Ṣé ó yẹ kí Kristẹni kan ní ìbọn torí kó lè dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olubi?

Lóòótọ́ Kristẹni kan lè dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú, síbẹ̀ kò gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó tako ìlànà Bíbélì. Àwọn ìlànà Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé kò yẹ káwa Kristẹni máa lo àwọn ohun ìjà tó lè gbẹ̀mí èèyàn irú bí ìbọn, ì báà jẹ́ ìbọn ìléwọ́ tàbí oríṣi ìbọn míì. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀:

Ẹ̀mí ṣeyebíye lójú Jèhófà, pàápàá jù lọ, ẹ̀mí èèyàn. Onísáàmù náà Dáfídì sọ pé Jèhófà “ni orísun ìyè.” (Sm. 36:9) Torí náà, tí Kristẹni kan bá fẹ́ dáàbò bo ara rẹ̀ tàbí àwọn ohun ìní rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun ò gbẹ̀mí èèyàn, torí pé tí ẹ̀mí èèyàn bá ti ọwọ́ rẹ̀ bọ́, ó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nìyẹn.​—Diu. 22:8; Sm. 51:14.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun ìjà tó lè gbẹ̀mí èèyàn wà lóríṣiríṣi, síbẹ̀ ìbọn máa ń jẹ́ kó rọrùn láti pààyàn yálà ẹni náà mọ̀ọ́mọ̀ tàbí kò mọ̀ọ́mọ̀. * Yàtọ̀ síyẹn, tí olubi kan bá rí ìbọn lọ́wọ́ ẹni tó wá ṣe níbi, ó ṣeé ṣe kó wá bó ṣe máa gbèjà ara rẹ̀, ìyẹn sì lè mú kẹ́nì kan gba ẹ̀mí ẹnì kejì.

Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n mú idà dání, àmọ́ kì í ṣe torí kí wọ́n lè fi dáàbò bo ara wọn. (Lúùkù 22:​36, 38) Ìdí tí Jésù fi ní kí wọ́n mú idà dání ni pé ó fẹ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ẹ̀kọ́ náà sì ni pé wọn gbọ́dọ̀ jà kódà táwọn jàǹdùkú bá dojú kọ wọ́n. (Lúùkù 22:52) Lẹ́yìn tí Pétérù fi  idà gé etí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ àlùfáà àgbà, Jésù pàṣẹ fún un pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, Jésù fún wọn ní ìlànà kan táwa Kristẹni ń tẹ̀ lé títí dòní, ó sọ pé: “Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.”​—Mát. 26:​51, 52.

Bó ṣe wà nínú Míkà 4:​3, àwa èèyàn Ọlọ́run ti ‘fi idà wa rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, a sì ti fi ọ̀kọ̀ wa rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.’ Torí pé àwa Kristẹni ń ṣe ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, ó bá ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ mu pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:​17, 18) Ọ̀pọ̀ ewu ni Pọ́ọ̀lù dojú kọ, kódà ó kojú àwọn “dánàdánà,” síbẹ̀ kò fìgbà kan ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Bíbélì torí pé ó fẹ́ dáàbò bo ara rẹ̀. (2 Kọ́r. 11:26) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ó sì fi ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, ìyẹn ọgbọ́n tó “sàn ju àwọn ohun èlò ìjà.”​—Oníw. 9:18.

Àwa Kristẹni mọ̀ pé ẹ̀mí ṣe pàtàkì ju ohun ìní tara lọ. Bíbélì sọ pé, ‘Ìwàláàyè kò wá láti inú àwọn ohun téèyàn ní.’ (Lúùkù 12:15) Torí náà, tí Kristẹni kan bá fi pẹ̀lẹ́tù bá adigunjalè kan sọ̀rọ̀ àmọ́ tí kò gbà, kí Kristẹni náà fi ìmọ̀ràn tí Jésù fún wa sílò, tó sọ pé: “Má ṣe dúró tiiri lòdì sí ẹni burúkú.” Ó tiẹ̀ lè gba pé ká yọ̀ǹda ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti ti àwọ̀lékè wa fún onítọ̀hún, ìyẹn ni pé ká yọ̀ǹda ohun tẹ́ni náà fẹ́ gbà lọ́wọ́ wa. (Mát. 5:​39, 40; Lúùkù 6:29) * Ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà dáàbò bo ara wa ni pé ká má tiẹ̀ ṣe ohun tó máa mú káwọn adigunjalè dájú sọ wá. Tí a kì í bá fi àwọn “àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé [wa] hàn sóde lọ́nà ṣekárími,” táwọn aládùúgbò sì mọ̀ pé jẹ́jẹ́ wa la máa ń lọ, ó ṣeé ṣe káwọn adigunjalè tàbí àwọn ìpáǹle míì má fojú sí wa lára.​—1 Jòh. 2:16; Òwe 18:10.

