Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Ó dáa, wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí:

Táwọn òbí tó ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì bá fẹ́ ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìjọ tó ń sọ èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa ló yẹ kí wọ́n lọ?

Àwọn ọmọ máa kọ́ èdè tí wọ́n ń sọ nílùú tí wọ́n kó lọ níléèwé tàbí kí wọ́n kọ́ ọ ládùúgbò. Ó máa ṣe àwọn ọmọ yín láǹfààní tí wọ́n bá gbọ́ ju èdè kan lọ. Ó yẹ káwọn òbí wo èdè tó máa mú kó rọrùn fáwọn ọmọ wọn láti lóye òtítọ́, lẹ́yìn náà wọ́n máa pinnu ìjọ tí wọ́n máa lọ, bóyá ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn ni àbí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ìlú tí wọ́n kó lọ. Bí àwọn ọmọ ṣe máa sún mọ́ Jèhófà ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù sáwọn òbí Kristẹni, kì í ṣe ohun táwọn fúnra wọn fẹ́.​—w17.05, ojú ìwé 9 sí 11.

Nígbà tí Jésù bi Pétérù pé: “Ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ bí?” kí ni “ìwọ̀nyí” tí Jésù sọ túmọ̀ sí? (Jòh. 21:15)

Ó jọ pé àwọn ẹja tí Pétérù pa ni Jésù ń sọ, ó sì lè jẹ́ òwò ẹja tí Pétérù ń ṣe. Lẹ́yìn tí Jésù kú, Pétérù pa dà sídìí òwò ẹja tó ń ṣe tẹ́lẹ̀. Torí náà, kò yẹ káwa Kristẹni jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa dí ìjọsìn wa lọ́wọ́.​—w17.05, ojú ìwé 22 àti 23.

Kí nìdí tí Ábúráhámù fí ní kí Sárà pe ara rẹ̀ ní arábìnrin òun? (Jẹ́n. 12:​10-13)

Ọbàkan Ábúráhámù ni Sárà. Tí Sárà bá sọ pé ìyàwó Ábúráhámù lòun wọ́n lè pa Ábúráhámù, Ábúráhámù ò sì ní lè ní irú ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí fún un.​—wp17.3, ojú ìwé 14 àti 15.

Báwo ni Elias Hutter ṣe ran àwọn tó fẹ́ kọ́ èdè Hébérù lọ́wọ́?

Ó fẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú ní tààràtà, àwọn ọ̀rọ̀ àsomọ́ tó máa ń ṣáájú àtàwọn tó máa ń kẹ́yìn ọ̀rọ̀. Ó fi lẹ́tà tó fún pọ̀ tẹ àwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, àmọ́ àwọn lẹ́tà tó ní àlàfo láàárín ló fi tẹ àwọn ọ̀rọ̀ àsomọ́ tó máa ń ṣáájú àtàwọn tó máa ń kẹ́yìn ọ̀rọ̀. Wọ́n lo irú ọgbọ́n yìí nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures​—With References.​—wp17.4, ojú ìwé 11 àti 12.

Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí Kristẹni kan fi sọ́kàn tó bá ń ronú pé kóun ní ìbọn láti dáàbò bo ara òun lọ́wọ́ àwọn olubi?

Lára ohun tó yẹ kó fi sọ́kàn ni pé: Ẹ̀mí ṣeyebíye lójú Jèhófà. Jésù ò sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n mú idà dání kí wọ́n lè fi dáàbò bo ara wọn. (Lúùkù 22:​36, 38) Torí náà, ó yẹ káwa èèyàn Ọlọ́run fi idà wa rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀. Bákan náà, ẹ̀mí ṣe pàtàkì ju ohun ìní tara lọ. A kì í ṣe ohun tó máa da ẹ̀rí ọkàn àwọn míì láàmú, a sì máa ń sapá láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere. (2 Kọ́r. 4:2)​—w17.07, ojú ìwé 31 àti 32.

Kí nìdí tí ohun tí Mátíù àti Lúùkù sọ nípa ìgbà tí Jésù wà ní kékeré fi yàtọ̀ síra?

Mátíù sọ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù, ohun tí Jósẹ́fù pinnu láti ṣe nígbà tó gbọ́ pé Màríà lóyún àti àlá kan tí Jósẹ́fù lá níbi tí áńgẹ́lì kan ti sọ fún un pé kó sá lọ sí Íjíbítì. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún sọ nípa àlá míì tí Jósẹ́fù lá níbi tí áńgẹ́lì kan ti sọ fún un pé kó pa dà sílẹ̀ Ísírẹ́lì àti bó ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Màríà ni àkọsílẹ̀ Lúùkù dá lé ní tiẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ nípa ìgbà tí Màríà lọ kí Èlísábẹ́tì àtohun tí Màríà ṣe nígbà tí Jésù dúró ní tẹ́ńpìlì.​—w17.08, ojú ìwé 32.

Kí ni díẹ̀ lára ìṣòro tí Bíbélì ti là já?

Àwọn ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n lò nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ ń yí pa dà bọ́dún ṣe ń gorí ọdún. Bákan náà, bí nǹkan ṣe ń yí pa dà lágbo òṣèlú ti mú kí èdè àjùmọ̀lò yí pa dà. Yàtọ̀ síyẹn, lemọ́lemọ́ làwọn èèyàn ń ta ko iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì.​—w17.09, ojú ìwé 19 sí 21.

Ṣé o ní áńgẹ́lì tó ń dáàbò bò ẹ́?

Rárá. Lóòótọ́, ìgbà kan wà tí Jésù sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹ kò tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí [ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù]; nítorí mo sọ fún yín pé nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mát. 18:10) Ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé àwọn áńgẹ́lì máa ń kíyè sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn òun, kì í ṣe pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní áńgẹ́lì tó ń dáàbò bò ó.​—wp17.5, ojú ìwé 5.

Ìfẹ́ wo ló ga jù?

Ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà, ìyẹn a·gaʹpe, ni ìfẹ́ tó ga jù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ yìí máa ń mú ká lọ́yàyà, ká sì kóni mọ́ra, ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi í hàn ni pé ká máa lo ara wa fáwọn míì.​—w17.10, ojú ìwé 7.