Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  December 2017

“Mo Mọ̀ Pé Yóò Dìde”

“Mo Mọ̀ Pé Yóò Dìde”

“Ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.”​—⁠JÒH. 11:⁠11.

ORIN: 142129

1. Kí ló dá Màtá lójú pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí àbúrò òun? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

MÀTÁ tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀. Ìdí sì ni pé Lásárù àbúrò rẹ̀ ti kú. Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tó lè tù ú nínú? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé Jésù fi dá a lójú pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Jésù sọ lè má mú gbogbo ẹ̀dùn ọkàn tí Màtá ní kúrò, síbẹ̀ ó gbà pé òótọ́ ni Jésù sọ. Ó ní: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòh. 11:​20-24) Ó dá Màtá lójú pé àjíǹde máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. Jésù wá ṣe iṣẹ́ ìyanu, ó jí Lásárù dìde lọ́jọ́ yẹn gan-an.

2. Kí nìdí tó fi yẹ kó o nírú ìdánilójú tí Màtá ní?

2 A ò lè retí pé kí Jésù tàbí Jèhófà Baba rẹ̀ ṣe irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ fún wa lónìí. Àmọ́, ǹjẹ́ ó dá ẹ lójú bíi ti Mátà pé èèyàn rẹ tó kú máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú? Bóyá ọkọ tàbí aya rẹ ló kú, ó sì lè jẹ́ bàbá rẹ, ìyá rẹ tàbí àwọn òbí rẹ àgbà. Bóyá ọmọ rẹ ni kò sì sí mọ́. Ó ń ṣe ẹ́ bíi pé kọ́jọ́ náà ti dé kẹ́ ẹ lè dì mọ́ra, kẹ́ ẹ bá ara yín sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ sì jọ máa rẹ́rìn-ín. Bíi ti  Màtá, ìwọ náà lè fi ìdánilójú sọ pé: ‘Mo mọ̀ pé èèyàn mi tó kú máa jíǹde nígbà àjíǹde.’ Síbẹ̀, á dáa kí olúkúlùkù wa ronú lórí ìdí tí òun fi gbà pé lóòótọ́ ni àjíǹde máa wáyé.

3, 4. Àwọn wo ni Jésù ti jíǹde, báwo nìyẹn sì ṣe mú kí ìrètí àjíǹde túbọ̀ dá Màtá lójú?

3 Kò dájú pé Màtá tó ń gbé nítòsí Jerúsálẹ́mù wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù jí ọmọ opó kan dìde nítòsí Náínì nílùú Gálílì. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kó gbọ́ nípa rẹ̀. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kó ti gbọ́ nípa ọmọbìnrin Jáírù tí Jésù jí dìde. Ó ṣe tán, àwọn tọ́rọ̀ ṣojú wọn “mọ̀ pé [ọmọbìnrin náà] ti kú.” Síbẹ̀, Jésù di ọwọ́ ọmọbìnrin náà mú, ó sì sọ pé: “Ọmọdébìnrin, dìde!” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì dìde. (Lúùkù 7:​11-17; 8:​41, 42, 49-55) Màtá àti Màríà mọ̀ pé Jésù lágbára láti wo aláìsàn sàn. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sọ pé ká ní Jésù wà lọ́dọ̀ àwọn ni, Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ ì bá má kú. Àmọ́ ní báyìí tó ti kú, kí ló dá wọn lójú? Kíyè sí i pé Màtá sọ pé Lásárù máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn “ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Kí ló jẹ́ kó dá a lójú pé àbúrò rẹ̀ máa jíǹde? Kí nìdí tó fi lè dá ìwọ náà lójú pé àwọn òkú máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú àti pé ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn èèyàn tìẹ náà?

4 Àwọn ìdí pàtàkì wà tó fi yẹ kó o gbà pé àjíǹde máa wáyé. Bá a ṣe ń jíròrò díẹ̀ lára wọn, wàá rí àwọn ohun kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣeé ṣe kó o má tiẹ̀ ronú kàn tẹ́lẹ̀, àmọ́ wọ́n á jẹ́ kí ìrètí tó o ní láti rí èèyàn rẹ tó ti kú túbọ̀ dájú.

ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ TÓ FÚN WA NÍRÈTÍ!

5. Kí ló mú kí Màtá gbà pé Lásárù máa jíǹde?

5 Ẹ rántí pé Màtá ò sọ pé ‘Mo pé yóò dìde.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde.” Àwọn iṣẹ́ ìyanu táwọn wòlíì ti ṣe kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló jẹ́ kí Màtá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú bẹ́ẹ̀. Ìgbà tí Màtá wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti kọ́ nípa àwọn àjíǹde yìí nílé àti nínú sínágọ́gù. Ó ṣeé ṣe kó rántí àwọn àjíǹde mẹ́ta tó wà nínú Ìwé Mímọ́.

6. Iṣẹ́ ìyanu àrà ọ̀tọ̀ wo ni Èlíjà ṣe, báwo ni iṣẹ́ ìyanu yìí ṣe rí lára Màtá?

6 Nígbà tí Èlíjà wà láyé, Ọlọ́run fún un lágbára láti jí òkú dìde, ìyẹn sì ni àjíǹde àkọ́kọ́ tó wáyé. Ní Sáréfátì, ìyẹn ìlú kan tó wà ní etíkun Fòníṣíà, opó aláìní kan fi inú rere hàn sí wòlíì Èlíjà. Ọlọ́run wá mú kí ìyẹ̀fun àti òróró obìnrin náà pọ̀ lọ́nà ìyanu débi pé obìnrin náà àti ọmọ rẹ̀ ń jẹun lọ títí ìyàn tó mú nígbà yẹn fi dópin. (1 Ọba 17:​8-16) Nígbà tó yá, ọmọ obìnrin náà ṣàìsàn, ó sì kú. Bí Èlíjà ṣe wá ràn án lọ́wọ́ nìyẹn. Èlíjà na ara lé òkú ọmọ náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà pé: “Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, mú kí ọkàn ọmọ yìí padà wá sínú rẹ̀.” Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Ọlọ́run gbọ́ àdúrà Èlíjà, ẹ̀mí ọmọ náà sì pa dà sínú rẹ̀. Àjíǹde àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn nìyẹn. (Ka 1 Àwọn Ọba 17:​17-24.) Ó dájú pé Màtá ti gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu yìí.

7, 8. (a) Báwo ni Èlíṣà ṣe ran obìnrin kan lọ́wọ́? (b) Kí ni iṣẹ́ ìyanu tí Èlíṣà ṣe fi hàn nípa Jèhófà?

7 Wòlíì Èlíṣà tí Èlíjà gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ ló ṣe àjíǹde kejì tí Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kàn. Obìnrin ará Ṣúnémù kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì gba Èlíṣà lálejò, ó sì tọ́jú rẹ̀ gan-an, àmọ́ obìnrin náà ò rọ́mọ bí. Gẹ́gẹ́ bí ìlérí Jèhófà nípasẹ̀ wòlíì Èlíṣà, Jèhófà mú kí obìnrin tó yàgàn yìí àti ọkọ rẹ̀ tó ti dàgbà ní ọmọkùnrin kan. Lọ́dún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, ọmọ náà kú. Ẹ wo bí inú  ìyá ọmọ yẹn ṣe máa bà jẹ́ tó. Ó tọrọ àyè lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀, ó sì rìnrìn-àjò nǹkan tó tó máìlì mọ́kàndínlógún [19] (tàbí 30 km) lọ bá Èlíṣà lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì. Wòlíì Èlíṣà kọ́kọ́ rán Géhásì ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí Ṣúnémù kó lè jí ọmọ náà dìde, àmọ́ Géhásì ò rí i ṣe. Ẹ̀yìn ìyẹn ni màmá ọmọ náà àti Èlíṣà wá dé.​—⁠2 Ọba 4:​8-31.

