Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  December 2016

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Ó dáa, wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí:

Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Jésù ń tọ́ka sí nígbà tó ń fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìmọ̀ràn tó wà nínú Mátíù 18:15-17?

Ó ń sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ táwọn tọ́rọ̀ kàn lè yanjú láàárín ara wọn. Síbẹ̀ ó tún jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì débi pé ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́ tí wọn ò bá yanjú ẹ̀. Irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè ní ẹ̀tàn tàbí èrú nínú, ó sì lè ba èèyàn lórúkọ jẹ́.w16.05, ojú ìwé 7.

Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe táá mú kó o túbọ̀ gbádùn kíka Bíbélì?

O lè ṣe àwọn nǹkan yìí: Kà á bíi pé ìwọ gan-an ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ kó o lè rí àwọn ẹ̀kọ́ tó o lè fi sílò. Bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi ohun tí mò ń kà yìí ran àwọn míì lọ́wọ́?’ Lo àwọn ohun èlò ìwádìí tí ètò Ọlọ́run ti ṣe kó o lè mọ̀ sí i nípa ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà.w16.05, ojú ìwé 24 sí 26.

Ṣó burú tí Kristẹni kan bá ń ṣọ̀fọ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó nígbàgbọ́ nínú àjíǹde?

Ti pé Kristẹni kan nígbàgbọ́ nínú àjíǹde kò ní kó má lẹ́dùn ọkàn. Ábúráhámù ṣọ̀fọ̀ nígbà tí Sárà ìyàwó rẹ̀ kú. (Jẹ́n. 23:2) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ẹ̀dùn ọkàn tí Kristẹni kan ní máa dín kù.wp16.3, ojú ìwé 4.

Ìsíkíẹ́lì orí 9 mẹ́nu kan ọkùnrin kan tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé àti ọkùnrin mẹ́fà tó ní ohun ìjà lọ́wọ́. Ta ni wọ́n ṣàpẹẹrẹ?

Wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwọn ọmọ ogun ọ̀run tó pa Jerúsálẹ́mù run, àwọn náà ló sì máa pa ayé Sátánì run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Lónìí, ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì náà dúró fún Jésù Kristi, torí pé òun ló ń sàmì sí àwọn tó máa là á já.w16.06, ojú ìwé 16 àti 17.

Àwọn nǹkan wo ló fẹ́ mú kí Bíbélì pa run, àmọ́ tí Bíbélì borí?

Lákọ̀ọ́kọ́, orí òrépèté àti awọ ni wọ́n kọ Bíbélì sí, àwọn nǹkan yìí sì máa ń tètè bà jẹ́. Ìkejì, àwọn olóṣèlú àtàwọn aṣáájú ìsìn gbìyànjú láti pa Bíbélì run. Ìkẹta ni pé àwọn kan sapá láti yí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ pa dà.wp16.4, ojú ìwé 4 sí 7.

Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn?

Mọ ohun tó o nílò gan-an, má ṣe ra àwọn ohun tí kò pọn dandan. Gbéṣirò lé bó o ṣe máa ná owó rẹ àtàwọn ohun tó o fẹ́ rà. Fún àwọn míì ní ohun tí o kò nílò mọ́ tàbí kó o tà wọ́n, san gbogbo gbèsè tó o jẹ. Dín iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ò ń ṣe kù, kó o sì ṣètò bó o ṣe máa ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.w16.07, ojú ìwé 10.

Kí ni Bíbélì sọ pé ó níye lórí ju góòlù àti fàdákà lọ?

Jóòbù 28:12, 15 fi hàn pé ọgbọ́n Ọlọ́run sàn ju góòlù àti fàdákà lọ. Bó o ṣe ń wá ọgbọ́n Ọlọ́run, sapá láti máa rẹ ara rẹ sílẹ̀, kó o sì mú kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára.w16.08 ojú ìwé 18 àti 19.

Ṣó bọ́gbọ́n mu kí arákùnrin kan dá irùngbọ̀n sí lóde òní?

Láwọn ilẹ̀ kan, kò sóhun tó burú téèyàn bá ní irùngbọ̀n tó ṣe rẹ́múrẹ́mú, ìyẹn ò sì ní káwọn èèyàn má gbọ́ ìwàásù. Síbẹ̀ àwọn arákùnrin kan nírú ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè pinnu pé àwọn ò ní dá irùngbọ̀n sí. (1 Kọ́r. 8:9) Àmọ́ láwọn ilẹ̀ míì, kò bójú mu rárá fáwọn Kristẹni láti dá irùgbọ̀n sí.w16.09, ojú ìwé 21.

Kí nìdí tá a fi gbà pé ìtàn tí Bíbélì sọ nípa ìjà Dáfídì àti Gòláyátì wáyé lóòótọ́?

Èèyàn lè ga bíi Gòláyátì lóòótọ́ torí pé íǹṣì mẹ́fà péré ni Gòláyátì fi ga ju ẹni tó ga jù láyé báyìí. Ẹni gidi sì ni Dáfídì torí pé wọ́n rí àfọ́kù òkúta kan tó ti wà látayé ìgbàanì tí wọ́n kọ “ilé Dáfídì” sí lára, Jésù náà sì sọ̀rọ̀ nípa Dáfídì. Bákan náà, wọ́n ti ṣàwárí ibi tí Bíbélì sọ pé ìjà náà ti wáyé.wp16.5, ojú ìwé 13.

Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìmọ̀, òye àti ọgbọ́n?

Ẹni tó ní ìmọ̀ lẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́, tó sì ní ọ̀pọ̀ ìsọfúnni. Ẹni tó ní òye máa ń mọ bí àwọn ọ̀rọ̀ kan ṣe so kọ́ra. Àmọ́ ẹni tó ní ọgbọ́n máa ń fi òye lo ìmọ̀ tó ní láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.w16.10, ojú ìwé 18.