Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ta Ló Ń Darí Àwa Èèyàn Ọlọ́run Lónìí?

Ta Ló Ń Darí Àwa Èèyàn Ọlọ́run Lónìí?

“Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín.”​HÉB. 13:7.

ORIN: 125, 43

1, 2. Kí ló ṣeé ṣe káwọn àpọ́sítẹ́lì Jésù máa rò lẹ́yìn tí Jésù pa dà sọ́run?

ÀWỌN àpọ́sítẹ́lì Jésù wà lórí Òkè Ólífì, wọ́n ń wojú ọ̀run. Wọ́n ń wo Jésù ọ̀gá wọn tó sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn bó ṣe ń gòkè lọ sọ́run títí tó fi wọnú òfuurufú. (Ìṣe 1:​9, 10) Nǹkan bí ọdún méjì ni Jésù ti fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, tó ń gbà wọ́n níyànjú, tó sì ń darí wọn. Ní báyìí tí kò sí pẹ̀lú wọn mọ́, kí ni wọ́n máa ṣe?

2 Kí Jésù tó lọ, ó gbéṣẹ́ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: ‘Ẹ ó jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.’ (Ìṣe 1:8) Báwo ni wọ́n á ṣe ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí? Lóòótọ́ Jésù fi dá wọn lójú pé wọ́n máa tó rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. (Ìṣe 1:5) Síbẹ̀, kí wọ́n tó lè wàásù kárí ayé, àwọn kan gbọ́dọ̀ múpò iwájú, kí wọ́n sì rí i pé ohun gbogbo wà létòlétò. Láyé àtijọ́, Jèhófà mú káwọn èèyàn rẹ̀ wà létòlétò, ó sì darí wọn nípasẹ̀ àwọn aṣojú rẹ̀. Torí náà, àwọn àpọ́sítélì yẹn lè máa ronú pé, ‘Ṣé Jèhófà máa yan aṣáájú míì fún àwọn?’

3. (a) Ìpinnu pàtàkì wo làwọn àpọ́sítélì ṣe lẹ́yìn tí Jésù pa dà sí ọ̀run? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí Jésù gòkè ọ̀run, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yẹ Ìwé Mímọ́ wò, wọ́n sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tọ́ àwọn  sọ́nà. Wọ́n wá yan Mátíásì rọ́pò Júdásì Ísíkáríótù kí àwọn àpọ́sítélì lè pé méjìlá. (Ìṣe 1:​15-26) Kí nìdí tó fi pọn dandan pé kí wọ́n yan àpọ́sítélì kejìlá? Ìdí ni pé àwọn àpọ́sítélì náà mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn pé méjìlá. * Kì í ṣe torí pé Jésù ń wá àwọn ọ̀rẹ́ ló ṣe yan àwọn àpọ́sítẹ́lì, Jésù yàn wọ́n torí iṣẹ́ pàtàkì tó fẹ́ kí wọ́n ṣe láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àmọ́, iṣẹ́ wo nìyẹn, báwo sì ni Jèhófà ṣe lo Jésù láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ náà? Ǹjẹ́ àwọn kan wà tó ń ṣe irú iṣẹ́ yìí láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí? Báwo la sì ṣe lè máa “rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú” láàárín wa, pàápàá jù lọ àwọn tó para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”?​—Héb. 13:7; Mát. 24:45.

ÌGBÌMỌ̀ OLÙDARÍ Ń ṢIṢẸ́ LÁBẸ́ ÌDARÍ JÉSÙ

4. Iṣẹ́ wo ni àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà míì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?

