NÍ March 26, 1937, àwọn ọkùnrin méjì kan wa ọkọ̀ akẹ́rù wọn lọ sílùú Sydney, nílẹ̀ Ọsirélíà, ó ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu, ọkọ̀ náà sì ti bu gan-an. Ọdún kan gbáko ni wọ́n fi rìnrìn-àjò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ kan kìlómítà lọ sáwọn ìgbèríko àtàwọn abúlé tó wà ní gbùngbùn ilẹ̀ Ọsirélíà kí wọ́n tó pa dà sí Sydney. Àmọ́, kí ni wọ́n ń wá kiri? Ṣé wọ́n kàn mọ̀lú lọ ni tàbí wọ́n lọ gbafẹ́? Rárá o. Arákùnrin Arthur Willis àti Bill Newlands wà lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara tó mú ìhìn rere Ìjọba Ọ̇lọ́run lọ sí àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Ọsirélíà.

Títí di ọdún 1929, ìwọ̀nba àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì * tó wà ní Ọsirélíà ti wàásù ní púpọ̀ lára àwọn ìlú tó wà létíkun. Aṣálẹ̀ làwọn gbùngbùn orílẹ̀-èdè náà, àwọn èèyàn tó ń gbébẹ̀ kò sì fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Aṣálẹ̀ yìí fẹ̀ gan-an, kódà ó ju ìlọ́po mẹ́fà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ. Bó ti wù kó rí, àwọn ará yẹn mọ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ jẹ́rìí Jésù “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” títí kan àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Ọsirélíà. (Ìṣe 1:⁠8) Àmọ́, báwo ni wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ tó ń kani láyà yìí? Wọ́n gbà pé Jèhófà máa bù kún ìsapá àwọn, torí náà wọ́n pinnu láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

ÀWỌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́

Lọ́dún 1929, àwọn ìjọ tó wà ní Queensland àti Western Australia ṣe àwọn ọkọ̀ akẹ́rù tó lágbára tó sì lè rìn nínú aṣálẹ̀. Ọkọ̀ náà ni wọ́n sì fi ń wàásù ní gbogbo aṣálẹ̀ tó wà lágbègbè yẹn. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó jẹ́ akínkanjú tó sì mọ mọ́tò tún ṣe ló rìnrìn-àjò náà. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí wàásù láwọn ibi táwa Ẹlẹ́rìí ò tíì dé rí.

Kẹ̀kẹ́ làwọn aṣáájú-ọ̀nà tí kò ní mọ́tò máa ń gùn lọ sáwọn ìgbèríkọ. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Bennett Brickell tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23]. Lọ́dún 1932, ó gbéra láti ìlú Rockhampton, ìpínlẹ̀ Queensland, láti lọ wàásù láwọn ìgbèríko tó wà ní apá àríwá ìlú náà, oṣù márùn-ún ló sì lò níbẹ̀. Orí kẹ̀kẹ́ kan ṣoṣo yìí ló gbé bùláńkẹ́ẹ̀tì, aṣọ, oúnjẹ àti ìwé rẹpẹtẹ sí. Nígbà tí táyà kẹ̀kẹ́ rẹ̀ lá, ó ṣì ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, pẹ̀lú ìdánilójú pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú òun. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í ti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ fún ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kìlómítà, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kú sójú ọ̀nà ibẹ̀ torí òùngbẹ. Ohun tó lé lọ́gbọ̀n ọdún ni Arákùnrin Brickell fi rin ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà jákèjádò ilẹ̀ Ọsirélíà, ó máa ń gun kẹ̀kẹ́ tàbí alùpùpù, ó sì máa ń wọ mọ́tò nígbà míì. Òun ló kọ́kọ́ wàásù fáwọn ẹ̀yà  Aborigine, ìyẹn àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ọsirélíà, ó sì ṣèrànwọ́ láti dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀. Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ ọ́n dáadáa, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún un gan-an.

WỌ́N BORÍ ÌṢÒRO

Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ilẹ̀ táwọn tó ń gbé lójú kan ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, Ọsirélíà làkọ́kọ́, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tàwọn tó ń gbé láwọn ìgbèríko tó jẹ́ ení-tere èjì-tere. Èyí mú kó pọn dandan fún àwọn èèyàn Jèhófà láti máa wá àwọn èèyàn náà lọ títí kan àwọn tó ń gbé níbi tó jìnnà jù lọ nílẹ̀ náà kí wọ́n lè wàásù fún wọn.

