Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  December 2017

Ẹ̀yin Òbí​—Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè “Di Ọlọ́gbọ́n fún Ìgbàlà”

Ẹ̀yin Òbí​—Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè “Di Ọlọ́gbọ́n fún Ìgbàlà”

“Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.”​2 TÍM. 3:15.

ORIN: 141, 134

1, 2. Kí nìdí táwọn òbí kan fi máa ń bẹ̀rù nígbà táwọn ọmọ wọn bá fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́ kí wọ́n sì ṣèrìbọmi?

ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ń ṣèrìbọmi. Ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ ọ̀dọ́ tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú òtítọ́, tí wọ́n sì yàn láti sin Jèhófà. (Sm. 1:​1-3) Tó o bá jẹ́ òbí, kò sí àní-àní pé wàá máa wọ̀nà fún ọjọ́ táwọn ọmọ rẹ máa ṣèrìbọmi.​—Fi wé 3 Jòhánù 4.

2 Síbẹ̀, ẹ̀rù lè máa bà ẹ́. Ó ṣeé ṣe kó o ti rí àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ṣèrìbọmi àmọ́ tí wọ́n ń ronú pé àwọn ò rídìí tó fi yẹ káwọn máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Kódà, àwọn kan tiẹ̀ ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Torí náà, ẹ̀rù lè máa bà ẹ́ pé bóyá ìfẹ́ tí ọmọ rẹ ní níbẹ̀rẹ̀ lè di tútù lẹ́yìn tó bá ṣèrìbọmi. Ọ̀rọ̀ ọmọ náà lè wá dà bíi tàwọn ará ìjọ Éfésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí Jésù sọ nípa wọn pé: “Ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.” (Ìṣí. 2:4) Kí lo lè ṣe tí irú ẹ̀ ò fi ní ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ, tí wàá sì ràn án lọ́wọ́ kó lè “dàgbà dé  ìgbàlà”? (1 Pét. 2:2) Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Tímótì yẹ̀ wò.

“ÌWỌ TI MỌ ÌWÉ MÍMỌ́”

3. (a) Báwo ni Tímótì ṣe di Kristẹni, báwo ló sì ṣe fi ohun tó kọ́ sílò? (b) Kí lohun mẹ́ta tí Pọ́ọ̀lù sọ pé Tímótì ṣe?

3 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ṣèbẹ̀wò àkọ́kọ́ sí Lísírà lọ́dún 47 Sànmánì Kristẹni, ni Tímótì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Kristi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tímótì lè má tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà yẹn, síbẹ̀ ó fi ohun tó kọ́ sílò. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ó dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ọdún mẹ́rìndínlógún [16] lẹ́yìn ìgbà yẹn, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì, ó sọ pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́, ní mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn àti pé láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́ [ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù], èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (2 Tím. 3:​14, 15) Kíyè sí ohun mẹ́ta tí Pọ́ọ̀lù sọ pé Tímótì ṣe (1) ó mọ ìwé mímọ́, (2) a yí i lérò pa dà láti gba àwọn ohun tó kọ́ gbọ́, àti (3) ó di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tó ní nínú Kristi Jésù.

4. Àwọn ìtẹ̀jáde wo ló ti mú kó rọrùn fún ẹ láti gbin ẹ̀kọ́ òtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ rẹ kéékèèké? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

4 Ó dájú pé ẹ̀yin òbí fẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ ìwé mímọ́, tá a wá mọ̀ lónìí sí Bíbélì lódindi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé báwọn ọmọ ṣe máa ń tètè lóye nǹkan yàtọ̀ síra, ó ṣe kedere pé àwọn ọmọ kéékèèké lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn èèyàn àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Ètò Jèhófà sì ti pèsè onírúurú ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn fídíò tẹ́yin òbí lè lò láti kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Èwo lára àwọn ìtẹ̀jáde yìí ló wà lédè rẹ? Máa rántí pé báwọn ọmọ rẹ bá lóye Ìwé Mímọ́, ìpìlẹ̀ wọn á lágbára, wọ́n á sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà bí wọ́n ṣe ń dàgbà.

