“Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti . . . ọ̀dọ̀ Baba.”​JÁK. 1:17.

ORIN: 148, 109

1. Àwọn ìbùkún wo ni ìràpadà mú kó ṣeé ṣe?

Ọ̀PỌ̀ ìbùkún ni ìràpadà tí Jésù Kristi ṣe ń mú wá fáráyé. Ìràpadà ló mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo lára àtọmọdọ́mọ Ádámù láti pa dà di ara ìdílé Ọlọ́run. Ìràpadà yìí náà láá mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun. Bó ti wù kó rí, ohun tí ìràpadà Kristi ṣe kọjá àǹfààní ayérayé táwọn adúróṣinṣin máa gbádùn. Bí Jésù ṣe fẹ̀mí rẹ̀ rúbọ tó sì fi hàn pé olódodo ni Jèhófà mú kó lè yanjú ọ̀ràn kan tó ṣe pàtàkì láyé àti lọ́run.​—Héb. 1:8, 9.

2. (a) Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì láyé àti lọ́run wo ló wà nínú àdúrà Jésù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Ní nǹkan bí ọdún méjì kí Jésù tó fẹ̀mí rẹ̀ rúbọ, ó ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mát. 6:9, 10)  Ká lè túbọ̀ mọyì ìràpadà náà, a máa jíròrò bí ìràpadà ṣe kan ọ̀rọ̀ sísọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, bó ṣe kan ìṣàkoso Ìjọba Ọlọ́run àti bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ.

“KÍ ORÚKỌ RẸ DI SÍSỌ DI MÍMỌ́”

3. Kí ni orúkọ Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀, báwo sì ni Sátánì ṣe ba orúkọ mímọ́ náà jẹ́?

3 Ohun àkọ́kọ́ tí Jésù ní ká máa gbàdúrà fún ni pé kí orúkọ Ọlọ́run di èyí tá a sọ di mímọ́. Orúkọ Jèhófà jẹ́ ká mọ bí ipò rẹ̀ ṣe ga lọ́lá tó, bó ṣe jẹ́ ẹni tí iyì rẹ̀ kò láfiwé tó sì tún jẹ́ ẹni mímọ́ jù lọ. Nínú àdúrà míì tí Jésù gbà, ó pe Jèhófà ní “Baba mímọ́.” (Jòh. 17:11) Torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀ náà jẹ́ mímọ́. Síbẹ̀, Sátánì dọ́gbọ́n fẹ̀sùn kan Jèhófà ní ọgbà Édẹ́nì pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fún èèyàn lófin. Ṣe ni Sátánì ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́ nígbà tó parọ́ mọ́ ọn.​—Jẹ́n. 3:1-5.

4. Báwo ni Jésù ṣe sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́?

4 Jésù ní tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà gan-an. (Jòh. 17:​25, 26) Ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. (Ka Sáàmù 40:​8-10.) Ó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ó tọ́, ó sì yẹ pé kí Jèhófà fún àwa èèyàn lófin. Kódà nígbà tí Sátánì mú káwọn èèyàn dá Jésù lóró tí wọ́n sì pa á, Jésù jẹ́ adúróṣinṣin sí Baba rẹ̀ ọ̀run. Bó ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà mú kó ṣe kedere pé èèyàn pípé lè ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sáwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run.

5. Báwo làwa náà ṣe lè sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́?

5 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ìwà wa. Jèhófà ní ká jẹ́ mímọ́. (Ka 1 Pétérù 1:15, 16.) Èyí gba pé ká jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo, ká sì máa fi gbogbo ọkàn wa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. Táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wa, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pa àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà mọ́. Bá a ṣe ń hùwà mímọ́, ṣe là ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn, tá a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún orúkọ Jèhófà. (Mát. 5:14-16) Torí pé a jẹ́ èèyàn Jèhófà, ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa fi hàn pé àwọn òfin Jèhófà ṣàǹfààní àti pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà. Nítorí àìpé wa, gbogbo wa la máa ń ṣàsìṣe. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ká sì jáwọ́ nínú ìwà èyíkéyìí tó lè tàbùkù sórúkọ Jèhófà.​—Sm. 79:9.

6. Kí ló mú kí Jèhófà kà wá sí olódodo bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá?

6 Lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi, Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Jèhófà máa ń gbà káwọn tó bá ya ara wọn sí mímọ́ fún un di ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó ka àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sí olódodo, ó sì gbà wọ́n ṣọmọ. Bákan náà, ó ka “àwọn àgùntàn mìíràn” sí olódodo, ó sì kà wọ́n sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jòh. 10:16; Róòmù 5:1, 2; Ják. 2:​21-25) Kódà ní báyìí, ìràpadà ń mú ká rí ojúure Jèhófà Baba wa, a sì ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́.

“KÍ ÌJỌBA RẸ DÉ”

7. Àwọn ìbùkún wo ni ìràpadà máa mú wá lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?