8 Nígbà tí wọ́n dẹ́bẹ̀, Èlíṣà dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú ọmọ náà, ó sì gbàdúrà. Jèhófà jí ọmọ náà dìde, ìyẹn sì múnú màmá rẹ̀ dùn gan-an. (Ka 2 Àwọn Ọba 4:​32-37.) Ó ṣeé ṣe kí obìnrin yìí rántí àdúrà tí Hánà gbà. Hánà ò rọ́mọ bí tẹ́lẹ̀, àmọ́ nígbà tó bí Sámúẹ́lì, ó sọ pé: ‘Jèhófà jẹ́ olùmúni sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù, Ó sì ń múni gòkè wá.’ (1 Sám. 2:⁠6) Ọlọ́run jí ọmọdékùnrin tó wà ní Ṣúnémù dìde, èyí sì fi hàn pé ó lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde.

9. Ṣàlàyé bí àjíǹde kẹta tí Bíbélì mẹ́nu kàn ṣe wáyé.

9 Nǹkan àgbàyanu míì tún ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú Èlíṣà. Àádọ́ta [50] ọdún ni Èlíṣà fi ṣiṣẹ́ wòlíì, àmọ́ nígbà tó yá, ó ṣàìsàn, ó sì kú. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ lọ sin òkú ọkùnrin kan, àmọ́ bí wọ́n ṣe rí i pé àwọn ọlọ́ṣà ń bọ̀ wá bá àwọn, wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Èlíṣà, wọ́n sì sá lọ káwọn ọ̀tá yìí má bàa rí wọn mú. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, òkú Èlíṣà ti jẹrà ku egungun nìkan. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ọkùnrin náà fara kan egungun Èlíṣà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó wá sí ìyè, ó sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.” (2 Ọba 13:​14, 20, 21) Àwọn àkọsílẹ̀ yìí mú kó dá Màtá lójú pé Ọlọ́run lè jí àwọn tó ti kú dìde. Ó sì yẹ kí wọ́n mú kó dá ìwọ náà lójú pé agbára Ọlọ́run kàmàmà, kò sì ní ààlà.

ÀWỌN OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KÌÍNÍ

10. Kí ni Pétérù ṣe fún Dọ́káàsì nígbà tó kú?

10 Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, a rí i pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan jí òkú dìde. A ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí Jésù jí dìde nítòsí ìlú Náínì àti nílé Jáírù. Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pétérù náà jí Dọ́káàsì tá a tún mọ̀ sí Tàbítà dìde. Pétérù wá síbi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí, ó sún mọ́ òkú náà, ó sì gbàdúrà. Ó wá sọ pé: “Tàbítà, dìde!” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló dìde, Pétérù sì “fà á lé wọn lọ́wọ́ láàyè,” ìyẹn àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀. Àjíǹde yẹn ya àwọn tó wà níbẹ̀ lẹ́nu gan-an débi pé ‘ọ̀pọ̀ ènìyàn di onígbàgbọ́ nínú Olúwa.’ Ó dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí á jẹ́rìí nípa Jésù, wọ́n á sì sọ fáwọn míì pé Jèhófà lè jí òkú dìde.​—⁠Ìṣe 9:​36-42.

11. Kí ni Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn sọ pé ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe rí lára àwọn tọ́rọ̀ ṣojú wọn?

11 Àjíǹde míì tún wáyé níṣojú àwọn èèyàn. Ìgbà kan wà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ará nínú yàrá òkè kan nílùú Tíróásì, tó jẹ́ apá kan orílẹ̀-èdè Tọ́kì báyìí. Pọ́ọ̀lù bá wọn sọ̀rọ̀ títí di òru. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ wíńdò, ó ń gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ. Àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í tòògbé, ló bá ré bọ́ látorí àjà kẹta ilé náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Lúùkù oníṣègùn ló kọ́kọ́ dé ọ̀dọ̀ Yútíkọ́sì kó lè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Lẹ́yìn tí Lúùkù sì ti yẹ̀ ẹ́ wò, ó rí i pé kì í ṣe pé Yútíkọ́sì ṣèṣe tàbí pé ó dákú, ṣe ló kú fin-ín-fin-ín, ìyẹn sì ba àwọn ará nínú jẹ́ gan-an. Pọ́ọ̀lù sọ̀ kalẹ̀, ó gbé òkú náà mọ́ra, ó wá sọ pé: Ó ti jíǹde o! Ẹ ò rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn máa wú àwọn tó wà níbẹ̀ lórí gan-an! Bí wọ́n ṣe mọ̀ pé ọmọkùnrin náà ti kú  tẹ́lẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù sì jí i dìde mú kí wọ́n ní ìtùnú “lọ́nà tí kò ṣeé díwọ̀n.”​—⁠Ìṣe 20:​7-12.

