Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  June 2016

Jèhófà “Bìkítà fún Yín”

Jèhófà “Bìkítà fún Yín”

ṢÉ OHUN tá a sọ lókè yìí dá ẹ lójú, pé Jèhófà bìkítà fún ẹ àti pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an? Kí ló mú kó dá ẹ lójú? Ìdí kan ni pé Bíbélì ló sọ bẹ́ẹ̀. Ìwé 1 Pétérù 5:7 sọ pé: ‘Kó gbogbo àníyàn rẹ lé e, nítorí ó bìkítà fún ọ.’ Kí ló mú kó o gbà pé Jèhófà Ọlọ́run rí tìẹ rò àti pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ?

ỌLỌ́RUN Ń PÈSÈ ÀTIJẸ ÀTIMU FÚN ÀWA ÈÈYÀN

Jèhófà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, tó bá di pé ká lawọ́ ká sì máa ṣoore

Bá a ṣe fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ máa ṣe sí wa náà ni Ọlọ́run máa ń ṣe sí wa. Ẹni tó lawọ́, tó sì jẹ́ onínúure la máa fẹ́ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn wa. Bíwọ náà ṣe mọ̀, Jèhófà lawọ́ gan-an, ojoojúmọ́ ló sì máa ń ṣoore fún gbogbo èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: ‘Ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.’ (Mát. 5:45) Àǹfààní wo ni oòrùn àti òjò ń ṣe wá? Ọ̀pọ̀ àǹfààní là ń rí, ọ̀kan lára ẹ̀ ni pé Ọlọ́run ń lo oòrùn àti òjò láti mú káwa èèyàn máa rí oúnjẹ jẹ, kí inú wa sì máa dùn gan-an. (Ìṣe 14:17) Ó ṣe kedere pé Jèhófà ń rí sí i pé ilẹ̀ ayé ń mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ jáde. Ta ni kì í gbádùn oúnjẹ aládùn, ó ṣe tán, wọ́n máa ń sọ pé bí ebi bá ti tán nínú ìṣẹ́, ìṣẹ́ bù ṣe.

Kí wá nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi rí oúnjẹ jẹ? Ìdí ni pé, àwọn alákòóso ò rí tàwọn èèyàn rò, bí wọ́n á ṣe gba agbára kún agbára tí wọ́n á sì to ọrọ̀ jọ pelemọ ni wọ́n ń lé, kò sí èyí tó kàn wọ́n pẹ̀lú àwọn ará ìlú. Àmọ́, Jèhófà máa tó fòpin sí ìwà wọ̀bìà yẹn nígbà tó bá mú àwọn ìjọba ayé yìí kúrò, á sì fi Ìjọba tiẹ̀ rọ́pò wọn. Jésù Kristi ọmọ Ọlọ́run ló máa jẹ́ Ọba Ìjọba náà. Lákòókò yẹn, kò sẹ́ni tí kò ní rí oúnjẹ jẹ. Ní báyìí ná,  Ọlọ́run ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń fòótọ́ inú sìn ín. (Sm. 37:25) Ṣé a wá lè sọ pé kò nífẹ̀ẹ́ wa?

JÈHÓFÀ MÁA Ń RÁYÈ GBỌ́ TIWA

Jèhófà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, tó bá di pé ká máa ráyè gbọ́ tàwọn ẹlòmíì

Àwọn ọ̀rẹ́ tó mọwọ́ ara wọn máa ń wà pẹ̀lú ara wọn. Wọn kì í sábà kánjú tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ tó kan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Tí ọ̀kan bá ń ṣàlàyé ìṣòro tàbí ìdààmú ọkàn tó ní, èkejì máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ọ. Ṣé Jèhófà náà máa ń fara balẹ̀ gbọ́ tiwa? Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ dáadáa. Elétíi-gbáròyé ni, ó ń gbọ́ àdúrà wa. Abájọ tí Bíbélì fi rọ̀ wá pé ká “máa ní ìforítì nínú àdúrà,” ká sì “máa gbàdúrà láìdabọ̀.”Róòmù 12:12; 1 Tẹs. 5:17.

Ṣé Jèhófà máa ń ráyè gbọ́ tiwa tá a bá gbàdúrà sí i? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì láti dáhùn ìbéèrè yẹn. Kí Jésù tó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, Bíbélì sọ pé, ó ń “bá a lọ nínú àdúrà gbígbà sí Ọlọ́run ní gbogbo òru náà.” (Lúùkù 6:12) Nínú àdúrà yẹn, ó ṣeé ṣe kí Jésù dárúkọ púpọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kó sọ àwọn ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní àti ibi tí wọ́n kù sí, kó sì wá bẹ Baba rẹ̀ ọ̀run pé kó ran òun lọ́wọ́ láti mọ èyí tóun máa yàn ní àpọ́sítélì. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì fi máa mọ́, Jésù mọ̀ pé àwọn tí òun yàn yìí kúnjú ìwọ̀n dáadáa. Inú Jèhófà, “Olùgbọ́ àdúrà,” máa ń dùn láti gbọ́ àdúrà téèyàn gbà tọkàntọkàn. (Sm. 65:2) Kódà téèyàn bá tiẹ̀ ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí gbàdúrà nípa ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, Jèhófà máa ń ráyè gbọ́ onítọ̀hún, kì í kán an lójú.

