Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ẹ Jẹ́ Kí Aráyé Gbọ́ Ìhìn Rere Nípa Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run

Ẹ Jẹ́ Kí Aráyé Gbọ́ Ìhìn Rere Nípa Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run

“Jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”—ÌṢE 20:24.

ORIN: 101, 84

1, 2. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run?

TỌKÀNTỌKÀN ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sí òun kò já sí asán. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:9, 10.) Pọ́ọ̀lù mọ̀ dáadáa pé kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe òun ni Ọlọ́run fi ṣàánú òun lọ́nà gíga bẹ́ẹ̀, ó sì mọ̀ pé òun ò lẹ́tọ̀ọ́ sí i torí pé òun ti fìyà jẹ àwọn Kristẹni rí.

2 Nígbà tó kù díẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù máa kú, ó kọ̀wé sí Tímótì tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, pé: “Mo kún fún ìmoore sí Kristi Jésù Olúwa wa, ẹni tí ó fi agbára fún mi, nítorí tí ó kà mí sí olùṣòtítọ́ nípa yíyan iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lé mi lọ́wọ́.” (1 Tím. 1:12-14) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wo ló ní lọ́kàn? Pọ́ọ̀lù sọ ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní nínú fún àwọn alàgbà tó wà ní ìjọ Éfésù, ó ní: “Èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan kan tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, bí mo bá sáà ti lè parí ipa ọ̀nà mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”Ìṣe 20:24.

3. Àkànṣe iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run gbé fún Pọ́ọ̀lù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

 3 “Ìhìn rere” nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà wo ni Pọ́ọ̀lù wàásù rẹ̀? Ó sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù pé: “Ẹ̀yin . . . ti gbọ́ nípa iṣẹ́ ìríjú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi fún mi nítorí yín.” (Éfé. 3:1, 2) Ọlọ́run gbéṣẹ́ fún Pọ́ọ̀lù pé kó wàásù ìhìn rere fáwọn tí kì í ṣe Júù káwọn náà lè wà lára àwọn tí Ọlọ́run yàn láti bá Kristi ṣàkóso nínú Ìjọba Mèsáyà. (Ka Éfésù 3:5-8.) Àwa Kristẹni òde òní lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Ó fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sóun kò “já sí asán.”

ṢÉ O MỌYÌ INÚ RERE ÀÌLẸ́TỌ̀Ọ́SÍ ỌLỌ́RUN?

4, 5. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọ̀kan náà ni “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run” àti ìhìn rere nípa “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run”?

4 Jèhófà ti gbéṣẹ́ fún àwa èèyàn rẹ̀ tá à ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí pé ká wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:14) “Ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run” làwa náà ń wàásù rẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Gbogbo ìbùkún tá à ń retí láti gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ nítorí pé Jèhófà fi inú rere hàn sí wa nípasẹ̀ Kristi. (Éfé. 1:3) Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Àwa ńkọ́, ṣé a lè ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù?—Ka Róòmù 1:14-16.

5 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a jíròrò onírúurú ọ̀nà táwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ gbà ń jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà. Torí náà, ó yẹ ká sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wọn kọjá ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè jadùn ìfẹ́ yìí. Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn tá a lè báwọn èèyàn sọ?

Ẹ JẸ́ KÁRÁYÉ GBỌ́ ÌHÌN RERE NÍPA ẸBỌ ÌRÀPADÀ

6, 7. Ǹjẹ́ a lè sọ pé ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run là ń kéde tá a bá sọ fáwọn èèyàn nípa ìràpadà? Ṣàlàyé.

6 Lónìí, ńṣe làwọn èèyàn ń gbé ìgbésí ayé bó ṣe wù wọ́n, wọn ò sì rídìí tí wọ́n á fi máa wá ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń rí i pé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ káwọn láyọ̀. Lẹ́yìn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù fáwọn kan ni wọ́n tó mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ gan-an, ipa tó ń ní lórí wa àti ohun tó yẹ ká ṣe ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Inú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá mọ̀ pé Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti rà wá pa dà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa.—1 Jòh. 4:9, 10.

7 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ó sọ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ [ìyẹn Jésù] àwa ní ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ẹni yẹn, bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ [ìyẹn Jèhófà].” (Éfé. 1:7) Ẹbọ ìràpadà Kristi yìí ni ẹ̀rí tó ga jù lọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì tún jẹ́ ká mọ bí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ṣe lágbára tó. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rà wá pa dà, àá rí ìdáríjì gbà, àá sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Héb. 9:14) Ẹ ò rí i pé ìròyìn rere lèyí jẹ́, kò ṣeé bò mọ́ra!

 MÚ KÍ ÀWỌN ÈÈYÀN NÍ ÀJỌṢE TÓ DÁA PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN

8. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí aráyé bá Ọlọ́run rẹ́?