4 Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn àpọ́sítélì bẹ̀rẹ̀ sí í múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni. Lọ́jọ́ yẹn, “Pétérù dìde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá náà,” wọ́n sì kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe ní òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣe 2:​14, 15) Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà sì di onígbàgbọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun yìí “ń bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.” (Ìṣe 2:42) Àwọn àpọ́sítélì yìí ló ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìnáwó nínú ìjọ. (Ìṣe 4:​34, 35) Àwọn náà sì ni wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọ́n ní: “Àwa yóò fi ara wa fún àdúrà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.” (Ìṣe 6:4) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń rán àwọn Kristẹni tó nírìírí lọ wàásù láwọn ilẹ̀ míì tí iṣẹ́ ìwàásù náà kò tíì dé. (Ìṣe 8:​14, 15) Nígbà tó yá, àwọn alàgbà kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró kún àwọn àpọ́sítélì kí wọ́n lè máa bójú tó ìjọ. Àwọn yìí ṣiṣẹ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ olùdarí, wọ́n sì ń darí bí nǹkan ṣe ń lọ ní gbogbo ìjọ.​—Ìṣe 15:2.

5, 6. (a) Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ran ìgbìmọ̀ olùdarí lọ́wọ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ran ìgbìmọ̀ olùdarí lọ́wọ́? (d) Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe tọ́ ìgbìmọ̀ olùdarí sọ́nà?

5 Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gbà pé Jèhófà ló ń darí ìgbìmọ̀ olùdarí nípasẹ̀ Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wọn. Kí ló mú kí èyí dá wọn lójú? Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ̀mí mímọ́ ran ìgbìmọ̀ olùdarí lọ́wọ́. (Jòh. 16:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ mú kí àwọn àpọ́sítẹ́lì àtàwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù máa ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni, ẹ̀mí mímọ́ ran ìgbìmọ̀ olùdarí lọ́wọ́ láti dórí ìpinnu nípa ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́. Àwọn ará tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà wọn, èyí sì mú kí ìjọ máa “bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.” (Ìṣe 16:​4, 5) Lẹ́tà tí ìgbìmọ̀ olùdarí kọ sí àwọn ìjọ tí wọ́n fi sọ ìpinnu wọn lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ fi hàn pé ìgbìmọ̀ náà ní ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́, tó jẹ́ ara èso ẹ̀mí mímọ́.​—Ìṣe 15:​11, 25-29; Gál. 5:​22, 23.

6 Ohun kejì ni pé, àwọn áńgẹ́lì ran ìgbìmọ̀ olùdarí lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, kí Kọ̀nílíù tó ṣèrìbọmi tó sì di Kèfèrí àkọ́kọ́ tó di Kristẹni, áńgẹ́lì kan sọ fún un pé kó ránṣẹ́ pe àpọ́sítélì Pétérù. Lẹ́yìn tí Pétérù wàásù fún Kọ̀nílíù àti ìdílé rẹ̀, Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin àárín wọn kò dádọ̀dọ́. Èyí mú káwọn àpọ́sítélì náà àtàwọn arákùnrin míì rí i pé Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gba àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́, àwọn náà sì gbà wọ́n sínú ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 11:​13-18) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn áńgẹ́lì ṣèrànwọ́ gidigidi fún ìgbìmọ̀ olùdarí láti rí i pé iṣẹ́ ìwàásù náà di ṣíṣe ó sì ń gbòòrò sí i.  (Ìṣe 5:​19, 20) Ohun kẹta ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ ìgbìmọ̀ olùdarí sọ́nà. Ìwé Mímọ́ làwọn alàgbà tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn náà máa ń tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń bójú tó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tàbí èyí tó jẹ mọ́ ìjọ.​—Ìṣe 1:​20-22; 15:​15-20.

7. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù ló darí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀?