‘YÍ LÉRÒ PA DÀ LÁTI GBÀ GBỌ́’

5. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé a yí ẹnì kan lérò pa dà “láti gbà gbọ́”? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé wọ́n yí Tímótì lérò pa dà láti gba ìhìn rere nípa Jésù gbọ́?

5 Ó ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọ lóye Ìwé Mímọ́. Àmọ́, tẹ́ ẹ bá máa gbin òtítọ́ sọ́kàn wọn, ohun tẹ́ ẹ máa kọ́ wọn kọjá ìtàn nípa àwọn èèyàn àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Pọ́ọ̀lù sọ pé a yí Tímótì “lérò padà láti gbà gbọ́.” Èdè Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò fún gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí pé “kí ohun kan dáni lójú kéèyàn sì gbà gbọ́ pé òótọ́ ni.” Àtikékeré ni Tímótì ti mọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó rí àwọn ẹ̀rí tó jẹ́ kó dá a lójú pé Jésù ni Mèsáyà. Lédè míì, àwọn ẹ̀rí yẹn ló jẹ́ káwọn nǹkan tó kọ́ dá a lójú. Kò sí àní-àní, ẹ̀kọ́ tí Tímótì kọ́ dá a lójú débi pé ó ṣèrìbọmi, ó sì dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì.

6. Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè dẹni tá a yí lérò pa dà?

6 Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ kí wọ́n sì dẹni tá a yí lérò pa dà, bíi ti Tímótì? Lákọ̀ọ́kọ́, o gbọ́dọ̀ mú sùúrù. Èèyàn ò lè di Kristẹni ní ọ̀sán kan òru kan, bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́ kì í ṣe ogún ìdílé tó o lè fún àwọn ọmọ rẹ. Ọmọ kọ̀ọ̀kan ló máa lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ̀ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè dá a lójú kó sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (Ka Róòmù 12:1.) Bó ti wù kó rí, iṣẹ́ ńlá lẹ̀yin òbí máa ṣe kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, pàápàá nígbà táwọn ọmọ yín bá ń bi yín láwọn ìbéèrè. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò.

7, 8. (a) Báwo ni bàbá kan ṣe fi sùúrù ran ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ láti lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́? (b) Àwọn ìgbà wo ló ti gba pé kíwọ náà mú sùúrù fáwọn ọmọ rẹ?

7 Arákùnrin Thomas, tó ní ọmọbìnrin  ọlọ́dún mọ́kànlá [11] sọ pé: “Ọmọ mi máa ń béèrè àwọn ìbéèrè bíi, ‘Ṣé kì í ṣe ẹfolúṣọ̀n ni Jèhófà fi dá àwọn nǹkan tó wà láyé?’ tàbí, ‘Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí kì í fi dá sọ́rọ̀ òṣèlú tá ò sì kì í dìbò?’ Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń kóra mi níjàánu kí n má bàa fún un lésì tí kò ní jẹ́ kó ronú jinlẹ̀. Ó ṣe tán, kì í ṣe ọ̀rọ̀ gbankọgbì kan ló máa ń jẹ́ kọ́rọ̀ dáni lójú, àwọn ẹ̀rí tó múná dóko téèyàn fara balẹ̀ ṣàlàyé ló ń mú kọ́rọ̀ dáni lójú.”

8 Arákùnrin Thomas mọ̀ pé ó gba sùúrù kéèyàn tó lè kọ́mọ lẹ́kọ̀ọ́. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, gbogbo Kristẹni ló gbọ́dọ̀ máa mú sùúrù. (Kól. 3:12) Arákùnrin yẹn mọ̀ pé kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan lèèyàn ń bọ́ ọmọ tó rù yó, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò. Torí náà, ó máa ń bá ọmọ náà fèrò wérò nínú Ìwé Mímọ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè dá a lójú. Arákùnrin Thomas sọ pé: “Tó bá kan àwọn kókó tó ṣe pàtàkì gan-an, èmi àtìyàwó mi máa ń fẹ́ kọ́mọ wa sọ èrò rẹ̀ nípa ohun tá à ń kọ́ ọ, ká lè mọ̀ bóyá ẹ̀kọ́ náà yé e tàbí kò yé e. Inú wa máa ń dùn tó bá bi wá ní ìbéèrè. Kí n sòótọ́, ọkàn mi kì í balẹ̀ tó bá sọ pé òun ò ní ìbéèrè kankan nípa ohun tá a kọ́ ọ.”