8 Ojúṣe wa ni láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé wọ́n lè dọ̀rẹ́ Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wọn. Bí ọ̀tá laráyé jẹ́ lójú Ọlọ́run kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà tí Jésù rú. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè, ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.” (Jòh. 3:36) A mà dúpẹ́ o, pé ẹbọ tí Kristi rú mú ká lè bá Ọlọ́run rẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin tí a sọ di àjèjì àti ọ̀tá nígbà kan rí nítorí tí èrò inú yín wà lórí àwọn iṣẹ́ tí ó burú, ni ó tún ti mú padà rẹ́ nísinsìnyí nípasẹ̀ ẹran ara ẹni yẹn nípasẹ̀ ikú rẹ̀.”—Kól. 1:21, 22.

9, 10. (a) Iṣẹ́ wo ni Kristi gbé lé àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́? (b) Báwo làwọn “àgùntàn mìíràn” ṣe ń ran àwọn ẹni àmì òróró yìí lọ́wọ́?

9 Pọ́ọ̀lù sọ pé Kristi fa “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́” lé àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tó wà láyé. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jọ wà láyé nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ó sọ pé: “Ohun gbogbo wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni ti ó tipasẹ̀ Kristi mú wa padà bá ara rẹ̀ rẹ́, tí ó sì fún wa ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́, èyíinì ni, pé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi ń mú ayé kan padà bá ara rẹ̀ rẹ́, láìṣírò àwọn àṣemáṣe wọn sí wọn lọ́rùn, ó sì fi ọ̀rọ̀ ìpadàrẹ́ náà lé wa lọ́wọ́. Nítorí náà, àwa jẹ́ ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń pàrọwà nípasẹ̀ wa. Gẹ́gẹ́ bí àwọn adípò fún Kristi, àwa bẹ̀bẹ̀ pé: ‘Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́.’”—2 Kọ́r. 5:18-20.

10 Ohun iyì gbáà làwọn “àgùntàn mìíràn” kà á sí pé àwọn ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹni àmì òróró lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí. (Jòh. 10:16) Torí pé àwọn àgùntàn mìíràn dà bí aṣojú ikọ̀ fún Kristi, wọ́n ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ń mú káwọn èèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kódà àwọn ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ náà. Apá pàtàkì lèyí jẹ́ tó bá di pé ká jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ọlọ́run, ká sì wàásù ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.

SỌ FÁWỌN ÈÈYÀN PÉ ỌLỌ́RUN MÁA Ń GBỌ́ ÀDÚRÀ

11, 12. Kí nìdí tó fi jẹ́ ìròyìn ayọ̀ pé àwọn èèyàn lè gbàdúrà sí Jèhófà?

11 Ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń gbàdúrà ni pé kí ara lè tù wọ́n, wọ́n ò gbà pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà. Ó yẹ kírú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé “Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà. Dáfídì tó wà lára àwọn tó kọ Sáàmù sọ pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá. Àwọn nǹkan ìṣìnà ti já sí alágbára ńlá jù mí lọ. Ní ti àwọn ìrélànàkọjá wa, ìwọ tìkára rẹ yóò bò wọ́n.”—Sm. 65:2, 3.

12 Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe é dájúdájú.” (Jòh. 14:14) Ó ṣe kedere pé àwọn ohun tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ohunkóhun.” Jòhánù mú kó dá wa lójú pé: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòh. 5:14) Inú wa máa ń dùn láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àdúrà kì í wulẹ̀ ṣe oògùn atura, kàkà bẹ́ẹ̀, àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé àwa èèyàn lásánlàsàn lè dúró níwájú “ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” Jèhófà! (Héb. 4:16) Ẹ jẹ́ ká kọ́ wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà lọ́nà tó  tọ́, sí Ẹni tó tọ́ àti fún ohun tó tọ́. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Jèhófà, wọ́n á sì rí ìtùnú gbà nígbà ìṣòro.—Sm. 4:1; 145:18.

A MÁA GBÁDÙN INÚ RERE ÀÌLẸ́TỌ̀Ọ́SÍ ỌLỌ́RUN NÍNÚ AYÉ TUNTUN

13, 14. (a) Àwọn àǹfààní àgbàyanu wo làwọn ẹni àmì òróró ṣì máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú? (b) Iṣẹ́ ńlá wo làwọn ẹni àmì òróró máa ṣe fún aráyé?

13 Kì í ṣe inú ayé búburú yìí nìkan la ti máa gbádùn inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, a tún máa gbádùn rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí Ọlọ́run fún àwọn 144,000, pé wọ́n á bá Kristi ṣàkóso, ó ní: “Ọlọ́run, ẹni tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi nífẹ̀ẹ́ wa, sọ wá di ààyè pa pọ̀ pẹ̀lú Kristi, àní nígbà tí a ti kú nínú àwọn àṣemáṣe—nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí a ti gbà yín là—ó sì gbé wa dìde pa pọ̀, ó sì mú wa jókòó pa pọ̀ ní àwọn ibi ọ̀run ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, pé nínú àwọn ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀ kí a lè fi ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ títayọ ré kọjá hàn gbangba nínú oore ọ̀fẹ́ rẹ̀ sí wa ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.”—Éfé. 2:4-7.

