“Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”ÒWE 11:2.

ORIN: 38, 69

1, 2. Kí ló fà á tí Ọlọ́run fi kọ Sọ́ọ̀lù sílẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

ONÍRẸ̀LẸ̀ èèyàn ni Sọ́ọ̀lù nígbà tó jọba ní Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn sì mọyì rẹ̀ gan-an. (1 Sám. 9:1, 2, 21; 10:20-24) Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn tó di ọba ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé kò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ mọ́. Nígbà kan tí wòlíì Sámúẹ́lì kò tètè dé sí ìlú Gílígálì níbi tí wọ́n fàdéhùn sí, Sọ́ọ̀lù ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn ọmọ ogun Filísínì ń bọ̀ wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù sì sá fi í sílẹ̀. Sọ́ọ̀lù bá ronú pé, ‘Á dáa kí n tètè wá nǹkan ṣe, mi ò gbọ́dọ̀ jáfara.’ Ló bá ṣe ohun tí kò tọ́ sí i, ó rú ẹbọ sí Ọlọ́run, inú Jèhófà ò sì dùn sóhun tó ṣe.1 Sám. 13:5-9.

2 Nígbà tí Sámúẹ́lì dé Gílígálì, ó bá Sọ́ọ̀lù wí gidigidi. Dípò tí Sọ́ọ̀lù á fi gba ìbáwí, ṣe ló ń ṣàwáwí, ó ń di ẹ̀bi ru àwọn míì, kò sì ka ohun tó ṣe sí bàbàrà. (1 Sám. 13:10-14) Bí Sọ́ọ̀lù ṣe ń kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ kan ló ń bọ́ sórí òmíì títí Jèhófà fi kọ̀ ọ́ lọ́ba, tó sì pàdánù ojúure rẹ̀. (1 Sám. 15:22, 23) Ó mà ṣé o, ìbẹ̀rẹ̀ ayé Sọ́ọ̀lù dùn bí oyin, àmọ́  ìgbẹ̀yìn rẹ̀ wá korò bí iwọ.1 Sám. 31:1-6.

3. (a) Èrò wo lọ̀pọ̀ èèyàn ní tó bá dọ̀rọ̀ ká mọ̀wọ̀n ara ẹni? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

3 Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àwọn gbọ́dọ̀ yọrí ọlá ju àwọn tó kù lọ, torí pé ìwà tèmi-làkọ́kọ́ ló kúnnú ayé yìí. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n kọjá àyè wọn. Bí àpẹẹrẹ, òṣèré kan tó ti wá di olóṣèlú sọ pé: “Èmi ti kọjá ẹni tẹ́nì kan á sọ fún pé kó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, kò sí ìwọ̀n kankan tí mo fẹ́ mọ̀.” Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà tàbí lédè míì, ká mọ̀wọ̀n ara wa? Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹni, kí ni kò sì túmọ̀ sí? Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọjá àyè wa kódà bí kò bá tiẹ̀ rọrùn? A máa dáhùn ìbéèrè méjì àkọ́kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí. A sì máa dáhùn ìbéèrè kẹta nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

KÍ NÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ MỌ̀WỌ̀N ARA WA?

4. Kí la lè pè ní “àwọn ìṣe ìkùgbù”?

4 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó bá mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ kò ní kọjá àyè rẹ̀. (Ka Òwe 11:2.) Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà bí Dáfídì ṣe gbàdúrà pé kí Jèhófà “fa [òun] sẹ́yìn kúrò nínú àwọn ìṣe ìkùgbù.” (Sm. 19:13) Kí la lè pè ní “àwọn ìṣe ìkùgbù”? Ẹni tó máa ń kùgbù ṣe nǹkan kì í fara balẹ̀ ronú kó tó ṣe nǹkan, ó sì máa ń kọjá àyè rẹ̀. Torí àìpé wa, gbogbo wa pátá la máa ń kọjá àyè wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ Ọba Sọ́ọ̀lù tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ tán, tó bá ti mọ́ọ̀yàn lára láti máa kọjá àyè rẹ̀, kò ní pẹ́ tí onítọ̀hún á fi kọjá àyè rẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Sáàmù 119:21 sọ pé Jèhófà máa ‘bá àwọn oníkùgbù wí lọ́nà mímúná.’ Kí nìdí tó fi máa ṣe bẹ́ẹ̀?

