Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  June 2017

Jèhófà Ń Tù Wá Nínú Nínú Gbogbo Ìpọ́njú Wa

Jèhófà Ń Tù Wá Nínú Nínú Gbogbo Ìpọ́njú Wa

“Ọlọ́run ìtùnú gbogbo . . . ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”2 KỌ́R. 1:3, 4.

ORIN: 38, 56

1, 2. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń tù wá nínú nígbà ìpọ́njú, ìdánilójú wo sì ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wa?

Ọ̀DỌ́KÙNRIN kan tí kò tíì ṣègbéyàwó lọ bá alàgbà kan tó ti ṣègbéyàwó. Ó ṣe díẹ̀ tí ọ̀dọ́kùnrin náà ti ń ronú lórí ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:28 tó sọ pé: “Àwọn tí wọ́n [ṣègbéyàwó] yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” Ọ̀dọ́kùnrin náà wá bi alàgbà yẹn pé: “Kí ni ‘ìpọ́njú’ tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ, báwo sì ni màá ṣe kojú rẹ̀ tí n bá gbéyàwó?” Kí alàgbà náà tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ó sọ fún ọ̀dọ́kùnrin náà pé kó ronú lórí ọ̀rọ̀ kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, pé Jèhófà ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”2 Kọ́r. 1:3, 4.

2 Bàbá onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó sì máa ń tù wá nínú tá a bá níṣòro. Ìwọ náà lè rántí àwọn ìgbà tí Jèhófà ti ràn ẹ́ lọ́wọ́, tó sì tọ́ ẹ sọ́nà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó dá wa lójú pé ire wa ni Jèhófà ń fẹ́ bó ṣe fẹ́ ire fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà àtijọ́.Ka Jeremáyà 29:11, 12.

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?

 3 Kò sí àní-àní pé tá a bá mọ ohun tó ń fa ìṣòro kan, ìyẹn á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè kojú ìṣòro náà. Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn tó bá kan ìṣòro táwọn tó ṣègbéyàwó máa ń ní tàbí ìṣòro tó máa ń yọjú nínú ìdílé. Kí wá làwọn nǹkan tó máa ń fa ‘ìpọ́njú nínú ẹran ara’ tí Pọ́ọ̀lù sọ? Àwọn àpẹẹrẹ ìgbà àtijọ́ àti tòde òní wo ló lè tù wá nínú? Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè kojú àwọn ìṣòro náà.

‘ÌPỌ́NJÚ NÍNÚ ẸRAN ARA’

4, 5. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó máa ń fa ‘ìpọ́njú nínú ẹran ara’?

4 Nígbà tí Jèhófà ń so tọkọtaya àkọ́kọ́ pọ̀, ó sọ pé: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’ (Jẹ́n. 2:24) Àmọ́ torí àìpé ẹ̀dá, kì í rọrùn fẹ́nì kan láti fi àwọn òbí sílẹ̀ kó lè ní ìdílé tiẹ̀. (Róòmù 3:23) Tí obìnrin kan bá ti lọ́kọ, kò ní sí lábẹ́ ìdarí àwọn òbí rẹ̀ mọ́, ọkọ rẹ̀ láá bẹ̀rẹ̀ sí í darí rẹ̀. Ọlọ́run ló sọ pé kí ọkọ jẹ́ orí aya. (1 Kọ́r. 11:3) Èyí kì í sábà rọrùn fáwọn tọkọtaya kan. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé aya gbọ́dọ̀ gbà pé ọkọ òun láá máa darí òun kì í tún ṣe àwọn òbí òun mọ́. Èyí lè fa àwọn ìṣòro kan láàárín tọkọtaya àtàwọn mọ̀lẹ́bí, ó sì lè fa àìgbọ́ra-ẹni-yé láàárín tọkọtaya náà.

5 Látìgbà tí ìyàwó kan bá ti sọ fún ọkọ rẹ̀ pé òun ti lóyún ni àwọn méjèèjì á ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn ayọ̀ lèyí, síbẹ̀ wọ́n lè máa ṣàníyàn nípa ìlera obìnrin náà nígbà tó wà nínú oyún àti lẹ́yìn tó bá bímọ. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tí wọ́n ń náwó lé á máa pọ̀ sí i bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Wọ́n á tún ṣe ọ̀pọ̀ àyípadà lẹ́yìn tí wọ́n bá bímọ. Bí àpẹẹrẹ, bí ìyá náà ṣe máa tọ́jú ọmọ rẹ̀ ló máa gbà á lọ́kàn, ó sì lè má fi bẹ́ẹ̀ rí tọkọ rẹ̀ rò mọ́. Èyí lè mú káwọn ọkọ kan máa ronú pé ìyàwó àwọn ti pa àwọn tì. Yàtọ̀ síyẹn, bùkátà ọkùnrin náà tún ti pọ̀ sí i. Ní báyìí tọ́mọ ti wà láàárín wọn, ó gbọ́dọ̀ wá bó ṣe máa tọ́jú rẹ̀, kó sì pèsè fún un.

