jẹ́ ará Foníṣíà àti Náámánì ará Síríà tó jẹ́ adẹ́tẹ̀. (Lúùkù 4:25-27) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù wàásù fún obìnrin kan tó jẹ́ ará Samáríà, ó sì tún lo ọjọ́ méjì ní ìlú Samáríà nígbà tó rí i pé àwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ òun.​—Jòh. 4:21-24, 40.

BÍ WỌ́N ṢE BORÍ Ẹ̀TANÚ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KÌÍNÍ

12, 13. (a) Báwo ló ṣe rí lára àwọn àpọ́sítélì nígbà tí Jésù ń wàásù fún obìnrin ará Samáríà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jákọ́bù àti Jòhánù ò tètè lóye ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wọn?

12 Kò rọrùn fáwọn àpọ́sítélì Jésù láti fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu lọ́kàn wọn. Ó yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí wọ́n rí i pé Jésù  ń wàásù fún obìnrin kan tó jẹ́ ará Samáríà. (Jòh. 4:9, 27) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù kì í bá àwọn obìnrin sọ̀rọ̀ ní gbangba, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ èyí tó jẹ́ ará Samáríà tí ìgbésí ayé rẹ̀ ń kọni lóminú. Àwọn àpọ́sítélì tiẹ̀ tún ń bẹ Jésù pé kó jẹun. Àmọ́ ìdáhùn tí Jésù fún wọn jẹ́ kí wọ́n rí i pé ó ń gbádùn ọ̀rọ̀ tó ń bá obìnrin náà sọ débi pé kò ṣe tán àtijẹun. Iṣẹ́ ìwàásù dà bí oúnjẹ fún Jésù torí pé ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ kó ṣe nìyẹn, gbogbo èèyàn sì ni Jésù fẹ́ wàásù fún títí kan obìnrin ará Samáríà yẹn.​—Jòh. 4:31-34.

13 Jákọ́bù àti Jòhánù ò tètè lóye ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wọn yìí. Nígbà kan, Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rìnrìn-àjò gba Samáríà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá ibi tí wọ́n lè sùn mọ́jú. Àmọ́ àwọn ará Samáríà ò gbà wọ́n sílé. Èyí múnú bí Jákọ́bù àti Jòhánù, wọ́n wá sọ fún Jésù pé kó jẹ́ káwọn pe iná wá láti ọ̀run kó lè jẹ ìlú náà run. Àmọ́ Jésù bá wọn wí lọ́nà mímúná. (Lúùkù 9:51-56) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jákọ́bù àti Jòhánù ò ní sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ká sọ pé Gálílì tó jẹ́ ìlú wọn làwọn èèyàn ti kọ̀ láti gbà wọ́n sílé. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ẹ̀tanú tí wọ́n ní sáwọn ará Samáríà ló mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn ará Samáríà tẹ́tí sí àpọ́sítélì Jòhánù nígbà tó wàásù lágbègbè náà, ó sì ṣeé ṣe kójú tì í tó bá rántí ohun tó sọ pé kó ṣẹlẹ̀ sílùú wọn lọ́jọ́ kìíní àná.​—Ìṣe 8:14, 25.

14. Báwo làwọn àpọ́sítélì ṣe yanjú ìṣòro kan tó ṣeé ṣe kó jẹ mọ́ èdè?

14 Kò pẹ́ lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni ọ̀rọ̀ kan jẹyọ. Àwọn tó ń pín oúnjẹ fáwọn opó bẹ̀rẹ̀ sí í gbójú fo àwọn opó tó ń sọ èdè Gíríìkì. (Ìṣe 6:1) Ó lè jẹ́ pé èdè wọn tó yàtọ̀ ló fa ẹ̀tanú yìí. Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì tètè yanjú ọ̀rọ̀ náà, wọ́n yan àwọn ọkùnrin tó tóótun láti bójú tó bí wọ́n ṣe máa pín oúnjẹ. Ẹni tẹ̀mí làwọn tí wọ́n yàn, gbogbo wọn ló sì ń jẹ́ orúkọ Gíríìkì. Ó dájú pé èyí máa fi àwọn opó tí wọ́n gbójú fò náà lọ́kàn balẹ̀.

15. Báwo ni Pétérù ṣe kẹ́kọ̀ọ́ pé kò yẹ kóun máa ṣe ojúsàájú? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

15 Lọ́dún 36 Sànmánì Kristẹni, iṣẹ́ ìwàásù náà túbọ̀ gbòòrò sí i. Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn Júù nìkan ni àpọ́sítélì Pétérù máa ń bá ṣe wọléwọ̀de. Àmọ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ojúsàájú, Pétérù wàásù fún ọ̀gágun Róòmù kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù. (Ka Ìṣe 10:28, 34, 35.) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù ṣọ̀rẹ́, wọ́n sì jọ ń jẹun. Àmọ́ lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù nílùú Áńtíókù, kò sì bá wọn jẹun mọ́. (Gál. 2:11-14) Èyí mú kí Pọ́ọ̀lù bá Pétérù wí, Pétérù sì gba ìbáwí náà. Nígbà tí Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sàwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù ní Éṣíà Kékeré, ó sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.​—1 Pét. 1:1; 2:17.

