Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  December 2016

 Ìtàn Ìgbésí Ayé

Mo Di “Ohun Gbogbo fún Ènìyàn Gbogbo”

Mo Di “Ohun Gbogbo fún Ènìyàn Gbogbo”

Lọ́dún 1941, bàbá mi halẹ̀ mọ́ màmá mi pé: “Tí n bá gbọ́ pẹ́nrẹ́n pó o ṣèrìbọmi, màá kúrò ńlé fún ẹ!” Màmá mi ò fi ìhàlẹ̀ yẹn pè, wọ́n ṣèrìbọmi láti fi hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Ohun tí bàbá mi sọ páwọn máa ṣe yẹn náà ni wọ́n ṣe, wọ́n fi wá sílẹ̀ lọ. Mi ò ju ọmọ ọdún mẹ́jọ lọ nígbà yẹn.

KÓ TÓ dìgbà yẹn ni mo ti fẹ́ràn kí n máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Màmá mi gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kan, mo sì máa ń gbádùn àwọn ìwé náà, ní pàtàkì àwọn àwòrán inú wọn. Bàbá mi kì í fẹ́ kí màmá mi sọ ohun tí wọ́n ń kọ́ fún mi. Àmọ́, ó máa ń wù mí láti mọ ohun tí wọ́n ń kọ́, torí náà mo máa ń da ìbéèrè bò wọ́n. Bí màmá mi ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn nígbà tí bàbá mi ò bá sí nílé. Ohun tí wọ́n kọ́ mi wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, èmi náà bá pinnu pé màá ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́wàá lọ́dún 1943, mo ṣèrìbọmi nílùú Blackpool, lórílẹ̀-èdè England.

MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN JÈHÓFÀ

Àtìgbà yẹn lèmi àti màmá mi ti jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí. Tá a bá fẹ́ wàásù fáwọn èèyàn, ẹ̀rọ giramafóònù la máa ń lò. Àwọn giramafóònù yìí tóbi, ọ̀kan lára wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó kìlógíráàmù márùn-ún. Ẹ ò rí i pé ẹrù ńlá nìyẹn fún ọmọ kékeré bíi tèmi!

Nígbà tí mo pọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá [14], mo sọ fún màmá mi pé mo fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Wọ́n  wá ní kí n kọ́kọ́ sọ fún ìránṣẹ́ àwọn ará (tá à ń pè ní alábòójútó àyíká báyìí). Arákùnrin náà gbà mí nímọ̀ràn pé kí n wáṣẹ́ kan kọ́ ná, kí n lè bójú tó ara mi tí mo bá ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Mo sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn ọdún méjì tí mo ti ń ṣiṣẹ́, mo bá alábòójútó àyíká míì sọ̀rọ̀ pé mo fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ó ní “Kí lo tún ń dúró ṣe?”

Ní April 1949, a kó kúrò nílé tá à ń gbé, a tà lára àwọn àga àti tábìlì wa, a sì fún àwọn èèyàn ní èyí tó kù. Lẹ́yìn náà a kó lọ sílùú Middleton, nítòsí ìlú Manchester, a sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin, mo sọ fún arákùnrin kan pé kó jẹ́ ká jọ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ní ká lọ sí ìjọ tuntun kan tó wà nílùú Irlam. Màmá mi àti arábìnrin kan sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wọn lọ ní ìjọ míì.

Nígbà tá a débẹ̀, ètò Ọlọ́run ní kí èmi àtìkejì mi máa darí àwọn ìpàdé ìjọ torí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sáwọn arákùnrin tó lè bójú tó ìjọ tuntun yẹn. Iṣẹ́ yìí kà mí láyà torí pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] ni mí nígbà yẹn. Ìgbà tó yá, wọ́n gbé mi lọ sí ìjọ Buxton. Àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ò pọ̀, wọ́n sì nílò ìrànwọ́ láti tẹ̀ síwájú. Mo gbà pé àwọn ìrírí yẹn máa ṣe mí láǹfààní lọ́jọ́ iwájú.