9. Báwo lo ṣe lè mú kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ wọ àwọn ọmọ rẹ lọ́kàn?

9 Táwọn òbí bá ń fi sùúrù kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, á ṣeé ṣe fáwọn ọmọ wọn láti lóye “ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́. (Éfé. 3:18) Ẹ máa lo àwọn ìtẹ̀jáde tó bá ọjọ́ orí wọn mu, tí wọ́n á sì tètè lóye. Bí ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣe túbọ̀ ń dá wọn lójú, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ rọrùn fún wọn láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì títí kan àwọn ọmọléèwé wọn. (1 Pét. 3:15) Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn ọmọ rẹ lè ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú? Ǹjẹ́ àlàyé tí Bíbélì ṣe dá àwọn ọmọ rẹ lójú? * Ó ṣe kedere pé kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó lè wọ àwọn ọmọ rẹ lọ́kàn, wàá ní láti mú sùúrù. Àmọ́, gbogbo ìsapá rẹ láti mú kí wọ́n lóye òtítọ́ tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.​—Diu. 6:​6, 7.

10. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o jẹ́ káwọn ọmọ rẹ mọ̀?

10 Àpẹẹrẹ ẹ̀yin òbí tún ṣe pàtàkì tẹ́ ẹ bá fẹ́ káwọn ọmọ yín nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Arábìnrin Stephanie, tó ní ọmọbìnrin mẹ́ta sọ pé: “Àtìgbà táwọn ọmọ mi ti wà ní kékeré ni mo ti máa ń bi ara mi pé, ‘Ṣé mo máa ń jẹ́ káwọn ọmọ mi mọ ìdí tí mo fi gbà pé Jèhófà wà lóòótọ́, pé ó nífẹ̀ẹ́ wa àti pé àwọn ìlànà rẹ̀ bọ́gbọ́n mu? Ṣé mò ń jẹ́ kó ṣe kedere sáwọn ọmọ mi pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́?’ Mi ò lè retí pé kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wọn tí kò bá jinlẹ̀ lọ́kàn tèmi alára.”

“DI ỌLỌ́GBỌ́N FÚN ÌGBÀLÀ”

11, 12. Kí ni ọgbọ́n, kí sì nìdí tá a fi sọ pé kì í ṣe ọjọ́ orí la fi ń mọ ẹni tó gbọ́n?

11 Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, a ti rí i pé Tímótì lóye Ìwé Mímọ́, àti pé ohun tó gbà gbọ́ dá a lójú. Àmọ́ kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ìwé mímọ́ lè mú kí Tímótì “di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà”?

12 Ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ kejì ṣàlàyé pé nínú Bíbélì ọgbọ́n túmọ̀ sí “kéèyàn lo ìmọ̀ àti òye láti yanjú ìṣòro, láti dènà ewu tàbí yẹra fún un, láti lé àfojúsùn ẹni bá tàbí láti fúnni ní ìmọ̀ràn kí onítọ̀hún lè fọgbọ́n hùwà. Ọgbọ́n ni òdìkejì ìwà òmùgọ̀.” Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.” (Òwe 22:15) Ó ṣe kedere nígbà náà pé ọgbọ́n  tí ẹnì kan ní la fi ń mọ̀ pé ó dàgbà nípa tẹ̀mí. Kì í ṣe ọjọ́ orí la fi ń mọ̀ pé ẹnì kan dàgbà nípa tẹ̀mí, kàkà bẹ́ẹ̀ bí onítọ̀hún ṣe ń bẹ̀rù Jèhófà tó sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò ló ń fi hàn bẹ́ẹ̀.​—Ka Sáàmù 111:10.