7 Nínú àdúrà tí Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa gbà, ó tún sọ pé: “Kí Ìjọba rẹ dé.” Báwo ni ìràpadà ṣe kan ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run? Ìràpadà ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] láti di ọba àti àlùfáà pẹ̀lú  Kristi lọ́run. (Ìṣí. 5:9, 10; 14:1) Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ló máa ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n á mú káwọn èèyàn onígbọràn jàǹfààní ìràpadà náà jálẹ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún tí wọ́n á fi ṣàkóso. Ayé á di Párádísè, gbogbo àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ á di pípé, èyí á sì mú káwọn tó wà nínú ìdílé Ọlọ́run, láyé àti lọ́run wà níṣọ̀kan. (Ìṣí. 5:13; 20:6) Jésù máa fọ́ orí ejò náà yán-án yán, á sì palẹ̀ gbogbo ọ̀tẹ̀ Sátánì mọ́ pátápátá.​—Jẹ́n. 3:15.

8. (a) Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ bí Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó? (b) Báwo la ṣe ń fi hàn pé ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ni wá?

8 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ bí Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó. Kété lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi ló bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ níbi gbogbo tó dé. (Lúùkù 4:43) Nígbà tó ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ìdágbére kó tó pa dà sọ́run, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹ́rìí òun “dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:6-8) Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe máa mú káwọn èèyàn kárí ayé mọ̀ nípa ìràpadà, á sì jẹ́ kí wọ́n di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Lónìí, à ń fi hàn pé a jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run bá a ṣe ń ran àwọn arákùnrin Kristi lọ́wọ́ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run níbi gbogbo láyé.​—Mát. 24:14; 25:40.

“KÍ ÌFẸ́ RẸ ṢẸ”

9. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jéhófà máa mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ fún aráyé?

9 Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ”? Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá tó dá ohun gbogbo. Awí-bẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ ni, ohun tó bá sì ti sọ gbọ́dọ̀ ṣẹ dandan. (Aísá. 55:11) Láìka ọ̀tẹ̀ Sátánì sí, Jèhófà máa mú ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé ṣẹ. Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ ni pé káwọn ọmọ Ádámù àti Éfà tó jẹ́ pípé kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:28) Ká sọ pé Ádámù àti Éfà kú láìbímọ ni, ìfẹ́ Ọlọ́run pé kí wọ́n fọmọ wọn kún ayé kò bá má ṣẹ. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n ní àwọn ọmọ. Nípasẹ̀ ìràpadà, Ọlọ́run á mú káwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ di pípé kí wọ́n sì wà láàyè títí láé. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an, ìfẹ́ rẹ̀ sì ni pé káwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn gbádùn ìgbésí ayé wọn.

10. Àǹfààní wo ni ìràpadà máa ṣe àwọn tó ti kú?

10 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹgbàágbèje èèyàn tó ti kú láìmọ Jèhófà, tí wọn ò sì jọ́sìn rẹ̀? Àjíǹde àwọn òkú máa wà lọ́lá ìràpadà Kristi. Baba wa ọ̀run máa jí wọn dìde, á sì fún wọn láǹfààní àtikẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ rẹ̀, wọ́n á sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìṣe 24:15) Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn wà láàyè ni, kò fẹ́ ká kú. Torí pé òun ni Orísun ìyè, tó bá ti jí àwọn òkú dìde, á di Baba wọn. (Sm. 36:9) Òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú àdúrà yẹn nígbà tó pe Jèhófà ní “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mát. 6:9) Jèhófà máa lo Jésù láti jí àwọn òkú dìde. (Jòh. 6:​40, 44) Nígbà tí ayé bá di Párádísè, Jésù máa mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé òun ni “àjíǹde àti ìyè.”​—Jòh.11:25.

11. Kí ni ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá”?

11 Kì í ṣe àwọn èèyàn kéréje nìkan ló máa jàǹfààní àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe, torí Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni arákùnrin àti arábìnrin àti ìyá mi.” (Máàkù 3:35) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́  ni pé kí àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n máa jọ́sìn rẹ̀. Àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà Kristi tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa wà lára àwọn tó máa sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.”​—Ìṣí. 7:9, 10.

12. Báwo ni àdúrà àwòṣe náà ṣe jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún àwọn èèyàn onígbọràn?

12 Jésù jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún aráyé onígbọràn nínú àdúrà tó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Torí náà, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. (Aísá. 8:13) Orúkọ Jésù túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà,” ìràpadà tí Jésù ṣe ló máa mú ká ní ìgbàlà, ìyẹn sì máa mú ògo àti ọlá wá fún orúkọ Jèhófà. Bákan náà, Ìjọba Ọlọ́run máa mú káwọn èèyàn onígbọràn gbádùn àwọn àǹfààní tí ìràpadà máa mú wá. Àdúrà àwòṣe tí Jésù sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹ́ kó dá wa lójú pé kò sóhun tó lè mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run má ṣẹ.​—Sm. 135:6; Aísá. 46:9, 10.