ÌRÈTÍ TÓ DÁJÚ

12, 13. Tá a bá ronú nípa àwọn àjíǹde tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká wá ìdáhùn sí?

12 Bíi ti Màtá, ó yẹ kó dá ìwọ náà lójú pé Ọlọ́run àti Olùfúnni-ní-Ìyè wa lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bí Èlíjà, Jésù àti Pétérù wà níbẹ̀ nígbà tí àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn wáyé, wọ́n sì wáyé lásìkò tí Jèhófà ń lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ìyanu. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó kú lẹ́yìn àsìkò yẹn? Bó ṣe jẹ́ pé kò sí àkọsílẹ̀ pé Ọlọ́run jí àwọn èèyàn dìde lẹ́yìn ìgbà yẹn, ṣé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí lè retí pé Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde lọ́jọ́ iwájú? Ṣé wọ́n lè fi ìdánilójú sọ ohun tí Màtá sọ pé: “Mo mọ̀ pé [àbúrò mi] yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn”? Kí ló fún Màtá nírú ìdánilójú bẹ́ẹ̀, kí lá sì mú kó dá ìwọ náà lójú pé àjíǹde máa wáyé?

13 Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan wà tó jẹ́ ká mọ̀ pé ó dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lójú pé àjíǹde máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn.

14. Kí ni ohun tí Bíbélì sọ nípa Ábúráhámù kọ́ wa nípa àjíǹde?

14 Ẹ ronú nípa ohun tí Ọlọ́run ní kí Ábúráhámù ṣe fún Ísákì, ìyẹn ọmọ kan ṣoṣo tó fi ọjọ́ ogbó bí tó sì ti ń wá tipẹ́. Jèhófà sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, mú ọmọkùnrin rẹ, ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi, Ísákì, . . . kí o sì fi í rúbọ . . . gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun.” (Jẹ́n. 22:⁠2) Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe máa rí lára Ábúráhámù. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà ti ṣèlérí pé nípasẹ̀ ọmọ Ábúráhámù ni gbogbo orílẹ̀-èdè máa bù kún ara wọn. (Jẹ́n. 13:​14-16; 18:18; Róòmù 4:​17, 18) Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jèhófà tún sọ pé irú-ọmọ náà máa wá “nípasẹ̀ Ísákì.” (Jẹ́n. 21:12) Àmọ́ báwo ni gbogbo ìyẹn ṣe máa ṣeé ṣe tí Ábúráhámù bá fi Ísákì rúbọ? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Ábúráhámù gbà pé Ọlọ́run lè jí Ísákì dìde. (Ka Hébérù 11:​17-19.) Bíbélì ò sọ pé Ábúráhámù gbà pé láàárín wákàtí mélòó kan tàbí láàárín ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ Ísákì máa jíǹde. Ábúráhámù ò mọ ìgbà tí ọmọ òun máa jíǹde, àmọ́ ó gbà gbọ́ pé Jèhófà máa jí Ísákì dìde.

15. Ìrètí wo ni Jóòbù ní?

