Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) June 2017

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti July 31 sí August 27, 2017 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣé o ti ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Jèhófà Ń Tù Wá Nínú Nínú Gbogbo Ìpọ́njú Wa

Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro táwa Kristẹni lè ní lẹ́yìn tá a bá ṣègbéyàwó tá a sì ní ìdílé? Tá a bá sì ń kojú àwọn ìṣòro yìí, báwo ni Ọlọ́run ṣe lè tù wá nínú?

Máa Fọkàn sí Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí

Àwọn ìṣúra wo ló yẹ ká mọyì, báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Ọkàn Àwọn Èèyàn Ló Ṣe Pàtàkì, Kì Í Ṣe Ìrísí Wọn

Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan fi sùúrù bá Ọkùnrin aláìrílégbé kan sọ̀rọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?

Ṣé Wàá Yanjú Èdèkòyédè Kí Àlàáfíà Lè Jọba

Àwọn ń wá àlàáfíà lójú méjèèjì. Àmọ́ tẹ́nì kan kò bá bọ̀wọ̀ fún wọn tàbí tó fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í bínú. Kí lá lè tá ò fi ní hùwà bẹ́ẹ̀?

‘Ìbùkún Ni fún Ìlóyenínú Rẹ’

Dáfídì ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń yin Ábígẹ́lì. Kí ló mú kí Dáfídì yìn ín, kí la sì lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Ábígẹ́lì?

Pọkàn Pọ̀ Sórí Ọ̀rọ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Jù

Ọ̀rọ̀ pàtàkì wo ló kan gbogbo èèyàn? Kí nìdí tó fi yẹ ká pọkàn pọ̀ sí i?

Fara Mọ́ Ìṣàkóso Jèhófà!

Àǹfààní wo ló máa ṣe ẹ́ tó o bá gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí Jésù fi pe àwọn oníṣòwò tó ń tajà nínú tẹ́ńpìlì ní “robbers”?