À ń kéde àsọyé ìta gbangba nílùú Rochester, ìpínlẹ̀ New York, lọ́dún 1953

Lọ́dún 1951, mo gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àmọ́ nígbà tó di December 1952, ìjọba ní kí n wá ṣiṣẹ́ ológun. Mo jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé mi ò ní lè ṣe iṣẹ́ ológun torí pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni  mí, àmọ́ ilé ẹjọ́ ò gbà pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni mí. Torí náà, wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́fà. Ibẹ̀ ni mo wà nígbà tí mo gba ìwé pé kí n máa bọ̀ ní kíláàsì kejìlélógún [22] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Torí náà, ní July 1953 lẹ́yìn tí mo kúrò lẹ́wọ̀n, mo wọkọ̀ ojú omi tí wọ́n ń pè ní Georgic, a sì forí lé ìpínlẹ̀ New York.

Nígbà tí mo débẹ̀, mo lọ sí Àpéjọ Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun tí wọ́n ṣe lọ́dún 1953. Lẹ́yìn náà ni mo wá wọkọ̀ ojú irin lọ síbi tí ilé ẹ̀kọ́ náà wà, nílùú South Lansing, ìpínlẹ̀ New York. Ṣẹ́ ẹ rántí pé kò pẹ́ tí mo kúrò lẹ́wọ̀n, torí náà mi ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Kódà, ṣe ni mo tọrọ owó lọ́wọ́ ẹnì kan tá a jọ wọkọ̀ ojú irin kí n lè fi san owó ọkọ̀ tó gbé mi dé ìlú South Lansing.

A LỌ SÌN NÍLẸ̀ ÀJÈJÌ

Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ò láfiwé torí ó jẹ́ ká lè “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo” lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. (1 Kọ́r. 9:22) Àwa mẹ́ta ni wọ́n rán lọ sórílẹ̀-èdè Philippines, èmi, Paul Bruun àti Raymond Leach. Ọ̀pọ̀ oṣù la fi dúró ká tó rí físà gbà, lẹ́yìn tá a sì gbà á tán, a wọkọ̀ ojú omi. Àwọn ibi tá a gbà kọjá ni Rotterdam, Òkun Mẹditaréníà, Suez Canal, Òkun Íńdíà, Màléṣíà àti Hong Kong. Odindi ọjọ́ mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] la lò lójú agbami! Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a dé ìlú Manila ní November 19, 1954.

Èmi àti Raymond Leach tá a jọ ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì rèé nígbà tá à ń lọ sórílẹ̀-èdè Philippines, ọjọ́ mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] la lò nínú ọkọ̀ ojú omi

A wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tá a lè ṣe kára wa lè mọlé, ká lè mojú ilẹ̀ ká sì tún kọ́ èdè wọn. Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n ní káwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó wà nílùú Quezon City tó jẹ́ pé Gẹ̀ẹ́sì lèyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn ibẹ̀ ń sọ. Ìdí nìyẹn tá ò fi gbọ́ èdè Tagalog tó bẹ́ẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lóṣù mẹ́fà tá a ti débẹ̀. Inú wa dùn pé ibi tí wọ́n gbé wa lọ lẹ́yìn náà mú ká lè sọ èdè náà dáadáa.

Lọ́jọ́ kan tá a tòde ẹ̀rí dé ní May 1955, èmi àti Arákùnrin Leach rí àwọn ìdìpọ̀ lẹ́tà tí ètò Ọlọ́run fi ránṣẹ́ sí wa. Wọ́n ní ká lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Nígbà yẹn, mi ò ju ọmọ ọdún méjìlélógún [22] lọ, àmọ́ iṣẹ́ yẹn mú kí n “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo” láwọn ọ̀nà míì tí mi ò ronú kàn.