13. Báwo lọmọ kan ṣe lè fi hàn pé òun ní ọgbọ́n fún ìgbàlà?

13 Àwọn ọmọ tó dàgbà nípa tẹ̀mí dé ìwọ̀n tí ọjọ́ orí wọn mọ kì í jẹ́ kí àwọn ojúgbà wọn tàbí ìfẹ́ ọkàn tiwọn máa “bì [wọ́n] kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún.” (Éfé. 4:14) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń tẹ̀ síwájú bí wọ́n ṣe ń lo “agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Héb. 5:14) Wọ́n ń fi hàn pé àwọn túbọ̀ ń dàgbà nípa tẹ̀mí tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, yálà àwọn òbí wọn tàbí àwọn àgbàlagbà míì wà níbẹ̀ tàbí wọn ò sí níbẹ̀. (Fílí. 2:12) Irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tí wọ́n bá máa rí ìgbàlà. (Ka Òwe 24:14.) Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń kọ́ wọn láwọn ìlànà Bíbélì, ẹ sì jẹ́ kí wọ́n máa rí i nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe yín pé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ lẹ̀yin náà ń tẹ̀ lé.​—Róòmù 2:​21-23.

Kí nìdí tó fi yẹ kí ẹ̀yin òbí máa ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́? (Wo ìpínrọ̀ 14 sí 18)

14, 15. (a) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kí ọmọ kan tó fẹ́ ṣèrìbọmi ronú lé? (b) Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ìbùkún tí wọ́n á rí tí wọ́n bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà?

14 Tó o bá fẹ́ káwọn ọmọ rẹ nígbàgbọ́, ó kọjá kó o kàn máa sọ fún wọn pé ohun kan ló tọ́ tàbí pé ohun kan ni kò tọ́. Á dáa kó o tún mọ èrò wọn. O ò ṣe bi wọ́n láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé kó o sá fún àwọn nǹkan tí ẹran ara ń fẹ́? Kí ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìgbà gbogbo làwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣeni láǹfààní?’​—Aísá. 48:​17, 18.

15 Ohun míì wà tó tún yẹ kó o jíròrò pẹ̀lú ọmọ rẹ tó fẹ́ ṣèrìbọmi. Ṣó mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣèrìbọmi àti ojúṣe tó wé mọ́ jíjẹ́ Kristẹni? Àǹfààní wo ló máa rí tó bá ṣèrìbọmi? Àwọn ìṣòro wo ló lè jẹ yọ? Báwo làwọn àǹfààní ibẹ̀ ṣe ju àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó yọjú lọ? (Máàkù 10:​29, 30) Ó  ṣeé ṣe kó dojú kọ àwọn ipò tó máa dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò lẹ́yìn tó bá ṣèrìbọmi. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kọ́mọ rẹ ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ìbéèrè yìí dáadáa kó tó ṣèrìbọmi. Ẹ̀yin òbí, ẹ máa ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ìbùkún tí wọ́n á rí tí wọ́n bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà àtohun tó máa ń tẹ̀yìn àìgbọràn yọ. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ rọrùn fún wọn láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, wọ́n á sì ní ìdánilójú pé ìgbà gbogbo làwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣeni láǹfààní.​—Diu. 30:​19, 20.

