Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) February 2017

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti April 3 sí 30, 2017 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ohun Tí Jèhófà Ní Lọ́kàn Máa Ṣẹ!

Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ayé àti àwa èèyàn? Kí nìdí tí nǹkan kò fi rí bó ṣe fẹ́ báyìí? Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìràpadà tí Jésù san ló máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ?

Ìràpadà​—“Ọrẹ Pípé” Tí Baba Fún Wa

Ìràpadà tí Jésù ṣe mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún wa, àmọ́ ó tún yanjú ọ̀ràn kan tó ṣe pàtàkì láyé àti lọ́run.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Fi Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Hàn sí Wa Lónírúurú Ọ̀nà

Douglas àti Mary Guest jọlá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní Kánádà àtìgbà tí wọ́n ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Bìràsílì àti Pọ́túgàl.

Jèhófà Ń Darí Àwọn Èèyàn Rẹ̀

Nígbà àtijọ́, Jèhófà lo àwọn èèyàn kan láti darí àwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn ẹ̀rí wo ló mú ká gbà pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run ti àwọn wọ̀nyí lẹ́yìn?

Ta Ló Ń Darí Àwa Èèyàn Ọlọ́run Lónìí?

Jésù ṣèlérí pé òun máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn òun títí di ìparí ètò àwọn nǹkan. Báwo ló ṣe ń darí àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà kò ní “jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra.” Ṣé èyí túmọ̀ sí pé Jèhófà ti kọ́kọ́ máa ń díwọ̀n ohun tá a lè mú mọ́ra kó tó wá pinnu irú àdánwò táá jẹ́ kó dé bá wa?

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

“Kò Sí Ọ̀nà Tó Burú Jù Tàbí Jìn Jù”

Níparí àwọn ọdún 1920 sí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930, àwọn aṣáájú-ọ̀nà fi ìtara wọn hàn nígbà tí wọ́n wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé àwọn ìgbèríko Ọsirélíà.