Mò ń sọ àsọyé lédè Bicol ní àpéjọ àyíká kan

Bí àpẹẹrẹ, ìta gbangba níwájú ṣọ́ọ̀bù kan ni mo ti sọ àsọyé àkọ́kọ́ tí mo sọ nígbà tí mo di alábòójútó àyíká. Kò pẹ́ tí mo wá mọ̀ pé ohun táwọn ará lórílẹ̀-èdè Philippines kà sí àsọyé fún gbogbo èèyàn lèyí téèyàn bá sọ níta gbangba. Bí mo ṣe ń lọ láti ìjọ kan sí òmíì, mo máa ń sọ àsọyé láwọn gbàgede, nínú ọjà, níwájú àwọn gbọ̀ngàn ìlú tàbí níbi tí wọ́n ti máa ń gbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá àti láwọn ibi ìgbafẹ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń jẹ́ láwọn òpópónà. Ìgbà kan tiẹ̀ wà nílùú San Pablo City tí òjò kò jẹ́ kí n lè sọ àsọyé nínú ọjà, mo bá dábàá pé káwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú jẹ́ ká lo Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbà tí ìpàdé parí, àwọn arákùnrin náà bi mí pé ṣé a máa lè sọ pé ìpàdé fún gbogbo èèyàn la ṣe yẹn, ó ṣe tán, kì í ṣe ìta gbangba la ti ṣe é!

Ilé àwọn ará ni wọ́n máa ń fi mí wọ̀ sí. Lóòótọ́, ilé àwọn ará kì í fi bẹ́ẹ̀ tóbi, àmọ́ wọ́n máa ń wà ní mímọ́. Orí ẹní tí wọ́n tẹ́ sórí pákó ni mo sábà máa ń sùn. Ilé wọn kì í ní balùwẹ̀, torí náà mo kọ́ béèyàn ṣe ń dọ́gbọ́n wẹ̀ níta. Mo máa ń wọkọ̀ akérò tí mo bá ń lọ láti ìjọ kan sí òmíì, nígbà míì mo sì máa ń wọ bọ́ọ̀sì tàbí ọkọ̀ ojú omi tó bá jẹ́ pé erékùṣù ni mò ń bẹ̀ wò. Jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí mo fi wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn, mi ò ní mọ́tò.

Bí mo ṣe ń lọ sóde ẹ̀rí tí mo sì ń bẹ àwọn ìjọ wò ló jẹ́ kí n mọ èdè Tagalog sọ. Kò sáyè àtigba tíṣà tó máa kọ́ mi. Àmọ́, mo máa ń tẹ́tí táwọn ará bá ń wàásù lóde ẹ̀rí àti nígbà tá a bá wà nípàdé. Inú wọn máa ń dùn láti kọ́ mi lédè wọn, mo sì mọyì sùúrù wọn àti bí wọ́n ṣe máa ń tọ́ mi sọ́nà.

 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì mú kí n túbọ̀ ṣe àwọn àtúnṣe. Nígbà tí Arákùnrin Nathan Knorr wá sórílẹ̀-èdè Philippines lọ́dún 1956, a ṣe àpéjọ ńlá kan, wọ́n sì ní kí n ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì tó ń fáwọn èèyàn ní ìsọfúnni. Mi ò ṣe iṣẹ́ yẹn rí, torí náà àwọn ará yọ̀ǹda ara wọn láti ràn mí lọ́wọ́. Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, a tún ṣe àpéjọ ńlá míì, Arákùnrin Frederick Franz sì ṣèbẹ̀wò láti oríléeṣẹ́ wa. Èmi ni wọ́n yàn ṣe alábòójútó àpéjọ náà, àmọ́ mo kẹ́kọ̀ọ́ nínú bí Arákùnrin Franz ṣe mú ara rẹ̀ bá àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè náà mu. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Franz wọ aṣọ ìbílẹ̀ àwọn èèyàn Philipines nígbà tó ń sọ àsọyé. Orúkọ aṣọ yẹn ni barong Tagalog, inú àwọn ará dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí aṣọ yẹn lọ́rùn ẹ̀.

