Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́ Oníwà Tútù—Ohun Tó Bọ́gbọ́n Mu Ni

Jẹ́ Oníwà Tútù—Ohun Tó Bọ́gbọ́n Mu Ni

Obìnrin kan wà tó ń jẹ́ Toñi, iṣẹ́ tó ń ṣe ni pé kó máa tọ́jú àwọn àgbàlagbà. Lọ́jọ́ kan, ó lọ sílé màmá àgbàlagbà kan tó ń tọ́jú. Lẹ́yìn tó kan ilẹ̀kùn, obìnrin kan jáde sí i. Kí lobìnrin náà fojú kan Toñi sí, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í bú u ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá, ó ní kò tètè dé wá tọ́jú màmá òun. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kì í ṣe pé Toñi pẹ́ dé. Láìka gbogbo ohun tóbìnrin yẹn sọ, Toñi ò fèsì. Ṣe ló tún ń bẹ obìnrin náà pé kó má bínú.

LỌ́JỌ́ míì tó tún lọ sílé màmá náà, obìnrin ọjọ́sí tún láálí ẹ̀. Kí wá ni Toñi ṣe? Ó sọ pé, “Ọ̀rọ̀ yẹn ká mi lára gan-an torí pé mi ò ṣẹ̀ ẹ́, ṣe ló dà bí ẹni tó só síni lẹ́nu, tó wá buyọ̀ sí i.” Síbẹ̀, Toñi tún bẹ obìnrin náà, ó sì sọ fún un pé òun mọ̀ pé ipò tí màmá rẹ̀ wà kò dùn mọ́ ọn nínú rárá.

Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Toñi, kí lo ò bá ṣe? Ṣé wàá lè fi pẹ̀lẹ́tù sọ̀rọ̀ bí Toñi ṣe ṣe? Ṣó máa rọrùn fún ẹ láti pa á mọ́ra? Ká sòótọ́, kò rọrùn láti gba ìwọ̀sí mọ́ra. Kò sí àní-àní pé ó gba ìsapá kéèyàn tó lè hùwà tútù, pàápàá tí wọ́n bá fi ìwọ̀sí lọ̀ wá tàbí tára bá ń kan wá.

Àmọ́ Bíbélì rọ àwa Kristẹni pé ká jẹ́ oníwà tútù. Kódà, Bíbélì sọ pé ọlọ́gbọ́n lẹni tó bá níwà tútù. Bí àpẹẹrẹ, Jákọ́bù sọ pé, “Ta ni nínú yín tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye? Kí ó fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn láti inú ìwà rẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú ìwà tútù tí ó jẹ́  ti ọgbọ́n.” (Ják. 3:13) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọlọ́gbọ́n lẹni tó bá ní ìwà tútù? Báwo la ṣe lè jẹ́ oníwà tútù?

ÌDÍ TÓ FI BỌ́GBỌ́N MU KÉÈYÀN JẸ́ ONÍWÀ TÚTÙ

Ìwà tútù máa ń pẹ̀tù sí ọ̀rọ̀. “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.”Òwe 15:1.

Tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀, téèyàn sì fa ìbínú yọ, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bu epo sínú iná. (Òwe 26:21) Àmọ́ téèyàn bá dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, ṣe ló máa bomi paná ọ̀rọ̀ náà. Kódà, ó lè pẹ̀tù sọ́kàn ẹni tó ń bínú.

Bó ṣe rí lọ́rọ̀ ti Toñi gan-an nìyẹn. Nígbà tí obìnrin yẹn kíyè sí bí Toñi ṣe fèsì, ńṣe ló bú sẹ́kún. Ó sọ pé ìṣòro tóun ní àti ọ̀rọ̀ ìdílé òun ló ka òun láyà. Ìyẹn wá mú kí Toñi fara balẹ̀ wàásù fún un, obìnrin náà sì gbà pé kó máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ló jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe? Ohun tó jẹ́ kó ṣeé ṣe ni pé Toñi ṣe sùúrù kò sì fìbínú sọ̀rọ̀.

A máa láyọ̀ tá a bá jẹ́ oníwà tútù. “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.”Mát. 5:5.

Kí ló mú káwọn oníwà tútù máa láyọ̀? Ìgbésí ayé wọn nítumọ̀, wọ́n sì tún mọ̀ pé ọjọ́ ọ̀la àwọn máa dùn bí oyin. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn tó ti fìgbà kan rí jẹ́ oníjàgídíjàgan àmọ́ tí wọ́n ti wá di oníwà tútù báyìí rí i pé àwọn ń láyọ̀ gan-an. (Kól. 3:12) Arákùnrin Adolfo tó jẹ́ alábòójútó àyíká nílẹ̀ Sípéènì sọ bí ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe rí kó tó rí òtítọ́.

Ó ní: “Ìgbésí ayé mi ò lórí kò nídìí. Kì í pẹ́ rárá tí mo fi máa ń fárígá, ó burú débi pé ṣe làwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń bẹ̀rù mi tí wọ́n sì máa ń yẹra fún mi. Lọ́jọ́ kan wọ́n gún mi níbi mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ níbi tí mo ti ń jà, ẹ̀jẹ̀ wá ń dà ṣùùrùṣù lára mi, díẹ̀ ló kù kí n kú. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ló jẹ́ kí n tún inú rò.”

Ní báyìí, Arákùnrin Adolfo ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa hùwà tútù, wọ́n sì tún ń rí i nínú ìwà rẹ̀. Ìyẹn wá mú kó dẹni tó ṣeé sún mọ́, tó sì ṣeé bá sọ̀rọ̀. Ó sọ pé inú òun ń dùn pé ìgbésí ayé òun ti nítumọ̀. Ó sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó ràn án lọ́wọ́ láti di oníwà tútù.

Tá a bá jẹ́ oníwà tútù, àá múnú Jèhófà dùn. “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.”Òwe 27:11.

Ṣe ni Sátánì Èṣù ń ṣáátá Jèhófà. Bí Jèhófà bá bínú torí ìwà àìlọ́wọ̀ tí Sátánì ń hù, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé Jèhófà máa ń “lọ́ra láti bínú.” (Ẹ́kís. 34:6) Táwa náà bá ń ṣe bíi ti Jèhófà, tí a kì í tètè bínú, tá a sì jẹ́ oníwà tútù, ìwà ọgbọ́n là ń hù, àá sì múnú Jèhófà dùn gan-an.Éfé. 5:1.

Ayé táwọn èèyàn ò ti nífẹ̀ẹ́ là ń gbé. A lè pàdé àwọn tí Bíbélì pè ní ‘ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu àti òǹrorò.’ (2 Tím. 3:2, 3) Síbẹ̀, kò yẹ ká torí ìyẹn sọ ìwà tútù wa nù. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rán wa létí pé ‘ọgbọ́n tí ó wá láti òkè lẹ́mìí àlàáfíà, ó sì ń fòye báni lò.’ (Ják. 3:17) Tá a bá ń wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, tá a sì ń fòye bá wọn lò, a jẹ́ pé ọgbọ́n Ọlọ́run ló ń darí wa. Nípa bẹ́ẹ̀, a ò ní gbaná jẹ táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó lè mú wa bínú. Paríparí rẹ̀, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Orísun ọgbọ́n.