Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) December 2017

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti January 29 sí February 25, 2018 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

“Mo Mọ̀ Pé Yóò Dìde”

Kí ló mú kó dá wa lójú pé àjíǹde máa wáyé lọ́jọ́ iwájú?

“Mo Ní Ìrètí Sọ́dọ̀ Ọlọ́run”

Kí nìdí tí àjíǹde fi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì táwa Kristẹni gbà gbọ́?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí, ìyẹn àwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì.

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, ṣé ìgbà gbogbo ni ìlà ìdílé tí Mèsáyà ti wá máa ń gba ọ̀dọ̀ àkọ́bí ọkùnrin kọjá?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ àwọn tọkọtaya Kristẹni lè lo ìfètòsọ́mọbíbí kan tí wọ́n ń pè ní IUD (ìyẹn intrauterine device)? Ǹjẹ́ ó bá ìlànà Ìwé Mímọ́ Mu?

Ẹ̀yin Òbí​—Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè “Di Ọlọ́gbọ́n fún Ìgbàlà”

Àwọn òbí kan máa ń bẹ̀rù nígbà táwọn ọmọ wọn bá fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì fẹ́ ṣèrìbọmi. Báwo ni wọ́n ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè dàgbà dé ìgbàlà?

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—“Ẹ Máa Ṣiṣẹ́ Ìgbàlà Yín Yọrí”

Ìrìbọmi kì í ṣe ohun ṣeréṣeré, àmọ́ kò yẹ kí ẹ̀yin ọ̀dọ́ bẹ̀rù tàbí fà sẹ́yìn láti ṣèrìbọmi.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Fi Àwọn Nǹkan Sílẹ̀ Kí N Lè Tẹ̀ Lé Jésù

Felix Fajardo ò ju ọmọ ọdún 16 lọ nígbà tó pinnu láti di ọmọlẹ́yìn Kristi. Kò kábàámọ̀ pé òun ń tẹ̀ lé Jésù lọ síbikíbi, bó tilẹ̀ jẹ́ ó ti lé ní 70 ọdún tó ti ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Atọ́ka Àwọn Àkòrí fún Ilé Ìṣọ́ 2017

Àwọn àkòrí tá a tò tẹ̀léra yìí máa jẹ́ kó o rí àwọn àpilẹ̀kọ tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ 2017.