16. Kí làwọn èèyàn sọ nípa àwọn Kristẹni ìgbàanì?

16 Ó dájú pé àwọn àpọ́sítélì kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù pé àwọn gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ “gbogbo onírúurú ènìyàn.” (Jòh. 12:32; 1 Tím. 4:10) Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fojú tó dáa wo àwọn míì bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pẹ́ kó tó mọ́ wọn lára. Gbogbo àwọn èèyàn nígbà yẹn gbà pé àwọn Kristẹni nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Tertullian ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì kọ̀wé nípa ohun táwọn kan sọ nípa àwọn Kristẹni. Ó ní: “Wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn . . . Kódà wọ́n ṣe tán láti kú fún ara wọn.” Àwọn Kristẹni yẹn gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀, èyí sì jẹ́ kí wọ́n máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n.​—Kól. 3:10, 11.

17. Báwo la ṣe lè fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu lọ́kàn wa? Sọ àpẹẹrẹ kan.

 17 Lónìí, ó lè pẹ́ díẹ̀ káwa náà tó lè fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu lọ́kàn wa. Arábìnrin kan láti ilẹ̀ Faransé sọ bó ṣe rí fún un, ó ní: “Jèhófà ti jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́, bí mi ò ṣe ní máa ṣe ojúsàájú àti bí màá ṣe máa fìfẹ́ hàn sí onírúurú èèyàn. Mò ń gbìyànjú láti borí ẹ̀tanú bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún mi. Ìdí nìyẹn tí mi ò fi dákẹ́ àdúrà lórí ọ̀rọ̀ yìí.” Arábìnrin míì láti orílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “Ó ṣòro díẹ̀ fún mi láti nífẹ̀ẹ́ ẹ̀yà kan. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń gbé èrò yìí kúrò lọ́kàn. Síbẹ̀ mo mọ̀ pé iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún mi láti ṣe. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí n wà lára ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan.” Ó yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa yẹ ara rẹ̀ wò dáadáa. Ṣé kì í ṣe pé ó yẹ ká fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu lọ́kàn wa bíi tàwọn arábìnrin méjì yìí?

ÌFẸ́ TÒÓTỌ́ MÁA Ń ṢẸ́GUN Ẹ̀TANÚ

18, 19. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn? (b) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

18 Ó yẹ ká máa rántí pé “àjèjì” ni gbogbo wa jẹ́ sí Ọlọ́run tẹ́lẹ̀. (Éfé. 2:12) Àmọ́ Jèhófà fà wá mọ́ra torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Hós. 11:4; Jòh. 6:44) Jésù náà sì tẹ́wọ́ gbà wá. Ṣe ló dà bí ìgbà tó ṣílẹ̀kùn fún wa ká lè di ara ìdílé Ọlọ́run. (Ka Róòmù 15:7.) Jésù fìfẹ́ tẹ́wọ́ gbà wá, kò sì tẹ́ńbẹ́lú wa láìka pé a jẹ́ aláìpé, torí náà kò yẹ káwa náà fojú tẹ́ńbẹ́lú ẹnikẹ́ni.

Ìfẹ́ so wá pọ̀ torí pé à ń jẹ́ kí ọgbọ́n tó wá láti òkè máa darí wa (Wo ìpínrọ̀ 19)

19 A mọ̀ pé ẹ̀tanú, rògbòdìyàn àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà á túbọ̀ máa pọ̀ sí i bí òpin ayé búburú yìí ṣe ń sún mọ́lé. (Gál. 5:19-21; 2 Tím. 3:13) Àmọ́ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń jẹ́ kí ọgbọ́n tó wá láti òkè máa darí wa, ọgbọ́n yìí máa ń jẹ́ ká wá àlàáfíà, ká má sì ṣe ojúsàájú. (Ják. 3:​17, 18) Inú wa máa ń dùn láti ní àwọn ọ̀rẹ́ láti ilẹ̀ míì, à ń kọ́ àṣà wọn kódà a tún máa ń kọ́ èdè wọn. Èyí ti jẹ́ kí àlàáfíà wa dà bí odò, kí òdodo wa sì dà bí ìgbì òkun.​—Aísá. 48:17, 18.

20. Kí ni ìfẹ́ tòótọ́ máa mú ká ṣe?

20 Arábìnrin tó wá láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ràn án lọ́wọ́. Ó ní: “Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ló mú kí n máa fojú tó dáa wo àwọn míì. Ẹ̀tanú tó ti jingíri sí mi lọ́kàn tẹ́lẹ̀ sì pòórá.” Arákùnrin tó wá láti Kánádà náà sọ pé: “Àìmọ̀kan ló ń jẹ́ kéèyàn máa ṣe ẹ̀tanú, àti pé ibi téèyàn ti wá kọ́ ló ń sọ irú ẹni téèyàn máa jẹ́.” Ó yani lẹ́nu pé arábìnrin tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ni arákùnrin náà fẹ́! Irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ tòótọ́ máa ń borí ẹ̀tanú àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Ìfẹ́ alọ́májàá yìí ló sì so gbogbo àwa Kristẹni tòótọ́ pọ̀.​—Kól. 3:14.