KÍYÈ sára, ẹ̀mí rẹ wà nínú ewu! Sátánì ọ̀tá rẹ ń dọdẹ rẹ, ohun tó sì fi ń gbéjà kò ẹ́ burú gan-an. Kí ni ohun náà? Ìpolongo ẹ̀tàn ni. Ohun tó ń lò yìí burú gan-an torí pé ó lè lò ó láti tàn ẹ́ jẹ tàbí kó sí ẹ lórí.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ìpolongo ẹ̀tàn tí Sátánì ń gbé jáde léwu gan-an, àmọ́ àwọn Kristẹni kan kò kíyè sára. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ní Kọ́ríńtì dá ara wọn lójú jù, wọ́n rò pé ìgbàgbọ́ àwọn lágbára débi pé mìmì kan ò lè mi àwọn. (1 Kọ́r. 10:12) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ fún wọn pé: “Mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ti sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́ kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.”​—2 Kọ́r. 11:3.

Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé kò yẹ kí ẹnikẹ́ni dá ara rẹ̀ lójú jù. Tá ò bá fẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn wá jẹ tàbí kó sí wa lórí, a gbọ́dọ̀ gbà pé àwọn ìpolongo ẹ̀tàn tí Sátánì ń gbé jáde léwu. Torí náà, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti dáàbò bo ara wa.

BÁWO NI ÌPOLONGO Ẹ̀TÀN ṢE LÉWU TÓ?

Kí la lè pè ní ìpolongo ẹ̀tàn? Ìpolongo ẹ̀tàn ni àwọn ọ̀rọ̀ tàbí àgbéjáde tó ń ṣini lọ́nà, tí wọ́n fi ń tan àwọn èèyàn jẹ tàbí tí wọ́n fi ń yí wọn lérò pa dà láti ronú tàbí hùwà lọ́nà kan. Nínú ìwé kan tó ń jẹ́ Propaganda and Persuasion, àwọn kan sọ pé àwọn ìpolongo yìí sábà máa ń kún fún “irọ́, yíyí òtítọ́ po, ẹ̀tàn, ká ṣini lọ́nà, ká ṣe awúrúju” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwé náà fi kún un pé ìpolongo ẹ̀tàn “burú gan-an, ó léwu, ó sì kún fún ọgbọ́nkọ́gbọ́n.”

Báwo ni ìpolongo ẹ̀tàn ṣe burú tó? Ó burú gan-an torí pé èèyàn lè má tètè fura sí i. Ṣe ló dà bí afẹ́fẹ́ panipani tí kò lóòórùn téèyàn ò sì lè fojú rí. Kéèyàn tó mọ̀, èèyàn á ti fà á símú débi táá fi ṣàkóbá  fúnni. Torí pé èèyàn kì í tètè fura sí ìpolongo ẹ̀tàn, ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Vance Packard sọ pé: “Ìpolongo ẹ̀tàn máa ń nípa lórí ọ̀pọ̀ wa ju bá a ṣe rò lọ.” Ọ̀mọ̀wé kan sọ nínú ìwé Easily Led​—A History of Propaganda pé táwọn èèyàn bá ti gba ìpolongo ẹ̀tàn gbọ́, ṣe ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ẹhànnà, èyí ló máa ń fa ìpẹ̀yàrun, ogun, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìjà ẹ̀sìn àtàwọn ìwà burúkú míì.

èèyàn lásánlàsàn bá lè tàn wá jẹ pẹ̀lú àwọn ìpolongo ẹ̀tàn, kí lo rò pé Sátánì máa ṣe? Àtìgbà tí Ọlọ́run ti dá àwa èèyàn ni Sátánì ti ń kíyè sí ìwà wa. Bíbélì sọ pé Sátánì ló ń darí “gbogbo ayé” báyìí. Torí náà, ó lè lo ohunkóhun tó wà nínú ayé láti tan irọ́ kálẹ̀. (1 Jòh. 5:19; Jòh. 8:44) Sátánì ti rọ́wọ́ mú débi pé ó ti ‘fọ́ ojú inú àwọn’ èèyàn, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (2 Kọ́r. 4:4; Ìṣí. 12:9) Kí lo lè ṣe tí Sátánì ò fi ní rí ẹ mú?