15 Jóòbù náà gbà pé àjíǹde máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. Ó mọ̀ pé tí wọ́n bá gé igi  kan lulẹ̀, ó lè tún pa dà hù. Àmọ́ kì í ṣe bọ́rọ̀ èèyàn ṣe rí nìyẹn. (Jóòbù 14:​7-12; 19:​25-27) Téèyàn bá kú, kò lè jí ara rẹ̀ dìde kó sì máa wà láàyè nìṣó. (2 Sám. 12:23; Sm. 89:48) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ò lè jí ẹni tó kú dìde o. Kódà, Jóòbù gbà pé Jèhófà ti ní àsìkò kan lọ́kàn tó máa rántí òun nínú ibojì. (Ka Jóòbù 14:​13-15.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ò mọ ìgbà tí ìyẹn máa jẹ́, síbẹ̀, ó gbà pé Ẹni tó dá àwa èèyàn lágbára láti jí òun dìde, á sì ṣe bẹ́ẹ̀.

16. Ọ̀rọ̀ ìṣírí wo ni áńgẹ́lì kan sọ fún wòlíì Dáníẹ́lì?

16 Ọkùnrin olóòótọ́ míì tá a tún sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni Dáníẹ́lì. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi sin Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà kan, áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ fún Dáníẹ́lì pé ó jẹ́ “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi,” ó sì ní kó “ní àlàáfíà” kó sì “jẹ́ alágbára.”​—⁠Dán. 9:​22, 23; 10:​11, 18, 19.

17, 18. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún Dáníẹ́lì?

17 Dáníẹ́lì ti darúgbó, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó máa ronú ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sóun lọ́jọ́ iwájú. Ṣé Dáníẹ́lì máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú? Bẹ́ẹ̀ ni! Ní ẹsẹ tó kẹ́yìn nínú ìwé Dáníẹ́lì, áńgẹ́lì yẹn sọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún Dáníẹ́lì lọ́jọ́ iwájú, ó ní: “Ní ti ìwọ fúnra rẹ, máa lọ síhà òpin; ìwọ yóò sì sinmi.” (Dán. 12:13) Dáníẹ́lì tó ti darúgbó mọ̀ pé àwọn tó ti kú ń sinmi ni, wọn ò sì ní “ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù.” Ibi tí Dáníẹ́lì náà sì máa tó lọ nìyẹn. (Oníw. 9:10) Àmọ́, kò ní wà níbẹ̀ títí lọ gbére. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa jí i dìde.

18 Áńgẹ́lì náà tún sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” Áńgẹ́lì yẹn ò sọ ọjọ́ tàbí àsìkò tí ìyẹn máa ṣẹlẹ̀. Dáníẹ́lì máa kú, ó sì máa sinmi. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ tó sọ fún un pé ‘ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ’ túmọ̀ sí pé ó máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú, bó bá tiẹ̀ kú tó sì lo ọ̀pọ̀ ọjọ́ nínú sàréè. Ìyẹn sì máa jẹ́ “ní òpin àwọn ọjọ́.” Bíbélì Jerusalem Bible sọ pé: “Ìwọ yóò dìde, ìwọ yóò sì gba ìpín rẹ ní ìkẹyìn ọjọ́.”

Bíi ti Màtá, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àjíǹde máa wáyé (Wo ìpínrọ̀ 19 àti 20)

19, 20. (a) Báwo làwọn ohun tá a jíròrò tán yìí ṣe jọra pẹ̀lú ohun tí Màtá sọ fún Jésù? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

19 Màtá ní ọ̀pọ̀ ìdí láti gbà pé Lásárù àbúrò òun “yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Ìdánilójú tí Màtá fi dá Jésù lóhùn àti ìlérí Ọlọ́run fún Dáníẹ́lì fi àwa Kristẹni lọ́kàn balẹ̀. Kò sí àní-àní, àwọn òkú máa jíǹde.

20 Àwọn ohun tó ṣẹlẹ́ láyé àtijọ́ jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn òkú máa jíǹde. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń fojú sọ́nà fún àjíǹde ọjọ́ iwájú. Àmọ́, ǹjẹ́ ohun kan wà tó jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn òkú lè jíǹde kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀? Tó bá wà, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú bíi ti Màtá pé àjíǹde máa wáyé. Bó ti wù kó rí, ìgbà wo nìyẹn máa wáyé? Àwọn kókó yìí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.