7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbìmọ̀ olùdarí ló ń bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ láwọn ìjọ tó wà nígbà yẹn, wọ́n gbà pé Jésù ni Aṣáájú àwọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Ó [ìyẹn Kristi] fúnni ní àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì.’ Ó wá fi kún un pé: “Ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tí í ṣe orí, Kristi.” (Éfé. 4:​11, 15) Dípò tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn á fi máa fi orúkọ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì pe ara wọn, Bíbélì sọ pé ‘a tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni.’ (Ìṣe 11:26) Lóòótọ́ Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará pé kí wọ́n máa “di àwọn àṣà àfilénilọ́wọ́ mú ṣinṣin,” ìyẹn àwọn àṣà tó bá Ìwé Mímọ́ mu táwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tó ń múpò iwájú fi lélẹ̀. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù fi kún un: “Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin [títí kan àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ olùdarí] ni Kristi; . . . ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 11:​2, 3) Ó ṣe kedere pé Jésù Kristi tá a ṣe lógo ló ń darí ìjọ, òun alára sì wà lábẹ́ ìdarí Jèhófà tó jẹ́ Orí ohun gbogbo.

“IṢẸ́ YÌÍ KÌ Í ṢE TÈÈYÀN”

8, 9. Àwọn nǹkan wo ni Arákùnrin Russell ṣe bẹ̀rẹ̀ látọdún 1870?

8 Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1870, Arákùnrin Charles Taze Russell àtàwọn tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbìyànjú láti mú káwọn èèyàn máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. Kí wọ́n lè máa gbé ẹ̀kọ́ òtítọ́ jáde lónírúurú èdè, wọ́n dá àjọ kan sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1884, tí wọ́n pè ní Zion’s Watch Tower Tract Society, Arákùnrin Russell sì jẹ́ ààrẹ àjọ náà. * Ọwọ́ gidi ló fi mú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbangba-gbàǹgbà ló sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀kọ́ èké ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan àti àìleèkú ọkàn. Ó fòye mọ̀ pé nígbà tí Kristi bá pa dà wá, a ò ní fojú lásán rí i, àti pé “àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” máa dópin lọ́dún 1914. (Lúùkù 21:24) Arákùnrin Russell lo gbogbo àkókò rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló sì náwó nára kó lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó ṣe kedere pé, Arákùnrin Russell ni Jèhófà àti Jésù tó jẹ́ orí ìjọ lò lásìkò yẹn.

9 Arákùnrin Russell kò wá báwọn èèyàn á ṣe máa gbógo fún un. Lọ́dún 1896, ó sọ pé: “A kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa júbà wa tàbí àwọn ìwé wa, a ò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pè wá ní Ẹni Ọ̀wọ̀ tàbí Rábì. Bẹ́ẹ̀ la ò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa fi orúkọ wa pe ara rẹ̀.” Ó wá sọ nígbà tó yá pé: “Iṣẹ́ yìí kì í ṣe tèèyàn.”

10. (a) Ìgbà wo ni Jésù yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”? (b) Ṣàlàyé bí wọ́n ṣe fi ìyàtọ̀ sáàárín Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti àjọ Watch Tower Society bọ́dún ṣe ń gorí ọdún.

10 Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí Arákùnrin Russell kú, ìyẹn lọ́dún 1919, Jésù yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Kí nìdí tó fi yàn wọ́n? Ó fẹ́ kí wọ́n máa pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu’ fún àwọn ará ilé rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Mát. 24:45) Kódà láwọn ọdún yẹn, àwùjọ kéréje àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró kan wà ní oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n sì ń mú kó dé ọ̀dọ̀ àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Lẹ́yìn ọdún 1940, ọ̀rọ̀ náà “ìgbìmọ̀ olùdarí” bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Nígbà yẹn, a gbà pé àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà ni àwọn tó wà nínú àjọ Watch Tower Bible and Tract Society. Àmọ́ nígbà tó di  ọdún 1971, wọ́n jẹ́ kó ṣe kedere pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí tá a rí àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ yàtọ̀ sí àjọ Watch Tower Society àtàwọn olùdarí rẹ̀ tá a gbé kalẹ̀ lọ́nà òfin. Àtìgbà yẹn làwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí kò ti sí mọ́ lára àwọn tó ń darí àjọ Watch Tower Bible and Tract Society. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn arákùnrin tó jẹ́ ara “àgùntàn mìíràn” ni wọ́n ń darí ìgbòkègbodò àjọ Watch Tower Bible and Tract Society àtàwọn àjọ míì táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní. Èyí mú kí Ìgbìmọ̀ Olùdarí lè máa tọ́ wa sọ́nà kí wọ́n sì pọkàn pọ̀ sórí pípèsè àwọn ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí. (Jòh. 10:16; Ìṣe 6:4) Ilé Ìṣọ́ July 15, 2013 jẹ́ ká mọ̀ pé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró, àwọn ló sì para pọ̀ jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí.

