Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

Tí ìtọ́ni bá wá látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run, kí ló yẹ káwọn alábòójútó àyíká, àwọn alàgbà àtàwọn míì tó ń múpò iwájú ṣe?

Ó yẹ kí wọ́n tètè gbé ìgbésẹ̀. Wọ́n lè bi ara wọn pé: ‘Ṣé mo máa ń fún àwọn míì níṣìírí láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run bá fún wa? Ṣé mo máa ń tètè gba ìtọ́ni táwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú fún wa, ṣé mo sì máa ń tì wọ́n lẹ́yìn?’w16.11, ojú ìwé 11.

Ìgbà wo làwọn Kristẹni tòótọ́ lọ sígbèkùn Bábílónì Ńlá?

Kò pẹ́ lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì kú ni èyí ṣẹlẹ̀. Nígbà yẹn, àwọn kan tó ka ara wọn sí àwùjọ aṣáájú bẹ̀rẹ̀ sí í kóra jọ. Ṣọ́ọ̀ṣì àti ìjọba ń gbé ẹ̀sìn Kristẹni tó di apẹ̀yìndà lárugẹ, wọ́n sì ń gbìyànjú láti bo àwọn Kristẹnì tó dà bí àlìkámà mọ́lẹ̀. Àmọ́, ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ọdún 1914, àwon ẹni àmì òróró bẹ̀rẹ̀ sí í já ara wọn gbà lọ́wọ́ ìsìn èké.w16.11, ojú ìwé 23 sí 25.

Kí ló mú kí iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì tí Lefèvre d’Étaples ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀?

Láwọn ọdún 1520, Lefèvre túmọ̀ Bíbélì sí èdè Faransé kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lè rí i kà. Bó ṣe ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì lọ́nà tó yéni yékéyéké nípa lórí Martin Luther, William Tyndale àti John Calvin.wp16.6, ojú ìwé 10 sí 12.

Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín “gbígbé èrò inú ka ẹran ara” àti “gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí”? (Róòmù 8:6)

Àwọn tó ń gbé èrò inú wọn ka ẹran ara máa ń gbájú mọ́ bí wọ́n á ṣe tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, òun ni wọ́n sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, tí wọ́n sì fi ń ṣayọ̀. Àmọ́, ẹni tí ń gbé èrò inú rẹ̀ ka ẹ̀mí máa ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ darí èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe òun, ó sì máa ń ṣe ohun tó wu Jèhófà. Ikú ló máa ń gbẹ̀yìn àwọn tó bá gbé èrò wọn ka ẹran ara, àmọ́ àwọn tó bá gbé èrò wọn ka ẹ̀mí máa ní ìyè àti àlàáfíà.w16.12, ojú ìwé 15 sí 17.

Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe láti dín àníyàn kù?

Mọ àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù, má ṣe ohun tó kọjá agbára rẹ, ya àkókò sọ́tọ̀ lójoojúmọ́ tí wàá fi máa sinmi, máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, jẹ́ kí inú rẹ máa dùn, máa ṣe eré ìmárale déédéé kó o sì máa sùn dáadáa.w16.12, ojú ìwé 22 sí 23.

Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì sọ pé, “A ṣí Énọ́kù nípò padà láti má ṣe rí ikú”? (Héb. 11:5)

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà rọra mú kí Énọ́kù sùn kó sì gba ibẹ̀ kú láìjẹ kó mọ̀ pé òun ti fẹ́ kú.wp17.1, ojú ìwé 12 àti 13.

Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà?

Ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà tàbí tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan lòun lè ṣe, kì í sì í kọjá àyè rẹ̀. Ó yẹ ká máa ro tàwọn míì mọ́ tiwa, ká má sì máa ka ara wa sí bàbàrà.w17.01, ojú ìwé 18.

Kí ló fi hàn pé Ọlọ́run ló darí ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní bó ṣe ń darí Ìgbìmọ̀ Olùdarí lónìí?

Ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ kí wọ́n lóye Ìwé Mímọ́. Àwọn áńgẹ́lì ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n sì fi ń tọ́ àwọn ará sọ́nà. Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí náà nìyẹn.w17.02, ojú ìwé 26 sí 28.

Àwọn nǹkan wo ló mú ká gbà pé ẹ̀bùn iyebíye ni ìràpadà jẹ́?

Nǹkan mẹ́rin ni: Ìkíní, ẹni tó fún wa lẹ́bùn náà. Èkejì, ìdí tó fi fún wa. Ẹ̀kẹta, ohun tó yọ̀ǹda kó lè fún wa lẹ́bùn náà àti ìkẹrin, bí ẹ̀bùn náà ṣe bọ́ sí àkókò tá a nílò rẹ̀. Ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn kókó mẹ́rin yìí.wp17.2, ojú ìwé 4 sí 6.

Ṣé Kristẹni kan lè yí ìpinnu tó ti ṣe pa dà?

Ó yẹ kí bẹ́ẹ̀ ni wa túmọ̀ sí bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ nígbà míì, ó lè gba pé ká yí ìpinnu kan tá a ti ṣe pa dà. Nígbà táwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà, Ọlọ́run yí ìpinnu tó ṣe nípa wọn pa dà. Nígbà míì, a lè yí ìpinnu kan pa dà torí pé a rí àwọn ìsọfúnni tuntun gbà tàbí torí ipò nǹkan tó yí pa dà.w17.03, ojú ìwé 16 àti 17.

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣòfófó?

Tá a bá ń ṣòfófó tàbí tá à ń tan ọ̀rọ̀ kan kálẹ̀, ṣe la máa dá kún ìṣòro tó wà nílẹ̀. Yálà wọ́n hùwà àìdáa sí wa tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, tá a bá ń sọ̀rọ̀ náà kiri, ìyẹn ò ní yanjú ìṣòro náà.w17.04, ojú ìwé 21.