Mo tún ṣe àwọn àtúnṣe míì nígbà tí mo di alábòójútó àgbègbè. Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń fi fíìmù The Happiness of the New World Society han àwọn èèyàn níta gbangba. Kì í sábà rọrùn torí pé àwọn kòkòrò máa ń yọ wá lẹ́nu gan-an. Iná ẹ̀rọ tó ń gbé àwòrán jáde ló ń fà wọ́n mọ́ra, wọ́n á wá lẹ̀ mọ́ ẹ̀rọ náà. Tí fíìmù náà bá tán, àá wá bẹ̀rẹ̀ sí í nu àwọn kòkòrò yẹn. Kì í ṣe iṣẹ́ kékeré láti máa fi sinimá han àwọn èèyàn, àmọ́ inú wa máa ń dùn gan-an báwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń mọ̀ pé kárí ayé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà.

Àwọn àlùfáà Kátólíìkì máa ń fúngun mọ́ àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n má gbà wá láyè láti ṣe  àwọn àpéjọ wa. Nǹkan míì tí wọ́n tún máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń lu aago ṣọ́ọ̀ṣì léraléra tá a bá ń sọ àsọyé nítòsí ṣọ́ọ̀ṣì wọn ká má bàa gbádùn àsọyé náà. Síbẹ̀, gbogbo ìyẹn ò dá iṣẹ́ náà dúró, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà ládùúgbò yẹn ló sì ti di ìránṣẹ́ Jèhófà báyìí.

IṢẸ́ ÌSÌN MI YÍ PA DÀ

Lọ́dún 1959, ètò Ọlọ́run fi lẹ́tà kan ránṣẹ́ sí mi pé kí n lọ máa sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, èyí tó jẹ́ kí n túbọ̀ kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan sí i. Nígbà tó yá, wọ́n ní kí n máa ṣèbẹ̀wò sí àwọn orílẹ̀-èdè míì. Nígbà kan tí mò ń rìnrìn-àjò, mo pàdé ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Janet Dumond, míṣọ́nnárì lòun náà lórílẹ̀-èdè Thailand. Lẹ́yìn tá a ti bá ara wa sọ̀rọ̀ fúngbà díẹ̀, a ṣègbéyàwó. Ọdún kọkànléláàádọ́ta [51] rèé tá a ti ṣègbéyàwó, a sì jọ ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn Jèhófà pa pọ̀.

Èmi àti Janet rèé ní ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Philippines

Tá a bá ní ká máa kà á, mo ti lọ bẹ àwọn èèyàn Jèhófà wò ní orílẹ̀-èdè tó tó mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] báyìí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí pé ìṣẹ́ ìsìn tí mo kọ́kọ́ ṣe ló mú kí n lè bá onírúurú èèyàn ṣiṣẹ́. Àwọn ìbẹ̀wò tí mò ń ṣe yìí ti jẹ́ kí n rí i kedere pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn.Ìṣe 10:34, 35.

We make sure that we have a regular share in the ministry

A ṢÌ Ń ṢE ÀWỌN ÌYÍPADÀ TÓ YẸ

Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó láti máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará lórílẹ̀-èdè Philippines! Iye àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn ti tó ìlọ́po mẹ́wàá iye tí wọ́n jẹ́ nígbà tí mo kọ́kọ́ débẹ̀. Èmi àti Janet ṣì jọ ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Philippines nílùú Quezon City. Kódà lẹ́yìn tí mo ti sìn nílẹ̀ àjèjì fún ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún, mo ṣe tán láti ṣe àwọn ìyípadà tí Jèhófà bá ní kí n ṣe. Tá a bá sì wo bí ètò Ọlọ́run ṣe ń tẹ̀ síwájú, àá rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká múra tán láti ṣe àwọn ìyípadà tó bá yẹ ká lè máa ṣiṣẹ́ sin Jèhófà àtàwọn ará wa nìṣó.

Inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń rí i tí iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pọ̀ sí i níbẹ̀

A gbà pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ohunkóhun tí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣe ti wá, a sì ti rí i pé kò sí ohun tó tún lè fúnni láyọ̀ bíi kéèyàn máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. A tún ti ṣe àwọn ìyípadà kan kí iṣẹ́ ìsìn wa lè túbọ̀ máa gbádùn mọ́ àwọn ará. Ìpinnu wa ni pé bí Jèhófà ti ń bẹ, àá máa di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.”

A ṣì ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà nílùú Quezon City