Ìgbìmọ̀ olùdarí láwọn ọdún 1950

11. Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe máa ń ṣe iṣẹ́ wọn?

11 Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń panu pọ̀ ṣe ìpinnu. Lọ́nà wo? Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà máa ń ṣèpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èyí sì máa ń mú kí àárín wọn gún kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan. (Òwe 20:18) Nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ọdọọdún ni wọ́n máa ń yí ẹni tó jẹ́ alága pa dà torí pé kò sí èyíkéyìí lára wọn tó gbà pé òun lọ́lá ju àwọn tó kù lọ. (1 Pét. 5:1) Ohun kan náà ni ìgbìmọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò máa ń ṣe. Kò sí èyíkéyìí lára àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ka ara rẹ̀ sí ọ̀gá àwọn yòókù, kàkà bẹ́ẹ̀ arákùnrin ni wọ́n kara wọn sí, wọ́n sì gbà pé “ará ilé” làwọn àti pé ẹrú olóòótọ́ ló ń bọ́ àwọn tó sì ń bójú tó àwọn.

Jésù yan ẹrú olóòótọ́ lọ́dún 1919, àtìgbà yẹn sì ni ẹrú yìí ti ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwa èèyàn Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 10, 11)

“NÍ TI TÒÓTỌ́, TA NI ẸRÚ OLÓÒÓTỌ́ ÀTI OLÓYE?”

12. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò báyìí?

12 Ìgbìmọ̀ Olùdarí kò sọ pé Ọlọ́run mí sí àwọn, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe ẹni pípé tí kò lè ṣàṣìṣe. Torí náà, wọ́n lè ṣàṣìṣe nínú àlàyé tí wọ́n ń ṣe lórí ẹ̀kọ́ Bíbélì àti nínú àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń fún agboolé ìgbàgbọ́. Kódà, ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index ní ìsọ̀rí kan tá a pè ní “Beliefs Clarified.” Nínú rẹ̀, a to àwọn àtúnṣe tá a ṣe sáwọn ohun tá a gbà gbọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé látọdún 1870. * Ohun kan ni pé, Jésù ò sọ pé ẹrú olóòótọ́ á máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó pé pérépéré. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe máa dáhùn ìbéèrè Jésù pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye?” (Mát. 24:45) Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ni ẹrú náà? Ẹ jẹ́ ká jíròrò bí àwọn kókó mẹ́ta tó ran ìgbìmọ̀ olùdarí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ́wọ́ ṣe ń ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́.

13. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ń ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́?

13 Ẹ̀mí mímọ́ ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ti ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́ láti lóye àwọn òtítọ́ Bíbélì tí wọn kò lóye tẹ́lẹ̀. Àpẹẹrẹ kan làwọn àtúnṣe tó bá àwọn ohun tá a gbà gbọ́ bó ṣe wà nínú àwọn ìwé atọ́ka Index àti Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tá a tọ́ka sí nínú ìpínrọ̀ tó ṣáájú. Ó dájú pé kò sẹ́ni tó lè sọ pé ọpẹ́lọpẹ́ òun la fi ṣàwárí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” tá a sì ń ṣàlàyé wọn. (Ka 1 Kọ́ríńtì 2:10.) Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ náà ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ, pé: “Nǹkan wọ̀nyí ni àwa pẹ̀lú ń sọ, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi kọ́ni nípasẹ̀ ọgbọ́n ẹ̀dá ènìyàn, bí kò ṣe pẹ̀lú àwọn tí a fi kọ́ni nípasẹ̀ ẹ̀mí.” (1 Kọ́r. 2:13) Kí la máa sọ pé ó ń mú kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ túbọ̀ ṣe kedere tó sì ń mú kó gbòòrò sí i látọdún 1919, láìka ti pé ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ẹ̀sìn ti ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ àwọn èèyàn tí wọ́n sì ń ṣì wọ́n lọ́nà? Kò sí àlàyé míì ju pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló mú kó ṣeé ṣe.