14 Àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ṣì máa ṣe fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nígbà tí wọ́n bá ń bá Kristi ṣàkóso lọ́run á kọjá àfẹnusọ. (Lúùkù 22:28-30; Fílí. 3:20, 21; 1 Jòh. 3:2) Àwọn ni Jèhófà máa dìídì “fi ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ títayọ ré kọjá hàn gbangba” sí. Wọ́n máa para pọ̀ jẹ́ “Jerúsálẹ́mù Tuntun,” ìyẹn ìyàwó Kristi. (Ìṣí. 3:12; 17:14; 21:2, 9, 10) Wọ́n á pẹ̀lú Jésù láti ‘wo àwọn orílẹ̀-èdè sàn,’ wọ́n á sì mú kí aráyé jàǹfààní látinú àwọn ohun tí Jèhófà pèsè fún wọn kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, kí wọ́n sì dẹni pípé.—Ka Ìṣípayá 22:1, 2, 17.

15, 16. Báwo ni Jèhófà ṣe máa fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sáwọn “àgùntàn mìíràn” lọ́jọ́ iwájú?

15 Ìwé Éfésù 2:7, jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ṣì máa fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn nínú “ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀.” Ó dájú pé nínú ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí, a máa jọlá “ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ títayọ ré kọjá.” (Lúùkù 18:29, 30) Jèhófà máa fi inú rere rẹ̀ hàn sọ́mọ aráyé láwọn ọ̀nà tó yani lẹ́nu, ọ̀kan ni pé á jí àwọn òkú dìde. (Jóòbù 14:13-15; Jòh. 5:28, 29) Jèhófà máa jí àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó ti kú kí Kristi tó fara rẹ̀ rúbọ. Bákan náà, ó máa jí gbogbo àwọn “àgùntàn mìíràn” tó fòótọ́ sìn ín títí dójú ikú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, gbogbo wọn á sì máa sin Jèhófà nìṣó.

16 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kú láìmọ Jèhófà Ọlọ́run. Ọlọ́run máa jí àwọn náà dìde, á sì fún wọn láǹfààní láti mọ òun kí wọ́n sì yàn láti fara wọn sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. Jòhánù sọ pé: “Mo sì rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Ṣùgbọ́n a ṣí àkájọ ìwé mìíràn sílẹ̀; àkájọ ìwé ìyè ni. A sì ṣèdájọ́ àwọn òkú láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn. Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn.” (Ìṣí. 20:12, 13) Ohun kan ni pé a máa ní láti kọ́ àwọn tó máa jíǹde yìí láwọn ìlànà inú Bíbélì, wọ́n á sì ní láti máa fàwọn ìlànà náà sílò. Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run máa fún aráyé láwọn ìtọ́ni tuntun látinú “àwọn àkájọ ìwé” náà. Àwọn ìlànà tá a máa tẹ̀ lé ló wà nínú àwọn àkájọ ìwé náà. Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ló jẹ́ pé  Jèhófà máa jẹ́ kí aráyé lóye ohun tó wà nínú àwọn àkájọ ìwé náà.

Ẹ MÁA SỌ ÌHÌN RERE NÁÀ FÚN ARÁYÉ

17. Kókó wo ló yẹ ká máa fi sọ́kàn tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn?

17 Àkókò yìí gan-an ló yẹ ká fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wa pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, pàápàá bí òpin ṣe ń sún mọ́lé! (Máàkù 13:10) Kò sí àní-àní, ìhìn rere ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà jẹ́. Ká máa fi kókó yìí sọ́kàn nígbà tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn. Ká má sì gbàgbé pé ká bàa lè fògo fún Jèhófà la ṣe ń wàásù. Nípa bẹ́ẹ̀, àá jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé inú rere Jèhófà ló máa mú ká gbádùn àwọn ìbùkún àgbàyanu nínú ayé tuntun.

Máa lo ìtara gẹ́gẹ́ bí “ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”1 Pét. 4:10 (Wo ìpínrọ̀ 17 sí 19)

18, 19. Ọ̀nà wo là ń gbà polongo inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà?

18 Tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn, ká máa ṣàlàyé fún wọn pé aráyé máa jàǹfààní lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n á jadùn gbogbo oore tí ẹbọ ìràpadà ní, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ́n á di pípé. Bíbélì sọ pé: “A óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Inú rere àrà ọ̀tọ̀ tí Jèhófà ní sí wa láá jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀.

19 Inú wa dùn pé à ń sọ ìlérí amọ́kànyọ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣípayá 21:4, 5, fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, èyí tó sọ pé: “[Ọlọ́run] yòó . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ìyẹn Jèhófà sì wí pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: “Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.” Tá a bá ń fìtara wàásù ìhìn rere yìí fáwọn èèyàn, ṣe là ń polongo inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà!