Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  December 2017

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ àwọn tọkọtaya Kristẹni lè lo ìfètòsọ́mọbíbí kan tí wọ́n ń pè ní IUD (ìyẹn intrauterine device)? Ǹjẹ́ ó bá ìlànà Ìwé Mímọ́ Mu?

Tọkọtaya Kristẹni tó bá fẹ́ lo irú ìfètòsọ́mọbíbí yìí gbọ́dọ̀ gbé àwọn ẹ̀rí tó wà nípa rẹ̀ wò dáadáa, kí wọ́n sì tún ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Bíbélì tó bá a mu. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n ṣèpinnu táá jẹ́ kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ níwájú Jèhófà.

ígbà tí Ádámù àti Éfà nìkan wà láyé àti ìgbà tó jẹ́ pé ẹni mẹ́jọ péré ló wà láyé, ìyẹn lẹ́yìn Ìkún Omi, Jèhófà pàṣẹ pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀.” (Jẹ́n. 1:28; 9:1) Bíbélì ò sọ pé Ọlọ́run pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fáwa Kristẹni. Torí náà, tọkọtaya kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá àwọn máa fètò sí iye ọmọ táwọn máa bí àti ìgbà tí wọ́n máa fẹ́ bímọ. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí wọ́n gbé yẹ̀ wò?

Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìfètòsọ́mọbíbí èyíkéyìí tá a bá yàn. Fún ìdí yìí, a kì í ṣẹ́ oyún torí pé a fẹ́ fètò sọ́mọ bíbí. Ẹni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́yún ti ṣe ohun tó lòdì sí Ìwé Mímọ́. Torí náà, àwa Kristẹni kì í ṣe ohunkóhun tó máa dá ẹ̀mí ọmọ tó ń dàgbà bọ̀ légbodò. (Ẹ́kís. 20:13; 21:​22, 23; Sm. 139:16; Jer. 1:5) Àmọ́, kí la lè sọ nípa ìfètòsọ́mọbíbí tí wọ́n ń pè ní IUD?

A ti jíròrò kókó yìí rí nínú Ile-Iṣọ Na November 15, 1979 ojú ìwé 30 àti 31. Lásìkò tá a gbé àpilẹ̀kọ yẹn jáde, tí obìnrin kan bá fẹ́ lo ìfètòsọ́mọbíbí IUD, ṣe ni wọ́n máa ń ki ike kan sínú ilé ọmọ rẹ̀ kó má bàa lóyún. Àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ bí IUD ṣe ń ṣiṣẹ́ gan-an nígbà yẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló sọ pé ike yẹn kì í jẹ́ kí àtọ̀ ọkùnrin dé ibi tí ẹyin obìnrin wà kó má bàa di oyún. Ó sì ṣe kedere pé tí àtọ̀ ọkùnrin kò bá dà pọ̀ mọ́ ẹyin obìnrin, kò lè doyún.

 Síbẹ̀, ẹ̀rí wà pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àtọ̀ ọkùnrin máa ń dà pọ̀ mọ́ ẹyin obìnrin táá sì di ọlẹ̀. Bí ìyẹn bá sì ti ṣẹlẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ọlẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà nínú okùn ilé ọmọ, táwọn olóyìnbó ń pè ní Fallopian tube. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kó lọ sílé ọmọ kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà. Ní ti ọlẹ̀ tó ń bọ̀ nínú ilé ọmọ, ó ṣeé ṣe kí ike IUD ṣèdíwọ́, tí ọlẹ̀ náà kò sì ní lè dàgbà bó ṣe yẹ. Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, bí ìgbà téèyàn ṣẹ́yún ni. Àpilẹ̀kọ náà wá sọ pé: “Torí náà, tí Kristẹni kan bá ń ronú pé kóun lo ìfètòsọ́mọbíbí IUD, ó ṣe pàtàkì kó ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ìsọfúnni yìí àti ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀mí èèyàn.”​—Sm. 36:9.

Ǹjẹ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn dókítà ti ṣe àwọn àtúnṣe kan sí ọ̀nà tí IUD gbà ń ṣiṣẹ́ lẹ́yìn tá a gbé àpilẹ̀kọ yẹn jáde lọ́dún 1979?

Oríṣi IUD méjì ló ti wà báyìí. Ọ̀kan máa ń lo kọ́pà (Copper T), àtọdún 1988 ni wọ́n ti ń lò ó lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Èkejì máa ń tú èròjà hormone sínú ara, àtọdún 2001 ni wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó. Àlàyé wo làwọn oníṣègùn ṣe nípa IUD méjèèjì yìí?

Kọ́pà: Bá a ṣe ṣàlàyé, IUD máa ń jẹ́ kó nira fún àtọ̀ ọkùnrin láti lọ dà pọ̀ mọ́ ẹyin obìnrin. Yàtọ̀ síyẹn, ṣe ni IUD oníkọ́pà dà bí oògùn apakòkòrò ní ti pé ó máa ń pa àtọ̀ tó fẹ́ lọ bá ẹyin. * Bákan náà, IUD oníkọ́pà kì í jẹ́ kí ilé ọmọ rí ara gba ọlẹ̀ sí, nípa bẹ́ẹ̀ ọlẹ̀ náà kò ní lè dàgbà di ọmọ.

Èròjà hormone: Onírúurú IUD tó ní èròjà hormone ló wà, iṣẹ́ wọn sì jọra pẹ̀lú àwọn oògùn tí kì í jẹ́ kí obìnrin lóyún. Àwọn IUD yìí máa ń tú hormone sínú ilé ọmọ, iṣẹ́ rẹ̀ sì jọ ti IUD oníkọ́pà. Àmọ́ láfikún sí i, ó tún máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ míì. Ó jọ pé irú IUD yìí kì í jẹ́ káwọn obìnrin kan pèsè ẹyin ọmọ rárá. Ó ṣe tán, bí kò bá sí ẹyin, kò sóhun tí àtọ̀ ọkùnrin máa sọ di ọlẹ̀. Yàtọ̀ sí pé kì í jẹ́ kí obìnrin lè pèsè ẹyin, IUD tó ní hormone kì í jẹ́ kí ilé ọmọ rí ara gba ọlẹ̀ sí. * Bákan náà, ó máa ń jẹ́ kí omi ara inú obìnrin ki, débi pé kò ní rọrùn fún àtọ̀ láti gba ojú ara obìnrin lọ sílé ọmọ.

Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn IUD méjèèjì kì í jẹ́ kí ilé ọmọ rí ara gba ọlẹ̀ sí. Àmọ́, tí ilé ẹyin bá pèsè ẹyin tí àtọ̀ pàdé rẹ̀ tó sì wá di ọlẹ̀ ńkọ́? Ọlẹ̀ náà lè wá sínú ilé ọmọ àmọ́ kó má ríbi dúró torí iṣẹ́ tí IUD ti ṣe síbẹ̀, ìyẹn sì máa fòpin sí oyún náà láìtọ́jọ́. Ká sòótọ́, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kì í sábà ṣẹlẹ̀, àmọ́ ó lè ṣẹlẹ̀. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú àwọn tó ń lo oògùn tí kì í jẹ́ kí obìnrin lóyún.

Torí náà, kò sẹ́ni tó lè fi ìdánilójú sọ pé tí obìnrin kan bá ń lo èyíkéyìí lára àwọn oríṣi IUD méjèèjì yìí, àtọ̀ kò lè dà pọ̀ mọ́ ẹyin rẹ̀ kó sì di ọlẹ̀. Àmọ́, ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe fi hàn pé eku káká ni obìnrin fi máa lóyún tó bá ń lo IUD torí iṣẹ́ tí IUD ń ṣe lára obìnrin.

Tọkọtaya Kristẹni kan tó ń ronú àtilo ìfètòsọ́mọbíbí IUD lè jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú dókítà tó mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa. Á dáa kí wọ́n béèrè nípa irú IUD tó wà ní àgbègbè wọn kí wọ́n sì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn àǹfààní tí wọ́n máa rí àtàwọn ewu tó wà níbẹ̀. Wọn ò gbọ́dọ̀ retí pé kí ẹnikẹ́ni ṣe ìpinnu fún wọn, kódà bí onítọ̀hún bá tiẹ̀ jẹ́ dókítà. (Róòmù 14:12; Gál. 6:​4, 5) Ìpinnu ara ẹni ni. Ó yẹ kí tọkọtaya ṣe ìpinnu tó máa múnú Ọlọ́run dùn, táá sì jẹ́ kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ níwájú Ọlọ́run.​—Fi wé 1 Tímótì 1:​18, 19; 2 Tímótì 1:3.

^ ìpínrọ̀ 4 Ìwé kan tí àjọ National Health Service lórílẹ̀-èdè England gbé jáde sọ pé: “IUD oníkọ́pà gbẹ́ṣẹ́ gan-an, tipátipá la fi ń rí àwọn tí kò ṣiṣẹ́ fún. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé nínú ọgọ́rùn-ún [100] obìnrin tó ń lo IUD, tipátipá ni wọ́n fi máa ń rí obìnrin kan tó lóyún láàárín ọdún kan. Bí kọ́pà inú IUD náà bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa gbéṣẹ́ tó.”

^ ìpínrọ̀ 5 Torí pé àwọn IUD tó ní hormone kì í jẹ́ kí ilé ọmọ rí ara gba nǹkan sí, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn oníṣègùn máa ń fún àwọn obìnrin tí nǹkan oṣù wọn máa ń ya ní IUD yìí kó lè dín bí nǹkan oṣù náà ṣe ń ya kù.