6-8. Báwo ni àìrọ́mọbí ṣe lè fa ìṣòro nínú ìdílé?

6 Ìṣòro kan tún wà táwọn tọkọtaya míì máa ń ní. Wọ́n lè máa wá ọmọ lójú méjèèjì, síbẹ̀ kí wọ́n má rọ́mọ bí. Tí obìnrin kan ò bá rọ́mọ bí, ó lè ní ẹ̀dùn ọkàn. Ti pé ẹnì kan ṣègbéyàwó, ó sì rọ́mọ bí kò ní kó má ṣàníyàn, síbẹ̀ ‘ìpọ́njú nínú ẹran ara’ náà ni àìrọ́mọbí jẹ́. (Òwe 13:12) Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ohun ìtìjú àti ìbànújẹ́ ló máa ń jẹ́ fún obìnrin tí kò rọ́mọ bí. Bí àpẹẹrẹ, inú Rákélì ìyàwó Jékọ́bù kò dùn bó ṣe ń rí i tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń bímọ lémọ. (Jẹ́n. 30:1, 2) Lónìí, wọ́n sábà máa ń bi àwọn míṣọ́nnárì tó ń sìn nílẹ̀ táwọn èèyàn ti ń bímọ rẹpẹtẹ pé kí nìdí tí wọn ò fi bímọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míṣọ́nnárì náà máa ń fọgbọ́n dá wọn lóhùn, síbẹ̀ àwọn èèyàn ṣì máa ń sọ fún wọn pé, “Ọlọ́run á pèsè ọmọ fún yín o.”

7 Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè England ń wá ọmọ lójú méjèèjì, àmọ́ kò rọ́mọ bí títí tó fi dàgbà kọjá ẹni tó lè bímọ. Arábìnrin náà sọ pé ìbànújẹ́ dorí òun kodò torí òun mọ̀ pé ó di inú ayé tuntun kóun tó lè bímọ. Òun àtọkọ rẹ̀ wá pinnu láti gba ọmọ kan tọ́. Síbẹ̀  arábìnrin náà sọ pé: “Mo ṣì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí mo mọ̀ pé ọmọ téèyàn gbà tọ́ yàtọ̀ sọ́mọ ẹni.”

8 Bíbélì sọ pé “a ó pa [obìnrin kan] mọ́ láìséwu nípasẹ̀ ọmọ bíbí.” (1 Tím. 2:15) Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé tí ẹnì kan bá bímọ, ó máa rí ìyè àìnípẹ̀kun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé tí obìnrin kan bá ní ọmọ tó ń tọ́jú, tó sì tún ń tọ́jú ilé, kò ní ráyè òfófó, kò sì ní máa tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀. (1 Tím. 5:13) Síbẹ̀, ó ṣì máa ní àwọn ìṣòro tó wọ́pọ̀ nínú ìdílé.

Báwo lẹnì kan tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú ṣe lè fara dà á? (Wo ìpínrọ̀ 9 àti 12)

9. Ọ̀nà wo ni ikú ọkọ tàbí aya gbà jẹ́ àdánù ńlá?

9 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó wà nínú ìgbéyàwó, ìṣòro kan wà tí kì í sábà wá síni lọ́kàn, ìyẹn kéèyàn pàdánù ọkọ tàbí aya rẹ̀. Àdánù ńlá ni ikú ọkọ tàbí aya jẹ́, èyí sì ti fa ìṣòro tó lé kenkà fún ọ̀pọ̀. Àwọn tí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí kì í ronú pé ó lè ṣẹlẹ̀ sáwọn láé. Àmọ́ a dúpẹ́ pé a nírètí àjíǹde bí Jésù ti ṣèlérí. (Jòh. 5:28, 29) Kí ni ìrètí yìí lè ṣe fún ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú? Ó máa tù ú nínú, á sì fi í lọ́kàn balẹ̀. Ọ̀nà kan rèé tí Jèhófà Baba wa ń gbà fi Bíbélì tù wá nínú nígbà ìṣòro. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ṣe jàǹfààní látinú ìtùnú tí Jèhófà ń fúnni.