5. Kí nìdí tó fi burú pé kéèyàn máa kọjá àyè rẹ̀?

5 Kéèyàn kọjá àyè rẹ̀ burú ju kéèyàn ṣèèṣì ṣe ohun tí kò yẹ. Lákọ̀ọ́kọ́, tá a bá kọjá àyè wa, ó fi hàn pé a ò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Èkejì ni pé, tá a bá ń kọjá àyè wa, àá máa ní ìforígbárí pẹ̀lú àwọn èèyàn. (Òwe 13:10) Ẹ̀kẹta sì ni pé, táwọn èèyàn bá mọ̀ pé a ti kọjá àyè wa, ó lè kó ìtìjú bá wa, ká sì dẹni ẹ̀tẹ́. (Lúùkù 14:8, 9) Ó ṣe kedere pé ìkùgbù kì í bímọre. Bí Bíbélì ṣe sọ, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn mọ̀wọ̀n ara rẹ̀.

BÁ A ṢE LÈ FI HÀN PÉ A MỌ̀WỌ̀N ARA WA

6, 7. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, báwo ló sì ṣe jọra pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà?

6 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmẹ̀tọ́mọ̀wà jọra gan-an. Bíbélì fi hàn pé onírẹ̀lẹ̀ èèyàn kì í gbéra ga, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í jọra rẹ̀ lójú. Bíbélì tún pe ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ní “ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú.” (Fílí. 2:3) Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn sábà máa ń mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó mọ ibi tágbára òun mọ, ó máa ń gba àṣìṣe rẹ̀, ó sì máa ń gbàmọ̀ràn. Inú Jèhófà máa ń dùn sáwọn onírẹ̀lẹ̀.

7 Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan lòun lè ṣe, kì í sì kọjá àyè rẹ̀. Èdè Gíríìkì tí wọ́n lò fún ìmẹ̀tọ́mọ̀wà nínú Bíbélì fi hàn pé amẹ̀tọ́mọ̀wà èèyàn máa ń ro tàwọn míì mọ́ tiẹ̀, kì í sì kọjá àyè rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn.

8. Báwo lèèyàn á ṣe mọ̀ pé òun ti fẹ́ máa kọjá àyè òun?

8 Báwo lèèyàn a ṣe mọ̀ pé òun ti fẹ́ máa kọjá àyè òun? Díẹ̀ rèé lára àwọn nǹkan téèyàn fi lè mọ̀. A lè bẹ̀rẹ̀ sí í  ka ara wa sí bàbàrà torí pé a láwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. (Róòmù 12:16) Ó lè jẹ́ pé à ń pe àfiyèsí sí ara wa lọ́nà tí kò tọ́. (1 Tím. 2:9, 10) A sì lè máa wá báwọn èèyàn á ṣe gba èrò tiwa kìkì nítorí pé a lẹ́nu láwùjọ, tàbí torí pé a mọ àwọn èèyàn dáadáa, tàbí kẹ̀ torí a rò pé èrò tiwa ló tọ̀nà. (1 Kọ́r. 4:6) Tírú ìwà yìí bá ti mọ́ wa lára, a tiẹ̀ lè má fura pé àṣejù ti fẹ́ máa wọ ọ̀rọ̀ wa, àti pé a ti ń kọjá àyè wa.

9. Kí ló mú káwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í kọjá àyè ara wọn? Sọ àpẹẹrẹ kan látinú Bíbélì.

9 Téèyàn bá jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gba òun lọ́kàn, wẹ́rẹ́ báyìí lonítọ̀hún á bẹ̀rẹ̀ sí í kọjá àyè ara rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìmọtara-ẹni-nìkan, ìlara àti ìbínú òdì wà lára ohun tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn kọjá àyè wọn. Nínú Bíbélì, àwọn èèyàn bí Ábúsálómù, Ùsáyà àti Nebukadinésárì jẹ́ kí àwọn iṣẹ́ ti ara wọ̀ wọ́n lẹ́wù débi pé wọ́n kọjá àyè wọn, Jèhófà sì rẹ̀ wọ́n wálẹ̀.2 Sám. 15:1-6; 18:9-17; 2 Kíró. 26:16-21; Dán. 5:18-21.

10. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan látinú Bíbélì.

10 Àmọ́ ṣá o, àwọn ìdí míì wà tó lè mú kéèyàn kọjá àyè rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Bíbélì ròyìn pé ó ṣẹlẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 20:2-7 àti Mátíù 26:31-35. Ṣé a lè sọ pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ló fà á tó fi jọ pé Ábímélékì àti Pétérù kọjá àyè ara wọn? Àbí ohun tó fà á ni pé wọn ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti pé wọn ò wà lójúfò? Torí pé a ò rínú, á dáa ká má ṣe máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́.Ka Jákọ́bù 4:12.

Ó YẸ KÁ MỌ ÀYÈ WA

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn mọ àyè rẹ̀ nínú ìṣètò Ọlọ́run?

