Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) January 2017

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti February 27 sí April 2, 2017 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú

Ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tó ti sìn nílẹ̀ òkèèrè ló kọ́kọ́ lọ́ tìkọ̀ kí wọ́n tó lọ. Àmọ́, kí ló mú kí wọ́n ṣọkàn akin? Kí ni wọ́n sì ti kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn lórílẹ̀-èdè mí ì?

“Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Kí O sì Máa Ṣe Rere”

Inú Jèhófà máa ń dùn láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe àwọn ohun tá ò lè dá ṣe fúnra wa, àmọ́ ó retí pé ká ṣe ipa tiwa. Báwo ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2017 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tá a lè ṣe àti ohun tá ò lè ṣe?

Mọyì Òmìnira Tó O Ní

Kí ni òmìnira tí Ọlọ́run fún wa túmọ̀ sí, kí sì ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀? Báwo la ṣe lè fọ̀wọ̀ wọ àwọn mí ì tí wọ́n bá ṣèpinnu?

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Ẹni Tó Mẹ̀tọ́mọ̀wà

Kí ni ìmẹ̀tọ́mọ̀wà, kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, báwo ló sì ṣe jọra pẹ̀lú ìwà ìrẹ̀lẹ̀?

O Lè Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà Bí Kò Bá Tiẹ̀ Rọrùn

Báwo la ṣe lè jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà tí iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run bá yí pa dà, táwọn èèyàn bá ń yìn wá tàbí tí wọ́n ń ṣàríwísí wa, àtìgbà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu tá ò sì mọ ibi tọ́rọ̀ kan máa já sí?

Fi ‘Nǹkan Wọ̀nyí Lé Àwọn Olùṣòtítọ́ Lọ́wọ́’

Báwo làwọn tó ti dàgbà ṣe lè ran àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí lọ́wọ́ kí wọ́n lè gba àfikún iṣẹ́? Báwo làwọn tí wọ́n ń faṣẹ́ lé lọ́wọ́ ṣe lè fi hàn pé àwọn mọyì àwọn àgbà tó ti wà nídìí iṣẹ́ ṣáájú àwọn?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, báwo ni wọ́n ṣe ń mú iná láti ibì kan dé ibòmí ì?