ỌLỌ́RUN ṢE TÁN LÁTI DÁRÍ JÌ WÁ

Jèhófà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, tó bá di pé ká ṣe tán láti dárí jini

Lóòótọ́ àwọn èèyàn gbà pé ọ̀rẹ́ méjì lè ṣẹ ara wọn, àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn fún wọn láti dárí ji ara wọn tí wọ́n bá ṣẹ ara wọn. Nígbà míì, àwọn ọ̀rẹ́ tó ti ń bára wọn bọ̀ látọdúnmọ́dún máa ń tú ká torí pé wọn ò lè dárí ji ara wọn. Ṣé irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà? Rárá o. Bíbélì gba gbogbo àwọn tó ń fọkàn sin Ọlọ́run níyànjú pé kí wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí ji àwọn, “nítorí tí òun yóò dárí jì lọ́nà títóbi.” (Aísá. 55:6, 7) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi máa ń dárí jì wá?

Ìdí ni pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ìfẹ́ rẹ̀ kò sì láfiwé. Ìfẹ́ tó ní sáwa èèyàn jinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó fi rán Jésù,  Ọmọ rẹ̀ wá sáyé pé kó wá ra àwa èèyàn pa dà, kó sì dá wa nídè kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àtàwọn ìṣòro tí ẹ̀ṣẹ̀ kó àwa èèyàn sí. (Jòh. 3:16) Àǹfààní tí ìràpadà yẹn mú wá kò mọ síbẹ̀ o. Ẹbọ ìràpadà yìí ló mú kí Ọlọ́run máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ jì wọ́n. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Bí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, òun jẹ́ aṣeégbíyèlé àti olódodo tí yóò fi dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.” (1 Jòh. 1:9) Torí pé Jèhófà ń dárí jì wá, ó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá a ṣọ̀rẹ́. Ó sì dájú pé inú wa máa ń dùn pé Jèhófà ń dárí jì wá fàlàlà.

Ó Ń DÚRÓ TÌ WÁ NÍGBÀ ÌṢÒRO

Jèhófà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, tó bá di pé ká dúró tini nígbà ìṣòro

Àwọn èèyàn máa ń sọ pé ìgbà ìpọ́njú là ń mọ̀rẹ́. Ṣé Jèhófà náà máa ń dúró tini nígbà ìpọ́njú? Bíbélì sọ pé: “Bí [ìránṣẹ́ Ọlọ́run] tilẹ̀ ṣubú, a kì yóò fi í sọ̀kò sísàlẹ̀, nítorí pé Jèhófà ń ti ọwọ́ rẹ̀ lẹ́yìn.” (Sm. 37:24) Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà gbà ń ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn. Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní erékùṣù St. Croix tó wà lójú agbami Caribbean.

Àwọn ọmọ kíláàsì ọ̀dọ́bìnrin kan ń fòòró ẹ̀mí ẹ̀ torí pé kò kí àsíá. Ohun tó gbà gbọ́ ló sì mú kó pinnu pé òun ò ní kí àsíá. Ọ̀dọ́bìnrin náà gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, lẹ́yìn náà ó pinnu pé òun á bá wọn sọ̀rọ̀. Nígbà tó yá, ó ṣàlàyé ọ̀rọ̀ àsíá fáwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Ìwé Ìtàn Bíbélì ni ọ̀dọ́bìnrin náà lò, ó sọ nípa bí ohun tí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ṣe nígbà yẹn lọ́hùn-ún ṣe kan òun. Ó wá sọ pé: “Jèhófà dá ẹ̀mí àwọn Hébérù mẹ́ta yẹn sí torí pé wọn ò jọ́sìn ère.” Lẹ́yìn tó ṣàlàyé tán, ó fún àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ ní ìwé náà. Ǹjẹ́ ẹ mọye àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ tó fẹ́ ìwé náà? Mọ́kànlá! Inú ọ̀dọ́bìnrin yìí dùn gan-an. Kí nìdí? Ó gbà pé Jèhófà ló mú kí òun nígboyà àti ọgbọ́n tí òun fi bójú tó ọ̀rọ̀ yẹn.

Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé bóyá ni Jèhófà tiẹ̀ bìkítà fún ẹ tàbí pé bóyá ló nífẹ̀ẹ́ rẹ, ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Sáàmù 34:17-19; 55:22; àti 145:18, 19. Sún mọ́ àwọn tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́tipẹ́, kó o ní kí wọ́n sọ bí Jèhófà ṣe ń bójú tó wọn látọdún yìí wá. Gbàdúrà sí Jèhófà nígbàkigbà tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Wàá rí i pé lóòótọ́ ni Jèhófà ‘bìkítà fún ọ.’