ṢE OHUN TÍ KÒ NÍ JẸ́ KÍ SÁTÁNÌ RÍ Ẹ TÀN JẸ

Jésù sọ ohun tó o lè ṣe tí Sátánì kò fi ní lè tàn ẹ́ jẹ, ó ní: “Mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá [ẹ] sílẹ̀ lómìnira.” (Jòh. 8:​31, 32) Lójú ogun, àwọn ọ̀tá máa ń dá ọgbọ́nkọ́gbọ́n kí wọ́n lè ṣi àwọn sójà lọ́nà, àmọ́ àwọn sójà náà máa ń wá ìsọfúnni tó jóòótọ́ káwọn ọ̀tá má bàa tàn wọ́n jẹ. Jèhófà ti fún wa ní ìsọfúnni tó jóòótọ́ nínú Bíbélì. Bíbélì ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o lè ṣe tí Sátánì ò fi ní rí ẹ tàn jẹ.​—2 Tím. 3:​16, 17.

Sátánì alára náà mọ̀ pé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn tó fi ń lo àwọn nǹkan inú ayé kó o má bàa ráyè ka Bíbélì tàbí kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Má ṣe jẹ́ kó rí ẹ mú! (Éfé. 6:11) Torí náà, rí i dájú pé o lóye òtítọ́ ní kíkún. (Éfé. 3:18) Èyí máa gba pé kó o sapá gan-an. Ohun kan wà tí òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Noam Chomsky sọ tó yẹ kó o fi sọ́kàn, ó ní: “Kò sẹ́ni tó máa rọ́ ìmọ̀ sí ẹ lórí. Ìwọ fúnra rẹ lo máa kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè ní ìmọ̀.” Torí náà, máa “fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́” kó o lè lóye òtítọ́ ní kíkún.​—Ìṣe 17:11.

Tó ò bá fẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn ẹ́ jẹ, o gbọ́dọ̀ mọ àwọn ẹ̀tàn tí Sátánì ń lò, kó o má sì jẹ́ kó rí ẹ mú

Má ṣe gbàgbé pé Sátánì kì í fẹ́ káwọn èèyàn ronú jinlẹ̀ tàbí yiri ọ̀rọ̀ wò kí wọ́n tó ṣèpinnu. Kí nìdí tó fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìwé kan sọ pé ìpolongo ẹ̀tàn máa kó sáwọn èèyàn lórí tí wọn ò bá ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí  wọ́n gbọ́. (Ìwé Media and Society in the Twentieth Century) Torí náà, má kàn gbà pé òótọ́ ni ohunkóhun tó o bá ṣáà ti gbọ́, rí i dájú pé o ronú jinlẹ̀. (Òwe 14:15) Rí i pé o lo làkáàyè tí Ọlọ́run fún ẹ kó o lè mọ ohun tó jẹ́ òótọ́.​—Òwe 2:​10-15; Róòmù 12:​1, 2.

MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÈṢÙ DÁ ÌYAPA SÍLẸ̀ LÁÀÁRÍN WA