Àpẹẹrẹ kan ni ti Stuart Keltie àti William Torrington tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lọ́dún 1933, wọ́n gba aṣálẹ̀ títẹ́rẹrẹ kan tó ń jẹ́ Simpson Desert kọjá, iyanrìn ló sì kún aṣálẹ̀ náà. Wọ́n fẹ́ lọ wàásù nílùú Alice Springs, tó wà ní gbùngbùn ilẹ̀ Ọsirélíà. Ẹnu ìrìn àjò yẹn ni mọ́tò wọn bà jẹ́ sí, torí náà wọ́n gbé mọ́tò náà sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ̀ kan ni Arákùnrin Keltie ní, tó sì jẹ́ pé igi ló wà ní ẹsẹ̀ kejì, kò tìtorí ìyẹn sọ pé òun ò lọ mọ́, ṣe ló gun ràkúnmí. Ìsapá àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí ò já sásán torí pé nígbà tó yá, wọ́n pàdé ọkùnrin kan tó ní òtẹ́ẹ̀lì nílùú William Creek tó jẹ́ ibùdókọ̀ rélùwéè. Charles Bernhardt lorúkọ ọkùnrin náà. Nígbà tó yá, ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ta òtẹ́ẹ̀lì rẹ̀, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà. Odindi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lòun nìkan fi dá wàásù láwọn ilẹ̀ olóoru tó jìnnà jù lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà.

Arthur Willis ń múra láti lọ wàásù láwọn ìgbèríko Ọsirélíà.​—Perth, Western Australia, 1936

Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wàásù nígbà yẹn nílò ìgboyà àti ìforítì kí wọ́n lè borí àwọn ìṣòro tí wọ́n dojú kọ. Nígbà kan táwọn Arákùnrin Arthur Willis àti Bill Newlands tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ lọ wàásù láwọn ìgbèríko tó wà ní Ọsirélíà, ó gbà wọ́n ní ọ̀sẹ̀ méjì kí wọ́n tó dé ibi tí wọ́n ń lọ. Ìdí sì ni pé òjò rẹpẹtẹ ti rọ̀, aṣálẹ̀ náà sì ti di ẹrọ̀fọ̀, ìyẹn sì mú kí wọ́n ṣe làálàá gan-an kí wọ́n tó lè wa mọ́tò wọn gba ọ̀nà yẹn. Àbí ẹ ò rí nǹkan, kéèyàn fi ọ̀sẹ̀ méjì rin kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n [32] péré! Nígbà míì, ṣe ni wọ́n máa ń làágùn yọ̀bọ̀ nínú oòrùn tó ń mú ganrín-ganrín bí wọ́n ṣe ń wa mọ́tò wọn gba inú iyanrìn tó ga bí òkè, àtàwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó jẹ́ kìkì òkúta, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n tún gbanú odò kọjá. Lọ́pọ̀ ìgbà, mọ́tò wọn máa ń bà jẹ́, tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fẹsẹ̀ rìn tàbí kí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ lọ sí abúlé tó wà nítòsí, ó sì máa ń gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ nígbà míì. Lẹ́yìn ìyẹn wọ́n á ní sùúrù fún ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan kí ohun tí wọ́n á fi pààrọ̀ ohun tó bà jẹ́ náà tó tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Láìka gbogbo ìṣòro yìí sí, wọ́n pinnu pé àwọn á máa bá iṣẹ́ náà lọ. Nígbà tí Arthur Willis máa sọ bó ṣe rí lára rẹ̀, ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé ìròyìn The Golden Age ló sọ, pé: “Kò sí ọ̀nà tó burú jù tàbí jìn jù fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti lọ wàásù.”

Arákùnrin Charles Harris tó ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé bí àwọn ìgbèríko yẹn ṣe wà níbi àdádó àti ìyà téèyàn máa jẹ kó tó débẹ̀ mú kóun túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ó tún sọ pé: “Èèyàn á gbádùn ayé ẹ̀ gan-an tó bá jẹ́ ìwọ̀nba ẹrù lèèyàn ní. Tí Jésù bá lè sùn níta nígbà míì, ó yẹ káwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí iṣẹ́ ìsìn wa bá gbà bẹ́ẹ̀.” Ohun tí púpọ̀ lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà sì ṣe nìyẹn. A dúpẹ́ pé wọn ò jẹ́ kó sú àwọn, ìyẹn ló sì mú kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run débi gbogbo ní Ọsirélíà, ọ̀pọ̀ ló sì tipa bẹ́ẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 4 Ọdún 1931 làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.​—Aísá. 43:10.