11 Téèyàn bá mọ àyè rẹ̀ nínú ìṣètò Ọlọ́run, kò ní kọjá àyè rẹ̀. Ọlọ́run ètò ni Jèhófà, torí náà oníkálukú wa ló láyè tí Ọlọ́run fẹ́ kó wà. Gbogbo wa la níbi tá a ti wúlò nínú ìjọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ló sì ṣe pàtàkì. Torí pé Jèhófà jẹ́ onínúure, ó fún wa lẹ́bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ànímọ́ tó yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ sì ni agbára wa ò rí bákan náà. Ó fẹ́ ká máa fàwọn nǹkan yìí bọlá fún òun, ká sì máa fi ṣe àwọn míì láǹfààní. (Róòmù 12:4-8) Àǹfààní ńlá ni Jèhófà fi dá wa lọ́lá yìí, ó sì yẹ ká mọyì wọn ká sì máa lò wọ́n bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.Ka 1 Pétérù 4:10.

Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ bí iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run bá yí pa dà? (Wo ìpínrọ̀ 12 sí 14)

12, 13. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu bí ohun tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run bá ń yí pa dà?

12 Àmọ́ o, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ojú kan náà la máa wà títí lọ, nǹkan lè yí pa dà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù. Níbẹ̀rẹ̀, òun nìkan ló wà pẹ̀lú Jèhófà. (Òwe 8:22) Nígbà yẹn, ó bá Jèhófà ṣiṣẹ́ láti dá àwọn áńgẹ́lì, ayé àti ọ̀run àtàwa èèyàn nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Kól. 1:16) Nígbà tó sì yá, Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé. Ìgbà kan wà tó jẹ́ ọmọ jòjòló, lẹ́yìn náà ó di géńdé. (Fílí. 2:7) Lẹ́yìn tí Jésù ti fara rẹ̀ rúbọ, ó pa dà sọ́run, ó sì di Ọba Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914. (Héb. 2:9) Nǹkan máa tún yí pa dà fún Jésù. Ìdí sì ni pé, lẹ́yìn tí ẹgbẹ̀rún ọdún tó fi máa ṣàkóso bá parí, á gbé ìjọba náà pa dà fún Jèhófà, kí “Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”1 Kọ́r. 15:28.

13 Iṣẹ́ táwa náà ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run lè yí pa dà látàrí àwọn ìpinnu tá a máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ṣé àpọ́n ni ẹ́ tẹ́lẹ̀ àmọ́ tó o ti wá ṣègbéyàwó báyìí? Ṣé o ti di bàbá àbí ìyá àbúrò? Ṣé o ti tọ́mọ darí, tó o sì wá dín ohun tó ò ń ṣe kù kó o lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn  Ọlọ́run? Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìyípadà tó o ṣe yẹn ló ní ojúṣe àti àǹfààní tiẹ̀. Bí ipò wa ṣe ń yí pa dà bẹ́ẹ̀ ni ohun tá a lè ṣe ń dín kù, ó sì lè pọ̀ sí i nígbà míì. Ṣé ọ̀dọ́ ni ẹ́, àbí àgbàlagbà? Ṣé ara rẹ ṣì le dáadáa àbí ara ò fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́? Jèhófà máa ń kíyè sí ipò wa, ó sì máa ń wo ibi tó ti lè lò wá nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ohun tó ń retí ni pé ká ṣe ohun tágbára wa gbé, ó sì mọrírì ohunkóhun tá a bá ṣe.Héb. 6:10.

14. Báwo lẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè mú ká máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa?

14 Inú Jésù máa ń dùn sí iṣẹ́ èyíkéyìí tí Ọlọ́run bá gbé fún un, àwa náà sì lè láyọ̀ nínú iṣẹ́ tá à ń ṣe. (Òwe 8:30, 31) Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn máa ń mọyì iṣẹ́ tó ní nínú ìjọ. Kì í banú jẹ́ báwọn míì bá ń gbé ohun ribiribi ṣe nínú ìjọ tàbí tí kò bá ní àfikún iṣẹ́ ìsìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń lo ara rẹ̀ tokunratokunra nínú iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe lọ́wọ́, ó sì ń láyọ̀ torí ó mọ̀ pé Jèhófà ló fún òun ní àǹfààní náà. Bákan náà, ó mọyì iṣẹ́ táwọn míì ń ṣe nínú ètò Jèhófà. Lóòótọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ ká bọlá fáwọn míì, ká sì máa fayọ̀ tì wọ́n lẹ́yìn.Róòmù 12:10.