FI HÀN PÉ O MỌYÌ ÌRÀPADÀ NÁÀ

13. Kí ni ìrìbọmi tá a ṣe fi hàn?

13 Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì ìràpadà náà ni pé ká lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà, ká ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ká sì ṣe ìrìbọmi. Ìrìbọmi tá a ṣe fi hàn pé “a jẹ́ ti Jèhófà.” (Róòmù 14:8) Ó fi hàn pé à ń bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (1 Pét. 3:21) Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà yẹn torí pé ó máa ń wo ọlá ikú Kristi mọ́ wa lára. Ó dá wa lójú hán-ún pé Jèhófà máa fún wa ní gbogbo ohun tó ṣèlérí.​—Róòmù 8:32.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìràpadà náà? (Wo ìpínrọ̀ 13 àti 14)

14. Kí nìdí tí Jésù fi pàṣẹ pé ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa?

 14 Kí lọ̀nà míì tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì ìràpadà náà? Torí pé ìfẹ́ ló ń mú kí Jèhófà ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe, ó fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ máa fìfẹ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. (1 Jòh. 4:​8-11) A lè fi hàn pé a fẹ́ jẹ́ “ọmọ Baba [wa] tí ń bẹ ní ọ̀run” tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn aládùúgbò wa. (Mát. 5:43-48) A rántí pé lẹ́yìn tí Jésù ní ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó tún sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. (Mát. 22:37-40) Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa ni pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn bí Jésù ṣe pa á láṣẹ. Bá a ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, ńṣe là ń gbé ògo Ọlọ́run yọ. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run tó lè “di pípé nínú wa,” ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, pàápàá jù lọ àwọn ará wa.​—1 Jòh. 4:12, 20.

JÈHÓFÀ MÁA MÚ “ÀSÌKÒ TÍTUNILÁRA” WÁ

15. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ń ṣe fún wa báyìí? (b) Àwọn ìbùkún wo la máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú?

15 Tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà, Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá pátápátá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé Jèhófà máa ‘pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́.’ (Ka Ìṣe 3:19-21.) Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jèhófà ti gba àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣọmọ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. (Róòmù 8:​15-17) Ní ti àwa “àgùntàn mìíràn,” ṣe lọ̀rọ̀ wa dà bí ìgbà tí Jèhófà kọ orúkọ wa sílẹ̀ pé òun máa gbà wá ṣọmọ. Lẹ́yìn tá a bá ti di pípé, tá a sì ti yege ìdánwò ìkẹyìn, Jèhófà máa gbà wá ṣọmọ, bí ìgbà tó buwọ́ lu ìwé tó kọ orúkọ wa sí. (Róòmù 8:20, 21; Ìṣí. 20:7-9) Títí ayé ni Jèhófà á máa nífẹ̀ẹ́ àwa ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Títí láé sì ni ìràpadà náà á máa ṣe wá láǹfààní. (Héb. 9:12) Àǹfààńí tí ẹ̀bùn yìí ń ṣe wá kò ní pẹ̀dín láé. Kò sẹ́ni náà tàbí ohunkóhun tó lè gba ẹ̀bùn náà lọ́wọ́ wa.

16. Ìràpadà mú ká bọ́ lọ́wọ́ àwọn nǹkan wo?

16 Kò sí ohun tí Èṣù lè ṣe tó lè ní káwọn tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn má di ara ìdílé Jèhófà nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Jésù ti wá sáyé, ó sì ti kú “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.” Torí náà, ó ti san ìràpadà náà, kò sì ní tún un san mọ́. (Héb. 9:​24-26) Ìràpadà náà mú ká bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. Ọpẹ́lọpẹ́ Kristi tó kú fún wa, a ti bọ́ lọ́wọ́ ayé tó wà lábẹ́ àkóso Sátánì, a ò sì bẹ̀rù ikú mọ́.​—Héb. 2:14, 15.

17. Kí ni ìfẹ́ Jèhófà túmọ̀ sí fún ẹ?

17 Àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣeé fọkàn tán. Bó ṣe dájú pé bí ilẹ̀ bá ṣú ilẹ̀ máa mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló dá wa lójú pé Jèhófà ò ní já wa kulẹ̀ láé. Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà kì í yí pa dà. (Mál. 3:6) Ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa kọjá ìwàláàyè. Ó fún wa ní ìfẹ́ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Àwa fúnra wa sì ti wá mọ̀, a sì ti gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní nínú ọ̀ràn tiwa gbọ́. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:16) Ó dájú pé ayé yìí máa di Párádísè. Àá gbádùn ara wa gan-an, àá sì gbé ìfẹ́ Ọlọ́run yọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pa ohùn wa pọ̀ mọ́ tàwọn áńgẹ́lì lókè ọ̀run tí wọ́n ń sọ pé: “Ìbùkún àti ògo àti ọgbọ́n àti ìdúpẹ́ àti ọlá àti agbára àti okun ni fún Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé.Àmín.”​—Ìṣí. 7:12.