DÁFÍDÌ ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń yin obìnrin kan tó pàdé nígbà kan. Ábígẹ́lì lorúkọ obìnrin náà. Kí ló mú kí Dáfídì yin obìnrin yìí, kí la sì lè kọ́ lára obìnrin náà?

Ìgbà tí Dáfídì ń sá kiri nítorí Ọba Sọ́ọ̀lù ló pàdé obìnrin yìí. Obìnrin náà ti lọ́kọ, Nábálì sì lorúkọ ọkọ rẹ̀. Nábálì lówó gan-an, ó sì ní ọ̀pọ̀ ẹran ọ̀sìn ní ilẹ̀ olókè tó wà ní gúúsù ilẹ̀ Júdà. Ìgbà kan wà tí Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dáàbò bo àwọn olùṣọ́ àgùntàn Nábálì àtàwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Nígbà tó yá, Dáfídì ránṣẹ́ sí Nábálì pé kó fún àwọn ní ‘ohunkóhun tó bá lè yọ̀ǹda,’ káwọn lè jẹ. (1 Sám. 25:8, 15, 16) Tá a bá wo ohun tí Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ti ṣe fún Nábálì, ó dájú pé ohun tí Dáfídì béèrè yìí kò pọ̀ jù.

Àmọ́ Nábálì tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Òpònú” tàbí “Arìndìn” hùwà bí òpònú lóòótọ́. Ṣe ló fìbínú sọ̀rọ̀ sáwọn tí Dáfídì rán wá, kò sì fún wọn ní nǹkan kan. Inú bí Dáfídì gan-an, ó sì pinnu pé òun máa fìyà jẹ Nábálì fún ìwà àìnírònú tó hù yẹn. Kódà, àti Nábálì àtàwọn aráalé ẹ̀ ló máa jẹ nínú ìyà náà.1 Sám. 25:2-13, 21, 22.

Ábígẹ́lì fòye mọ ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀, torí náà ó lo ìgboyà, ó sì gbé ìgbésẹ̀ ní kíá. Ó lọ pàdé Dáfídì, ó sì bẹ̀ ẹ́ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó ní kó ro ti àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà. Ó tún kó oúnjẹ rẹpẹtẹ dání fún Dáfídì tó jẹ́ ọba lọ́la àti fún àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Dáfídì gbà pé Jèhófà ló mú kí Ábígẹ́lì wá pàdé òun kóun má bàa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ó sọ fún Ábígẹ́lì pé: ‘Ìbùkún ni fún ìlóyenínú rẹ, ìbùkún sì ni fún ìwọ tí o ti dá mi dúró lónìí yìí kí n má bàa wọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.’1 Sám. 25:18, 19, 23-35.

Ó dájú pé kò sẹ́ni tó máa fẹ́ dà bíi Nábálì, tí kò lẹ́mìí ìmoore. Bákan náà, tá a bá kíyè sí i pé ohun tó máa gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ kan kò ní dáa, ó yẹ ká tètè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Àwa náà lè ṣe bíi ti onísáàmù tó bẹ Ọlọ́run pé: “Kọ́ mi ní ìwà rere, ìlóyenínú àti ìmọ̀ pàápàá.”Sm. 119:66.

Àwọn míì lè kíyè sí ọgbọ́n tá a fi yanjú ọ̀rọ̀ kan. Yálà wọ́n sọ ọ́ fún wa tàbí wọn ò sọ ọ́, ó lè máa ṣe wọ́n bíi ti Dáfídì tó sọ pé: ‘Ìbùkún ni fún ìlóyenínú rẹ!’