TÍ ỌMỌ TÓ TI ṢÈRÌBỌMI BÁ Ń ṢIYÈ MÉJÌ

16. Kí ló yẹ kẹ́yin òbí ṣe tí ọmọ yín bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì lẹ́yìn tó ti ṣèrìbọmi?

16 Kí ló yẹ kó o ṣe tí ọmọ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì lẹ́yìn tó ti ṣèrìbọmi? Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan ayé lè bẹ̀rẹ̀ sí í wu ọmọ rẹ tó ti ṣèrìbọmi, ó sì lè máa ronú pé òun ò rídìí tó fi yẹ kóun máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. (Sm. 73:​1-3, 12, 13) Ó ṣe pàtàkì pé kẹ́yin òbí kíyè sí bẹ́ ẹ ṣe máa bójú tó irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, torí pé ọ̀nà tẹ́ ẹ bá gbà bójú tó ọ̀rọ̀ náà ló máa pinnu bóyá ọmọ yín á fọwọ́ gidi mú òtítọ́ tàbí á fi òtítọ́ sílẹ̀. Ẹ rí i pé ẹ ò gbaná jẹ tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, yálà ọmọ yín ṣì kéré tàbí ó ti dàgbà díẹ̀. Bẹ́ ẹ ṣe máa ràn án lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́ táá sì pa dà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló yẹ kó jẹ yín lógún.

17, 18. Tí ọmọ kan bá ń ṣiyè méjì, kí lẹ̀yin òbí lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́?

17 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kí ọmọ kan tó ṣèrìbọmi, ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣèlérí pé òun á nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn àti pé ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa gbawájú láyé òun. (Ka Máàkù 12:30.) Jèhófà ò fojú kékeré wo ìlérí yẹn, ẹnikẹ́ni lára wa kò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ìlérí tá a ṣe. (Oníw. 5:​4, 5) Torí náà, wá ìgbà tó wọ̀ tó o lè rán ọmọ rẹ létí àwọn kókó pàtàkì yìí, kó o sì ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Àmọ́ kó o tó ṣe bẹ́ẹ̀, ṣàyẹ̀wò àwọn ìmọ̀ràn tí ètò Ọlọ́run fún ẹ̀yin òbí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọmọ rẹ á rí bí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi ti ṣe pàtàkì tó àtàwọn ìbùkún tó wà nínú ẹ̀.

18 Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní, a gba ẹ̀yin òbí ní ìmọ̀ràn kan táá ràn yín lọ́wọ́. Ẹ̀ẹ́ rí i nínú àfikún tá a pè ní “Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè” lápá ẹ̀yìn ìwé náà. Ó sọ pé: “Má ṣe yára parí èrò sí pé ọmọ rẹ kò fẹ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó ò ń ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, nǹkan kan ló máa ń fà á.” Ó ṣeé ṣe káwọn ojúgbà rẹ̀ máa dà á láàmú láti hu àwọn ìwà kan. Ó sì lè máa ṣe é bíi pé ó dá nìkan wà tàbí pé àwọn ọ̀dọ́ míì ń tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ìjọsìn wọn ju òun lọ. Àkòrí yẹn wá fi kún un pé: “Lóòótọ́, irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí ò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o gbà gbọ́. Àmọ́ ó jẹ mọ́ àwọn nǹkan tó lè mú kó ṣòro fún ọmọ rẹ láti dúró lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ní báyìí.” Onírúurú àbá ló wà nínú àfikún yẹn tẹ́yin òbí lè lò láti ṣèrànwọ́ fáwọn ọmọ tó ti ń ṣiyè méjì.

19. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè mú káwọn ọmọ yín “di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà”?

19 Àǹfààní ńlá lẹ̀yin òbí ní, ó sì tún jẹ́ ojúṣe pàtàkì láti tọ́ àwọn ọmọ yín dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti rí i pé kì í kàn ṣe pé kẹ́ ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nìkan, ó tún ṣe pàtàkì pé kí ohun tí wọ́n ń kọ́ dá wọn lójú. Kò sí àní-àní pé tí ohun tí wọ́n kọ́ bá dá wọn lójú dáadáa, wọ́n á ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n á sì máa sìn ín tọkàntọkàn. Àdúrà wa ni pé kí Ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ìsapá ẹ̀yin òbí mú káwọn ọmọ yín “di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.”

^ ìpínrọ̀ 9 Nínú ìkànnì wa, ohun kan wà tá a pè ní Study Guides tó ń mú kó rọrùn láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé “Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? “ Àrànṣe gidi ló jẹ́ láti kọ́ tọmọdé tàgbà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó wà ní onírúurú èdè. Wàá rí i lórí Ìkànnì jw.org, lábẹ́ abala BIBLE TEACHINGS > BIBLE STUDY TOOLS.