Ohun míì táwọn ọmọ ogun máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń sọ àwọn nǹkan táá kó jìnnìjìnnì bá àwọn ọ̀tá wọn, kí wọ́n lè rẹ̀wẹ̀sì. Èyí lè mú káwọn ọ̀tá bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn jà tàbí kí wọ́n yapa síra wọn. Ọ̀gágun kan lórílẹ̀-èdè Jámánì gbà pé ìpolongo ẹ̀tàn ló mú káwọn fìdí rẹmi nínú Ogun Àgbáyé Kìíní, ó sọ pé ńṣe ni “ìpolongo ẹ̀tàn mú àwọn ṣìkún bí ìgbà tí òkété bá kó sẹ́nu ejò.” Irú ọgbọ́n yìí náà ni Sátánì máa ń lò. Ó máa ń fẹ́ ká kẹ̀yìn síra wa kí ọwọ́ rẹ̀ lè tètè tẹ̀ wá. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú kí èdèkòyédè wáyé láàárín àwọn ará kí wọ́n lè yapa síra wọn. Bákan náà, ó lè mú kí àwọn míì fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ torí ohun tí wọ́n kà sí àìṣèdájọ́ òdodo nínú ìjọ tàbí torí ohun tẹ́nì kan ṣe fún wọn.

Má ṣe jẹ́ kí Sátánì tàn ẹ́ jẹ! Jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tọ́ ẹ sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ ohun tá a lè ṣe tí àlàáfíà á fi jọba láàárín wa. Ó rọ̀ wá pé ká máa “dárí ji ara [wa] fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì” ká sì tètè máa yanjú aáwọ̀. (Kól. 3:​13, 14; Mát. 5:​23, 24) Ó kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe ya ara wa sọ́tọ̀ tàbí ya ara wa láṣo. (Òwe 18:1) Rí i dájú pé o mọ ohun tí wàá ṣe bí Sátánì bá gbé ẹ̀tàn rẹ̀ dé. Bi ara rẹ pé: ‘Kí ni mo ṣe nígbà tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan ṣẹ̀ mí? Ṣé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni mo ṣe àbí ohun tí Sátánì fẹ́?’​—Gál. 5:​16-26; Éfé. 2:​2, 3.

MÁ ṢIYÈ MÉJÌ

Bí sójà kan kò bá fọkàn tán ọ̀gá rẹ̀, kò ní jà dáadáa. Àwọn ọmọ ogun máa ń lo ìpolongo ẹ̀tàn láti mú káwọn ọ̀tá má fọkàn tán àwọn aṣáájú wọn. Wọ́n lè sọ pé: “Ẹ jẹ́ má gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọ̀gá yín!” Wọ́n sì lè sọ pé: “Wọ́n kàn fẹ́ tì yín sẹ́nu ikú ni!” Kí wọ́n lè kó sí wọn lórí, wọ́n lè tọ́ka sí àwọn àṣìṣe táwọn aṣáájú wọn ti ṣe. Ohun tí Sátánì náà  máa ń ṣe nìyẹn. Gbogbo ohun tó bá gbà ló máa ń ṣe kó lè rí i pé a ò fọkàn tán àwọn tí Jèhófà ń lò láti darí wa.

Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara rẹ? Pinnu pé bíná ń jó bíjì ń jà, o ò ní fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, wàá sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn tó ń múpò iwájú kódà bí àìpé wọn bá tiẹ̀ fara hàn kedere. (1 Tẹs. 5:​12, 13) Bíbélì rọ̀ wá pé ká “má ṣe tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò” wa nígbà táwọn apẹ̀yìndà tàbí àwọn ẹlẹ̀tàn míì bá sọ̀rọ̀ òdì sí ètò Ọlọ́run. Bọ́rọ̀ wọn bá tiẹ̀ dà bí òótọ́, má ṣe gbà wọ́n gbọ́. (2 Tẹs. 2:2; Títù 1:10) Fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba Tímótì sílò. Di òtítọ́ tó o gbà mú gírígírí, má sì gbàgbé ibi tó o ti kọ́ ọ. (2 Tím. 3:​14, 15) Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà tó fi yẹ kó o fọkàn tán ètò yìí torí òun ni Jèhófà ti ń lò láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn.​—Mát. 24:​45-47; Héb. 13:​7, 17.