14. Bó ṣe wà nínú Ìṣípayá 14:​6, 7, báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ń ran àwa èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ lóde òní?

 14 Àwọn áńgẹ́lì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Iṣẹ́ ńlá ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń ṣe torí pé àwọn ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù táwa ajíhìnrere tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ń ṣe kárí ayé. Kí la rò pé ó mú kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ náà láṣeyanjú? Òótọ́ kan ni pé, àwọn áńgẹ́lì ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. (Ka Ìṣípayá 14:​6, 7.) Àìmọye ìgbà làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ti kan ilẹ̀kùn àwọn èèyàn tó jẹ́ pé wọ́n á ní kò pẹ́ táwọn gbàdúrà pé kí Ọlọ́run rán ẹnì kan sáwọn! * Ohun míì tún ni pé wọ́n ń ṣenúnibíni sáwọn ará wa láwọn orílẹ̀-èdè kan, síbẹ̀ àwọn èèyàn ń tẹ́tí sí ìhìn rere, wọ́n sì ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ilẹ̀ náà. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tí kò bá sí ìtìlẹyìn àwọn áńgẹ́lì, kò ní ṣeé ṣe.

15. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn aṣáájú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì? Sọ àpẹẹrẹ kan.

15 Wọ́n gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ka Jòhánù 17:17.) Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1973. Nígbà tí Ile-Iṣọ Na February 1, 1974 ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dun 1973 yẹn, ó béèrè ìbéèrè kan pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn èèyàn tí kò tíì ṣíwọ́ nínú sìgá mímú àti àṣìlò tábà yẹ lẹ́ni tó lè ṣèrìbọmi?’ Ìtẹ̀jáde yẹn wá dáhùn pé: ‘Ẹ̀rí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé wọn ò yẹ.’ Lẹ́yìn tí Ilé Ìṣọ́ yẹn ti jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó ṣàlàyé pé bí ẹnì kan bá kọ̀ tí kò  jáwọ́ nínú sìgá mímú, kí wọ́n yọ onítọ̀hún lẹ́gbẹ́. (1 Kọ́r. 5:7; 2 Kọ́r. 7:1) Ó wá fi kún un pé: ‘Orí ìpinnu tá a dé yìí kì í ṣe bí ẹni pàṣẹ wàá tàbí bí ẹni jẹ gàba léni lórí. Ìpinnu náà lè dà bí èyí tó le, àmọ́ ìpinnu Ọlọ́run ni, ó sì wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.’ Ẹ̀sìn mélòó ló múra tán láti gbé gbogbo ìpinnu wọn karí Ìwé Mímọ́, kódà táwọn ìpinnu kan kò bá tiẹ̀ bá àwọn ọmọ ìjọ wọn lára mu? Ìwé kan tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “Ìgbà gbogbo làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì máa ń yí ẹ̀kọ́ wọn pa dà kí wọ́n lè tẹ̀ síbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ̀ sí.” Bó ṣe jẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń gbára lé dípò èrò èèyàn, ta la wá lè sọ pé ó ń darí àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí?