ÌTÙNÚ NÍGBÀ ÌṢÒRO

10. Báwo ni Hánà ṣe rí ìtùnú nígbà ìṣòro? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

10 Hánà ìyàwó Ẹlikénà ní ìṣòro kan. Kò rọ́mọ bí àmọ́ Pẹ̀nínà orogún rẹ̀ ń bímọ lémọ. (Ka 1 Sámúẹ́lì 1:4-7.) Gbogbo ìgbà ni Pẹ̀nínà máa ń fojú pọ́n ọn, èyí sì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ bá Hánà. Kó lè rí ìtùnú, ó gbàdúrà sí Jèhófà. Bíbélì sọ pé, “ó gbàdúrà [fún àkókò gígùn] níwájú Jèhófà.” Ṣé ó dá a lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà rẹ̀? Ó ṣeé ṣe, torí pé lẹ́yìn tó gbàdúrà tán, ‘ìdàníyàn fún ara ẹni kò hàn lójú rẹ̀ mọ́.’ (1 Sám. 1:12, 17, 18) Ó dá a lójú pé Jèhófà máa jẹ́ kóun rọ́mọ bí tàbí pé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà òun lọ́nà míì.

11. Báwo ni àdúrà ṣe lè tù wá nínú?

11 A ò lè sá fún ìṣòro torí a jẹ́ aláìpé àti pé inú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso la wà. (1 Jòh. 5:19) Àmọ́ inú wa dùn pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” Ọ̀nà kan tá a lè gbà rí ìrànwọ́ nígbà ìṣòro ni pé ká gbàdúrà sí Jèhófà. Nígbà tí Hánà níṣòro, ó tú gbogbo ọkàn rẹ̀ jáde fún Jèhófà. Bákan náà, tá a bá ń kojú ìṣòro, kì í ṣe pé ká kàn sọ ìṣòro tá a ní fún Jèhófà, ṣe ló yẹ ká rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà, ká sọ gbogbo bó ṣe rí lára wa fún un, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn.Fílí. 4:6, 7.

12. Kí ló jẹ́ kí opó kan tó ń jẹ́ Ánà láyọ̀?

12 Tá a bá tiẹ̀ ń kojú ìṣòro tó le, bóyá ìṣòro àìrọ́mọbí tàbí ikú ẹnì kejì wa, a ṣì lè rí ìtùnú. Lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wòlíì obìnrin kan tó ń jẹ́ Ánà tó ti pàdánù ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ọdún méje péré tí wọ́n ṣègbéyàwó. Bíbélì ò sọ bóyá ó bímọ tàbí kò bímọ. Àmọ́ kí ni Ánà ń ṣe títí tó fi pé ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84]? Lúùkù 2:37 sọ pé: ‘Kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ, ó sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ lóru àti lọ́sàn-án pẹ̀lú ààwẹ̀ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.’ Ó ṣe kedere pé Ánà ń láyọ̀ bó ṣe ń fòótọ́ inú sin Jèhófà, ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀.

13. Sọ àpẹẹrẹ bí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ ṣe lè tù wá nínú táwọn ìbátan wa ò bá tiẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.

13 Tá a bá ń bá àwọn ará wa kẹ́gbẹ́,  a máa rí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó máa dúró tì wá nígbà ìṣòro. (Òwe 18:24) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Paula sọ pé inú òun bà jẹ́ nígbà tóun wà lọ́mọ ọdún márùn-ún torí pé màmá òun fi Jèhófà sílẹ̀. Kò rọrùn fún un láti gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Àmọ́ Arábìnrin Ann tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níjọ wọn fà á mọ́ra, ó ràn án lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, èyí sì fi Paula lọ́kàn balẹ̀. Paula wá sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi àti Ann kò bára wa tan, síbẹ̀ bó ṣe fà mí mọ́ra tù mí nínú gan-an. Ohun tó jẹ́ kí n máa sin Jèhófà nìṣó nìyẹn.” Paula ṣì ń fòótọ́ sin Jèhófà nìṣó. Bákan náà, inú rẹ̀ dùn gan-an pé màmá rẹ̀ ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Inú Arábìnrin Ann náà dùn torí pé ó mú Paula bí ọmọ.

14. Ìbùkún wo làwọn tó ń tu àwọn míì nínú máa ń rí?

14 Òótọ́ kan ni pé, tá a bá ń ronú nípa bá a ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́, ó lè mú ká gbọ́kàn kúrò lórí ẹ̀dùn ọkàn wa. Àwọn arábìnrin tó ti ṣègbéyàwó àtàwọn tí kò tíì ṣe bẹ́ẹ̀ máa ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere, tí wọ́n sì ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́. Bí wọ́n á ṣe bọlá fún Jèhófà tí wọ́n á sì ṣèfẹ́ rẹ̀ ló jẹ wọ́n lọ́kàn. Àwọn kan tiẹ̀ gbà pé iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ káwọn gbọ́kàn kúrò lórí ìṣòro àwọn, ó sì máa ń fún àwọn ní ìtùnú. Ká sòótọ́, gbogbo wa  la máa pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ, tá a bá jẹ́ kí ire àwọn ará àti tàwọn tá à ń wàásù fún jẹ wá lọ́kàn. (Fílí. 2:4) Àpẹẹrẹ àtàtà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ nínú èyí. Ó fi ara rẹ̀ wé “abiyamọ” torí pé ó máa ń ṣìkẹ́ àwọn ará ìjọ Tẹsalóníkà, ó sì tún dà bíi bàbá fún wọn.Ka 1 Tẹsalóníkà 2:7, 11, 12.