Àwa Kristẹni kì í ṣe ohun tó máa da ẹ̀rí ọkàn àwọn míì láàmú. (Róòmù 14:21) Táwọn ará bá mọ̀ pé ẹnì kan nínú ìjọ ní ìbọn tó fi ń dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olubi, ó lè ṣe wọ́n bákan, kódà ó lè mú káwọn míì kọsẹ̀. Ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará máa mú ká gba tiwọn rò, ká sì fi ire wọn ṣáájú tiwa, kódà ó lè gba pé ká yááfì ohun tí òfin gbà wá láyè láti ní.​—1 Kọ́r. 10:​32, 33; 13:​4, 5.

Àwa Kristẹni máa ń sapá láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere. (2 Kọ́r. 4:2; 1 Pét. 5:​2, 3) Tí Kristẹni kan bá ní ìbọn tó fi ń dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olubi, àwọn alàgbà máa lo Ìwé Mímọ́ láti gbà á nímọ̀ràn. Àmọ́ tí kò bá gba ìmọ̀ràn náà, a ò ní ka ẹni bẹ́ẹ̀ sí àpẹẹrẹ rere nínú ìjọ, kò sì ní láǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni tó bá ń ṣiṣẹ́ tó gba pé kó máa gbébọn. Ẹ ò rí i pé ó sàn kírú ẹni bẹ́ẹ̀ wáṣẹ́ míì ṣe! *

Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bó ṣe máa dáàbò bo ara rẹ̀, ìdílé rẹ̀ àtàwọn ohun ìní rẹ̀, òun náà ló sì máa pinnu irú iṣẹ́ tó máa ṣe. Àmọ́ o, ká rántí pé àwọn ìlànà Bíbélì fi ọgbọ́n Jèhófà hàn, ó sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn mọyì àwọn ìlànà yẹn, èyí sì mú kí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní ní ìbọn torí káwọn lè dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn olubi. Wọ́n gbà pé táwọn bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, táwọn sì ń fi ìlànà Bíbélì sílò, àwọn á wà lábẹ́ ààbò Ọlọ́run títí láé.​—Sm. 97:10; Òwe 1:33; 2:​6, 7.

Nígbà ìpọ́njú ńlá, Jèhófà ni àwọn Kristẹni máa gbẹ́kẹ̀ lé wọn ò ní gbèjà ara wọn

^ ìpínrọ̀ 3 Kristẹni kan lè pinnu pé òun nílò ìbọn tóun á fi máa ṣọdẹ tàbí tóun lè fi dáàbò bo ara òun lọ́wọ́ àwọn ẹranko ẹhànnà. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, láwọn ìgbà tí kò bá lo ìbọn náà, ó yẹ kó yọ ọta kúrò nínú rẹ̀ tàbí kó tiẹ̀ tú ìbọn náà palẹ̀, kó sì tọ́jú rẹ̀ síbi tọ́wọ́ àwọn míì kò ti ní tó o. Láwọn ìlú tí ìjọba kò ti fọwọ́ sí i pé kéèyàn ní ìbọn tàbí tí wọ́n ṣòfin nípa bí wọ́n á ṣe lò ó, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ pa òfin ìjọba mọ́.​—Róòmù 13:1.

^ ìpínrọ̀ 2 Láti mọ ohun tó o lè ṣe tẹ́nì kan bá fẹ́ fipá bá ẹ lòpọ̀, wo àpilẹ̀kọ náà “Bi A Ṣe Lè Dènà Ifipa-bobinrin-Lopọ” nínú Jí! March 8, 1993.

^ ìpínrọ̀ 4 Tó o bá fẹ́ àlàyé púpọ̀ sí i nípa bóyá Kristẹni kan lè ṣe iṣẹ́ tó gba pé kéèyàn gbébọn, wo àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2005, ojú ìwé 31; àti January 15, 1984, ojú ìwé 17 àti 18.