“Ẹ MÁA RÁNTÍ ÀWỌN TÍ Ń MÚ IPÒ IWÁJÚ”

16. Sọ ọ̀nà kan tá a lè gbà máa rántí Ìgbìmọ̀ Olùdarí.

16 Ka Hébérù 13:7. Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa “rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín” wa. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa rántí Ìgbìmọ̀ Olùdarí nínú àdúrà wa. (Éfé. 6:18) Ẹ wo iṣẹ́ bàǹtàbanta tí wọ́n ń ṣe, àwọn ló ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa, wọ́n ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé, wọ́n sì ń mójú tó ọ̀rọ̀ ìnáwó, ìyẹn owó táwọn èèyàn fi ń ti iṣẹ́ ìwàásù náà lẹ́yìn. Kò sí àní-àní pé ó yẹ ká máa rántí wọn ní gbogbo ìgbà tá a bá ń gbàdúrà!

17, 18. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Olùdarí? (b) Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń ti ẹrú olóòótọ́ àti Jésù lẹ́yìn?

17 Àmọ́ o, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan la fi ń rántí Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn bí wọ́n ṣe ń tọ́ wa sọ́nà. Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa, àwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ àyíká àti àgbègbè. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń yan àwọn alábòójútó àyíká, àwọn alábòójútó àyíká náà sì máa ń yan àwọn alàgbà ìjọ. Àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ń fi hàn pé àwọn ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Olùdarí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n ń gbà látọ̀dọ̀ wọn. Bí gbogbo wa bá ń fara wa sábẹ́ àwọn ọkùnrin tí Jésù ń lò láti máa múpò iwájú tá a sì ń ṣègbọràn sí wọn, ńṣe là ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wa.​—Héb. 13:17.

18 A tún lè fi hàn pé à ń rántí Ìgbìmọ̀ Olùdarí tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó ṣe tán, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n fara wé ìgbàgbọ́ àwọn tó ń múpò iwájú láàárín wọn. Ẹrú olóòótọ́ ń lo ìgbàgbọ́ tó lágbára torí pé wọ́n ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń rọ̀ wá pé káwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé ìwọ náà wà lára àwọn àgùntàn mìíràn tó ń ti àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí? Wo bí inú rẹ ṣe máa dùn tó nígbà tí Jésù Aṣáájú wa bá sọ pé: “Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, ẹ ti ṣe é fún mi.”​—Mát. 25:​34-40.

19. Ṣé wàá máa tẹ̀ lé Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wa láìbojú wẹ̀yìn? Kí nìdí?

19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti pa dà sọ́run, síbẹ̀ kò gbàgbé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Mát. 28:20) Ó mọ bí ẹ̀mí mímọ́, àwọn áńgẹ́lì àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran òun lọ́wọ́ láti múpò iwájú nígbà tó wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà. Torí náà, ó ń lo ẹ̀mí mímọ́, àwọn áńgẹ́lì àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ran ẹrú olóòótọ́ lọ́wọ́. Ẹrú olóòótọ́ yìí ń “tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ.” (Ìṣí. 14:4) Bá a ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ẹrú náà ń fún wa, ó ṣe kedere pé Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wa là ń tẹ̀ lé. Láìpẹ́, Jésù máa ṣamọ̀nà wa wọnú ayé tuntun níbi tá a ti máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìṣí. 7:​14-17) Ó dájú pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn èèyàn tí wọ́n ń pè ní aṣááju lónìí tó lè ṣe irú ìlérí bẹ́ẹ̀!

^ ìpínrọ̀ 3 Kò sí àní-àní pé Jèhófà dìídì ṣètò àwọn àpọ́sítélì méjìlá kí wọ́n lè jẹ́ “òkúta ìpìlẹ̀ méjìlá” ti Jerúsálẹ́mù Tuntun. (Ìṣí. 21:14) Torí náà, kò sídìí láti fi ẹlòmíì rọ́pò àpọ́sítélì èyíkéyìí tó bá jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú.

^ ìpínrọ̀ 8 Lọ́dún 1955, wọ́n yí orúkọ àjọ náà sí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.

^ ìpínrọ̀ 12 Tún wo ìsọ̀rí tá a pè ní “Ìlàlóye Nípa Àwọn Ohun Tá A Gbà Gbọ́” nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 14 Wo ìwé Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 58 sí 59.