BÍ ÌDÍLÉ ṢE LÈ RÍ ÌTÙNÚ

15. Ta ni Jèhófà sọ pé kó máa kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́?

15 Apá míì tó tún yẹ ká fún láfiyèsí ni ìtùnú tá a lè pèsè fáwọn tó ní ìdílé. Nígbà míì, àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ máa ń sọ fáwọn tó dàgbà dénú nínú ìjọ pé kí wọ́n bá ọmọ àwọn kẹ́kọ̀ọ́. Ká sòótọ́, àwọn òbí ni Bíbélì ní kó máa kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́. (Òwe 23:22; Éfé. 6:1-4) Àmọ́ nígbà míì, àwọn òbí lè nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn míì nínú ìjọ. Síbẹ̀, ìyẹn ò ní káwọn òbí náà pa ojúṣe wọn tì. Ó ṣe pàtàkì pé káwọn òbí máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ déédéé.

16. Tá a bá fẹ́ ran àwọn ọmọ lọ́wọ́, kí ló yẹ ká fi sọ́kàn?

16 Tí òbí kan bá sọ pé kẹ́nì kan máa kọ́ ọmọ òun lẹ́kọ̀ọ́, kò yẹ kẹ́ni náà gba ojúṣe òbí náà ṣe. Àwọn ìgbà míì wà tí wọ́n lè sọ fún Ẹlẹ́rìí kan pé kó máa kọ́ ọmọ táwọn òbí rẹ̀ kò sí nínú ètò lẹ́kọ̀ọ́. Síbẹ̀ ó yẹ kí Ẹlẹ́rìí náà fi sọ́kàn pé òun fẹ́ kọ́ ọmọ náà lẹ́kọ̀ọ́ ni, kì í ṣe pé òun fẹ́ di òbí ọmọ náà. Tí wọ́n bá sì ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, ohun tó dáa jù ni pé kí wọ́n ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nílé àwọn ọmọ náà, kó sì jẹ́ níṣojú àwọn òbí rẹ̀ tàbí níṣojú Ẹlẹ́rìí míì tó dàgbà dénú, wọ́n sì lè ṣe é ní gbangba níbi táwọn èèyàn wà. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn míì ò ní máa ro èròkérò nípa ohun tí wọ́n ń ṣe. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn òbí náà lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kí wọ́n sì bójú tó ojúṣe tí Ọlọ́run fún wọn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

17. Báwo làwọn ọmọ ṣe lè jẹ́ orísun ìtùnú?

17 Táwọn ọmọ bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, wọ́n lè di orísun ìtùnú fáwọn tó wà nínú ìdílé wọn. Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn, tí wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ fún wọn. Wọ́n tún lè jẹ́ orísun ìtùnú tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ṣáájú Ìkún Omi, Lámékì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Sẹ́ẹ̀tì sin Jèhófà. Lámékì sọ nípa Nóà ọmọ rẹ̀ pé: “Yóò mú ìtùnú wá fún wa nínú iṣẹ́ wa àti nínú ìrora ọwọ́ wa tí ó jẹ́ àbáyọrí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà tí Jèhófà mú ègún tó gé fún ilẹ̀ kúrò. (Jẹ́n. 5:29; 8:21) Lónìí, àwọn ọmọ tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà máa ń jẹ́ orísun ìtùnú fáwọn tó wà nínú ìdílé wọn, torí pé á mú kó rọrùn fún ìdílé náà láti fara da ìṣòro nísinsìnyí, kí wọ́n sì la ayé búburú yìí já lọ́jọ́ iwájú.

18. Kí ló máa jẹ́ ká lè fara dà á láìka ìṣòro yòówù ká kojú?

18 Ọ̀pọ̀ lónìí ló ń rí ìtùnú nínú gbogbo ìpọ́njú wọn torí pé wọ́n máa ń gbàdúrà, wọ́n máa ń ṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì, wọ́n sì máa ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn Jèhófà. (Ka Sáàmù 145:18, 19.) Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ni Orísun ìtùnú máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro yòówù ká kojú nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.