NǸKAN TÉÈYÀN Ò NÍ ṢE TÓ BÁ MỌ̀WỌ̀N ARA RẸ̀

15. Kí la rí kọ́ lára Gídíónì?

15 Àpẹẹrẹ àtàtà ni Gídíónì tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹni. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà kọ́kọ́  bá a sọ̀rọ̀, Gídíónì sọ fún un pé òun ò já mọ́ nǹkan láàárín àwọn èèyàn òun. (Oníd. 6:15) Lẹ́yìn tí Gídíónì gbà láti ṣe iṣẹ́ Jèhófà, ó rí i dájú pé òun lóye ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe, ó sì bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. (Oníd. 6:36-40) Ọmọ akin ni Gídíónì, kò bẹ̀rù rárá. Síbẹ̀, ó fọgbọ́n ṣe iṣẹ́ náà. (Oníd. 6:11, 27) Kò wo iṣẹ́ náà bí ohun táá fi gbayì. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tó parí iṣẹ́ náà, ṣe ló pa dà sílé rẹ̀.Oníd. 8:22, 23, 29.

16, 17. Àwọn nǹkan wo lẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń fi sọ́kàn tó bá ń ronú nípa bóyá kóun gba iṣẹ́ tuntun?

16 Kéèyàn mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ kò ní kéèyàn má nàgà fún tàbí gba àfikún iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run. Ó ṣe tán Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa tẹ̀ síwájú. (1 Tím. 4:13-15) Àmọ́ ṣó dìgbà tí iṣẹ́ èèyàn bá yí pa dà, kéèyàn tó gbà pé òun ń tẹ̀ síwájú? Kò di dandan. A lè tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe lọ́wọ́, lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa sapá láti ní àwọn ànímọ́ tó yẹ Kristẹni, ká sì máa sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe lọ́wọ́.

17 Kí onírẹ̀lẹ̀ èèyàn tó gba iṣẹ́ tuntun, á kọ́kọ́ béèrè ohun tí iṣẹ́ náà máa gbà pé kóun ṣe. Lẹ́yìn ìyẹn, á fara balẹ̀ kíyè sí ipò ara rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, á ronú lórí bóyá òun á lè ṣe iṣẹ́ náà láìsí pé ojúṣe kan ń pa òmíì lára. Á tún wò ó bóyá òun lè gbé iṣẹ́ tóun ń ṣe lọ́wọ́ fún ẹlòmíì kóun lè ráyè fún iṣẹ́ tuntun náà. Tí kò bá ní lè ṣe ọ̀kan tàbí méjèèjì yìí, á jẹ́ pé ní báyìí á dáa kí wọ́n gbé iṣẹ́ tuntun náà fún ẹlòmíì táá lè ṣe é yanjú. Téèyàn bá fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ náà, tó sì fi í sádùúrà, èèyàn ò ní ṣe kọjá ohun tágbára rẹ̀ gbé. Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ láá fi sọ pé òun ò ní lè ṣe iṣẹ́ náà.

18. (a) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kí la máa ṣe tá a bá gba iṣẹ́ tuntun? (b) Báwo lẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè fi ìmọ̀ràn inú Róòmù 12:3 sílò?

18 Tá a bá gba iṣẹ́ tuntun, ẹ jẹ́ ká máa rántí Gídíónì tó gbára lé Jèhófà, tó sì jẹ́ kó tọ́ òun sọ́nà. Tá a bá ṣe bíi tiẹ̀, àá ṣàṣeyọrí. Ó ṣe tán, Jèhófà ló ní ká ‘jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá òun rìn.’ (Míkà 6:8) Torí náà, tá a bá gba iṣẹ́ tuntun, ó ṣe pàtàkì ká ronú tàdúràtàdúrà lórí ohun tí Jèhófà àti ètò rẹ̀ sọ pé ká ṣe. Ó yẹ ká ṣe tán láti mú èrò wa bá ti Jèhófà mu. Ká máa rántí pé kì í ṣe mímọ́ ṣe wa tàbí òye wa ló jẹ́ ká láǹfààní iṣẹ́ ìsìn, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà ní ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. (Sm. 18:35) Torí pé à ń bá Jèhófà rìn, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kò ní jẹ́ ká jọ ara wa lójú, a ò sì ní ro ara wa pin.—Ka Róòmù 12:3.

19. Kí nìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tàbí pé ká mọ̀wọ̀n ara wa?

19 Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tàbí tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ máa ń bọlá fún Jèhófà, torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, òun sì ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. (Ìṣí. 4:11) Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run á tẹ́ wa lọ́rùn, àá sì máa fi gbogbo ara ṣe iṣẹ́ náà. Àá máa bọ̀wọ̀ fáwọn ará wa, ìyẹn á sì mú ká wà níṣọ̀kan. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú ká gbà pé àwọn míì sàn jù wá lọ, kò ní jẹ́ ká kọjá àyè wa débi tá a fi máa ṣìwà hù. Ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé káwa èèyàn Jèhófà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì mọ̀wọ̀n ara wa, Jèhófà sì máa bù kún wa tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, tó bá ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀ ńkọ́? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn.