Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) January 2018

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti February 26 sí April 1, 2018 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

WỌ́N YỌ̀ǸDA ARA WỌN TINÚTINÚ

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​—Ní Madagásíkà

Ẹ jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn akéde tó ṣí lọ sórílẹ̀-èdè Madagásíkà kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí.

“Ó Ń Fi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀”

Bí ayé búburú yìí ṣe ń lọ sópin, a lè retí pé àwọn ìṣòro ìgbésí ayé á túbọ̀ máa peléke. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2018 jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló yẹ ká yíjú sí kó lè fún wa lókun.

Ìrántí Ikú Kristi Ń Mú Ká Wà Níṣọ̀kan

Àwọn ọ̀nà wo ni Ìrántí Ikú Kristi ń gbà mú káwa èèyàn Ọlọ́run wà níṣọ̀kan? Ìgbà wo la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tó kẹ́yìn?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fún Ẹni Tó Ni Ohun Gbogbo Ní Nǹkan?

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni pé ká máa fún un ní nǹkan. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fi àwọn ohun ìní wa bọlá fún Jèhófà?

Ìfẹ́ Wo Ló Ń Mú Kéèyàn Ní Ojúlówó Ayọ̀?

Báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe yàtọ̀ sí irú ìfẹ́ tó wà nínú 2 Tímótì 3:​2-4? Tó o bá mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, wàá ní ìtẹ́lọ́rùn àti ojúlówó ayọ̀.

Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Àwọn Tó Ń Sin Ọlọ́run Àtàwọn Tí Kò Sìn Ín

Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìwà táwọn èèyàn ayé ń hù àti ìwà táwa èèyàn Jèhófà ní?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ máa ń fi àwọn ìlànà inú Òfin Mósè yanjú èdèkòyédè?