MÁ ṢE JẸ́ KÍ SÁTÁNÌ KÓ JÌNNÌJÌNNÌ BÁ Ẹ

Àmọ́ o, kì í ṣe ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ nìkan ni Sátánì máa ń lò. Ó tún máa ń da jìnnìjìnnì bo àwọn èèyàn nígbà míì. Ìwé Easily Led​—A History of Propaganda sọ pé ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń kó jìnnìjìnnì bá àwọn ọ̀tá wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Philip M. Taylor sọ pé jìnìnjìnnì àti ìpolongo ẹ̀tàn wà lára ohun táwọn ọmọ ogun Ásíríà fi máa ń borí àwọn ọ̀tá wọn. Sátánì máa ń lo ìbẹ̀rù èèyàn, ìbẹ̀rù inúbiníbi, ìbẹ̀rù ikú àtàwọn nǹkan míì tó lè bani lẹ́rù láti kó jìnnìjìnnì bá wa ká lè fi Jèhófà sílẹ̀.​—Aísá. 8:12; Jer. 42:11; Héb. 2:15.

Má ṣe jẹ́ kí Sátánì kó jìnnìjìnnì bá ẹ débi tí wàá fi rẹ̀wẹ̀sì tàbí kọ Jèhófà sílẹ̀. Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara àti lẹ́yìn èyí tí wọn kò lè ṣe nǹkan kan jù bẹ́ẹ̀ lọ.” (Lúùkù 12:4) Fọkàn tán ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa dáàbò bò ẹ́, òun á fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” àti pé òun á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa bẹ̀rù kó o sì juwọ́ sílẹ̀.​—2 Kọ́r. 4:​7-9; 1 Pét. 3:14.

Àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù tó sì ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Àmọ́, máa rántí ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.” (Jóṣ. 1:9) Tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́, gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ‘àlàáfíà Ọlọ́run yóò máa ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ àti agbára èrò orí rẹ’ kó o lè lókun tí wàá fi borí gbogbo ìpolongo ẹ̀tàn tí Sátánì ń gbé jáde.​—Fílí. 4:​6, 7, 13.

Ṣé o rántí ìpolongo ẹ̀tàn tí Rábúṣákè tó jẹ́ aṣojú ọba Ásíríà sọ lòdì sí àwọn èèyàn Ọlọ́run? Ohun tó dọ́gbọ́n sọ ni pé, ‘Kò sóhun tó lè gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ Ásíríà. Kódà, Jèhófà Ọlọ́run yín kò lè ràn yín lọ́wọ́.’ Ó wá sọ pé: ‘Jèhófà fúnra rẹ̀ ló sọ fún wa pé ká wá gbéjà ko ilẹ̀ yìí.’ Kí wá ni Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀? Jèhófà ní: “Má fòyà nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, èyí tí àwọn ẹmẹ̀wà ọba Ásíríà sọ sí mi tèébútèébú.” (2 Ọba 18:​22-25; 19:6) Lẹ́yìn náà, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan, ó sì pa 185,000 àwọn ọmọ ogun Ásíríà ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo!​—2 Ọba 19:35.

JẸ́ ỌLỌ́GBỌ́N​—JÈHÓFÀ NI KÓ O MÁA TẸ́TÍ SÍ

Ṣé o ti wo fíìmù kan rí, tó o sì rí i pé wọ́n ń tan ẹnì kan jẹ? Bóyá ó tiẹ̀ ṣe ẹ́ bíi pé kó o sọ fún onítọ̀hún pé: ‘Má gbà wọ́n gbọ́! Irọ́ ni wọ́n ń pa!’ Wá wò ó bíi pé àwọn áńgẹ́lì ń sọ fún ìwọ náà pé: “Má ṣe jẹ́ kí Sátánì tàn ẹ́ jẹ!”

Má ṣe tẹ́tí sí àwọn ẹ̀tàn Sátánì. (Òwe 26:​24, 25) Tẹ́tí sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e nínú gbogbo ohun tó ò ń ṣe. (Òwe 3:​5-7) Ṣe ohun tó rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣe, ó ní: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀.” (Òwe 27:11) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò sẹ́ni tó máa tàn ẹ́ jẹ!